ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 6/22 ojú ìwé 15-17
  • Bí O Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Ewu Àkókò Ìsinmi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí O Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Ewu Àkókò Ìsinmi
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbára Dì Dáradára
  • Nígbà Tí O Bá Gúnlẹ̀
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Síhà Gbígbádùn Ìsinmi
  • Gbádùn Ìsinmi Láìkábàámọ̀!
    Jí!—1996
  • Ohun Tí Ó Yẹ Kí O Ṣọ́ra Fún
    Jí!—1996
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Ìsinmi?
    Jí!—1996
Jí!—1998
g98 6/22 ojú ìwé 15-17

Bí O Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Ewu Àkókò Ìsinmi

ÀKÓKÒ ìsinmi—kí ló wá sọ́kàn rẹ? Nínajú ní àwọn etíkun tí oòrùn ti ń mú, tí àwọn ọ̀pẹ tó léwé lórí gan-an ń pèsè ìbòòji tó tura? Tàbí ìgbádùn ti mímí atẹ́gùn títura, tó tutù nini lórí òkè?

Síbẹ̀, o lè máa dààmú nípa ojú ọjọ́ tí ó lè máà dára, ìdádúró níbùdókọ̀ òfuurufú, àmódi tí ń ṣeni nítorí rírìnrìn àjò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ohun tó wù kí ó jẹ́ èrò rẹ, kí ni o lè ṣe láti gbádùn ìsinmi rẹ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó?

Gbára Dì Dáradára

Àwọn ọlọgbọ́n ènìyàn tí ń lọ lo ìsinmi máa ń wéwèé ṣáájú ni. Wọ́n máa ń gba àwọn ìwé ìrìn àjò àti ìwé ẹ̀rí ìlera sílẹ̀ ṣáájú kí ìrìn àjò wọn tó bẹ̀rẹ̀. Àwọn ìwádìí nípa àwọn ìṣòro ìlera tó lè kojú wọn máa ń mú kí wọ́n pinnu àwọn egbòogi tí wọ́n máa lò láti dènà àrùn.

Nígbà tí àwọn kan bá ń lọ sí àwọn àgbègbè tí ibà ti ń jà, wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn egbòogi agbóguntibà lọ́jọ́ mélòó kan kí wọ́n tó gbéra. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n sábà ń gba ìmọ̀ràn pé kí wọ́n máa lo irú egbòogi bẹ́ẹ̀ jálẹ̀jálẹ̀ àkókò ìsinmi wọn àti fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin lẹ́yìn náà pàápàá láti dáàbò bò wọ́n. Ìdí ni pé àwọn kòkòrò tí ń gbé àrùn ibà ń pamọ nínú ara pẹ́ tó bẹ́ẹ̀. Àmọ́ àwọn ìgbésẹ̀ ìṣọ́ra mìíràn tún ṣe kókó.

Dókítà Paul Clarke, láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìlera àti Egbòogi Ilẹ̀ Olóoru ní London, dámọ̀ràn pé: “Bákan náà ni àwọn ohun tí ń lé kòkòrò sá tí a fi ń kun ara tàbí ọrùn ọwọ́, àti nǹkan tí a fi ń bo ọrùn ẹsẹ̀, àpò ẹ̀fọn àti nǹkan tí ń báná ṣiṣẹ́ tí a fi ń fọ́n oògùn apakòkòrò, tún ṣe pàtàkì.” Ó dára jù pé kí o ti ra àwọn ohun èlò bí ìwọ̀nyí kí o tó gbéra lọ lo ìsinmi.

Àmódi tí ń ṣeni nítorí rírìnrìn àjò kì í jẹ́ kí ìrìn àjò kankan dùn mọ́ni. Kí ló ń fà á? Olùwádìí kan sọ pé àmódi tí ń ṣeni nítorí rírìnrìn àjò máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn àmì ìsọfúnni tuntun tí ń wá nítorí pé a wà níbi tí kò mọ́ni lára bá pọ̀ nínú ọpọlọ. Bí ó bá jẹ́ bí ọkọ̀ ojú omi ṣe ń lọ, bí ọkọ̀ òfuurufú ṣe ń gbọ̀n jìgìjìgì, tàbí ariwo ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ rẹ ló ń fa ìṣòro yìí, gbìyànjú láti pọkàn pọ̀ sórí ohun kan tó dúró gbagidi, bóyá ibi tí ó jọ pé ilẹ̀ òun òfuurufú ti pàdé tàbí títì tó wà níwájú. Bí afẹ́fẹ́ bá ń fẹ́ lọ fẹ́ bọ̀ dáradára, yóò pèsè afẹ́fẹ́ oxygen tí a nílò gidigidi. Bí àmódi tí ń ṣeni nítorí rírìnrìn àjò bá le gan-an, a lè lo àwọn egbòogi antihistamine láti dín àwọn àmì àrùn náà kù. Àmọ́, ó yẹ kí a ṣèkìlọ̀ pé: Ṣọ́ra fún àwọn àbájáde tí a kò retí tẹ́lẹ̀, bí òòyì, nítorí pé, nínú àwọn ipò kan, ìwọ̀nyí lè wu ọ́ léwu.

Àwọn ìrìn àjò òfuurufú lọ sí ọ̀nà jíjìn ní àwọn ewu tiwọn fún ìlera, bí ìpàdánù omi ara. Àìṣeǹkan àti kíká sórí ìjókòó fún àkókò gígùn lè mú kí ẹ̀jẹ̀ ẹsẹ̀ àwọn kan máa dì. Bí ẹ̀jẹ̀ dídì náà bá kúrò láyè rẹ̀, tó dé ẹ̀dọ̀fóró kan tàbí ọkàn àyà, àwọn ìyọrísí rẹ̀ lè léwu púpọ̀. Nítorí náà, nígbà tí àwọn kan bá ń rìnrìn àjò ọlọ́nà jíjìn, wọ́n lè ní láti máa rìn lọ rìn bọ̀ ní ọ̀nà àárín, tó pín àyè ìjókòó, tàbí kí wọ́n máa na itan àti ẹsẹ̀ lórí ìjókòó. Láti dín ìpàdánù omi ara kù, máa mu ọ̀pọ̀ ohun mímu tí kò ní èròjà ọtí líle nínú.

Ṣé ohun tí ń bà ọ́ lẹ́rù nínú wíwọ ọkọ̀ òfuurufú la mẹ́nu bà yìí? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí o fọkàn balẹ̀, kí o mọ̀ pé wíwọ ọkọ̀ òfuurufú kò léwu tó oríṣi ọ̀nà èyíkéyìí mìíràn láti fi rìnrìn àjò. A gbọ́ pé ó fi ìgbà 500 láàbò ju gígun alùpùpù lọ, ó sì fi ìgbà 20 láàbò ju wíwọ mọ́tò lọ! Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn mìíràn yóò tọ́ka sí i pé a gbé irú ìṣirò bẹ́ẹ̀ karí àfiwéra iye kìlómítà tí a ń rìn ni, kì í ṣe lórí iye àkókò tí a ń fi rìnrìn àjò.

Kíkó àwọn ọmọdé rin ìrìn àjò jẹ́ ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ kan. Òṣìṣẹ́ orí rédíò kan, Kathy Arnold, dámọ̀ràn pé: “Wéwèé ìrìn àjò rẹ bí ìgbà tí àwọn ológun ń ṣe nǹkan gẹ́lẹ́.” Bí ó bá tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé o kò lè ṣe ìyẹn, kó àwọn ìwé, àwọn ohun ìṣeré, tàbí àwọn nǹkan mìíràn tó lè fa ọkàn àwọn ọmọdé mọ́ra dání. Èyí yóò túbọ̀ mú kí gbogbo ìdílé náà gbádùn rírin ìrìn àjò.

Nígbà Tí O Bá Gúnlẹ̀

Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń lọ lo ìsinmi máa ń sọ pé, ‘Ó ń gba ọjọ́ mẹ́rin tàbí márùn-ún kí ara mi tó mọlé.’ Lóòótọ́, ó ń gba àkókò kí ara tó mọlé ní àyíká tuntun. Nítorí náà, ó lè jẹ́ ọ̀nà ọgbọ́n láti má ṣe máa sá sókè sódò ní ọjọ́ kìíní tàbí ọjọ́ kejì tí o bá gúnlẹ̀. Jẹ́ kí ara àti ẹ̀mí rẹ mú ara bá ọ̀nà ìṣeǹkan tuntun náà mu. Kíkùnà láti ṣe èyí lè fa àìfararọ, kí ó sì ba àǹfààní tí ìsinmi rẹ lè ṣe jẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí ìdíwọ̀n kan ṣe fi hàn, ó kéré tán, ìdajì àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn kárí ayé tí ń lọ sẹ́yìn odi lọ́dọọdún ní ń ṣe oríṣi àìsàn kan tàbí ní ń ní oríṣi ìpalára kan. Nípa bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dókítà Richard Dawood, olóòtú ìwé Travellers’ Health, ṣe wí, “ọ̀nà láti ní ìlera tí kò yẹ kí arìnrìn-àjò kankan gbójú fò ni dídènà àrùn.” Níwọ̀n bí arìnrìn-àjò kan ti ní láti mú ara bá onírúurú bakitéríà inú afẹ́fẹ́, oúnjẹ, àti omi, mu, ó ṣe pàtàkì pé kí ó ṣọ́ oúnjẹ jẹ láàárín ọjọ́ mélòó kan àkọ́kọ́.

Dókítà Dawood kìlọ̀ pé: “A kò gbọ́dọ̀ wulẹ̀ gbà pé oúnjẹ kan dára láìlárùn bí kò bá jẹ́ pé ó dáni lójú pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ sè é, tó sì jinná dénú—bó bá jẹ́ ẹran, kò gbọ́dọ̀ ku àmì pupa lára rẹ̀.” Síbẹ̀, àwọn oúnjẹ tí a sè pàápàá gba ìfura. Nítorí náà, “rí i dájú pé oúnjẹ ọ̀sán òní kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ àná tí a tún gbé kaná, tí a tún bù sáwo.”

Nípa bẹ́ẹ̀, bí o bá ń lo ìsinmi ní ibi kan tó yàtọ̀ pátápátá sí ibi tí o ń gbé, ó ṣeé ṣe kí o má lè máa jẹun nígbà tí o fẹ́, níbi tí o fẹ́ ẹ, kí o má sì lè jẹ ohun tí o ń fẹ́ gẹ́lẹ́. Ṣùgbọ́n ohun kékeré ni èyí jẹ́ láti mú kí o lè yẹra fún àrùn ìgbẹ́ gbuuru tí a gbọ́ ìròyìn pé ó ti bá ìpín méjì nínú márùn-ún àwọn arìnrìn-àjò tí ń lọ sẹ́yìn odi fínra.

Ní ti ohun mímu, omi inú ìgò sábà máa ń wà láìlẹ́gbin ju omi tí a ń rí ládùúgbò lọ. Àmọ́ ṣá, láti yẹra fún àwọn àrùn, ó bọ́gbọ́n mu pé kí o mu omi inú ìgò tàbí omi inú agolo tí a ṣí lójú rẹ. Ó tún lè bọ́gbọ́n mu láti yẹra fún fífi omi dídì sínú omi tí o fẹ́ mu. Bí kò bá dá ọ lójú pé kò lẹ́gbin, máa kà á sí ohun tí ó lè ṣèpalára.

Àwọn Kókó Pàtàkì Síhà Gbígbádùn Ìsinmi

Lẹ́yìn ìwádìí tí ó ṣe láàárín àwọn òǹkàwé rẹ̀, olóòtú ìwé kan nípa ìrìn àjò sọ pé: “Bí o bá ka ojú ọjọ́ sí kókó pàtàkì nínú àwọn ohun tó mú kí ìsinmi kan gbádùn mọ́ ọ tàbí tí kò mú kí ó dára tó, o tún ní láti ka àwọn ọ̀rẹ́ tí o bá kẹ́gbẹ́ sí kókó tó ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Ní gidi, a fi hàn pé “ìbákẹ́gbẹ́ rere” jẹ́ kókó tó ń múni gbádùn ìsinmi “lọ́pọ̀ ìgbà ju àwọn hòtẹ́ẹ̀lì tí iṣẹ́ wọn tẹ́ni lọ́rùn, ìrìn àjò tí kò ní ìṣòro, oúnjẹ àdíndùn, àti àwọn ìran wíwọnilọ́kàn lọ.”

Àmọ́ ibo ni o ti lè rí àwọn ọ̀rẹ́ gbígbámúṣé nígbà ìsinmi? Ó dára, ọ̀nà kan láti ṣe èyí ni kí o kọ̀wé ṣáájú sí ọ́fíìsì Watch Tower Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè tí o wéwèé láti lọ lo ìsinmi. Wọn yóò fún ọ ní àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sún mọ́ ibi tí o fẹ́ wà jù, wọn yóò sì fún ọ ní àwọn àkókò ìpàdé tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. Àwọn àdírẹ́sì ọ́fíìsì mélòó kan wà lójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí, o sì lè rí àwọn púpọ̀ sí i nínú ìwé Yearbook Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí a tẹ̀ jáde ní lọ́ọ́lọ́ọ́.

Ohun pàtàkì kan tí yóò mú kí o gbádùn ìsinmi rẹ, kí o sì yẹra fún àbámọ̀ èyíkéyìí nígbà kan náà ni ṣíṣègbọràn sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n inú Bíbélì pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Bí o bá nímọ̀lára pé o fẹ́ yẹra fún títẹ̀lé àwọn ìlànà àti ìhùwà Kristẹni nígbà tí o wà níbi ìsinmi àdádó kan, fi ọgbọ́n mọ̀ pé èyí jẹ́ àìlera kan, kí o sì bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti gbógun ti ìfẹ́-ọkàn yẹn. Àwọn òbí pẹ̀lú tún ní láti fiyè sí àwọn ohun tí àwọn ọmọ wọn bá ń ṣe. Níbikíbi tí o bá wà, máa rántí pé, “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ni a wà yìí.—2 Tímótì 3:1.

Nígbà tí ìdílé yín bá ń lo ìsinmi pọ̀, má rò pé Màmá yóò máa ṣe gbogbo ohun tí ó máa ń ṣe nílé. Múra tán láti ṣèrànwọ́ ní ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ilé ojoojúmọ́. Ní ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀. Irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ yóò dá kún bí gbogbo yín yóò ṣe gbádùn ìsinmi tó.

Ǹjẹ́ ìsinmi rẹ yóò gbádùn mọ́ ọ? Ó dájú pé àwọn àyànláàyò fọ́tò, káàdì àfiránṣẹ́ tí kò nílò àpò ìwé, àti àwọn ohun ìrántí mélòó kan, bóyá tó jẹ́ àwọn iṣẹ́ ọnà díẹ̀ tí a ṣe ní àdúgbò yóò máa múni rántí àwọn àkókò aláyọ̀. Ní pàtàkì ṣáá, àwọn ọ̀rẹ́ tuntun yóò máa jẹ́ ohun ìrántí. Má ta wọ́n nù. Máa kọ̀wé sí wọn láti sọ àwọn ìrírí wíwọnilọ́kàn. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni o lè gbà mú kí ìsinmi rẹ jẹ́ àkókò ìgbádùn ní tòótọ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn Ìránnilétí Díẹ̀ fún Àkókò Ìsinmi

Kí o tó gbéra

• Ní gbogbo ìwé ìrìn àjò àti ìwé ẹ̀rí ìlera tó yẹ

• Ní àwọn egbòogi ìdènà àrùn lọ́wọ́

Nígbà ìrìn àjò

• Máa mu ọ̀pọ̀ ohun mímu tí kò ní èròjà ọtí líle, sì máa dára yá bí o bá ń wọkọ̀ òfuurufú lọ síbi jíjìn

• Kó àwọn nǹkan tó ń fa ọkàn ọmọdé mọ́ra dání fún wọn

Nígbà tí o bá gúnlẹ̀

• Fún ara àti ẹ̀mí rẹ lákòókò láti mọlé

• Fi oúnjẹ rẹ àti ohun mímu rẹ mọ sórí àwọn tí ó dá ọ lójú pé kò lẹ́gbin

• Máa wà lójúfò nípa ti ìwà rere

• Máa bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé ṣàjọpín iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Nígbà tí o bá ń lo ìsinmi, ṣọ́ra fún ẹgbẹ́ tí o ń kó

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́