Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Fi Ń Jẹ Gbèsè
MICHAEL àti Reena ṣayẹyẹ àjọ̀dún ọdún kìíní ìgbéyàwó wọn nípa pípadà lọ sí ibi tí wọ́n ti lo ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì ẹ̀yìn ìgbéyàwó wọn. Ṣùgbọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kejì ìgbéyàwó wọn, wọ́n fojú kojú pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí kò bára dé. Láìka bí wọ́n ṣe ń ṣọ́ nǹkan lò sí, wọn kò lè san gbogbo owó tí wọ́n ní láti san.
Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn tọkọtaya mìíràn. Robert ní ẹ̀yáwó akẹ́kọ̀ọ́ kékeré kan láti san nígbà tí ó gbé Rhonda níyàwó, aya rẹ̀ sì ní owó láti san lórí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ nìkan. Robert sọ pé: “Àwa méjèèjì ń ṣiṣẹ́ lójú méjèèjì, àwa méjèèjì sì ń gba 2,950 dọ́là lóṣooṣù. Ṣùgbọ́n kò gbé wa dé ibì kankan.” Rhonda sọ pé: “A kò tí ì ra nǹkan tí ó pọ̀ jù tàbí kí a ṣe ohunkóhun láṣejù. Ibi tí owó wa ń gbà lọ kò yé mi ṣá.”
Robert àti Rhonda kì í ṣe ọ̀lẹ. Bẹ́ẹ̀ sì ni Michael àti Reena pẹ̀lú. Kí ni ìṣòro wọn? Gbèsè káàdì ìrajà àwìn. Láàárín ọdún àkọ́kọ́ ìgbéyàwó wọn, Michael àti Reena jẹ gbèsè 14,000 dọ́là lórí káàdì ìrajà àwìn wọn. Lẹ́yìn ọdún méjì tí wọ́n ṣègbéyàwó, àròpọ̀ gbèsè Robert àti Rhonda lórí káàdì ìrajà àwìn wọ́n jẹ́ 6,000 dọ́là.
Anthony, baálé ilé kan tí ó ti lé ní ogójì ọdún, kojú ìṣòro ọ̀ràn ìnáwó nínú ìgbésí ayé rẹ̀ pẹ̀lú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìṣòro rẹ̀ kò tan mọ́ káàdì ìrajà àwìn. Ní 1993, ilé iṣẹ́ tí ó ti ń ṣiṣẹ́ dín iye òṣìṣẹ́ kù, ipò iṣẹ́ alábòójútó tí Anthony wà, tí wọ́n ti ń san 48,000 dọ́là fún un lọ́dún, bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, pípèsè fún ìdílé rẹ̀ ẹlẹ́ni mẹ́rin wá di ìpènijà ńlá fún un. Lọ́nà jíjọra, agbára káká ni Janet, òbí anìkàntọ́mọ kan tí ń gbé New York City, fi ń rí owó tí ó tó láti gbọ́ bùkátà pẹ̀lú nǹkan bí 11,000 dọ́là tí ń wọlé fún un lọ́dọọdún.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ òtítọ́ pé a lè dín ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìṣòro owó kù nípa níná an lọ́nà bíbẹ́tọ̀ọ́mu, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé a ń gbé ní sànmánì tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wà ní ipò àìláǹfààní nípa rírìn “nínú àìlérè èrò inú wọn.” (Éfésù 4:17) Grace W. Weinstein sọ nínú ìwé rẹ̀, The Lifetime Book of Money Management, pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìlànà ọ̀ràn ìnáwó ni ètò ọrọ̀ ajé, àwọn ọ̀nà ìṣarasíhùwà tuntun sípa ìnáwó àti ìfowópamọ́, àti ọ̀nà ìgbésí ayé tí ń yí padà, tí kò ṣeé sọ tẹ́lẹ̀, ti yí padà, tí ó sì ti dorí rẹ̀ kodò.” Nínú ayé tí ó ti dojú rú pátápátá tí a ń gbé, ó túbọ̀ ń ṣòro sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti bójú tó ọ̀ràn ìnáwó tiwọn àti ti ìdílé wọn.
Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, Michael àti Reena, Robert àti Rhonda, Anthony, àti Janet ti tiraka láti bójú tó ọ̀ràn ìnáwó wọn pẹ̀lú àṣeyege. Kí a tó ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò irú ìpèsè ìnáwó tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, tí ó dá kún ìṣòro owó tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ní—ìyẹn ni káàdì ìrajà àwìn.