Ohun Tí Ó Yẹ Kí O Ṣọ́ra Fún
AKỌ̀RÒYÌN Lance Morrow kọ̀wé pé: “Ohun tí ó hàn gbangba jù lọ nípa ète tí ìsinmi wà fún ni ìyàtọ̀, àkókò ìdáwọ́dúró, yíyí iṣẹ́ àṣetúnṣe ojoojúmọ́ padà.” Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣàkíyèsí pé àwọn kan máa ń ní másùnmáwo tí wọ́n bá ń darí bọ̀ láti ibi ìsinmi, tí wọ́n fi ṣèlérí pé “àwọn kì yóò tún dán an wò mọ́ láé.”
Síbẹ̀, dípò gbígbàgbé nípa lílọ fún ìsinmi, yóò bọ́gbọ́n mu láti ṣàyẹ̀wò tẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀fìn tí ó lè ṣẹlẹ̀, kí a sì gbégbèésẹ̀ láti yẹra fún wọn.
Dáàbò Bo Àwọn Ohun Ìní Rẹ
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ti darí láti ìsinmi tí wọ́n sì rí i pé wọ́n ti fọ́ ilé àwọn nígbà tí àwọn kò sí nílé. Nítorí náà, kí o tó lọ fún ìsinmi, ní kí àwọn ọ̀rẹ́ tàbí aládùúgbò máa bẹ ilé rẹ wò déédéé. Wọ́n tilẹ̀ lè lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀, kí ó má baà fi bẹ́ẹ̀ hàn pé o kò sí nílé. Sọ pé kí wọ́n máa kó àwọn ìwé agbéròyìnjáde rẹ, kí wọ́n sì máa kó lẹ́tà tí ó bá wà nínú àpótí lẹ́tà rẹ lójoojúmọ́, nítorí pé kò sí ohun tí ń fi hàn pé ènìyàn kò sí nílé bí òkìtì àwọn ìwé agbéròyìnjáde tàbí àpótí lẹ́tà tí ó hàn pé ó kún fún àwọn lẹ́tà tí a kò kó kúrò.
Ó tún yẹ kí o pa àwọn ohun ìní rẹ mọ́ níbi tí o ti lọ lo ìsinmi rẹ. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n máa ń ronú pé àwọn àjèjì lọ́rọ̀, gbogbo àwọn arìnrìn àjò afẹ́ sì ni àwọn olè lè kó nífà. Nítorí náà, ohun tí ó dára láti ṣe ni pé kí o fi owó àti àwọn ìwé ṣíṣeyebíye tí ó bá wà lọ́wọ́ rẹ pamọ́ síbi ìtọ́jú-nǹkan-sí hòtẹ́ẹ̀lì náà tàbí sí ibòmíràn tí ó láàbò. Ṣọ́ra fún àwọn àjèjì, ìyẹn kò sì ní kí o di aláìnínúure.
Ọdọọdún ni Miami, Florida, U.S.A., ń gbàlejò àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn onísinmi láti ilẹ̀ òkèèrè àti láti abẹ́lé. Ní pàtàkì, àwọn ọ̀daràn máa ń ṣiṣẹ́ ní àwọn agbègbè ìgbafẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìwé ìròyìn Time sọ pé ní 1992, “ní Florida nìkan, 36,766 àlejò, tí wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè àti láti abẹ́lé, ni a ṣìkà pa, fipá bá lò pọ̀, jà lólè tàbí kó nífà lọ́nà míràn.”
Nígbà tí o bá lọ fún ìsinmi, ṣọ́ra ní pàtàkì fún àwọn jáwójáwó. Àwọn ọkùnrin gbọ́dọ̀ tọ́jú àpamọ́wọ́ wọn sí ibi tí kò ti ní hàn síta tí ó sì láàbò, irú bí àpò abẹ́nú jákẹ́ẹ̀tì tàbí àpò iwájú ṣòkòtò. Àwọn arìnrìn àjò tí wọ́n nírìírí sábà máa ń lo ọgbọ́n ní títọ́jú owó sára. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń fi owó, ìwé àṣẹ ìrìn àjò, àti òǹtẹ̀ àṣẹ ìwọ̀lú sínú àpamọ́wọ́ pẹlẹbẹ, kékeré kan tí wọ́n fi okùn rẹ̀ kọ́ ọrùn, tí wọ́n óò sì tẹ̀ ẹ́ bọ abẹ́ aṣọ wọn. Àwọn obìnrin gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí àwọn agunkẹ̀kẹ́ tàbí alálùpùpù má baà já àpò tí wọ́n gbé dání gẹngẹ mọ́ wọn lọ́wọ́.
Àwọn ọ̀daràn ń bá a lọ láti wá àwọn ọ̀nà tuntun láti kó àwọn arìnrìn àjò afẹ́ nífà. Wọ́n ti ja àwọn èrò ọkọ̀ tí ń sùn lólè lóru nínú àwọn ọkọ̀ ojú irin tí ń rin ọ̀nà jíjìn ní àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Europe. Wọ́n lè tú ohun kan tí ń kunni lóorun sáfẹ́fẹ́ nínú àwọn iyàrá ọkọ̀ láti rí i dájú pé àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ kò jí nígbà tí wọ́n bá ń tú ẹrù wọn. Ní àkókò kan, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The European ti sọ, “a ronú pé àwọn olè fẹ̀lẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ ojú irin pẹ̀lú owó àti ẹrù jíjí tí ó lé ní 845,000 dọ́là.”
Dènà Ìjàm̀bá
Aláwàdà Robert Benchley sọ pé: “Ojútùú kan ṣoṣo tí mo ní fún ìṣòro ìjàm̀bá tí ó lè di ọ̀ràn ojoojúmọ́ ni láti máa sùn látàárọ̀ dalẹ́.” Àmọ́, ó fi kún un lẹ́yìn náà pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ṣì ṣeé ṣe pé tó bá yá ìwọ yóò dìde nílẹ̀.” Ohun tí a ń wí ni pé, ìjàm̀bá ń ṣẹlẹ̀ níbi gbogbo! Nítorí náà, kò yẹ kí ẹ̀rù jíjìyà ìjàm̀bá nígbà tí o wà ní ìsinmi dáyà fò ọ́ láti takú sílé. Àmọ́, ìdí pàtàkì wà fún ṣíṣọ́ra nígbà tí o bá lọ fún ìsinmi.
Ìrìnlọrìnbọ̀ ọkọ̀ lè má ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ní àwọn àkókò ìsinmi. Sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀ tí ó gùn tó 80 kìlómítà láàárín àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ ti mọ́ àwọn ará Germany lára. Ìwé ìròyìn Times ti August 14, 1989, ròyìn pé: “Ní ilẹ̀ Europe ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìdílé bẹ̀rẹ̀ ìsinmi tí ó ti di àṣà, tí wọ́n máa ń ṣe ní August—ó sì jẹ́ àkókò tí ó kún fún jàgídíjàgan, tí ó sì ń kó àárẹ̀ báni. . . . Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo òpópónà pàtàkì-pàtàkì tí ó jáde láti Paris ni ó dí pa. . . . Láàárín July 28 sí Aug. 1, ènìyàn 102 ló kú nínú ìforígbárí ọkọ̀ lójú pópó.” Nítorí náà, fi ọgbọ́n dúró díẹ̀ láti sinmi nínú pákáǹleke tí ó ti bá iṣan níbi sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀.
Ìwé agbéròyìnjáde The European gbani nímọ̀ràn pé kí àwọn awakọ̀ máa “dá ìrìn àjò wọn dúró di ọjọ́ Sunday—tàbí kí wọ́n rìnrìn àjò ní alẹ́.” Síbẹ̀, ó gbà pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn onísinmi “ṣì rinkinkin mọ́ gbígbéra ní àkókò kan náà.” Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Ìlọ́lùpọ̀ ní ilẹ̀ Europe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó bọ́gbọ́n mu láti rìnrìn àjò nígbà tí òpópónà kò kún, má ṣe gbójú fo òtítọ́ náà pé rírìnrìn àjò ní alẹ́ léwu. Ènìyàn kì í ríran dáradára lálẹ́, nípa bẹ́ẹ̀, ṣíṣeé ṣe láti ní ìjàm̀bá lè pọ̀. Òwúrọ̀ kùtùkùtù lè jẹ́ àkókò tí ó dára jù láti rìnrìn àjò.
Lẹ́yìn tí o bá dé ibi tí o ti ń lọ lo ìsinmi rẹ, má ṣe gbójú fo àwọn ohun mìíràn tí ó lè fa ìjàm̀bá dá. Bí o kò bá tí ì ṣiṣẹ́ agbára fún àkókò gígùn láàárín ọdún, àwọn iṣan ara rẹ lè ní ìṣòro tí o bá lo ara rẹ jù láìfèrò sí i. Nítorí náà, ṣe eré ìdárayá níwọ̀nba ní àwọn ọjọ́ àkọ́kọ́, nígbà tí ara rẹ lè ṣí ṣílẹ̀ gan-an sí ìpalára.
Rí i Pé O Kò Ṣàìsàn
Gẹ́gẹ́ bí ìwé 2,000 Everyday Health Tips for Better Health and Happiness ti sọ, “ìṣòro ìlera tí ó wọ́pọ̀ jù lọ tí àwọn arìnrìn àjò máa ń ní nígbà ìrìn àjò sí ilẹ̀ òkèèrè dá lórí oúnjẹ, omi àti àwọn àrùn àkóràn díẹ̀.” Àwọn ilé iṣẹ́ aṣojú arìnrìn àjò lè fúnni nímọ̀ràn lórí bí a ṣe lè yẹra fún irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, ó sì tóyeyẹ láti tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn wọn.
Ní agbègbè púpọ̀, ó ṣe pàtàkì láti yẹra fún mímu omi ẹ̀rọ. Sì rántí pé ó lè jẹ́ irú omi bẹ́ẹ̀ ni ó di ìgàn omi dídì. Ó tún lè bọ́gbọ́n mu láti yẹra fún jíjẹ àwọn ewébẹ̀, ọbẹ̀ mayonnaise, àwọn oúnjẹ oníwàrà, ẹran tútù tàbí èyí tí kò jiná wọnú, ìṣáwùrú, àti èso tútù, àyàfi tí o bá lè bó èèpo rẹ̀ fúnra rẹ. Ní àwọn Ilẹ̀ Olóoru, ó yẹ kí o se ògidì mílíìkì kí o tó mu ún.
Oòrùn ni lájorí okùnfà ìjàm̀bá fún àwọn onísinmi tí wọn kì í wọṣọ tó bo gbogbo ara, àwọn ewu náà sì ti pọ̀ sí i lọ́nà àrà ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí nítorí ozone tí ń bà jẹ́ lójú òfuurufú. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn kókó ọlọ́yún dúdú tí ń ṣokùnfà ikú, irú àrùn jẹjẹrẹ tí ń ṣokùnfà ikú jù lọ, di ìlọ́po méjì ní United States láàárín 1980 sí 1993. Ní Australia, a ti rí àwọn ṣẹ́ẹ̀tì alápá péńpé tí ó ní ọ̀rọ̀ amóríwú náà “GBÉ E WỌ̀! FÚN ÌPARA SÁRA! DÉ E SÓRÍ!” (Gbé ṣẹ́ẹ̀tì wọ̀, fún ìpara adáàbò boni lọ́wọ́ ìtànṣán olóró sára, sì ju fìlà sórí.) Àmọ́, má ṣe jẹ́ kí a tàn ọ́ sínú èrò ààbò èké. Àwọn ìpara adáàbòboni lọ́wọ́ ìtànṣán olóró kì í ṣe ohun tí kò lábùkù.
Ìrìn àjò òfuurufú tí ń gbéni la àwọn agbègbè mélòó kan tí àkókò agogo wọn yàtọ̀ síra kọjá lè yọrí sí àárẹ̀ ọpọlọ òun ara. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ kì í ṣe àrùn, àárẹ̀ ọpọlọ òun ara lè ṣèpalára fún ìlera ara ẹnì kan, ní pàtàkì bí kì í bá ṣe ẹni tí ara rẹ̀ dá ṣáká. Ìwádìí kan tí a ṣe nípa àwọn arìnrìn àjò òfuurufú láàárín London sí San Francisco, tí ó jẹ́ fún wákàtí mẹ́jọ, fi hàn pé “mímú ara bá àyíká mu . . . béèrè fún ohun tí kò dín sí ọjọ́ méje sí mẹ́jọ.” Ìwé náà, The Body Machine, pẹ̀lú, ròyìn pé àwọn arìnrìn àjò kan tí wọ́n tètè la àwọn agbègbè mélòó kan tí àkókò agogo wọn yàtọ̀ síra kọjá ní “ìtẹ̀sí àìlèsọ̀rọ̀ síta, lílọ́ra, tí ṣíṣe àṣìṣe wọn sì lè di ìlọ́po méjì. Ìpalára bá ìpọkànpọ̀ àti agbára ìrántí pẹ̀lú.”a
Ní àfikún, ìrìn àjò òfuurufú ń mú kí ìrànkálẹ̀ àrùn láti kọ́ńtínẹ́ǹtì kan sí òmíràn láàárín wákàtí díẹ̀ túbọ̀ rọrùn. Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Germany náà, Nassauische Neue Presse, sọ pé: “Ìdààmú ti bá àwọn dókítà gan-an nípa àwọn ‘àjèjì’ àrùn bí ibà tàbí mẹ́dọ̀wú tí àwọn onísinmi ń kó bọ̀ láti Áfíríkà, Éṣíà, tàbí Gúúsù America. Lọ́dọọdún, nǹkan bí 2,000 àwọn ará Germany ń gbé ibà wálé.” Lẹ́yìn tí àjàkálẹ̀ àrùn bubonic ti fa ikú ní India ní 1994, wọ́n gbé àwọn ìgbésẹ̀ lílágbára fún ìdènà àrùn láti má ṣe jẹ́ kí ó ràn dé àwọn orílẹ̀-èdè míràn.
Àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àìlera líle koko, àti àwọn aláboyún, gbọ́dọ̀ lo ìṣọ́ra púpọ̀ tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú ìṣẹ̀lẹ̀ púpọ̀ jù lọ, kò sí ìdí dan-índan-ín pé kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ má ṣe rìnrìn àjò, ó yẹ kí wọ́n gba ìmọ̀ràn dókítà wọn ṣáájú. Ó bọ́gbọ́n mu kí gbogbo ẹni tí ó bá ń rìnrìn àjò máa ní orúkọ, àdírẹ́sì, àti nọ́ḿbà tẹlifóònù ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí kan tí a lè kàn sí bí ìjàm̀bá bá ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́.
Ẹni tí ó nílò abẹ́rẹ́ insulin déédéé láti mú kí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà déédéé gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé líla àwọn agbègbè mélòó kan kọjá yóò da ìtòlẹ́sẹẹsẹ àfìṣọ́raṣe rẹ̀ nípa oúnjẹ àti abẹ́rẹ́ gbígbà rú. Yóò ní láti ṣètò tí ó yẹ. Bákan náà, arìnrìn àjò tí ń lo ìhùmọ̀ ìmúwàdéédéé ìlùkìkì ọkàn-àyà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òún ní nọ́ḿbà tẹlifóònù onímọ̀ àrùn ọkàn-àyà lọ́wọ́.
Ní àfikún sí i, ẹnì kan tí ó bá gbára lé irú egbòogi kan yóò ní láti tọ́jú rẹ̀ sínú ẹrù ìfàlọ́wọ́ rẹ̀ nítorí ewu ńláǹlà lè ṣẹlẹ̀ bí ó bá wà nínú ẹrù tí ó sọnù tàbí tí a ṣì darí gba ibòmíràn. Wíwọ aṣọ kan ṣoṣo fún ọjọ́ mélòó kan láìpààrọ̀ rẹ̀ lè ṣàìbáradé; wíwà láìlo egbòogi tí ó pọn dandan fún ìwọ̀nba wákàtí mélòó kan lè gboni lẹ́mìí.
Kò yẹ kí a fi ojú kéré àwọn ewu rírìnrìn àjò ìsinmi. Síbẹ̀, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìdí gúnmọ́ kan tí ó fi yẹ kí o jẹ́ kí wọ́n dáyà fò ọ́ láti fìdí mọ́lé. Ṣáà wulẹ̀ ṣọ́ra ni. Rántí: Ìmúrasílẹ̀ yíyẹ ń ṣèrànwọ́ láti gbéjà ko àwọn ewu tí ó lè ṣẹlẹ̀. Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n náà: “Ọlọ́gbọ́n ènìyàn rí wàhálà tí ń bọ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀; aláìmọ̀kan wọ inú rẹ̀, ó sì jìyà.”—Owe 22:3, The New English Bible.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìmọ̀ràn lórí ohun tí ó yẹ kí o ṣe nípa àárẹ̀ ọpọlọ òun ara, wo Jí!, June 8, 1986 (Gẹ̀ẹ́sì.) ojú ìwé 19 sí 21.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Nígbà ìsinmi, ṣọ́ ohun tí o ń jẹ