ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/8 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • BÍbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
Jí!—1996
g96 9/8 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Àwọn Mẹ́ḿba Mormon Ẹnú yà mí gan-an nígbà tí mo ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ṣọ́ọ̀ṣì Mormon—Ìmúpadàbọ̀sípò Ohun Gbogbo Ha Ni Bí?” (November 8, 1995) Ẹ pe ara yín ní Kristẹni tòótọ́ nítorí pé ẹ kọ̀ jálẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú ogun. Àmọ́, inú mi dùn sí àwọn mẹ́ḿba Mormon tí wọ́n jà nínú Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n sì ran àwọn Júù, tí Hitler ń ṣenúnibíni sí, lọ́wọ́. Kí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lákòókò yẹn yàtọ̀ sí pé wọ́n fọwọ́ lẹ́rán, wọ́n sì ń wò ó bí mílíọ̀nù mẹ́fà Júù ṣe ń kú?

G. D., Germany

Òtítọ́ ni pé àwọn mẹ́ḿba Mormon ní United States àti Britain gbógun ti ètò ìjọba Nazi. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ ní Germany gangan. Ìwé náà “The Nazi State and the New Religions,” tí òpìtàn Christine King, gíwá Yunifásítì Staffordshire ní England ṣe, ròyìn pé: “Àwọn mẹ́ḿba Mormon kó wọnú iṣẹ́ ológun, ẹgbẹ̀ta mẹ́ḿba Mormon ló wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Germany ní 1940. . . . Àwọn mẹ́ḿba Mormon ń bá a lọ ní títẹnu mọ́ ‘àwọn góńgó dídọ́gba’ ti ìsìn Mormon àti Ìjọba Àjùmọ̀ní Orílẹ̀-Èdè. . . . Àwọn olóri Mormon kan bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn ìjọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn ohun ìpìlẹ̀ Ìjọba Àjùmọ̀ní Orílẹ̀-Èdè, ní gbígbàdúrà fún Führer, sísọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ‘ẹni tí a pè láti ọ̀run.’ . . . Ìròyìn nípa méjì péré lára àwọn mẹ́ḿba Mormon tí wọ́n ta ko àwọn ẹgbẹ́ Nazi ni a rí gbọ́.” Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwùjọ kan kọ̀ láti ṣètìlẹ́yìn fún ìṣàkóso Nazi. Nípa bẹ́ẹ̀, ìjọba Hitler dájú sọ wọ́n. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọ́n jìyà ìfisẹ́wọ̀n ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àwọn púpọ̀ sì kú síbẹ̀. Wo ìtẹ̀jáde wa August 22, 1995.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.

Àṣìṣe Fọ́tò Ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Àròsọ Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀—Ìkófìrí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ha Ni Bí?” (December 8, 1995) gbádùn mọ́ni gan-an. Síbẹ̀síbẹ̀, ó jọ pé àwòran William Morris, ayàwòrán àti òǹkọ̀wé ọ̀rúndún kọkàndínlógún ló wà níbi tó yẹ̀ kí àwòran Jules Verne wà ní ojú ewé 3.

R. G., United States

Púpọ̀ àwọn òǹkàwé ló rí àṣìṣe yìí. A ṣe àṣìṣe nínú ètò ìkówèéjọ ni, a sì ṣi lébẹ́ẹ̀lì lẹ̀ sórí fọ́tò William Morris nínú fáìlì fọ́tò wa. Ẹ máà bínú nítorí àṣìṣe náà.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.

Àgbàyanu Àgbáálá Ayè Lẹ́yìn tí mo ka àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín náà “Àgbàyanu Àgbáálá Ayé—Ibo Ni Ó Ti Wá?” (January 22, 1996), mo wá ní òye kedere sí i nípa èrò ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa àgbáálá ayé. Lílo ọ̀pọ̀ yanturu ìsọfúnni oníṣirò, orísun ìsọfúnni, àti ìtọ́kasí pẹ̀lú ìjáfáfá gbé kókó pàtàkì inú ohun tí ẹ kọ jáde. Èmi gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kan yóò lo ìsọfúnni tí ẹ kọ dáradára.

M. P., United States

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti ka àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ jíjọra nínú àwọn ìwé ìròyìn, àmọ́ wọ́n sábà máa ń kùnà láti fi ògo irú àwọn àgbàyanu bẹ́ẹ̀ fún Oníṣẹ́ Ọnà kan. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín pèsè ohun tí a nílò láti dí àlàfo yẹn.

P. B., Ítálì

Kì í ṣe pé àkọsílẹ̀ náà jẹ́ òkodoro òtítọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń fún ìgbàgbọ́ lókun. Ó gbé ìmọrírì wa ró fún Ọlọ́run wa—Olùdásílẹ̀ àgbàyanu àgbáálá ayé, aṣeniníkàyéfì!

C. S., ilẹ̀ Gíríìsì

Ohun amóríyá gbáà ni ó jẹ́ láti ka àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Ọmọ ọdún 14 ni mí, àgbáálá ayé sì ti máa ń fìgbà gbogbo jọ mí lójú lọ́nà gígadabú. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ kí n mọ̀ pé ẹ̀dá ènìyàn kò tó nǹkan ní ìfiwéra pẹ̀lú ìdíjúpọ̀ tí ó wà nínú ìṣẹ̀dá yìí.

M. D., ilẹ̀ Potogí

Mo ka àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà pẹ̀lú ìdàníyàn àrà ọ̀tọ̀. Inú mi dùn pé Jí! jíròrò irú kókó ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó fún mi ní òye jíjinlẹ̀ síwájú sí i nípa àwọn àràmàǹdà àgbáálá ayé, ní pàtàkì ìsọfúnni nípa ẹ̀rí “àwọn àlàfo” tí wọ́n tóbi ní ìwọn 100 mílíọ̀nù ọdún ìmọ́lẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ní ìta àti nínú àlàfo. Èyí gbé ìṣòro dìde fún àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá òde òní! Ìwọ̀nba tí a mọ̀ ní ti gidi nípa àgbáálá ayé wa wọ̀ mí lọ́kàn.

D. K., Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́