ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 11/8 ojú ìwé 26-27
  • Ìtọ́sọ́nà Ta Ni O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtọ́sọ́nà Ta Ni O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọwọ́ Ọlọ́run Ń Darí Àwọn Ènìyàn Rẹ̀
  • Gbá Ọwọ́ Ọlọ́run Mú Ṣinṣin!
  • ‘Ẹ Dúró Gbọn-in Kí ẹ Sì Rí Ìgbàlà Jèhófà’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • ‘Jáà Ni Ìgbàlà Mi’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Iṣẹ́ Ìyanu ní Òkun Pupa
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ọlọ́run Dá Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Nídè
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 11/8 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ìtọ́sọ́nà Ta Ni O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?

BÀBÁ kan ké sí ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún márùn-ún pé: “Ó yá ká lọ!” Bàbá náà na ọwọ́ sí i, ọmọkùnrin náà kò sì lọ́ra bí ó ti nawọ́, tí ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ kóńkó gbá àwọn ìka bàbá rẹ̀ mú. Ibi yòó wù kí ìrìn àjò náà lè gbé wọn lọ, ọmọ náà gbẹ́kẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà òbí rẹ̀, ó sì ń tẹ̀ lé e pẹ̀lú ìgbọ́kànlé. Ohun yòó wù kí ó ṣẹlẹ̀, ibi tí ọmọ náà ti dì í mú pinpin kò jẹ́ já.

Níwọ̀n bí a ti ń gbé ní àkókò tí ọrọ̀ ajé, ìṣèlú, àti ipò nǹkan ti ara ẹni kò dáni lójú, ìwọ kò ha ní tẹ́wọ́ gba ọwọ́ atọ́nisọ́nà kan láti orísun tí o lè gbẹ́kẹ̀ lé láìmikàn bí? Síbẹ̀, a ń gbé ní àkókò kan tí àwọn ẹni ibi ń fi àwọn tí wọn kò nírìírí ṣèfà jẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, ìdí rere wà láti ṣọ́ra nípa irú ẹni tí a ń gbẹ́kẹ̀ lé. Bóyá a ti já ọ kulẹ̀ pátápátá nígbà kan rí, nígbà tí ẹnì kan tí o gbọ́kàn lé fún ìtọ́sọ́nà já ọ kulẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì fún wa níṣìírí láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Wòlíì Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ pé: “Nítorí èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, èmi óò wí fún ọ pé, Má bẹ̀rù; èmi ó ràn ọ́ lọ́wọ́.” (Aísáyà 41:13) Àpọ́sítélì Pétérù sì gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí òún lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ̀yín ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó ń bìkítà fún yín.”—Pétérù Kìíní 5:6, 7.

Síbẹ̀, o lè béèrè pẹ̀lú èrò rere pé, ‘Kí ni ìdí tí mo ṣe ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà?’ A rí àwọn ìdí gbígbéṣẹ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí nínú àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì.

Ọwọ́ Ọlọ́run Ń Darí Àwọn Ènìyàn Rẹ̀

Ọ̀wọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó parí sí alẹ́ Nísàn 14, ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, sọ ète Fáráò afiṣẹ́ninilára àti àwọn ará Íjíbítì dòfo, kí wọ́n baà lè tú àwọn ènìyàn Ọlọ́run, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, sílẹ̀ kúrò lóko ẹrú. (Ẹ́kísódù 1:11-13; 12:29-32) Ní Nísàn 15, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun náà dorí kọ ọ̀nà aginjù lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. Ọ̀nà tí ó ṣe tààràtà jù lọ sí ibẹ̀ ni ti àríwá Mémúfísì, ní etíkun Mẹditaréníà, tí ó sún mọ́ ilẹ̀ tí àwọn Filísínì tí a bẹ̀rù náà ń gbé, ó sì dé Ilẹ̀ Ìlérí náà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ní ọ̀nà míràn lọ́kàn.—Ẹ́kísódù 13:17, 18; Númérì 33:1-6.

Ọlọ́run pèsè ìtọ́sọ́nà tí ó ṣeé fojú rí fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, tí ó fara hàn bí ọwọ̀n ìkúukùu ní ọ̀sán àti ọwọ̀n iná ní òru. (Ẹ́kísódù 13:21, 22) Pa pọ̀ pẹ̀lú àràmérìíyìírí àdánidá yìí, Jèhófà lo ọkùnrin olùṣòtítọ́ náà, Mósè, gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Ẹ́kísódù 4:28-31) Nítorí náà, ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro wà pé ọwọ́ Ọlọ́run ń tọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́nà.

Ní ibi ìpàgọ́ wọn kejì, Étámù, “létí ijù,” Jèhófà darí Mósè láti yí padà, kí wọ́n sì pàgọ́ sí etí Òkun Pupa, ní Píháhírótì. (Ẹ́kísódù 13:20) Ìgbésẹ̀ tí ó jọ pé a kò lè ṣàlàyé yìí mú kí Fáráò parí èrò sí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “há ní ilẹ̀ náà.” Fáráò yí ọkàn padà nígbà tí a ki í láyà. Ní báyìí tí ó ti ṣe tán láti tún kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́rú padà, ó kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lépa wọn.—Ẹ́kísódù 14:1-9.

Nípa kíkó orílẹ̀-èdè gba ọ̀nà míràn, lọ sínú ohun tí ó dájú pé ó jẹ́ pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó já sí Òkun Pupa, ó jọ pé Mósè ń ṣètò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà tí àwọn òkè ńlá yóò fi ká wọn mọ́ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àgọ́ ní Píháhírótì, Òkun Pupa, àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò tí ń sún mọ́ wọn bọ̀. Ó jọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wá di ohun àfojúsùn rírọrùn tí a lè tètè tẹ̀ lórí ba tàbí kí a pa run.

Ipa wo ni èyí ní lórí wọn? Wọn óò ha fi ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìtọ́sọ́nà Jèhófà hàn bí? Nínú gbogbo ohun tí a lè fojú rí, ipò náà kò láyọ̀lé. Nítorí náà, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣojo. Kódà, àwọn mìíràn tún bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè. Àwọn mìíràn tilẹ̀ ti ṣe tán láti juwọ sílẹ̀, kí wọ́n sì padà sí oko ẹrú ní Íjíbítì.—Ẹ́kísódù 14:10-12.

Gbá Ọwọ́ Ọlọ́run Mú Ṣinṣin!

Nínú ipò yìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti fi ìgbẹ́kẹ̀lé bíi ti ọmọdé kan hàn nínú Olódùmarè. Gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà kò mọ̀ pé Jèhófà ní ète rere fún fífún Mósè ní ìtọ́ni láti sọdá Òkun Pupa ní Píháhírótì. Nípa mímú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá sí Ilẹ̀ Ìlérí ní ìhà gúúsù ilẹ̀ àwọn Filísínì, Jèhófà fi ìjìnlẹ̀ òye onífẹ̀ẹ́ hàn. Lẹ́yìn ọdún 215 ní Íjíbítì, kò sí iyè méjì púpọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò múra sílẹ̀ fún ogun pẹ̀lú orílẹ̀-èdè tí ó ní àwọn jagunjagun ewèlè. Nítorí náà, Jèhófà yan ọ̀nà kan tí yóò yẹ irú ìforígbárí bẹ́ẹ̀ sílẹ̀.a—Ẹ́kísódù 13:17, 18.

Ìdáǹdè orílẹ̀-èdè náà àti bí wọ́n ṣe ṣẹ́gun Fáráò àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ní Òkun Pupa jẹ́rìí lọ́nà àgbàyanu sí agbára ìdáǹdè tí Ọlọ́run ní. Síwájú sí i, ẹ wo bí ọpẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí ó jẹ́ pé, bí wọn kò tilẹ̀ mọ ìdí tí Ọlọ́run ṣe tọ́ wọn sọ́nà lọ́nà pàtàkì kan, wọn kò já ọwọ́ Ọlọ́run jù sílẹ̀, ṣe pọ̀ tó! Wọ́n gbá a mú ṣinṣin, wọ́n sì rí yíya Òkun Pupa sí méjì lọ́nà ìyanu àti pípa àwọn ọ̀tá wọn run. Ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú ìtọ́sọ́nà Jèhófà ni a san èrè fún.—Ẹ́kísódù 14:19-31.

Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ jẹ́ kí a ronú nípa àpẹẹrẹ ọmọ kan tí ó di ọwọ́ òbí kan mú. Bí ọmọ kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn, báwo ni yóò ṣe hùwà padà? Dípò jíjọ̀wọ́ rẹ̀ tàbí dídẹwọ́ ìwàmú rẹ̀, ọmọ náà yóò fún ọwọ́ rẹ̀ kóńkó náà pinpin mọ́ àwọn ìka òbí rẹ̀. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó ń fi ìgbẹ́kẹ̀lé aláìyingin hàn pé òbí náà yóò fún òun ní ìtọ́sọ́nà àti okun tí kò lè kùnà nígbà ìṣòro.

Lọ́nà jíjọra, tí a bá ń ní wàhálà nínú ìgbésí ayé wa, a ní láti dì í mú pinpin, kí a sì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run sí i! Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, lè di ìmọ́lẹ̀ tí ń tọ́ wa sọ́nà. (Orin Dáfídì 119:105) Bákan náà, rántí pé sùúrù máa ń bá ìgbẹ́kẹ̀lé rìn. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ fún Jèhófà lákòókò láti yanjú àwọn nǹkan, kódà fún sáà àkókò díẹ̀, a lè ṣàìlóye ìdí tí ó fi ń tọ́ wa sí irú ipa ọ̀nà kan lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni, a lè gbẹ́kẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.—Ẹ́kísódù 15:2, 6; Diutarónómì 13:4; Aísáyà 41:13.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí Píháhírótì, wo Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 638 sí 639, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́