ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 10/22 ojú ìwé 18-20
  • Èé Ṣe Tí Ọlọ́run Ń Jẹ́ Kí Ohun Búburú Ṣẹlẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Ọlọ́run Ń Jẹ́ Kí Ohun Búburú Ṣẹlẹ̀?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Búburú Kì Í Wá Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run
  • Fífàyègbà Tí Ọlọ́run Fàyè Gba Ìwà Ibi
  • Kókó Ọ̀ràn Kan Tí Ó Kàn Ọ́
  • Jèhófà—Ọlọ́run Onífẹ̀ẹ́ Tí Ń Bìkítà
  • Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègba Ìjìyà?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Pọ̀ Láyé?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ń Jẹ́ Ká Jìyà?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 10/22 ojú ìwé 18-20

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Èé Ṣe Tí Ọlọ́run Ń Jẹ́ Kí Ohun Búburú Ṣẹlẹ̀?

LIDIJA jẹ́ ọ̀dọ́langba kan lásán nígbà tí ogun bẹ́ sílẹ̀ ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ rẹ̀—orílẹ̀-èdè tí a mọ̀ sí Yugoslavia tẹ́lẹ̀. Ó sọ pé: “Mo lo ọ̀pọ̀ ọ̀sán àti òru lábẹ́ òrùlé ṣíṣókùnkùn kan. Nígbà púpọ̀ ni mo ń ní ìdẹwò láti sá jáde, àní bí yóò bá tilẹ̀ yọrí sí ikú pàápàá! Kí ogun tóó dé, a ní gbogbo ohun tí a nílò, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ẹ̀mí ń bẹ la fi ń ṣayọ̀.”

Láìpẹ́, àwọn másùnmáwo àti hílàhílo ogun wáá nípa búburú lórí Lidija lọ́nà tẹ̀mí. Ó sọ pé: “Fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, a kò lè jáde lọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù tàbí lọ sí àwọn ìpàdé. Ní tòótọ́, mo rò pé Jèhófà ń kọ̀ wá sílẹ̀ ni. Mo máa ń bi ara mi léèrè pé, ‘Òun kò ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ nísinsìnyí?’”

Àwọn ogun, ìwà ọ̀daràn, ìwà ipá, àrùn, ìjábá, ìjàm̀bá—àwọn ohun búburú bí ìwọ̀nyí lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ pàápàá. Nígbà tí ọ̀ràn ìbìnújẹ́ tí ó kanni gbọ̀ngbọ̀n bá sì ṣẹlẹ̀, o lè ṣe kàyéfì lọ́nà ti ẹ̀dá pé, ‘Èé ṣe tí Ọlọ́run ń jẹ́ kí àwọn ohun búburú wọ̀nyí ṣẹlẹ̀?’

Àwọn ènìyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́ béèrè irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí wòlíì Hábákúkù rí ipò burúkú tí àwọn àlámọ̀rí àárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run wà, ó dárò pé: “Olúwa, èmi óò ti ké pẹ́ tó, tí ìwọ kì yóò fi gbọ́! tí èmi óò kígbe sí ọ, ní ti ìwà ipá, tí ìwọ kì yóò sì gbà là! Èé ṣe tí o mú mi rí àìṣedéédéé, tí o sì jẹ́ kí n máa wo ìwà ìkà?” (Hábákúkù 1:2, 3) Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ mélòó kan lónìí ń ní irú wàhálà èrò ìmọ̀lára kan náà.

Ṣàgbéyẹ̀wò ìmọ̀lára tí Kristẹni ọ̀dọ́ kan ní lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀. Ó wí pé: “Apá kò ká mi mọ́, mo ń lọgun láti ojú fèrèsé, mo ń ké rara sí Jèhófà Ọlọ́run. . . . Mo dá a lẹ́bi fún ohun gbogbo. Báwo ni èyí ṣe lè ṣẹlẹ̀? Dádì jẹ́ bàbá tí kò láfiwé, àti ọkọ onífẹ̀ẹ́, èyí sì wáá ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí—ṣe Jèhófà kò bìkítà ni?” Lábẹ́ irú ipò yìí, ó wulẹ̀ bá ìwà ẹ̀dá mu láti nímọ̀lára ìdàrúdàpọ̀, ẹ̀dùn, tàbí ìbínú pàápàá. Rántí pé ó da wòlíì Hábákúkù olóòótọ́ pẹ̀lú láàmú pé a jẹ́ kí ìwà ibi máa wà. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹnì kan bá ń bá a lọ láti máa ní ìmọ̀lára ìkorò, ewú wà níbẹ̀. Ó lè di ẹni tí “àyà rẹ̀ bínú sí Olúwa.”—Òwe 19:3.

Nígbà náà, báwo ni o ṣe lè yẹra fún jíjuwọ́ sílẹ̀ fún ìmọ̀lára ìbínú àti ìkorò? Lákọ̀ọ́kọ́, o gbọ́dọ̀ mọ ibi tí àwọn ohun búburú ti ń wá.

Àwọn Ohun Búburú Kì Í Wá Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Bíbélì mú kí ó ṣe kedere pé Ọlọ́run kò fìgbà kankan pète pé kí a máa jìyà báyìí. Ó fi àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ sínú ibùgbé párádísè kan tí kò ti sí ìrora àti ìjìyà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Láìsíyè méjì, o mọ bí nǹkán ṣe dojú rú dunjú: Ẹ̀dá ẹ̀mí tí a kò lè fojú rí kan, tí a wáá mọ̀ sí Èṣù àti Sátánì nígbẹ̀yìn, sún Ádámù àti Éfà láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì, orí 3; Ìṣípayá 12:9) Nípa ṣíṣe èyí, Ádámù kó gbogbo àwọn ọmọ inú rẹ̀ sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àbájáde rẹ̀ tí ń bani nínú jẹ́.—Róòmù 5:12.

Ní kedere, kì í ṣe Ọlọ́run ló mú ohun búburú wá sórí ìran ènìyàn, bí kò ṣe ènìyàn fúnra rẹ̀. (Diutarónómì 32:5; Oníwàásù 7:29) Ní gidi, gbogbo ohun búburú tí àwọn ènìyàn ń fojú winá lónìí—àìsàn, ikú, ogun, àìṣèdájọ́ òdodo—jẹ́ àbájáde mímọ̀ọ́mọ̀ tí Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn. Síwájú sí i, gbogbo wa ni ohun tí Bíbélì pè ní “ìgbà àti èṣe” ń ṣẹlẹ̀ sí. (Oníwàásù 9:11) Àti ẹni búburú àti olódodo ní ń fara gbá àwọn ìjàm̀bá àti ọ̀ràn ìbìnújẹ́ òjijì.

Fífàyègbà Tí Ọlọ́run Fàyè Gba Ìwà Ibi

Nígbà tí ó jẹ́ ohun ìtùnú láti mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ni orísun ìwà ibi, síbẹ̀, o lè ṣe kàyéfì pé, ‘Èé ṣe tí ó fi yọ̀ǹda kí ìwà ibi máa bá a lọ?’ Lẹ́ẹ̀kan sí i, èyí rọ̀ mọ́ àwọn kókó ọ̀ràn tí a gbé dìde ní Édẹ́nì. Ọlọ́run sọ fún Ádámù pé bí ó bá ṣàìgbọràn, yóò kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Bí ó ti wù kí ó rí, Èṣù sọ fún Éfà pé bí ó bá jẹ nínú igi tí a kà léèwọ̀ náà, kì yóò kú! (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Nípa bẹ́ẹ̀, Sátánì pe Ọlọ́run ní elékèé. Síwájú sí i, Sátánì dọ́gbọ́n sọ pé ènìyàn yóò túbọ̀ jàǹfààní bí ó bá ń ṣe àwọn ìpinnu rẹ̀ fúnra rẹ̀, tí kò sì ní láti máa dúró kí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ohun tí ó ní láti ṣe fún un!

Ọlọ́run kò lè wulẹ̀ gbójú fo àwọn ìfẹ̀sùn kanni wọ̀nyí. Ìwọ ha ti rí akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ kan tí ń pe ọlá àṣẹ olùkọ́ níjà rí bí? Bí olùkọ́ náà bá jẹ́ kí ó mú un jẹ, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn pẹ̀lú yóò bẹ̀rẹ̀ sí í yájú. Lọ́nà kan náà, ìdàrúdàpọ̀ ì bá ti rú jáde níbi gbogbo, ká ní Jèhófà kò ko Sátánì lójú ní tààràtà. Jèhófà ṣe ìyẹn nípa yíyọ̀ǹda fún ènìyàn láti tẹ̀ lé ọ̀nà ìṣeǹkan ti Sátánì. Ènìyàn ha ti ń gbádùn òmìnira bíi ti Ọlọ́run tí Sátánì ṣèlérí rẹ̀ bí? Rárá. Ìṣàkóso Sátánì ti mú ìsọdahoro àti àìláyọ̀ wá, tí ń fi í hàn bí òpùrọ́ oníkúpani!

Ọlọ́run yóò ha fàyè gba ìwà ibi láti máa bá a lọ títí láé bí? Rárá. Láti yanjú àwọn kókó ọ̀ràn tí Sátánì gbé dìde, Ọlọ́run yóò mú òpin dé bá gbogbo ìwà ibi láìpẹ́. (Orin Dáfídì 37:10) Ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe yẹ kí a máa kojú rẹ̀ ní báyìí ná?

Kókó Ọ̀ràn Kan Tí Ó Kàn Ọ́

Ṣíwájú ohun gbogbo, kọ́kọ́ mọ̀ pé kókó ọ̀ràn yìí láàárín Ọlọ́run àti Sátánì kàn ọ́! Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ṣàyẹ̀wò ìwé Bíbélì tí a pè lórúkọ ọkùnrin olóòótọ́ náà, Jóòbù. Nígbà tí Ọlọ́run tọ́ka sí Jóòbù gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ olùjọ́sìn olóòótọ́, Sátánì dáhùn pé: “Jóòbù ì bá ha jọ́sìn rẹ bí kò bá rí ohun kan gbà níbẹ̀ bí?” (Jóòbù 1:9, Today’s English Version) Ní gidi, Sátánì jiyàn pé, bí a bá yọ̀ǹda fún òun láti dààmú ènìyàn, òún lè yí ènìyàn èyíkéyìí padà kúrò nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run!—Jóòbù 2:4, 5.

Sátánì ti tipa báyìí fọ̀rọ̀ èké ba gbogbo ènìyàn olùbẹ̀rù Ọlọ́run lórúkọ jẹ́. Ó ti fọ̀rọ̀ èké bà ọ́ lórúkọ jẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, Òwe 27:11 wí pé: “Ọmọ mi, kí ìwọ kí ó gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn; kí èmi kí ó lè dá ẹni tí ń gàn mí lóhùn.” Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí o bá jọ́sìn Ọlọ́run, láìka àwọn ìṣòro aronilára sí, o ń ṣèrànwọ́ láti fi Sátánì hàn bí elékèé ní ti gidi!

A gbà pé, nígbà tí àwọn ohun búburú bá ń ṣẹlẹ̀ sí wa, kì í rọrùn láti ronú lórí àwọn kókó ọ̀ràn tí ó rọ̀ mọ́ ọn. Diane, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá péré nígbà tí ìyá rẹ̀ kú, sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí pé, àwọn àdánwò tí n óò kojú nínú ìgbésí ayé mi yóò mú kí n di aláìnímọ̀lára tàbí ẹlẹ́dùn ọkàn.” Bí ó ti wù kí ó rí, mímọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi ti ràn án lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye yíyẹ nípa ìṣòro rẹ̀. Nísinsìnyí, ó wí pé: “Àní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tí ó ṣòro láti dojú kọ wà nínú ìgbèsí ayé mi, ọwọ́ Jèhófà ń wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.”

Diane rán wa létí kókó pàtàkì kan: Jèhófà kò retí pé kí a máa dá kojú àwọn pákáǹleke wọ̀nyí pẹ̀lú agbára tiwa fúnra wa. Orin Dáfídì 55:22 fún wa ní ìdánilójú pé: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Olúwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró: òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.” Kotoyo ọ̀dọ́ rí i pé èyí jẹ́ òtítọ́. Ó dojú kọ ọ̀ràn ìbìnújẹ́ nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ kú nínú ìsẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé ní Kobe, Japan, ní 1995. Nígbà tí ó ń gbẹnu sọ fún ara rẹ̀ àti àwọn àbúrò rẹ̀, ó wí pé: “Nítorí pé màmá mi kọ́ wa láti fọkàn tẹ Jèhófà, a lè fara dà á.”

Nípa ti Lidija, ọ̀dọ́mọdébìnrin tí a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ ńkọ́? Bí àkókò ti ń lọ, ó wáá mọ̀ pé Jèhófà kò kọ òun sílẹ̀ rárá. Ó sọ nísinsìnyí pé: “Jèhófà wà fún wa nígbà gbogbo. Ó ṣamọ̀nà wa, ó sì darí àwọn ìgbésẹ̀ wa.”

Jèhófà—Ọlọ́run Onífẹ̀ẹ́ Tí Ń Bìkítà

Ìwọ pẹ̀lú lè rí ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nígbà tí àwọn ohun búburú bá ṣẹlẹ̀ sí ọ. Èé ṣe? Nítorí pé Jèhófà ń bìkítà nípa rẹ! Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń yọ̀ǹda fún ohun búburú láti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere, ó ń pèsè ìtùnú onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú. (Kọ́ríńtì Kejì 1:3, 4) Ọ̀nà kan tí ó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni. O lè rí ‘àwọn ọ̀rẹ́ tí ó fi ara mọ́ni ju arákùnrin lọ,’ níbẹ̀, tí wọ́n lè fún ọ lókun nígbà tí ọ̀ràn tí ó kan èrò ìmọ̀lára bá ṣẹlẹ̀. (Òwe 18:24) Kotoyo rántí pé: “Láti ọjọ́ kejì ìsẹ̀lẹ̀ náà, a lọ sí ibi tí àwọn ará kóra jọ pọ̀ sí, a sì gba ìṣírí àti àwọn ohun kòṣeémánìí. Ìyẹn mú kí n nímọ̀lára ààbò. Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní Jèhófà àti àwọn ará, mo rò pé a lè fara da ohunkóhun.”

Nítorí tí Jèhófà mọ̀ ọ́ bí ẹnì kan, ó tún lè bójú tó àwọn àìní rẹ nígbà tí ohun búburú bá ṣẹlẹ̀. Daniel padà ronú sẹ́yìn lórí bí ó ṣe kojú ikú bàbá rẹ̀, ó wí pé: “Jèhófà ń di bàbá ẹni, ètò àjọ rẹ̀ sì ń pèsè àwọn ọkùnrin tẹ̀mí fúnni gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe. Nígbà gbogbo ni Jèhófà ń pèsè ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí ǹ bá máa bá dádì mi jíròrò lọ́nà àdánidá.” Diane ti nírìírí àbójútó onífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ́nà kan náà láti ìgbà tí ìyá rẹ̀ ti kú. Ó sọ pé: “Nípasẹ̀ àwọn àgbàlagbà tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí, tí wọ́n ń pèsè ìṣírí, ìdarísọ́nà, àti ìmọ̀ràn, ó ti tọ́ mi sọ́nà, ó sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti kojú ìrẹ̀wẹ̀sì èyíkéyìí.”

Dájúdájú, kì í ṣe ohun dídùn mọ́ni láti máa nírìírì ohun búburú. Ṣùgbọ́n, ní ìtùnú nípa mímọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀. Máa rán ara rẹ létí léraléra pé Ọlọ́run yóò ṣàtúnṣe ìṣòro náà láìpẹ́ láìjìnnà. Họ́wù, a óò pa gbogbo ohun tí ì bá máa múni rántí àwọn ohun búburú tí ó ti ṣẹlẹ̀ síni rí rẹ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín! (Aísáyà 65:17; Jòhánù Kìíní 3:8) Nípa lílo àǹfààní gbogbo ìpèsè tí Ọlọ́run ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ kí a lè kojú wọn, o lè ṣe ipa tìrẹ ní fífi Sátánì hàn ní elékèé. Láìpẹ́, ‘Ọlọ́run yóò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú rẹ.’—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Láìpẹ́, Jèhófà yóò fòpin sí gbogbo ohun búburú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́