Tulip—Òdòdó tí Ó ti La Pákáǹleke Kọjá
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ NETHERLANDS
Ẹ̀KA Àbójútó Ìrìn Àjò Afẹ́ ti Netherlands sọ pé: “Ńṣe ló máa ń jọ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún sarè ilẹ̀ . . . ń jí padà bí ìgbà ìrúwé bá dé ní Holland.” Lójijì, nínú ìbúrẹ́kẹ́ àwọ̀, àwọn ìlà òdòdó tulip títàn, tí ń rúwé, tò lọ láàárín àwọn pápá, ní mímú kí ògo ẹwà òdòdó tí ń fa àwọn arìnrìn àjò afẹ́ láti ibi gbogbo lágbàáyé mọ́ra yọ. Fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àlejò, àwọn òdòdó ọgbà fífani mọ́ra, tí wọ́n sì gbajúmọ̀ wọ̀nyí, wọ́pọ̀ gan-an ní Holland bí àwọn ẹ̀rọ afátẹ́gùnyípo, wàràkàṣì, àti bàtà onípákó. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé ilẹ̀ Turkey ni òdòdó tulip ti pilẹ̀ ṣẹ̀ ní ti gidi?
Òdòdó Tulip Netherlands Tí Ó Pilẹ̀ Ṣẹ̀ Láti Ilẹ̀ Gábásì
Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ilẹ̀ Turkey tí wọ́n ti wà láti ọ̀rúndún kejìlá ṣàgbéyọ òdòdó tulip, àmọ́, onímọ̀ nípa irúgbìn, Adélaïde L. Stork, sọ pé ní àwọn ọdún 1550 ni àwọn ìwé lítíréṣọ̀ ilẹ̀ Europe kọ́kọ́ mẹ́nu kan òdòdó tulip. Ní 1553, arìnrìn àjò kan láti ilẹ̀ Faransé kọ̀wé pé “àwọn àjèjì tí a mú ṣe kàyéfì” ń ra “àwọn òdòdó lílì pupa àti iṣu ìdí òdòdó” ṣíṣàjèjì ní àwọn ọjà Constantinople (Istanbul). Àwọn ènìyàn àdúgbò ń pe òdòdó náà ní dülbend, tí ó túmọ̀ sí “turban” [láwàní] ní èdè Turkish, Dókítà Stork sì ṣàlàyé pé, ọ̀rọ̀ yẹn “wá di orísun ìtàn ọ̀rọ̀ náà ‘tulip’.”
Ọ̀kan lára àwọn àjèjì tí àwọn òdòdó tí ó dà bíi láwàní yìí rùmọ̀lára rẹ̀ sókè ni Ogier Ghislain de Busbecq, ikọ̀ ilẹ̀ Austria ní ilẹ̀ Turkey (1555 sí 1562). Ó mú àwọn iṣu ìdí òdòdó díẹ̀ láti Constantinople lọ sí Vienna, níbi tí wọ́n ti gbìn wọ́n sínú ọgbà Ferdinand Kìíní, olú ọba Hapsburg. Òdòdó tulip gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lábẹ́ àbójútó akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ti Charles de L’Écluse—onímọ̀ nípa irúgbìn, ará Faransé, tí a fi orúkọ rẹ̀ lédè Látìn, Carolus Clusius, mọ̀ dáradára.
Láìpẹ́ láìjìnnà, òkìkí Clusius fa àfiyèsí Yunifásítì Leiden ní Netherlands mọ́ra, tí ó rọ̀ ọ́ láti wá di alábòójútó ọgbà irúgbìn yunifásítì náà. Ní October 1593, Clusius—àti “àwọn iṣu ìdí òdòdó tulip tí ó gbé pa mọ́”—dé Leiden. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà ìrúwé 1594, ọgbà tuntun tí Clusius ṣe wá di ìgbékalẹ̀ fún òdòdó tulip àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí yóò tanná ní Netherlands.
Ìgbawère Òdòdó Tulip—Àkókò Pákáǹleke
Àwọn àwọ̀ títàn rokoṣo àti ìrísí ṣíṣàjèjì tí òdòdó tulip ní rùmọ̀lára àwọn ará Netherlands sókè. Àwọn ìtàn àròsọ eré ìfẹ́ tí ó ní ìdíyelé àrà ọ̀tọ̀ tí àwọn olórí ilẹ̀ Turkey gbé kárí àwọn iṣu ìdí òdòdó náà mú kí olúkúlùkù aráàlú tí ipò jẹ lọ́kàn máa ṣe ìlara rẹ̀. Láìpẹ́ láìjìnnà, gbígbin iṣu ìdí òdòdó tulip wá di òwò tí ń mówó wọlé, nígbà tí iye tí a ń béèrè fún sì bẹ̀rẹ̀ sí í ga ju èyí tí ó wà lọ́wọ́ lọ, owó iṣu ìdí òdòdó ga sókè fẹ̀rẹ̀, ó sì tanná ran àkókò pákáǹleke tí àwọn òpìtàn ará Netherlands pè ní tulpenwoede, tàbí ìgbawèrè òdòdó tulip.
Ìgbawèrè òdòdó tulip dé òtéńté rẹ̀ ní àwọn ọdún 1630, nígbà tí, iṣu ìdí òdòdó tulip di ohun tí ó lókìkí jù lọ. Òpìtàn nípa iṣẹ́ ọnà, Oliver Impey, sọ pé nígbà náà lọ́hùn-ún, kò fi bẹ́ẹ̀ nira láti ra àwòrán òdòdó tulip tí Jan D. de Heem (ọmọ ilẹ̀ Netherlands tí ó jẹ́ àgbà ayàwòrán ohun aláìlẹ́mìí, ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún) yà láti ra iṣu ìdí òdòdó tulip ṣíṣọ̀wọ́n kan. Wọ́n gba iṣu ìdí òdòdó kan fún nǹkan orí ìyàwó, iṣu ìdí òdòdó mẹ́ta ni owó tí wọ́n gbà fún ilé ẹ̀gbẹ́ odò lílà kan, iṣu ìdí òdòdó kan, tí ó jẹ́ irú ẹ̀yà Tulipe Brasserie, ni a fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún ilé ìpọntí kan tí ó gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Àwọn tí ń fi iṣu ìdí òdòdó ṣòwò lè pa tó 44,000 dọ́là (U.S., lówó tòde òní) lóṣù kan. Orísun ìsọfúnni kan sọ pé: “Ní àwọn ilé àgbàwọ̀ àti ilé èrò láyìíká Holland, ọ̀rọ̀ àti òwò dá lórí ohun kan péré—iṣu ìdí òdòdó.”
Ìwe gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica fi kún un pé: “Iye owó tí ń ga láìsọsẹ̀ tan ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé alágbàtà àti òtòṣì lásán láti méfò ewu nípa òwò tulip. Àwọn ilé, dúkìá ìní, àti àwọn ilé iṣẹ́ ni wọ́n fi dúró kí wọ́n baà lè ra iṣu ìdí òdòdó tí wọn yóò tún tà lówó gọbọi. Wọ́n ń tà, wọ́n sì ń ṣe àtúntà léraléra lọ́pọ̀ ìgbà, tí iṣu ìdí òdòdó náà kò sì ní kúrò lójú kan.” Àlùbáríkà ń di ìlọ́po méjì ní wàràǹṣeṣà. Àwọn òtòṣì ń di ọlọ́rọ̀; àwọn ọlọ́rọ̀ ń ní àníkún ọrọ̀. Òwò iṣu ìdí òdòdó di ọjà àwọn olùméfò aláìníjàánu, àfi bí ó ṣe di òjijì, ní 1637, tí àwọn òǹtajà wá pọ̀ ju àwọn olùrà lọ—òwò náà sì dojú dé. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lọ́sàn-án kan òru kan ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Netherlands di ẹdun arinlẹ̀.
Ìfàlọ́kànmọ́ra Náà Ń Tẹ̀ Síwájú
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìfàlọ́kànmọ́ra òdòdó tulip la ìyọrísí àtubọ̀tán ìgbawèrè òdòdó tulip náà já, iṣẹ́ iṣu ìdí òdòdó tulip sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ní ti gidi, nígbà tí ó fi di ọ̀rúndún kejìdínlógún, òdòdó tulip ti ilẹ̀ Netherlands ti lókìkí gan-an débi pé olórí ilẹ̀ Turkey kan, Ahmed Kẹta, kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún òdòdó tulip wọlé wá láti Holland. Nítorí náà, lẹ́yìn ìrìn àjò gígùn, àwọn òdòdó tulip ti ilẹ̀ Turkey, tí wọ́n jẹ́ àmújáde láti ilẹ̀ Netherlands, wá padà sórí ilẹ̀ tí wọ́n ti pilẹ̀ ṣẹ̀.
Lónìí, gbígbin òdòdó tulip ní ilẹ̀ Netherlands ti di iṣẹ́ pàtàkì—tàbí òwò ẹwà, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ. Lára 34,000 kìlómítà ilẹ̀ níbùú lóròó tí orílẹ̀-èdè náà ní, nǹkan bí 7,700 ẹ́kítà ni wọ́n fi ṣọ̀gbìn iṣu ìdí òdòdó tulip. Lọ́dọọdún, àwọn 3,300 àgbẹ̀ tí ń ṣọ̀gbin rẹ̀ ń kó iye iṣu ìdí òdòdó tulip tí ó tó bílíọ̀nù méjì lọ sí orílẹ̀-èdè òkèèrè tí iye wọ́n ju 80 lọ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òdòdó tulip ti la pákáǹleke kọjá, bí ohun àyànláàyò inú ọgbà yìí ṣe fa ènìyàn lọ́kàn mọ́ra ti ń bá a bọ̀ láìsọsẹ̀. La àwọn ọ̀rúndún já, òdòdó rírẹwà yìí ti sún àwọn oníṣẹ́ ọnà, àwọn eléwì, àti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ láti ya àpẹẹrẹ ìgbékalẹ̀ ẹlẹ́wà ọlá àti àwọn àwọ̀ agbàfiyèsí rẹ̀ sórí ìpèlé aṣọ ìyàwòrán àti bébà. Lẹ́yìn tí ọ̀kan lára wọn, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rúndún kejìdínlógún, Johann Christian Benemann, ti kọ àkọsílẹ̀ kan ní èdè German lórí òdòdó tulip, ó pe àkọsílẹ̀ náà ní Die Tulpe zum Ruhm ihres Schöpffers, und Vergnügung edler Gemüther (Òdòdó Tulip fún Ògo Ẹlẹ́dàá Rẹ̀ àti Ìgbádùn Àwọn Tí Ipò Ọlá Jẹ Lọ́kàn). Adélaïde Stork sọ pé, ní ti Benemann àti ọ̀pọ̀ àwọn òǹṣèwé mìíràn, òdòdó tulip “kì í ṣe ohun èlò lọ́wọ́ ọlọ́gbà nìkan, àmọ́ ó ṣàgbéyọ ìtóbi lọ́lá àti ògo Ẹlẹ́dàá.” Ní wíwo òdòdó ẹlẹgẹ́ yìí, yóò ṣòro fún ọ láti jiyàn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]
Bí O Ṣe Lè Gbin Òdòdó Tulip Rẹ
NÍWỌ̀N bí omi tí ó wà bá ti pọ̀ tó, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ilẹ̀ ló bá a mu. Bí ó ti wù kí ó rí, a lè mú gbígbìn ín rọrùn nípa pípo ilẹ̀dú pọ̀ mọ́ iyanrìn, iyẹ̀pẹ̀ oníkoríko gbígbẹ, tàbí ajílẹ̀.
Gbin iṣu ìdí òdòdó tulip nígbà ìwọ́wé. Ọ̀nà méjì ni a lè gbà gbìn ín: O lè gbẹ́ ihò fún iṣu ìdí òdòdó kọ̀ọ̀kan, tàbí kí o kọ ebè gígùn láti gbin gbogbo iṣu ìdí òdòdó náà lẹ́ẹ̀kan náà.
Ohun tí ìrírí fi hàn nípa gbígbin iṣu ìdí òdòdó tulip ni pé: Iṣu ìdí òdòdó náà gbọ́dọ̀ wọlẹ̀ tó ìlọ́po méjì gíga rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé abẹ́ iṣu ìdí òdòdó (ibi pẹlẹbẹ) náà gbọ́dọ̀ jẹ́ nǹkan bí 20 sẹ̀ǹtímítà sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Gbin àwọn iṣu ìdí òdòdó náà ní sẹ̀ǹtímítà 12 síra.
Fi iyẹ̀pẹ̀ tí o gbẹ́ jáde bo iṣu ìdí òdòdó náà, sì bomi rin ín lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí ìdàgbàsókè lè bẹ̀rẹ̀. Bí èérún omi dídì púpọ̀ bá wà, lílé ẹrẹ̀ sórí rẹ̀ tàbí dída koríko gbígbẹ bò ó yóò dáàbò bo iṣu ìdí òdòdó náà, kò sì ní jẹ́ kí iyẹ̀pẹ̀ náà gbẹ. Kó koríko gbígbẹ náà kúrò ní ìgbà ìrúwé, nígbà tí àwọn èèhù rẹ̀ bá kọ́kọ́ yọ.
Gé orí àwọn òdòdó náà kúrò bí àwọn ewé irúgbìn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, irúgbìn náà yóò hu hóró èso, yóò sì fi oúnjẹ tí iṣu ìdí òdòdó náà nílò fún híhù ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e dù ú. Jẹ́ kí ewé rẹ̀ kù fúnra rẹ̀, kí o sì kó o kúrò bí àwọn ewé náà bá ti pọ́n.
Dípò gbígbin iṣu ìdí òdòdó tí kì í ṣe irú kan pàtó káàkiri, gbin àwọn ìdí òdòdó tí wọ́n jẹ́ irú kan náà ati àwọ̀ kan náà pa pọ̀ lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Lọ́nà yẹn, wọn óò mú oríṣiríṣi àwọ̀ híhàn ketekete wá, ìwọ óò sì gbádùn iṣẹ́ ọlọ́gbọ́nlóye ti ohun ọ̀gbìn tí ó wà nínú ọgbà rẹ ní kíkún.—Ibùdó Iṣu Ìdí Òdòdó fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè Jákèjádò Ayé, Holland/National Geographic.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 17]
Nísàlẹ̀ ojú ewé 16: Nederlands Bureau voor Toerisme; Apá òsì lókè, láàárín, àti apá ọ̀tún lókè: Internationaal Bloembollen Centrum, Holland; Nísàlẹ̀ ojú ewé 17: Nederlands Bureau voor Toerisme/Capital Press