ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/8 ojú ìwé 3-4
  • Abúlé Kárí Ayé Ṣùgbọ́n Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ Síbẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Abúlé Kárí Ayé Ṣùgbọ́n Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ Síbẹ̀
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ayé Lu
  • Ìdí Tí Àwọn Ènìyán Fi Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ Síbẹ̀
  • Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Láti Kórìíra Ẹ̀yà Mìíràn?
    Jí!—2003
  • Báwo Ni Ìwà Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà Ṣe Máa Kásẹ̀ Nílẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Wíwó Ògiri Palẹ̀ Láti Fi Kọ́ Afárá
    Jí!—1996
  • Àwọn Ògiri Ìdènà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 7/8 ojú ìwé 3-4

Abúlé Kárí Ayé Ṣùgbọ́n Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ Síbẹ̀

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ

O HA ti gbọ́ ìtàn àròsọ nípa ẹ̀yà ìran àwọn ènìyàn kan tí kò ní ẹnu, àti nítorí náà, tí kò lè jẹ tàbí mu nǹkan rí bí? A gbọ́ pé gbígbọ́ òórùn ní ń gbé ìwàláàyè wọn ró, ó sì jẹ́ òórùn àwọn ápù nígbà púpọ̀ jù lọ. Òórùn burúkú èyíkéyìí lè pa wọ́n.

A tún gbọ́ àhesọ nípa àwọn ènìyàn kan ní Ìwọ̀ Oòrun Áfíríkà, tí wọ́n ń ṣòwo wúrà. Olùṣàbójútó ọkọ̀ òkun ilẹ̀ Potogí kan nígbà náà ròyìn pé: “Ní 200 líìgì níkọjá ilẹ̀ ọba [Mali], a rí orílẹ̀-èdè kan, tí àwọn olùgbe rẹ̀ ní orí àti eyín ajá àti ìrù bíi ti ajá. Àwọn ni àwọn Adúláwọ̀ tí ó kọ̀ láti wọnú ìjíròrò nítorí pé wọn kò fẹ́ láti rí àwọn ènìyàn míràn.” Díẹ̀ nìwọ̀nyẹn lára àwọn èrò ṣíṣàjèjì tí a kà sí òtítọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ṣáájú sànmánì ìrìn àjò òun ìṣàwárí.

Ayé Lu

Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, a gbà gbọ́ pé irú àwọn ìtàn àròsọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ òtítọ́. Ṣùgbọ́n bí àwọn olùṣàwárí ti ń tú pílánẹ́ẹ̀tì ilẹ̀ ayé wò, wọn kò rí àwọn aláìlẹ́nu tí ń gbóòórùn àwọn ápù, tàbí àwọn ènìyàn aborí-ajá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí bojúbojú kan tí a kò mọ̀ nípa àwọn ènìyàn tí ń gbé ẹ̀yìn odi ibùgbé tiwa lónìí. Ayé ti di abúlé kárí ayé kan. Tẹlifíṣọ̀n ń gbé ìsọfúnni nípa ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ òkèèrè wáá bá wa níyàrá wa. Ìrìn àjò òfurufú ti mú kí a lè ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilẹ̀ òkèèrè wọ̀nyẹn láàárín wákàtí mélòó kan; àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyán sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dọọdún. Àwọn kan ń rìnrìn àjò nítorí ọrọ̀ ajé tàbí ìṣèlú. Ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ Àjọ Tí Ń Bójú Tó Owó Àkànlò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Iye Ènìyán sọ pé: “Ní ìwọ̀n títóbi ju tí ìgbàkígbà rí lọ—tí ó sì dájú pé yóò pọ̀ sí i—àwọn ènìyàn kárí ayé ń ṣí ara wọn nídìí, wọ́n sì ń ṣípò padà ní wíwá ìgbé ayé tí ó dẹrùn sí i.” Nǹkan bí 100 mílíọ̀nù ènìyàn ń gbé lẹ́yìn òde orílẹ̀-èdè tí a ti bí wọn.

Àwọn orílẹ̀-èdé túbọ̀ ń gbára lé ara wọn sí i ní ti ọrọ̀ ajé. Ìsokọ́ra ìgbékalẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ kárí ayé, tí ó dà bí ìgbékalẹ̀ iṣan ara kan lọ́nà gbígbórín, ń so gbogbo orílẹ̀-èdè ayé kọ́ra. Bí a ṣe ń ṣe pàṣípààrọ̀ èrò, ìsọfúnni, àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, ni àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ń para pọ̀, tí wọ́n sì ń mú ara bá ara wọn mu. Jákèjádò ayé, àwọn ènìyàn ń múra lọ́nà jíjọra ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àwọn ìlú ńlá kárí ayé ní ọ̀pọ̀ ìrísí jíjọra—ọlọ́pàá, àwọn hòtẹ́ẹ̀lì aláfẹ́, ètò ìrìnnà ọkọ̀, àwọn ibi ìtajà, àwọn báńkì, ìbàyíkájẹ́. Lọ́nà yìí, bí àwọn ènìyàn àgbáyé ṣe ń ní àjùmọ̀ṣe ni a ń rí ohun tí àwọn kán pè ní àṣẹ̀ṣẹ̀dé àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àgbáyé.

Ìdí Tí Àwọn Ènìyán Fi Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ Síbẹ̀

Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ènìyàn àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ń wọnú ara wọn, ó ṣe kedere pé, gbogbo wọn kọ́ ní ń ka ẹlòmíràn sí ará. Òǹkọ̀wé eré onítàn kan, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì, kọ̀wé ní èyí tí ó lé ní 2,000 ọdún sẹ́yìn pé: “Gbogbo ènìyán nítẹ̀sí láti dẹ́bi fún àtìpó.” Ó bani nínú jẹ́ pé bákan náà ni lónìí. A lè yára rí ẹ̀rí èyí nígbà tí a bá ń ka ìròyìn nínú ìwé agbéròyìnjáde nípa ìtara aláìmòye, ìkórìíra àlejò, “ìpaláparun ẹ̀yà ìran,” gbọ́nmisi-omi-òto ẹ̀yà ìran, ìrúkèrúdò ìsìn, ìpakúpa àwọn ará ìlú, pápá ìṣekúpani, àgọ́ ìfipábánilòpọ̀, ìdálóró, tàbí ìpalápalù ẹ̀yà.

Dájúdájú, kò sí ohun tí púpọ̀ lára wá lè ṣe láti yí ipa ọ̀nà ìforígbárí ẹ̀yà ìran padà. Wọ́n tilẹ̀ lè má kàn wá ní tààrà. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ lára wa ń níṣòro nítorí àìsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn àjèjì tí a ń bá pàdé—àwọn aládùúgbò, alájùmọ̀ṣiṣẹ́, tàbí akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni.

Kò ha ṣàjèjì pé àwọn ènìyàn tí ẹ̀yà ìran wọ́n yàtọ̀ síra sábà ń ní ìṣòro láti fọkàn tán ara wọn, kí wọ́n sì mọyì ara wọn bí? Bẹ́ẹ̀, pílánẹ́ẹ̀tì wá kún fún àìbáradọ́gba kíkàmàmà, ìjónírúurú aláìlópin. Ọ̀pọ̀ jù lọ wá mọyì ọ̀pọ̀ yanturu onírúurú oúnjẹ, orin, àti àwọ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú oríṣiríṣi irúgbìn, ẹyẹ, àti ẹran. Lọ́nà kan ṣáá, mímọyì tí a mọyì onírúurú nǹkan kì í sábà kan àwọn ènìyàn tí kò bá ń ronú tàbí hùwà lọ́nà tiwa.

Kàkà kí wọ́n fiyè sí àwọn apá dídára nínú àìbáradọ́gba láàárín ènìyàn, ọ̀pọ́ nítẹ̀sí láti máa pàfiyèsí sí ìyàtọ̀, kí wọ́n sì fi ṣe ìpìlẹ̀ àìfohùnṣọ̀kan. Èé ṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? Àǹfààní wo ló wà nínú sísapá láti bá àwọn ènìyàn tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọ́n yàtọ̀ sí tiwa sọ̀rọ̀ pọ̀? Báwo ni a ṣe lè wó àwọn ìdènà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ palẹ̀, kí a sì dí àlàfo ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀? Àwọn àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò gbìyànjú láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́