Ṣàkóso Ìgbésí Ayé Rẹ Nísinsìnyí!
ÌWÁDÌÍ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lórí ìhùwà àti ìsúnniṣe ẹ̀dá ènìyán ti ṣàǹfààní fún wa lọ́nà púpọ̀. Bóyá ó ti ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye tí ó túbọ̀ kún láti kojú àìsàn kan. Lákòókò kan náà, ó bọ́gbọ́n mu láti lo ìṣọ́ra nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ti àbá èrò orí ìmọ̀lára, ní pàtàkì àwọn tí ó jọ pé wọ́n ta ko àwọn ìlànà tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáradára.
Lórí kókó ọ̀rọ̀ apilẹ̀ àbùdá àti ìhùwà, àwọn ìbéèrè yìí dìde: A ha lè yẹ ẹrù iṣẹ́ wa sílẹ̀ kí a má sì gba ẹ̀bi fún ohun tí a ṣe bí? A ha lè ṣe àwáwí tàbí kí a tilẹ̀ dẹ́bi fún ẹnì kan tàbí ohun mìíràn kan fún àìlọ́gbọ́n nínú tàbí àṣìṣe èyíkéyìí, kí a wá tipa bẹ́ẹ̀ máa dara pọ̀ mọ́ àwọn tí iye wọn ń pọ̀ sí i nínú ìran “kì í ṣe ẹ̀bi mi” yìí bí? Rárá o. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ń fi tìfẹ́tìfẹ́ gba oríyìn fún àṣeyọrí èyíkéyìí nínú ìgbésí ayé, nítorí náà kí ní ṣe tí wọn kò ní fẹ́ láti gba ẹ̀bi fún àṣìṣe wọn lọ́nà kan náà?
Nídìí èyí, a lè béèrè pé, Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì Mímọ́, ní láti sọ nípa ẹni tàbí ohun tí ń ṣàkóso ìgbésí ayé wa?
Kí Ni Ojú Ìwòye Bíbélì?
Ohun tí a ní láti kọ́kọ́ mọ̀ ni pé gbogbo wa ni a bí nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà. (Orin Dáfídì 51:5) Ní àfikún, a ń gbé ní àkókò àrà ọ̀tọ̀ kan, tí a pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” nígbà tí àwọn ènìyàn ń nírìírí “àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò.” (Tímótì Kejì 3:1) Èyí túmọ̀ sí pé, ní ti gbogbo ènìyàn lápapọ̀, a ń kojú ìṣòro púpọ̀ nínú lílo àkóso gbígbámúṣé lórí ìgbésí ayé wa ju ti àwọn baba ńlá wa lọ.
Síbẹ̀síbẹ̀, gbogbo ènìyán lómìnira láti yan ipa ọ̀nà tiwọn, wọ́n lè ṣe àwọn yíyàn tiwọn. Dé àyè yẹn, wọ́n ń ṣàkóso ìgbésí ayé wọn. Èyí ti ń rí bẹ́ẹ̀ láti ìgbà ìjímìjí, a sì ti lè rí i nínú ọ̀rọ̀ Jóṣúà sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin óò máa sìn ní òní.”—Jóṣúà 24:15.
Bíbélì sọ pé a ti lé Sátánì Èṣù kúrò ní ọ̀run, ó sì ń lo ipa ìdarí alágbára lórí gbogbo ìran aráyé lápapọ̀ láti ṣe ibi, nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ó tún sọ fún wà pé, kódà, nígbà ayé àpọ́sítélì Jòhánù pàápàá, gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú nì. (Jòhánù Kìíní 5:19; Ìṣípayá 12:9, 12) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè ní ń ṣàkóso gbogbo ìgbésẹ̀ wa, kò sì yan àbáyọrí kan tí òun nìkan mọ̀ nípa rẹ̀ mọ́ wa, kò yẹ kí a ti ẹ̀bi gbogbo àṣìṣe tàbí ìkùna wa sórí Sátánì ní tààràtà. Òtítọ́ Ìwé Mímọ́ tí ń tọ́ni sọ́nà náà ni pé “olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ láti ọwọ́ ìfẹ́ ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà ìfẹ́ ọkàn náà, nígbà tí ó bá ti lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí yìí pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòó wù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni òun yóò ká pẹ̀lú.”—Gálátíà 6:7.
Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run yóò mú wa jíhìn fún ohun tí a bá ṣe lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti má ṣe gbìyànjú láti wí àwíjàre nítorí apilẹ̀ àbùdá wa àti àìpé tí a jogún. Ọlọ́run mú ẹgbẹ́ àwùjọ abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, oníwà ipá, ti Sódómù àti Gòmórà ìgbàanì jíhìn fún àwọn ìwà ìbàjẹ́ wọn. Ó ṣe kedere pé òun kò ka àwọn olùgbé ibẹ̀ sí ẹ̀dá aláìrìnnàkore, tí àá káàánú, tí kò lè ṣàìjẹ́ ẹni búburú nítorí apilẹ̀ àbùdá tí a rò pé ó lábùkù. Lọ́nà jíjọra, àwọn ènìyàn tí ń gbé ní ìgbà ayé Nóà ní àwọn ipá ìdarí ibi púpọ̀ láyìíká wọn; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n ní láti ṣe yíyàn kan, ìpinnu àdáṣe, bí wọn yóò bá la Ìkún Omi tí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sí ìgbà náà já. Àwọn díẹ̀ ṣe yíyàn tí ó tọ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀.
Wòlíì Hébérù náà, Ìsíkẹ́ẹ̀lì, jẹ́rìí sí i pé a ń béèrè fún ṣíṣàkóso àra ẹni bí a bá fẹ́ láti lẹ́tọ̀ọ́ sí ojú rere Ọlọ́run pé: “Ṣùgbọ́n bí ìwọ́ bá kìlọ̀ fún ènìyàn búburú, tí kò sì kúrò nínú búburú rẹ̀, tí kò yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀, yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n ọrùn rẹ mọ́.”—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 3:19.
Ìrànlọ́wọ́ Dídára Jù Lọ Tí Ó Wà
Dájúdájú, gbogbo wa nílò ìrànlọ́wọ́ láti lo ìṣàkóso ara ẹni nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, ìpènijà ni èyí sì jẹ́ fún púpọ̀ lára wa. Àmọ́, kò yẹ kí a bọ́hùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti jogún, òun yóò fún wa ní ìrànlọ́wọ́ dídára jù lọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó—ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti òtítọ́ onímìísí rẹ̀—bí a bá fẹ́ẹ́ ṣàtúnṣe ìhùwà wa. Láìka ìhùwà àtilẹ̀wá èyíkéyìí tí apilẹ̀ àbùdá ń fà tí a lè ní àti àwọn ipá ìdarí òde tí ó lè ní ipa lórí wa sí, a lè ‘bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣe òun àṣà rẹ̀, kí a sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ [ara wa] láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a.’—Kólósè 3:9, 10.
Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ní ìjọ Kọ́ríńtì ṣe àwọn ìyípadà amúnijígìrì kan nínú ìhùwà wọn. Àkọsílẹ̀ onímìísí wí fún wa pé: “Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pamọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra ènìyàn, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀ ohun tí àwọn kan lára yín sì ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”—Kọ́ríńtì Kìíní 6:9-11.
Nítorí náà, bí a bá ń bá àwọn àìpé wa jìjàkadì, ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ fún wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni òde òní ti fi hàn pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwọ́n lè ‘para dà nípa yíyí èrò inú wọn pa dà, kí àwọ́n lè fún ara àwọn ní ẹ̀rí ìdánilójú ìfẹ́ inú Ọlọ́run tí ó dára tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà tí ó sì pé.’ Wọ́n ń fi ohun yòó wù tí ó jẹ́ òótọ́, òdodo, mímọ́ níwà, dídára ní fífẹ́, ìwà funfun, yíyẹ fún ìyìn, bọ́ èrò inú wọn; wọ́n sì ń “bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” Wọ́n ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí líle, wọ́n sì ń tipa lílò ó kọ́ agbára ìwòye wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.—Róòmù 12:2; Fílípì 4:8; Hébérù 5:14.
Ó ń múni lọ́kàn yọ̀ láti mọ̀ nípa àwọn ìjàkadì wọn, ìkùnà onígbà kúkúrú wọn, àti àṣeyọrí wọn nígbẹ̀yìngbẹ́yín pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé yíyí ìhùwà wa padà sábà máa ń kan ọkàn àti ohun tí ó ń fẹ́ pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọ inú rẹ lọ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ; Ìmòye yóò pa ọ́ mọ́, òye yóò sì máa ṣọ́ ọ: Láti gbà ọ́ ní ọwọ́ ẹni ibi.”—Òwe 2:10-12.
Nítorí náà, bí o bá fẹ́ẹ́ fi ìyè àìnípẹ̀kun ṣe ìlépa rẹ nínú ìgbésí ayé—ìgbésí ayé láìsí àwọn ìdààmú ayé búburú, tí ó sì bọ́ lọ́wọ́ àìpé tí ń sọni di aláàárẹ̀—“tiraka” nínú ṣíṣàkóso ìgbésí ayé rẹ nísinsìnyí, sì fi ọgbọ́n àtọ̀runwá ṣamọ̀nà ara rẹ. (Lúùkù 13:24) Ṣàmúlò ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ Jèhófà kí o baà lè mú èso ìkóra ẹni níjàánu jáde. Fi ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ láti mú ìgbésí ayé rẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọ́run, kí o sì ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn náà pé: “Ju gbogbo ohun ìpamọ́, pa àyà rẹ mọ́; nítorí pé láti inú rẹ̀ wá ni orísun ìyè.” (Òwe 4:23) Láti di “ìyè tòótọ́ gidi” nínú ayé tuntun Ọlọ́run mú gírígírí—nínú èyí tí Jèhófà Ọlọ́run yóò ti ṣàtúnṣe gbogbo àbùkù inú apilẹ̀ àbùdá lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpada Jésù Kristi—tóye yẹ fún gbogbo ipá tí o ń sà láti ṣàkóso ìgbésí ayé rẹ̀ nínú ayé yìí!—Tímótì Kìíní 6:19; Jòhánù 3:16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè fún wa lókun àtiṣẹ́pá àwọn àbùkù jíjingíri
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run lórí ìwà híhù gírígírí