ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/8 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Habu—Àkòtagìrì Ejò
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 4/8 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Àwọn Àìdọ́gba Tí Ó Pín Wa Yẹ́lẹyẹ̀lẹ A fẹ́ láti fi ìmoore wa hàn fún ọ̀wọ́ kókó ẹ̀kọ́ náà, “Àìdọ́gba Ha Gbọ́dọ̀ Pín Wa Yẹ́lẹyẹ̀lẹ Bí?” (July 8, 1996) A ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹgbẹ́ àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni kárí ayé níhìn-ín ní Mexico fún nǹkan bí ọdún kan. Kódà, lẹ́yìn oṣù bíi mélòó kan, a ṣì ń ní ìṣòro mímú ara bá ipò nǹkan mu, àmọ́, a kò mọ ohun tó fà á. Àwọn àpilẹ̀kọ náà ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìṣòro náà sí àìdánilójú nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ṣíṣàjèjì. A ti ṣègbọràn sí gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà pé, “lílóye àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míràn lè mú ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i,” a sì ti ń rí ayọ̀ púpọ̀ nínú iṣẹ́ àyànfúnni wa.

C. H. àti J. H., Mexico

Ọ̀nà tí ẹ gbà gbé kókó ẹ̀kọ́ gbígbàfiyèsí yìí kalẹ̀, tí ẹ sì ṣàlàyé rẹ̀, wú mi lórí. Ní tòótọ́, àìdọ́gba ti ru ọ̀pọ̀ ìkórìíra sókè nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Ọ̀wọ́ kókó ẹ̀kọ́ yìí yóò wá ràn mí lọ́wọ́ nísinsìnyí láti fi òye gíga jù lọ wo àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míràn. Mo dàníyàn pé kí olúkúlùkù ẹni tó wà láyé lè ka àpilẹ̀kọ náà, kí wọ́n sì yí èrò òdì tí wọ́n ní nípa àwọn ẹlòmíràn pa dà!

G. O., Nàìjíríà

Àwọn àpilẹ̀kọ náà mú mi sunkún. Mo ní ọ̀rẹ́ kan tí ọ̀rọ̀ èmi pẹ̀lú rẹ̀ ń wọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ. Àmọ́, mo sábà máa ń lérò pé ìdènà kan tí kò ṣeé rí wà láàárín wa. Mo wá mọ̀ nísinsìnyí pé láti inú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó yàtọ̀ síra gan-an ni a ti wá. Nígbà tó bá yá, ìsọfúnni yìí yóò mú ìyàtọ̀ ńlá wá nípa bí mo ṣe ń bá a lò.

A. F., United States

Nígbà tí mo ń ṣèwádìí fún ìwé àkọgboyè mi ní kọ́lẹ́ẹ̀jì lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn, mo lo ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan ní orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà. Ó ṣeé ṣe fún mi láti mọ ọ̀pọ̀ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wà níbẹ̀, mo sì lọ sí àwọn ìpàdé wọn. Ìrírí tí ń runi lọ́kàn sókè ní! Bí àpilẹ̀kọ náà ti sọ, dídi ojúlùmọ̀ àwọn ènìyàn láti inú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míràn ń buyì kúnni. Ó ṣeé ṣe fún mi láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun àti ipò ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó nítumọ̀.

S. B., Ítálì

Habu Àpilẹ̀kọ náà, “Habu—Àkòtagìrì Ejò” (July 8, 1996), wú mi lórí gan-an. Ẹ kọ ọ́ lọ́nà tó gbádùn mọ́ni, àwọn àwòrán inú rẹ̀ sì kọyọyọ!

E. P., Ukraine

Àpilẹ̀kọ náà kún fún ẹ̀kọ́, ó sì ń dẹ́rìn-ín pani. Àmọ́ kókó kan ta ko ohun tí mo ti kọ́ tẹ́lẹ̀. Ẹ fa ọ̀rọ̀ yọ nínú ìwé kan tí ó dámọ̀ràn fífi ẹnu fa oró lójú àmì ibi tó ti buni ṣán náà. Ṣé èyí kò léwu ní gidi?

C. D., Nàìjíríà

Ó jọ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ògbógi nínú ìmọ̀ ìṣègùn kò gbà pẹ̀lú orísun ìsọfúnni tí a ti fa ọ̀rọ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ wa. Ní gidi, àwọn dókítà kan lérò pé ìgbìyànjú láti fẹnu fa oró lè léwu fún ẹni tí ń ṣètọ́jú náà, kò sì ṣàǹfààní fún ẹni tí ejò ṣán. Àwọn dókítà gbà pé ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni láti gbé ẹni tí ejò ṣán náà lọ sí ilé ìwòsàn kan bí ó bá ṣe lè yá tó.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.

Àwọn UFO A dúpẹ́ fún àpilẹ̀kọ náà, “Ojú-Ìwòye Bíbélì: Àwọn UFO—Ońṣẹ́ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Wọ́n Bí?” (July 8, 1996) Ní àdúgbò wa, àwọn ènìyàn kan gba àwọn ìròyìn nípa àwọn olùgbé-òde-ayé gbọ́. Ní ríronú pé Bíbélì kò jíròrò ọ̀ràn yí, wọ́n ní iyèméjì nípa Bíbélì. Àpilẹ̀kọ náà ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù ń gbìyànjú láti ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà àti pé kò ní bọ́gbọ́n mu láti gba àwọn ìròyìn tí kò fìdí múlẹ̀ nípa àwọn olùgbé-òde-ayé gbọ́.

A. W., Taiwan

Àwọn Òdòdó Tulip A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àgbàyanu àpilẹ̀kọ tí ó ní àkọlé náà, “Tulip—Òdòdó Tí Ó Ti La Pákáǹleke Kọjá.” (July 8, 1996) Mo rí ìsọfúnni nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ìsọfúnni àfàṣẹsí nípa gbígbin àwọn òdòdó tulip bí ohun tí ó fani lọ́kan mọ́ra jù lọ.

D. G., United States

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́