Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Oníṣẹ́ Ọnà Títóbi Jù Lọ Ẹ ṣeun fún ọ̀wọ́ “Wíwá Oníṣẹ́ Ọnà Títóbi Jù Lọ Kiri.” (November 8, 1995) Gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ ọnà kan fúnra mi, mo mọrírì àwọn àpilẹ̀kọ náà gidigidi. Ìjónírúurú aláìlẹ́gbẹ́ inú ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, iṣẹ́ ọnà eléwì inú Sáàmù, àti àwọn àyọkà Bíbélì tí a fi ẹwà èdè gbé kalẹ̀ míràn para pọ̀ láti fi hàn pé Jèhófà kò wulẹ̀ ṣọnà ìṣẹ̀dá lásán, ṣùgbọ́n ó ń gbádùn rẹ̀ pẹ̀lú!
B. R., United States
Níwọ̀n bí mo ti ń ṣe iṣẹ́ ọnà fún èyí tí ó lé ní 30 ọdún, mo fẹ́ láti gbóríyìn fún gbogbo àwọn tí wọ́n lọ́wọ́ sí pípèsè irú àpilẹ̀kọ àgbàyanu bẹ́ẹ̀! Ó jẹ́ ojú ìwé mẹ́sàn-án àrògún àti ìwòyeronú nípa atóbilọ́lá Ọlọ́run wa, Jèhófà, àti agbára ìṣẹ̀dá rẹ̀ gbígbéṣẹ́.
P. M., United States
Àwọn Onísìn Mormon Mo ka àpilẹ̀kọ “Ṣọ́ọ̀ṣì Mormon—Ìmúpadàbọ̀sípò Ohun Gbogbo Ha Ni Bí?” (November 8, 1995) pẹ̀lú ìháragàgà. A tọ́ mi dàgbà nínú agboolé onísìn Mormon, mo ṣe batisí, mo sì di àlùfáà onísìn Mormon, kí n tó di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ ṣáá, gbólóhùn kan gba àfiyèsí mi. Ẹ sọ pé ‘àlàyé ìsìn Mormon nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí tọkọtaya àkọ́kọ́ dá wé mọ́ ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí.’ Bí mo ṣe lè rántí, wọ́n kọ́ wa pé Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípa jíjẹ èso igi gidi.
D. A., United States
Ó ṣe wá láàánú, bí gbólóhùn yìí bá fa èdèkòyedè. A kò ní in lọ́kàn pé àwọn onísìn Mormon gbà gbọ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ náà fúnra rẹ̀ jẹ́ ìbálòpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnì kan lè ní ojú ìwòye yìí láti inú àkọsílẹ̀ ìwé “Book of Mormon.” (2 Nephi 2:22, 23, 25) Kàkà bẹ́ẹ̀, a sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ náà “wé mọ́” ìbálòpọ̀. Báwo? Ní ti pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìsìn Mormon ti sọ, ó ṣínà sílẹ̀ fún mímú irú ọmọ ẹ̀dá ènìyàn jáde. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé “Mormon Doctrine,” tí Bruce R. McConkie kọ, kí Ádámù tó ṣẹ̀, “kò lè bímọ. . . . Gẹ́gẹ́ bí ìwéwèé àṣesílẹ̀, Ádámù gbọ́dọ̀ dẹ́ṣẹ̀ . . . Gẹ́gẹ́ bí ẹni kíkú, ó lè lọ́mọ nísinsìnyí.” Ní ìtakora, Bíbélì kò kọ́ni pé Ádámù gbọ́dọ̀ dẹ́ṣẹ̀ kí ó lè mú irú ọmọ jáde. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé ìṣubú wọ́n jẹ́ nítorí ìwéwèé àṣesílẹ̀ Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé ó jẹ́ nítorí ìfẹ́ inú ara wọn láti dá wà lómìnira. (Oníwàásù 7:29) Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn onísìn Mormon láti yan ohun tí wọ́n fẹ́ láti gbà gbọ́, ọ̀ràn yìí ṣàpèjúwe pé ohun tí ìwé “The Book of Mormon” fi ń kọ́ni wulẹ̀ ṣàìbá Bíbélì mu ni.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò fìgbà kankan mọ ohun tí ó lè bá àwọn onísìn Mormon sọ, mo lè sọ pé, mo ti mọ̀ nípa wọn gan-an báyìí, ọpẹ́ ni fún àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí. Báwo ni àwọn onísìn Mormon ṣe lè sọ pé àwọ́n gbà gbọ́ pé Bíbélì àti ìwé The Book of Mormon jùmọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n má sì rí i pé méjèèjì ta ko ara wọn?
J. M., United States
Àwòrán Ìhòhò Lórí Kọ̀m̀pútà Mo fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àpilẹ̀kọ “Àwòrán Ìhòhò Lórí Kọ̀m̀pútà Wà fún Àwọn Ọmọdé” lábẹ́ ìpín “Wíwo Ayé.” (November 8, 1995) Mo ka èyí, ọkàn-àyà mí sì fẹ́rẹ̀ẹ́ dá kú! Ó fi bí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọ̀nyí ṣe léwu tó àti bí wọ́n ṣe wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ọmọdé tó hàn ní ti gidi. Àpilẹ̀kọ yìí yóò ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti wọn ìhà rere àti búburú tí irú ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà bẹ́ẹ̀ ní wò.
D. P., United States
Àrùn Tí Oúnjẹ Ń Fà Mo gbádùn àpilẹ̀kọ yín lórí “Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àrùn Tí Oúnjẹ Ń Fà.” (November 22, 1995) Ọlọ́wọ́ọ ṣíbí ni mí, n óò sì fẹ́ láti ṣàfikún kókó kan. Bí ẹnì kan bá kúndùn jíjẹ ẹran àsèèjinádénú, èyí kò lè ṣeé ṣe níbi tí a bá ti n ṣàníyàn nípa yíyẹra fún àwọn àrùn tí oúnjẹ ń fà. Òtítọ́ ni pé, síse ẹran jiná ń mú kí ó gbẹ, kí ó sì túbọ̀ ṣòro láti dà níkùn. Ọ̀nà kan tí ó dára láti fi se ẹran jiná, kí ó má sì gbẹ, ni sísè é pẹ̀lú ẹ̀fọ́ tàbí fífi ọ̀rá sè é jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́.
J. P. K., United States
A dúpẹ́ fún ìṣítí nípa oúnjẹ sísè yìí.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.