Habu—Àkòtagìrì Ejò
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ OKINAWA
ÌRỌ̀LẸ́ aláìmóríyá kan ni, kò sí afẹ́fẹ́ lóló tí ń fẹ́. Òjó ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ni, olúkúlùkú sì ń rọra fẹ́ra, kí ará lè tù wọ́n. Lójijì, ariwó ta: “Habu!” “Habu kán wà níbí!” Ariwo náà kó ìdágìrì bá àwọn ará abúlé. Àwọn àgbààgbá fagi yọ; àwọn ọmọdé ọlọ́fìn-íntótó ń sáré tọ̀ wọ́n. Òun dà? Ara ń wá kálukú pàpà. Bí ejò tí ń gùn ní nǹkan bíi mítà méjì yìí bá ṣánni, ikú ló ń bọ̀ yẹn. Ara àwọn ará abúlé balẹ̀, nígbà tí àwọn àgbàlagbà lu orí rẹ̀ ní pọ̀pá títí tí ó fi dá kú. Wọ́n yára gbé e jù sínú àpò kan, kí wọ́n lè tà á lóòyẹ̀.
Ní àwọn Erékùṣu Ryukyu, tí ó wà ní Òkun Ìlà Oòrun China, gbogbo ènìyàn láti orí ọmọdé dé orí òbí àgbà ní ń sá fún habu—ejò aláwọ̀ òfefèé tóótòòtó, tí ó ní orí bí orí ọ̀kọ̀—paramọ́lẹ̀ oníhò tí ó jẹ́ ti àdúgbò àwọn kan lára àwọn erékùṣù wọ̀nyí, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe ti àdúgbò gbogbo wọn. Ẹ jẹ́ kí a wáá wo ejò bíbani lẹ́rù yìí láwòfín. Àmọ́, rántí láti sá fún un, kí o sì jìnnà sí i níwọ̀nba!
Ìrísí Bíbani Lẹ́rù
Onírúurú habu ló wà. Oríṣi kán ní àdàlú àwọ ewé àti kọfí, tí ó rin dòdò, tí ń fún un ní àǹfààní ìfarapamọ́ gíga lọ́lá nínú ewéko àti ìràwé. Àwọn mìíràn ní ìrísí tí ó túbọ̀ dúdú sí i, tí ó bá àwọn ìgbòkègbodò àfòruṣe àti ìtẹ̀sí habu láti fara pa mọ́ sí ibi ṣíṣókùnkùn mu.
Ẹ̀dá yìí ní agbára tí a kò ní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ lè rí ohun tí ó bá jìnnà sí i. Ó ní ohun tí a ń pè ní àwọn ẹ̀yà ara oníhò, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan orí rẹ̀. Wọ́n jẹ́ ìjìnwọnú tí ń yára kẹ́fín ooru tí ó wà láàárín àwọn ihò imú àti àwọn ojú rẹ̀. Àwọn ihò méjèèjì ń ràn án lọ́wọ́ láti “rí” ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ aláìṣeéfojúrí tí àwọn ènìyàn ń nímọ̀lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ooru. Pẹ̀lú ìwọ̀nyí, habu kan lè fojú sun eku kékeré kan tí ara rẹ̀ lọ́ wọ́ọ́wọ́ọ́ láìtàsé, àní nínú òkùnkùn birimùbirimù pàápàá.
O lè ti rí ejò kan tí ń pọ́n ahọ́n rẹ̀ bérébéré. Ahọ́n rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ bí imú kejì lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Nípa ìpọ́nbérébéré bẹ́ẹ̀, habu ń ṣàkójọ àwọn kẹ́míkà inú afẹ́fẹ́, tí ó ń fi ahọ́n tẹ̀ mọ́ ẹ̀yà ara tí ń yára mọ kẹ́míkà tí ó wà ní àjà ẹnu rẹ̀. Bí imú kejì yìí ṣe ń báṣẹ́ lọ, habu náà lè ṣàkójọ ọ̀pọ̀ ìsọfúnni oníkẹ́míkà láti inú afẹ́fẹ́.
Àwọn olùṣèwádìí R. M. Waters àti G. M. Burghardt ti Yunifásítì Tennessee ṣàkíyèsí pé: “Habu máa ń pọ́n ahọ́n bérébéré lọ́nà yíyára kánkán gan-an léraléra lẹ́yìn tí ó bá ti gbéjà ko ohun kan.” Èé ṣe tí o fi máa ń wá ìmọ̀lára oníkẹ́míkà láti inú afẹ́fẹ́ lẹ́yìn ìgbéjàkoni náà? Ó jẹ́ nítorí pé ewu ìpadàgbéjàkoni máa ń wá láti ọ̀dọ̀ ohun ọdẹ tí ń gbékú tà náà, ní tirẹ̀, habu, sábà máa ń jánu lára ohun tí ó bá bù ṣán lẹ́yìn tí ó bá ti sọ ọ́, tí ó sì ti pọ oró sí i lára. Lẹ́yìn náà, bí oró náà ti ń jà, paramọ́lẹ̀ náà yóò máa wá ohun ọdẹ rẹ̀ kiri nípa fífi ahọ́n “kóòórùn” rẹ̀.
Gbàrà tí ọwọ́ rẹ̀ bá ti tó ohun ọdẹ tí kò lè ta pútú náà, ì báà jẹ́ eku, ọmọ ẹyẹ, tàbí ẹyẹ, habu náà yóò gbé e mì lódindi—orí, ẹsẹ̀, ìrù, irun ara, ìyẹ́, gbogbo rẹ̀. Àgbọ̀n ìsàlẹ rẹ̀ máa ń ṣí lẹ́yìn, láti gba párì náà láyè láti yà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, kí ohun ọdẹ tí ó tóbi jù náà lè ṣeé gbé mì. A bá odindi ológbò nínú ikùn habu kan tí ó wà fún àfihàn ní ọ̀kan lára àwọn ibùdó ìwádìí nípa habu ní Okinawa.
Bí habu bá pàdánù eyín bí abẹ́rẹ́ rẹ̀ nínú ìgbéjàkoni kan ńkọ́? Tuntun kan yóò hù rọ́pò rẹ̀. Kódà, àwọn habu kan ní eyín méjì ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ẹnu wọn! Yàtọ̀ sí ìyẹn, bí habu bá tilẹ̀ pàdánù àwọn eyín rẹ̀, ebi kò lè pa á. A mọ̀ nípa habu kan tí ó wà láàyè láìjẹ nǹkan mìíràn yàtọ̀ sí omi fún ọdún mẹ́ta.
Yíyẹra fún Ìgbéjàkoni Rẹ̀
Nígbà tí ṣèbé ìha Gúúsù Ìlà Oòrun Éṣíà àti mamba dúdú ti Áfíríkà ń pọ oró májèlé iṣan ara, habu ń pọ oró amẹ́jẹ̀sun lílágbára gan-an. A ń pè é ní amẹ́jẹ̀sun nítorí ó máa ń fa ìṣẹ̀jẹ̀ nípa bíba àwọn iṣan tí ń gbé ẹ̀jẹ̀ kiri ara jẹ́. Oró náà máa ń fa ìrora bí iná tí ń jóni àti ìwúlé, ó sì lè fa ikú.
Àwọn kán rò pé ejò náà máa ń fò jáde láti ibi tó gẹ̀gùn sí, tí ó sì ń lé ènìyàn ni, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn ènìyàn kì í ṣe oúnjẹ àyànláàyò fún habu. Kìkì bí o bá tẹ habu kan mọ́lẹ̀ láìmọ̀, tàbí tí o rìn ní agbègbè ìpínlẹ̀ rẹ̀, ni ó ṣeé ṣe kí ó gbéjà kò ọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ti gbéjà kò jẹ́ àwọn tí wọ́n rìn ní ibi tí àwọn habu ti ń wá ohun ọdẹ, irú bíi nínú àwọn ọgbà ewébẹ̀, tàbí oko ìrèké. Àwọn olùgbé erékùṣù kì í lọ síbi tí koríko bá ga láìsí ìdáàbòbò yíyẹ fún ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì máa ń gbé iná aláfọwọ́tẹ̀ dání lóru. Habu sábà máa ń jẹ̀ lóru. Má ṣe gbàgbé láé pé àwọn ejò yìí jẹ́ ògbóǹkangí agungi, èyí tí ń fàyè gbà wọ́n láti ní ìtura ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, kí wọ́n sì sún mọ́ àwọn ẹyẹ tí kò fura. Nítorí náà, máa ṣọ́ orí rẹ, títí kan ìgbésẹ̀ rẹ, nígbà tí o bá sún mọ́ agbègbè ibùgbé wọn!
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ọ̀nà dídára jù lọ láti bójú tó ọ̀ràn paramọ́lẹ̀ yìí ni láti má ṣe fún un láyè láti wọnú ilé. Dí gbogbo ihò tí ń bẹ nínú ìpìlẹ̀ ilé àti ògiri tí ó yọ sí gbangba. Jẹ́ kí ọgbà rẹ́ mọ́ láìsí koríko tí ó kún. Lédè míràn, má ṣe pèsè ibi ìlúgọ fún habu.
Bí Ó Bá Bù Ọ́ Ṣán Ńkọ́?
Kí ní lè ṣẹlẹ̀ bí o bá ṣalábàápàdé ọ̀kan lára àwọn ejò olóró wọ̀nyí? Ó ṣeé ṣe kí habu náà ká jọ, pẹ̀lú ìdajì ara rẹ̀ tí ó wà lókè ní ìrísí lẹ́tà S. Ó ń bọ̀ o! Ìpín méjì nínú mẹ́ta ara rẹ̀ sọ́gọ̀ọ́ọ̀rọ̀ síhà ọ̀dọ̀ rẹ, pẹ̀lu páárì rẹ̀ ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu, eyín rẹ ni yóò kọ́kọ́ kàn ọ́.
Má ṣojo. Rí i dájú pé habu ló gbéjà kò ọ́. O lè fi àpá pípọ́n méjì, tí ó jìnnà síra níwọ̀n sẹ̀ǹtímítà méjì, níbi tí àwọn eyín náà ti gún ọ, mọ̀ bí habu bá bù ọ́ ṣán. Àwọn kán lè ní eyín mẹ́ta tàbí mẹ́rin, èyí tí ń fi kún iye àpá pípọ́n náà. Láìpẹ́, ìmọ̀lára ìjóni kan, bíi pé ẹnì kán fi ọwọ́ rẹ sínú iná, ń lágbára sí i. Kí ni o lè ṣe? Kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, fa oró náà jáde, kí o sì tu ú sílẹ̀. Ìwé ìléwọ́ Handbook for the Control of Habu, or Venomous Snakes in the Ryukyu Islands sọ pé: “Ó kéré tán, fa ẹ̀jẹ̀ jáde nígbà mẹ́wàá.” Kọrí sí ilé ìwòsàn tí ó ní aporó fún oró habu. Àmọ́ ṣáá o, má ṣe sáré. Ìyẹ́n lè mú kí oró náà yára tàn ká ara rẹ, kí ó fi kún ìpalára náà, kí ó sì fawọ́ ìkọ́fẹpadà sẹ́yìn. Bí o kò bá níí lè dé ilé ìwòsàn kan láàárín 30 ìṣẹ́jú, di ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ náà ní ibì kan tí ó sún mọ́ ọkàn àyà ju ibi tí ejò náà ti bù ọ́ jẹ lọ, láti dènà ìyáratànkálẹ̀ oró náà. Bí ó ti wù kí ó rí, má ṣe dì í le jù, kí ó má baà dí ìṣàn ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́. Máa dín bí ó ti fún tó kù ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá-mẹ́wàá láti fàyè gba ìṣàn ẹ̀jẹ̀.
Masatoshi Nozaki àti Seiki Katsuren, ti ẹ̀ka ìṣèwádìí nípa habu ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìlera òun Àyíká ti Ẹkùn Ìpínlẹ̀ Okinawa, sọ fún Jí! pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn, kódà lẹ́yìn tí ó bá ti bù wọ́n ṣán, kò ní agbára ìdènà wíwà pẹ́ títí lòdì sí oró habu. Látijọ́, gígé ni a máa ń gé ẹ̀yà ara tí ó bá ti buni ṣán dà nù, ṣùgbọ́n lóde òní, àwọn ènìyàn kéréje ní ń pàdánù ẹ̀yà ara kankan, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kí wọ́n kú, nítorí pé habu bù wọ́n ṣán. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn egbòogi àti ọ̀nà ìtọ́jú gbígbéṣẹ́, ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ó bá bù ṣán lóde òní ń sàn. Kìkì àwọn tí kì í wá ìtọ́jú ìṣègùn, tàbí àwọn tí ọ̀na wọ́n jìn jù sí ibi ìtọ́jú ni wọ́n lè ní ìpalára líle koko.
Habu fún Títà
Àwọn ẹ̀dá kéréje ní ń fi habu ṣe ohun ọdẹ. Àwọn ológbò àti ajá tí a ń sìn nílé ní ìtẹ̀sí láti máa bá a ṣeré. Ejò aláìlóró kan tí ń jẹ́ akamata, àwọn ẹranko weasel kan, ẹlẹ́dẹ̀ igbó, àti àwọn àṣá wà lára àwọn tí ń pa á jẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kó ẹranko mongoose lọ sí àwọn Erékùṣù Ryukyu láti dín iye àwọn habu kù, èyí kò tí ì gbéṣẹ́ tó láti pa wọ́n run.
Ọ̀tá paraku ni ènìyán jẹ́ fún un. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ará abúlé tí wọ́n rọ́ gììrì jáde nígbà tí wọ́n gbọ́ igbe “Habu!” ní gbàrà tí wọ́n gbọ́ ọ, ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ń yán hànhàn láti mú habu kan ní gbàrà tí wọ́n bá ti rí i. Láìka ewu tí o ní nínú sí, iye owó tí a ń tà á lọ́jà, tí ó wà láàárín 80 dọ́là sí 100 dọ́là fún ẹyọ habu kan, jẹ́ ìdẹwò ńláǹlà kan fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Kí ni a ń fi habu ṣe? A ń lò ó fún àlọ̀kùn ejò gbígbẹ àti olómi tí a fi habu ṣe, tí a ń lo méjèèjì fún ète ìlera. Ọ̀pọ rẹ̀ ni a ń lò níbi àwọn àṣehàn láti fi fa àwọn arìnrìn àjò afẹ́ mọ́ra. Ó dájú pé, awọ rẹ̀ dára fún ṣíṣe àpò àti ìgbànú, a sì ń lo oró rẹ̀ láti fi ṣe aporó. Láìka irú àwọn ìwúlo bẹ́ẹ̀ sí, ìmọ̀ràn náà síbẹ̀síbẹ̀ ṣì ni pé, jìnnà sí habu!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Habu pẹ̀lú eyín rẹ̀ bí abẹ́rẹ́. Àgbọndò rẹ̀ ń ṣí kí ó lè gbé ẹran ìjẹ tí ó bá tóbi jù mì