ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 10/8 ojú ìwé 31
  • Jíjẹ Nǹkan Tí Yóò Fa Ìpalára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjẹ Nǹkan Tí Yóò Fa Ìpalára
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Igi Tẹ́ẹ́rẹ́ Tó Ń Fọ Eyín Mọ́
    Jí!—2003
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1999
  • Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Ran Ìdílé Kan Lọ́wọ́ Nígbà Ìpọ́njú
    Jí!—2004
Jí!—1996
g96 10/8 ojú ìwé 31

Jíjẹ Nǹkan Tí Yóò Fa Ìpalára

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍŃDÍÀ

ÀWỌN orin kúkúrú apàfiyèsí lórí rédíò ń fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti lò ó. Àwọn gbajúgbajà inú fíìmù ń polówó rẹ̀ nínú tẹlifíṣọ̀n, àwọn ìwé ìròyìn, àti àwọn ìwé agbéròyìnjáde gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń sinni sí ọ̀nà ìgbésí ayé arùmọ̀lára sókè, tí ń buyì kúnni. Àmọ́, ìkọ̀wé wínníwínní ara rẹ̀ kìlọ̀ pé lílo èròjà náà lè pa ọ́ lára. Kí ni ohun náà? Èròjà aṣèpalára, tí ó sì ń di bárakú, tí a mọ̀ sí pan ni.

Éṣíà ni wọ́n ti máa ń lo èròjà pan—wọ́n máa ń lò ó níbi púpọ̀ ní ilẹ̀ Íńdíà. Bí ó ti máa ń rí, àpòpọ̀ hóró èso betel lílọ̀, tábà, àti àwọn èròjà míràn tí ń mú ìtọ́wò dùn ni. Tábà àti hóró èso betel ní ń mú kí èròjà pan di bárakú. A máa ń gbé wọn sórí ewé ata betel tí a na ìfọ̀ ẹfun àti oje kajú sórí rẹ̀, tí í ṣe ìmújáde irúgbìn dídì. A óò fi ewé náà pọ́n ohun tó wà nínú rẹ̀, lẹ́yìn náà, a óò ki odindin rẹ̀ sí ẹnu. Irú rẹ̀ kan tí ó wọ́ pọ̀ ni èròjà pan masala, àwọn èròjà kan náà tí a pò pọ̀ ní gbẹrẹfu, tí a sì dì sínú àwọn àpò kéékèèké tí a lè gbé pẹ̀lú ìrọ̀rùn kí a sì lò ó nígbàkígbà.

Ó máa ń gbà àkókò láti jẹ ẹ́, ó sì máa ń fa itọ́ púpọ̀, tí a ní láti máa tu dànù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ilé tí èròjà pan ti wọ́ pọ̀ ní apẹ ìbẹ́tọ́sí, ṣùgbọ́n tí a kò bá sí nílé, ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ kan tàbí ògiri máa ń di ibi ìbẹ́tọ́sí. Èyí ló ń fa àwọn àbàwọ́n aláwọ̀ ilẹ̀ tí a ń rí lórí àwọn àkàsọ̀ ilé àti ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ àwọn ilé púpọ̀ ní Íńdíà.

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí Àjọ Aṣèwádìí Kúlẹ̀kúlẹ̀ ti Tata ṣe, ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn àrùn jẹjẹrẹ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ ní Íńdíà lọ́dọọdún jẹ́ àrùn jẹjẹrẹ ẹnu—nǹkan bí ìlọ́po méjì ìpíndọ́gba ti àgbáyé. Dókítà R. Gunaseelan, oníṣẹ́ abẹ ẹnu àti párì òkè mọ́ ojú, dara pọ̀ mọ́ àwọn oníṣẹ́ abẹ́ jákèjádò Íńdíà láti di ẹ̀bi náà ru jíjẹ èròjà pan. Ó sọ nínú ìwé agbéròyìnjáde Indian Express pé: “Gbogbo irú èròjà pan ló lè ṣèpalára fún ẹnu.” Ó sọ pé èròjà pan “dájúdájú lè ṣamọ̀nà sí jẹjẹrẹ ẹnu” àti pé “jíjẹ ẹ́ dà bíi fífọwọ́ fa àbùkù ojú.” Nítorí náà, lílo èròjà pan lè túmọ̀ sí jíjẹ nǹkan tí yóò fa ìpalára fúnni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn àrùn jẹjẹrẹ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ ní Íńdíà jẹ́ àrùn jẹjẹrẹ ẹnu

[Credit Line]

Fọ́tò àjọ WHO tí Eric Schwab yà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́