ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìsọfúnni Lọ́ọ́lọ́ọ́ Nípa Àgbáálá Ayé
  • Ìjínigbé Ń Pọ̀ Sí I
  • Ìkìlọ̀ Nípa Vitamin A
  • Pákó Tí Ń Dènà Kòkòrò
  • Ìrawọ́ Ẹ̀bẹ̀ fún Òkùnkùn
  • Àwọn Òbí Tí Ń Pa Ràndànràndàn
  • Ìkìlọ̀ Nípa Oúnjẹ Tí Kò Ní Ọ̀rá Púpọ̀ Nínú
  • Ìfẹ́ àti Ṣokoléètì
  • Afárá Tó Lọ sí Skye
  • Ọ̀fun Dídùn tí “Kọ̀m̀pútà” Fà
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Ǹjẹ́ Ojútùú Kan Tiẹ̀ Wà?
    Jí!—2000
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Lájorí Ohun Tó Ń Fà Á
    Jí!—2000
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2003
  • Jíjí Èèyàn Gbé Ti Di Òwò Tó Kárí Ayé
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 7/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ìsọfúnni Lọ́ọ́lọ́ọ́ Nípa Àgbáálá Ayé

Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Àwọn àwárí lọ́ọ́lọ́ọ́ ń mú kí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbalasa òfuurufú máa ṣàtúnrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àbá èrò orí. Fún àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà tí wọ́n ń yọjú jìnnàjìnnà wo inú ọ̀run pẹ̀lú Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú ti Hubble ti dórí ìparí èrò pé a ti fojú díwọ̀n pé 40 sí 50 bílíọ̀nù ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ló wà nínú àgbáálá ayé wa. Èyí yàtọ̀ sí ìfojúdíwọ̀n 100 mílíọ̀nù ti a ṣe tẹ́lẹ̀ rí. Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n ṣe ìkéde yìí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ inú Ẹgbẹ́ Onímọ̀ Ìjìnlẹ̀ Sánmà ti America ròyìn síwájú sí i pé àwọ́n ti rí, ó kéré tán, ìdajì lára “ìṣù tí ó kù” kí àgbáálá ayé ní, òṣùwọ̀n tí a kò rí tí ń pèsè agbára òòfàmọ́lẹ̀ tí ó di àwọn ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ pọ̀. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà sọ pé púpọ̀ lára àwọn ìṣù tí a kò rí náà lè ní ọ̀pọ̀ àwọn ìràwọ̀ tí ó ti kọṣẹ́ tí a ń pè ní ràrá funfun. Ní àfikún, àwọn àbá èrò orí nípa pílánẹ́ẹ̀tì Júpítà ni ìsọfúnni oníṣirò láti inú ọkọ̀ òfuurufú Galileo ti pè níjà. Ọ̀gá nínú ìwéwèédáwọ́lé onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà Ọ̀mọ̀wé Torrence Johnson, sọ pé: “Èrò ìrẹ̀lẹ̀ ló máa ń yọjú nígbà tí ìsọfúnni oníṣirò bá kọ́kọ́ dé. Àwọn àbáyọrí rẹ̀ kì í sábà bá àwọn àbá èrò orí wa mu dáradára.”

Ìjínigbé Ń Pọ̀ Sí I

Ìwé agbéròyìnjáde Jornal da Tarde sọ pé, ní ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ kan, àwọn ọ̀daràn ní Rio de Janeiro, Brazil, gba 1.2 bílíọ̀nù dọ́là (U.S.) kìkì láti inú iṣẹ́ ìjínigbé tí ń ga sókè sí i, wọ́n wá sọ ìjínigbé di pàtàkì orísun ibi tí owó ń gbà wọlé fún ìwà ọ̀daràn tí a ṣètòjọ ní ìlú ńlá yẹn. Ìjínigbé tún ti wá ni ìlọ́gbọ́n ọ̀làjú nínú. Àwọn kan ń jẹ́ “onífẹ́ẹ́rẹ́fẹ́,” tàbí fún àkókò kúkúrú, jíjí àwọn tí wọ́n wà lẹ́gbẹ́ kò-là-kò-ṣagbe gbé, “tí wọ́n sábà máa ń san ìràpadà díẹ̀díẹ̀,” àti èyí tí ó díjú, wíwéwèé dáadáa jí àwọn tí wọ́n túbọ̀ lọ́rọ̀ gbé. Ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn, ìjínigbé tún ti ń pọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé àwọn ògbógi ilẹ̀ Philippine dámọ̀ràn, pẹ̀lú àwọn ohun mìíràn, pé: Má ṣe dá nìkan rìnrìn àjò, ní pàtàkì tí ilẹ̀ bá ti ṣú. Nígbà gbogbo, máa sọ ibi tí ìwọ yóò wà fún ọ̀rẹ́ kan tí o gbẹ́kẹ̀ lé. Gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ síbi tí a tanná sí dáradára tí ó sì láàbò. Má ṣe fi àwọn ọmọ sílẹ̀ láìbójútó wọn.

Ìkìlọ̀ Nípa Vitamin A

Gẹ́gẹ́ bí àyẹ̀wò kínníkínní kan nípa àwọn 22,000 aláboyún, tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé The New England Journal of Medicine ti sọ, àwọn ìyá tí ń retí ọmọ́ ní láti ṣọ́ra fún lílo vitamin A. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀n kan vitamin A ṣe pàtàkì fún ìlera àti ìdàgbàsókè ọlẹ̀ inú ènìyàn, a ṣàwárí pé àpọ̀ju rẹ̀ lè ṣèpalára. Lẹ́tà ìròyìn náà, Tufts University Diet & Nutrition Letter, sọ pé, iye vitamin A tí a dámọ̀ràn fún aláboyún láti lò lóòjọ́ ni 4,000 ìwọ̀n tí gbogbogbòò fẹnu kò sí, àmọ́ àwọn obìnrin tí wọ́n bá lò ju ìwọ̀n 10,000 lọ lóòjọ́ “ní ìlọ́po méjì ààbọ̀ ewu bíbí ọmọ tí ó lábùkù ju àwọn obìnrin tí kì í lo àlòjù.” Nítorí pé ará máa ń tọ́jú vitamin A pa mọ́, kódà bí a bá ti ń lò ó púpọ̀ ṣáájú ìlóyún lè wu ọmọ náà léwu. A kò rí ewu nínú èròjà beta-carotene, tí a mú jáde láti inú irúgbìn tí a yí dà sí vitamin A lápá kan nínú ara.

Pákó Tí Ń Dènà Kòkòrò

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé ilé gogoro pagoda onípákó kan ní Nara, Japan, ti la 1,200 ọdún já láìsí pé àwọn òkété, ikán, tàbí àwọn kòkòrò tíntìntín bà á jẹ́. Àwọn aṣojú Yunifásítì Àpapọ̀ ti Seoul ní Korea àti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ará Japan méjì lọ láti wádìí ohun tí ó mú kí àwọn kòkòrò yẹra fún ilé gogoro pagoda. Nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò irú igi cypress tí wọ́n lò láti kọ́ ilé àtijọ́ náà, wọ́n ṣàwárí pé ó ní àwọn kẹ́míkà tí ó ṣàìbáradé gan-an fún àwọn òkété débi pé wọn kò jẹ́ feyín gé ohunkóhun tí a bá fi wọ́n kùn lára. Ilé iṣẹ́ gẹdú ní ilẹ̀ Japan ń mú nǹkan bí 4,000 tọ́ọ̀nu lẹ́búlẹ́bú pákó tí a rẹ́ jáde láti ara cypress yìí lọ́dọọdún, a sì retí pé àwọn èròjà tí a fá lára lẹ́búlẹ́bú pákó tí a rẹ́ náà lè rọ́pò àwọn májèlé kan tí a ń lò fún ṣíṣàkóso àwọn kòkòrò.

Ìrawọ́ Ẹ̀bẹ̀ fún Òkùnkùn

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ní ilẹ̀ Faransé ń jìjàdù fún òkùnkùn púpọ̀ sí i. Ìmọ́lẹ̀ púpọ̀ jọjọ ní àwọn agbègbè ìlú ńlá mú kí rírí ọ̀run ti ó kún fún ìràwọ̀ ní kedere fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Le Point ti sọ, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ń rọ àwọn aláṣẹ ìlú ńlá láti fi àwọn ìhùmọ̀ adarí ìmọ́lẹ̀, tí ń darí iná sílẹ̀, sára àwọn iná òpópónà àti láti béèrè pé tí ó bá ti di agogo 11 alẹ́, kí wọ́n máa pa àwọn iná ìpolówó ọjà àti ti àwọn ọ́fíìsì, àti ìpàtẹ iná ìgbì ìtànṣán ibi aláìṣeéfojúrí. Michel Bonavitacola, ààrẹ Ibùdó Ìdáàbòbo Òfuurufú Alẹ́, ṣàlàyé pé: “Lónìí, kò sí ọmọ kan láàárín ọgọ́rùn-ún tí yóò sọ pé òún ti rí Milky Way rí. Síbẹ̀, ohun àfiṣèranwò, títóbi lọ́lá, tí ó sì wà lọ́fẹ̀ẹ́lófò yìí, ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ibi tí a wà ní ti gidi nínú àgbáálá ayé.”

Àwọn Òbí Tí Ń Pa Ràndànràndàn

Ní ti ọ̀ràn pípèsè ìmọ̀ ìwé fún àwọn ọmọ wọn, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, L’Express, ti sọ, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òbí sọ pé “àṣeyọrí” àti “òmìnira” ni ohun tí ó gborí jù lọ, wọ́n sì lérò pé ẹrù iṣẹ́ àwọn ọmọ ló jẹ́ láti yan ìjẹ́pàtàkì ìwà wọn. Nígbà tí a béèrè bí góńgó ti ìmọ̀ ìwé bá jẹ́ láti kọ́ni ní ìjẹ́pàtàkì ìwà, ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn òbí àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín 6 sí 12 dáhùn pé bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìwé ìròyìn náà sọ pé ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òbí àti àwọn olùkọ́ tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ronú pé a kò mú àwọn ọmọdé gbaradì dáadáa fún ọjọ́ iwájú, síbẹ̀ wọ́n gbà gbọ́ lọ́nà tí kò bára mu pé àwọn ọmọdé yóò wá di ohun àmúṣọrọ̀ fún àwùjọ. Ìwádìí náà jẹ́rìí sí ìbẹ̀rù àwọn ògbógi kan, ìwé ìròyìn L’Express sọ pé “àwọn òbí kò tún mọ ipa wọn mọ́ lónìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ẹrù iṣẹ́ wọn mọ́.”

Ìkìlọ̀ Nípa Oúnjẹ Tí Kò Ní Ọ̀rá Púpọ̀ Nínú

Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Kánádà náà, Globe and Mail, sọ pé èsì àyẹ̀wò tí àwọn òǹrajà ṣe nípa títọ́ àwọn oúnjẹ ọlọ́ràá kínkínní wò fi hàn pé àwọn èròjà tí a fi kún wọn láti rọ́pò ọ̀rá nínú ọ̀pọ̀ oúnjẹ tí kò ní ọ̀rá púpọ̀ nínú kò dà bí ọ̀rá gidi lẹ́nu, èyí sì lè sún àwọn ènìyàn láti jẹ púpọ̀ rẹ̀ tàbí kí wọ́n fá àwọn mindinmín-ìndìn àti àwọn ìpẹ́pẹ́rẹ́ díẹ̀ sórí rẹ̀ láti fi rọ́pò. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé David Jenkins, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun aṣaralóore àti ìmọ̀ nípa ìṣe àti ìgbòkègbodò ìwàláàyè ní Yunifásítì Toronto, ti sọ, àwọn ìpẹ́pẹ́rẹ́ tí a fi kún un láti rọ́pò ọ̀rá, irú bíi ṣúgà, iyọ̀, àti àwọn ohun àtọwọ́dá amóúnjẹ ta sánsán, lọ́pọ̀ ìgbà kì í ṣara lóore. Ọ̀mọ̀wé Jenkins sọ pé: “Bí àwọn ènìyan bá pinnu pé ọkan lára ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dín ọ̀rá kù jẹ́ nípa jíjẹ oúnjẹ tí kò ní ọ̀rá púpọ̀ nínú, ìyẹn dára, níwọ̀n bí oúnjẹ náà bá ṣáà ti ṣara lóore.” Ó dámọ̀ràn pé ewébẹ̀, èso, àti hóró ọkà, bákan náà, ẹ̀pà àti oúnjẹ onísóyà tí kò ní ọ̀rá púpọ̀ nínú, jẹ́ àṣàyàn àfirọ́pò dáradára.

Ìfẹ́ àti Ṣokoléètì

Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ọkùnrin kan lè fún obìnrin kan ní ṣokoléètì gẹ́gẹ́ bí ìfihàn ìfẹ́ rẹ̀. Ó dùn mọ́ni nínú pé èrò ìmọ̀lára púpọ̀ sí i tí ń wá láti inú jíjẹ ṣokoléètì àti ìmọ̀lára kíkó wọnú ìfẹ́ lè ṣàjọpín ohun kan náà—ìmújáde omi ìsúnniṣe phenylethylamine púpọ̀ sí i nínú ọpọlọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Medical Post ti Toronto, Kánádà, ti sọ, Peter Godfrey, olùṣèwádìí ará Australia, ti pinnu ìgbékalẹ̀ “èérún ìfẹ́,” bí wọ́n ti pe omi ìsúnniṣe náà. Pẹ̀lú ìsọfúnni tuntun yìí lọ́wọ́ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀, wọ́n retí láti kọ́ púpọ̀ sí i nípa bí ọpọlọ ṣe ń sún èrò ìmọ̀lára ṣiṣẹ́. Síwájú sí i, ìwé agbéròyìnjáde Post sọ pé, ó “lè ṣàlàyé ìdí tí àwọn kan fi fọkàn fẹ́ ṣokoléètì gan-an.”

Afárá Tó Lọ sí Skye

Ìwé agbéròyìnjàde The Times ti London sọ pé, wọ́n ṣí irú afárá fífẹ̀ jù lọ, tí ó wà lófegè lápá kan, tí ó sì dúró déédéé, oníkìlómítà 2.4 ní gígùn kan láìpẹ́ yìí ní Scotland. Afárá náà so Erékùṣù Skye ti Scotland àti àwọn 9,000 olùgbé ibẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú etíkun ìwọ̀ oòrùn Scotland. Láti ṣàyẹyẹ ṣíṣí i, ẹgbẹ́ afunfèrè alápò awọ kan àti ìtọ́wọ́ àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àtijọ́ ṣáájú ìtọ́wọ̀ọ́rìn àwọn ọkọ̀ èrò—tí a ní kí gbogbo wọ́n sọdá láìsanwó fún ọjọ́ náà. Afárá náà rọ́pò ọkọ̀ ojú omi tí ń gbé àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti àwọn èrò lálọ àti lábọ̀ láti erékùṣù náà fún ọdún 23 tí ó kọjá. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Times ṣe sọ, akọ̀wé ilẹ̀ Scotland sọ pé, ó ti wá rọrùn báyìí fún àwọn awakọ̀ láti rìnrìn àjò láti Róòmù sí Uig, ní ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwá Skye, láìbọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn.

Ọ̀fun Dídùn tí “Kọ̀m̀pútà” Fà

Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail ti Kánádà sọ pé àwọn tí ń lo kọ̀m̀pútà tí wọ́n ń wá ìdásílẹ̀ fún ọwọ́ àti apá wọn nípa lílo ètò ìgbékalẹ̀ ọlọ́rọ̀ sísọ dojú kọ ohun tí àwọn kan kà sí ìṣòro tí ó túbọ̀ le koko—bárakú ohùn lílẹ̀ àti ìpàdánù ohùn pàápàá. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ni a gbọ́dọ̀ sọ ketekete àti pẹ̀lú ìgasókè ìró ohùn àti ìwọ̀n ohùn kan náà tí kọ̀m̀pútà náà yóò lóye, àwọn tí ń lò ó kì í mí bí ó ti yẹ, tí ó sì jọ pé àwọn okùn ohùn ń pàdánù ìfàro wọn. Dókítà Simon McGrail ti Yunifásítì Toronto sọ fún ìwé agbéròyìnjáde Globe pé, ìwúlé gọngọ tàbí ọgbẹ́ inú lè ṣẹlẹ̀ nínú àlàfo okùn ohùn náà bí wọ́n ti ń gbá ara wọn léraléra, tàbí kí àwon okùn náà fúnra wọn di aláàárẹ̀. Láti mú kí àwọn iṣan ohùn wà ní ipò lílera, àwọn ògbóǹtagí nípa ohùn dámọ̀ràn pé kí àwọn tí ń lò ó dín iye àkókò tí wọ́n ń lò nídìí irú àwọn kọ̀m̀pútà bẹ́ẹ̀ kù, kí wọ́n máa ṣíwọ́ ránpẹ́ léraléra, kí wọ́n máa mu omi púpọ̀, kí wọ́n sì yẹra fún ọtí líle, kaféènì, àti àwọn egbòogi tí ó lè mú àwọn okùn ohùn gbẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́