Wíwo Ayé
Ìdáríjini Póòpù
Ìwé ìròyìn L’Osservatore Romano sọ pé gẹ́gẹ́ bí ara ayẹyẹ ẹgbẹ̀rún ọdún tuntun, Póòpù John Paul Kejì ti pòkìkí pé Ọdún Mímọ́ lọdún 2000, ó sì ti nawọ́ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ sáwọn tó bá rìnrìn àjò wá sí Róòmù. Ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ló máa ń yọ àwọn ọmọ Ìjọ Àgùdà nínú ìyà ẹ̀ṣẹ̀. Ìwé ìròyìn Ìjọba Póòpù sọ pé: “Èrè wà fún gbogbo iṣẹ́ rere téèyàn bá ṣe nígbà tó wà nínú oore ọ̀fẹ́.” Àmọ́ o, ìwé ìròyìn kan náà sọ pé àṣà náà tún gbé àwọn ìbéèrè tí ń gba àfiyèsí dìde, àwọn ìbéèrè bíi, “Bí oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run bá wà fún gbogbo wa, kí la tún fẹ́ fi ìdáríjì Ṣọ́ọ̀ṣì ṣe?” àti pé, “Bí Ṣọ́ọ̀ṣì bá lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini pátápátá, kí ló dé tí ìdáríjini rẹ̀ tún máa ń láàlà nígbà míì?”
Àrùn Ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́
Ìwé ìròyìn Toronto Star sọ pé àrùn àìlágbára egungun jẹ́ àrùn ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ tí “ń ṣọṣẹ́ fún àwọn ará Amẹ́ríkà tí iye wọ́n lé ní mílíọ̀nù méjìdínlọ́gbọ̀n àti nǹkan bíi mílíọ̀nù kan ààbọ̀ àwọn ará Kánádà.” Bó ṣe ń ṣe ọkùnrin ló ń ṣe obìnrin, bó ṣe ń ṣe ọmọdé ló ń ṣe àgbà, ó sì “máa ń dé ságọ̀ọ́ ara nígbà tí àwọn èròjà inú egungun tó ti gbó bá tètè ń bà jẹ́ kó tó di pé egungun tuntun wá rọ́pò rẹ̀.” Àwọn tí àìsàn náà ń ṣe lè má tètè mọ̀, àfìgbà tí egungun wọ́n bá ṣẹ́. Àwọn ògbógi gbà pé àwọn ọ̀dọ́langba tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i àtàwọn ọmọ yunifásítì eléré ìdárayá tó ń ṣàṣejù nídìí ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ “ń sọ egungun wọn di ahẹrẹpẹ, egungun tó yẹ kí wọ́n máa fún lókun, kó lè bá wọn kalẹ́. Àwọn ọ̀dọ́ tí ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ kì í jẹ oúnjẹ tó lè mú kí egungun wọ́n gbó keke.” Ìròyìn náà sọ pé “nígbà téèyàn bá máa fi tó ọmọ ọdún méjìdínlógún, nǹkan bí ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo egungun rẹ̀ á ti tóbi dé ìwọ̀n tó lè tóbi dé; nígbà téèyàn bá sì fi dàgbà tó ọgbọ̀n ọdún, egungun rẹ̀ á ti gbó keke.” Ìròyìn náà dámọ̀ràn pé téèyàn bá fẹ́ kí egungun rẹ̀ gbó keke, kí ó ‘máa jẹ àwọn ohun tó ní èròjà káṣíọ̀mù àti fítámì D nínú dáadáa, kí ó máa ṣe eré ìdárayá déédéé, kí ó sì yẹra fún sìgá mímu àti ọtí àmujù.’
Àwọn Èrò Oníjàngbọ̀n Nínú Ọkọ̀ Òfuurufú
Ìwé ìròyìn Business Traveler International sọ pé: “Ìbínú fùfù nínú ọkọ̀ òfuurufú”—èyíinì ni ìwà àìníjàánu táwọn èrò inú ọkọ̀ òfuurufú ń hù—“ti pọ̀ sí i ní ìlọ́po irínwó nínú ọgọ́rùn-ún láàárín ọdún márùn-ún tó ti kọjá.” Kí ló fà á tó fi ròkè lálá báyẹn? Másùnmáwo lohun pàtàkì tó fà á. Àìtètèdé ọkọ̀ tàbí fífagilé ìrìn àjò, tàbí tí ọkọ̀ bá kún jù, àti ìbẹ̀rù fífò lófuurufú, gbogbo rẹ̀ ló ń kó èèyàn láyà sókè, ó sì lè wá yọrí sí ìbínú fùfù. Stuart Howard, tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Tí Ń Mójú Tó Ètò Ìrìn Àjò Àgbáyé sọ pé: “Àwọn iléeṣẹ́ tí ń fi ọkọ̀ òfuurufú kérò máa ń sọ pé ìrìn àjò òfuurufú yá, kò sì ní wàhálà kankan nínú, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀.” Aṣojú iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú pàtàkì kan gbà pé òfin má-mu-sìgá nínú ọkọ̀ òfuurufú wà lára nǹkan tó máa ń fa ìbínú nínú ọkọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ti wí, “àwọn amusìgá tí inú ń bí ló fa èyí tó pọ̀ ju ìdajì wàhálà táwọn èrò fà” nínú ọkọ̀ òfuurufú kan lọ́dún 1997. Nǹkan míì ni ọtí mímu, tó túbọ̀ máa ń pani béèyàn bá ṣe túbọ̀ ń ròkè lálá tó. Kí ni ìròyìn náà dámọ̀ràn pé kí o ṣe bí èrò kan nínú ọkọ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí pariwo? “Má ṣe pe àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ pé kí wọ́n máa bọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, dìde, kí o sì rọra lọ ṣàlàyé ìṣòro náà fáwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀.” Ó tún dábàá pé: “Wá ọgbọ́n dá tí irú ìwà gánrangànran bẹ́ẹ̀ kò fi ní yọ ẹ́ lẹ́nu, nípa mímú ìwé àkàgbádùn dání wá tàbí kí o máa gbọ́ orin atunilára” nínú rédíò kékeré kan.
Ìnáwó Ìsìnkú Ń Pọ̀ Sí I
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ń sun òkú níná báyìí kí ìnáwó ìsìnkú lè dín kù. Ẹgbẹ́ Àwọn Baba-Ǹ-Sìnkú Kárí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé ìpíndọ́gba iye táa fi ń sìnkú ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún [4,600] dọ́là lọ́dún 1996. Ṣùgbọ́n, ìwé ìròyìn Chicago Sun-Times sọ pé, “sísun òkú kò náni ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta dọ́là sí ẹgbàá dọ́là, ó sinmi lórí irú ohun èlò táa fẹ́ fi sun òkú náà, àti irú ìgò táa fẹ́ kó eérú rẹ̀ sí.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, tó bá ṣe pé ẹ fẹ́ sun òkú ni, ẹ ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ra ilẹ̀ tí ẹ máa sìnkú sí àti àwọn nǹkan tẹ́ẹ máa fi sàmì sí ojú oórì, tó lè fi ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún iye owó ìsìnkú pọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn náà sọ pé lára gbogbo àwọn tó kú ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1997, nǹkan bí ìpín mẹ́rìnlélógún nínú ọgọ́rùn-ún ni wọ́n sun, a sì ń retí pé ó máa tó ìpín méjìlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún ní ọdún mẹ́wàá sí i.
Àwọn Àkẹ̀kù Tí Ń Pa Rẹ́ Lọ
Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé àwọn ilẹ̀ táa ti ń rí àwọn àkẹ̀kù ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ti wà láìyingin fún ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún, àmọ́ ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ o, àwọn ìgárá ọlọ́ṣà, àwọn bàsèjẹ́, àtàwọn tí kò rí nǹkan míì ṣe ju pé kí wọ́n máa rìnrìn àjò afẹ́ kiri, ti fẹ́ ba ibẹ̀ jẹ́ báyìí o. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn kan lára àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ń fẹ́ láti kó àwọn àkẹ̀kù tó ṣeyebíye gan-an lọ sáwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí, tàbí kí a máà jẹ́ kí àwọn èèyàn ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ mọ́.” Ṣùgbọ́n o, àwọn míì sọ pé àwọn aráàlú lẹ́tọ̀ọ́ láti rí àkẹ̀kù wọ̀nyí bí wọ́n ṣe wà láti ìgbà ìwáṣẹ̀. Láti lè rí ojútùú sí ìṣòro yìí, Àjọ Àwọn Onímọ̀ Nípa Ohun Àkẹ̀kù Lágbàáyé ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkọsílẹ̀ àwọn ibi táwọn èèyàn ti fẹ́ bà jẹ́ kárí ayé. Ṣùgbọ́n títí di báa ti ń wí yìí, àádọ́ta ibi péré ló ti wà lákọọ́lẹ̀.
Ìtọ́jú Eyín Láìsí Ìròra Kẹ̀?
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbàtọ́jú eyín ni yóò fẹ́ káwọn dókítà eyín ṣíwọ́ lílo òòlù ìyọyín. Ìwé ìròyìn FDA Consumer sọ pé títí dé àyè kan, wọ́n lè ṣíwọ́ lílò ó láìpẹ́. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Àjọ Abójútó Oúnjẹ àti Oògùn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fọwọ́ sí lílo ẹ̀rọ kan tí wọ́n ń pè ní erbium:YAG tí ń lo ìtànṣán iná mànàmáná fún iṣẹ́ abẹ eyín. Ìwé ìròyìn náà sọ pé dípò kí àwọn dókítà eyín máa fi òòlù kékeré yọ eyín tó ti kẹ̀, wọ́n lè máa lo ẹ̀rọ onítànṣán mànàmáná yìí báyìí láti fi yọ ọ́, ní pàtàkì nípa fífi ooru yọ́ ẹran ìdí eyín tó ti kẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ẹ̀rọ tuntun yìí fi sàn ju òòlù tí wọ́n ń lò báyìí. Àǹfààní kan ni pé kì í jẹ́ kí eyín ròòyàn rárá. Fún ìdí yìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó wá gbàtọ́jú eyín kò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa lo àwọn oògùn tàbí abẹ́rẹ́ apàmọ̀lára. Àǹfààní míì ni pé níwọ̀n ìgbà tí dókítà eyín kò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa dúró dìgbà tí ẹ̀jẹ̀ ti sá kúrò ní ẹnu rẹ, ó lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lójú ẹsẹ̀. Ní àfikún, gbogbo ariwo mímì àti dídún òòlù náà kò ní sí mọ́. Àmọ́ o, ìṣòro kan tí ò ṣeé gbójú fò dá tó kù báyìí ni pé ẹ̀rọ tuntun yìí kò ṣeé lò lára eyín tó níhò tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n ti dí.
Pàǹtírí Ohun Èlò Alágbára Átọ́míìkì
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé láti àwọn ọdún 1960, ó ti lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] tọ́ọ̀nù ìdàrọ́ tí iléeṣẹ́ ohun èlò alágbára átọ́míìkì kárí ayé ti tú dàálẹ̀. Òkìtì ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tọ́ọ̀nù sì ń gùn ún lọ́dọọdún. Ibo ni àwọn pàǹtírí tí ń ṣekú pani wọ̀nyí ń lọ? Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ibùdó àwọn ohun èlò wọ̀nyí ni wọ́n to gbogbo rẹ̀ jọ sí tìrìgàngàn.” Àmọ́ o, ìwọ̀nba ẹ̀wádún díẹ̀ ni wọ́n wéwèé pé àwọn pàǹtírí olóró náà yóò fi wà ní ibùdó wọ̀nyí. Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé tó bá yá, yóò di dandan láti kó pàǹtírí ohun èlò alágbára átọ́míìkì lọ síbi tó ṣeé kó o sí fún àkókò pípẹ́. Ṣùgbọ́n ìṣòro tó wà nílẹ̀ ni pé orílẹ̀-èdè kankan kò tíì lè ṣe àjàalẹ̀ tó ṣeé kó pàǹtírí olóró wọ̀nyí sí. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, fún ìdí yìí, “iléeṣẹ́ alágbára átọ́míìkì ti kó sínú pàkúté tí òun fúnra rẹ̀ dẹ.”
Fífarajúwe Máa Ń Pe Ọ̀rọ̀ Wá sí Ìrántí
Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Ìwádìí tuntun fi hàn pé fífaraṣàpèjúwe máa ń jẹ́ kí iyè ẹni tí ń sọ̀rọ̀ sọ sí ọ̀rọ̀ tó wà lọ́kàn rẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń fọwọ́ ṣàpèjúwe bí nǹkan ti tóbi tó tàbí bó ṣe rí, àwọn ọ̀nà ìfaraṣàpèjúwe míì, bíi “ká máa ju apá fìrìfìrì báa ti ń sọ̀rọ̀ lọ,” tún ń ṣiṣẹ́ tó yàtọ̀. Robert Krauss, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìrònú òun ìṣesí ní Yunifásítì Columbia, sọ pé irú ìfaraṣàpèjúwe wọ̀nyí “máa ń rán àwọn èèyàn létí ọ̀rọ̀ tó sá pá wọn lórí” nípa ṣíṣílẹ̀kùn ohun tó pè ní “ilé ọ̀rọ̀.” Àwọn olùwádìí fi irú agbára ìrántí bẹ́ẹ̀ wé ohun tó máa ń sọ síni lọ́kàn nígbà tí òórùn kan, tàbí ìró, tàbí bí kiní kan ṣe rí lẹ́nu, bá ránni létí ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Fún àpẹẹrẹ, ohun tí Brian Butterworth, onímọ̀ nípa iṣan inú ọpọlọ sọ ni pé, gẹ́gẹ́ bí ìtasánsán lọ́fínńdà kan ti lè mú ẹ rántí ìyá rẹ àgbà, fífaraṣàpèjúwe lè jẹ́ kí o rántí ọ̀rọ̀ kan.
Ikú Lẹ́nu Iṣẹ́
Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé náà Le Monde, ròyìn pé kárí ayé, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn ni jàǹbá tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ n pa lójoojúmọ́. Àjọ Ẹgbẹ́ Àwọn Òṣìṣẹ́ Kárí Ayé sì sọ pé àádọ́ta lé rúgba mílíọ̀nù àwọn òṣìṣẹ́ ló ń fara pa lọ́dọọdún, èyí sì ń ṣekú pa mílíọ̀nù kan nínú wọn. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Iye àwọn tí ń kú lẹ́nu iṣẹ́ pọ̀ ju ìpíndọ́gba iye àwọn tí ń kú lọ́dọọdún nínú jàǹbá ojú ọ̀nà (990,000), àwọn tí ń kú nínú ìjà tí wọ́n ti ń lo ohun ìjà (502,000), àtàwọn ìwà ipá míì (563,000), àtàwọn tí àrùn éèdì ń pa (312,000).”
Àjàkálẹ̀ Àrùn Jẹjẹrẹ Ẹnu
Ìwé ìròyìn The Indian Express sọ pé nílùú Delhi, ní Íńdíà, àrùn jẹjẹrẹ ẹnu fi ìlọ́po mẹ́rin ju tìlúu Los Angeles, ní ìpínlẹ̀ California. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ohun tó lé ní ìpín méjìdínlógún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àrùn jẹjẹrẹ tó ń kọlu àwọn ọkùnrin nílùú Delhi jẹ́ àrùn jẹjẹrẹ ẹnu—látorí ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dún 1995. Olórí ohun tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ ẹnu ni jíjẹ ewé tábà, bidis (sìgá àwọn ará Íńdíà), àti pan masala (àpòpọ̀ tábà àti èso bẹ́tẹ́lì lílọ̀, àtàwọn èròjà míì), tí wọ́n máa ń ká sínú ewé, tí wọ́n sì máa ń jẹ lẹ́nu. Ìwé ìròyìn náà sọ pé ohun tí ń dáni níjì ni tàwọn ọmọléèwé tí kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí tòsì, tí púpọ̀ nínú wọn ń jẹ pan masala. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan kìlọ̀ pé àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ gbogbo àwọn ará Íńdíà ni “àjàkálẹ̀ àrùn jẹjẹrẹ ẹnu” á kọ lù.