ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 1/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Iye Ẹni Tí Ń Darúgbó ní China”
  • Àwọn Ọmọdé Aṣiṣẹ́gbowó —Ìṣòro Kan Tí Ń Gbilẹ̀ Sí I
  • Kíkájú Àìní Àwọn Ọmọdé
  • “Oríṣi Ogun Èròjà Opium Tuntun”
  • A Kẹ̀yìn sí Ìgbàgbọ́ Nínú Iná Ọ̀run Àpáàdì
  • Akọni Abo Ìnàkí
  • Yà Mú Tìrẹ
  • A So Sìgá Mímu Pọ̀ Mọ́ Ikú Àwọn Ọmọdé
  • Ìwádìí Lórí Ẹ̀jẹ̀ Tú Àṣírí
  • Iná Mọ́ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Tábà
    Jí!—1996
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
  • Ayé Kan Tí Sìgá Mímu Ti Di Bárakú Fún
    Jí!—2000
Jí!—1997
g97 1/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

“Iye Ẹni Tí Ń Darúgbó ní China”

Ìwé ìròyìn China Today sọ pé: “Iye ẹni tí ń darúgbó ní China ń pọ̀ sí i láìdábọ̀. Nígbà tí ọdún 1994 fi parí, China ní 116.97 mílíọ̀nù arúgbó tí ó ti lé ní ẹni 60 ọdún, ó jẹ́ ìbísí ìpín 14.16 nínú ọgọ́rùn-ún sí ti 1990.” Àwọn ènìyàn tí ó ti lé ní ẹni 60 ọdún nísinsìnyí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo olùgbé orílẹ̀-èdè náà, iye àwọn arúgbó sì ti ń pọ̀ sí i ní ìwọ̀n tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po mẹ́ta ìbísí iye ènìyàn lápapọ̀. Báwo ni a ṣe ń bójú tó wọn? Nígbà tí a ń fi owó ọ̀yà, owó àjẹmọ́nú ìfẹ̀yìntì, owó ìbánigbófò onípò, àti owó ìrànwọ́ bójú tó àìní àwọn púpọ̀, iye tí ó lé ní ìpín 57 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn arúgbó ní China ni àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ìbátan mìíràn ń bójú tó. Ìwé ìròyìn China Today sọ pé: “Níwọ̀n bí ipò ìbátan ìdílé ṣì fẹsẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà kan ṣáá ní China, tí China sì ní àṣà rere ti bíbọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà àti bíbójútó wọn, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn arúgbó ń gbé ọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn, àwọn yẹn sì ń bójú tó wọn dáradára. Kìkì ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn arúgbó ilẹ̀ China ní ń dá gbé fúnra wọn.”

Àwọn Ọmọdé Aṣiṣẹ́gbowó —Ìṣòro Kan Tí Ń Gbilẹ̀ Sí I

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé ṣe láìpẹ́ yìí, ìpín 13 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ọlọ́dún 10 sí 14 lágbàáyé—nǹkan bíi mílíọ̀nù 73 àwọn ọmọdé—ni a ń fipá mú ṣiṣẹ́. Ìròyìn náà fi kún un pé bí àkọsílẹ̀ oníṣirò bá wà nípa àwọn ọmọdé tí kò tó ọmọ ọdún mẹ́wàá àti àwọn ọmọbìnrin tí ń fi gbogbo àkókò ṣiṣẹ́ abẹ́lé, ó ṣeé ṣe kí iye agbo àwọn ọmọdé aṣiṣẹ́gbowó wọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọ tí ó fìdí kalẹ̀ sí Geneva náà ti ń gbìyànjú láti gbógun ti kí àwọn ọmọdé máa ṣiṣẹ́ gbowó láti 80 ọdún sẹ́yìn, ìṣòro náà ti ń bí sí i, ó sì ń gbòòrò sí i, ní pàtàkì ní ilẹ̀ Áfíríkà àti Latin America. Nígbà tí iṣẹ́ ẹrú àti àwọn ipò iṣẹ́ eléwu jẹ́ ìpín àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé wọ̀nyí, ìṣòro kan gbòógì tí a mẹ́nu bà ni iṣẹ́ aṣẹ́wó. Ìròyìn náà sọ pé, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, “àwọn àgbàlagbà ń rí bíbá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe bí ọ̀nà dídára jù lọ láti dènà kíkó [fáírọ́ọ̀sì HIV].” Ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune ti Paris sọ pé, àjọ náà “dẹ́bi fún àwọn aláṣẹ ìjọba tí . . . wọ́n ti ṣàìka ìṣòro náà sí.”

Kíkájú Àìní Àwọn Ọmọdé

Ìtẹ̀jáde The State of the World’s Children 1995, ìròyìn kan tí àjọ UNICEF (Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé) ṣe, sọ pé kò bọ́gbọ́n mu láti ronú pé àgbáyé kò lè kájú àwọn kòṣeémánìí ṣíṣe kókó tí àwọn ọmọdé nílò. Láti ṣàpèjúwe kókó wọn, àjọ UNICEF fúnni ní àwọn kókó oníṣirò wọ̀nyí: Àfikún ìnáwó tí a fojú bù láti kájú àìní kárí ayé fún ìjẹunrekánú àti ìtọ́jú ìlera ìpìlẹ̀ púpọ̀ tó jẹ́ bílíọ̀nù 13 dọ́là lọ́dún; fún ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, bílíọ̀nù 6 dọ́là; fún fífa omi dáradára àti ìmọ́tótó, bílíọ̀nù 9 dọ́là; fún ìfètò-sọ́mọ-bíbí, bílíọ̀nù 6 dọ́là—ó jẹ́ àròpọ̀ bílíọ̀nù 34 dọ́là lọ́dún. Wọ́n wí pé, fi ìyẹn wéra pẹ̀lú iye tí a fojú bù pé a ti ń ná lọ́dún sórí àwọn nǹkan wọ̀nyí: bọ́ọ̀lù golf, 40 bílíọ̀nù dọ́là; ọtí bíà àti wáìnì, 245 bílíọ̀nù dọ́là; sìgá, 400 bílíọ̀nù dọ́là; ìnáwó ológun, 800 bílíọ̀nù dọ́là. Wọ́n sọ pé, ó dájú pé a lè bójú tó gbogbo ọmọdé lágbàáyé bí a bá gbé àwọn ohun àkọ́múṣe yíyẹ kalẹ̀.

“Oríṣi Ogun Èròjà Opium Tuntun”

Bẹ́ẹ̀ ni ìwé agbéròyìnjáde The Times of India ṣe ṣàpèjúwe ìsapá torítọrùn tí àwọn ilé iṣẹ́ tábà United States ń ṣe láti rọni láti ra àwọn ohun àṣejáde wọn ní Éṣíà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò dín sí mílíọ̀nù kan ènìyàn tí àwọn àrùn tí ó tan mọ́ tábà ń pa lọ́dọọdún, ní Íńdíà nìkan, ìjọba ilẹ̀ Íńdíà kò tí ì ṣe òfin kankan lòdì sí tábà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Times náà ṣe wí, èyí jẹ́ nítorí ìpákúbẹ́kúbẹ́-rọni lílágbára tí àwọn ilé iṣẹ́ tábà, lábẹ́lé àti lẹ́yìn odi, ń ṣe, pa pọ̀ pẹ̀lú “àwọn òfin àpapọ̀ orílẹ̀-èdè United States tí ń halẹ̀ láti gbẹ́sẹ̀ lé òwò àjọṣe pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bá fàyè gba títa àwọn àṣejáde tábà ilẹ̀ United States.” A fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ìpín 99 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí ń gbé àrọko Íńdíà kò mọ̀ nípa ewu kankan tí tábà lílo ń mú wá. Àwọn ìpolówó ọjà ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde sábà máa ń fi amusìgá kan hàn bí adára-ẹni-lójú, tí ó fani mọ́ra, tí ó sì láàbò. Àwọn ilé iṣẹ́ tábà ní ń ṣonígbọ̀wọ́ àwọn ìdíje pàtàkìpàtàkì nínú àwọn eré ìdárayá lílókìkí, bí eré cricket. Sìgá tún jẹ́ orísun amówówọlé pàtàkì kan fún ìjọba, tí ó ti dókòwò lórí ilé iṣẹ́ sìgá mẹ́rin.

A Kẹ̀yìn sí Ìgbàgbọ́ Nínú Iná Ọ̀run Àpáàdì

Ìròyìn kan láti ọwọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ England ti kọ ojú ìwòye àtọwọ́dọ́wọ́ pé hẹ́ẹ̀lì jẹ́ ibi oníná àti ìdálóró ayérayé sílẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú ìròyìn náà, tí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì náà gbé jáde, “àwọn Kristẹni ti jẹ́wọ́ àwọn ìmọ̀ ìsìn ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀, tí ó sọ Ọlọ́run di àǹjọ̀nú tí ń bani láyọ̀ jẹ́ kan, tí ó sì ń dá àpá ńlá sínú èrò orí àwọn ènìyàn púpọ̀.” Ó fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà fún ìyípadà yí, ṣùgbọ́n lára wọn ni ìfẹ̀hónúhàn oníwà rere láti inú àti láti ẹ̀yìn òde ìsìn Kristẹni lòdì sí ẹ̀sìn ìbẹ̀rù, àti ìmọ̀lára tí ń pọ̀ sí i náà pé, èrò orí nípa Ọlọ́run kan tí ó yan àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ sínú ìdálóró ayérayé yàtọ̀ pátápátá sí ìṣípayá ìfẹ́ Ọlọ́run nínú Kristi.” Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n sọ pé, ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣì dojú kọ ọjọ́ ìdájọ́ kan, àti pé, àwọn tí wọ́n bá kùnà ìdánwò náà ni a óò fi sínú ipò ìparun kan, tàbí ipò àìsí. Ìwé agbéròyìnjáde Herald Tribune ti New York sọ pé: “Ìròyìn náà mú kí ó ṣe kedere pé, kò sí ṣíṣeéṣe pé gbogbo ènìyàn láti inú gbogbo ìsìn ni a óò gbà là láìjanpata.”

Akọni Abo Ìnàkí

Ọmọdékùnrin ọlọ́dún mẹ́ta kan kó sínú àhámọ́ kan tí a kó àwọn ìnàkí ilẹ̀ Áfíríkà méje sí ní Ọgbà Ẹranko Brookfield, ní àgbègbè àrọko kan ní Chicago, ọ̀kan lára àwọn abo ìnàkí náà sì gbà á là. Ọmọdékùnrin náà, tí ó ti ṣìnà kúrò lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀, gun ọgbà onírin tí ó ga ní sẹ̀ǹtímítà 122, ó sì já sórí kọnkéré ibi ìṣàfihàn náà tí ó jìn tó mítà mẹ́fà, ó sì fi orí ṣèṣe. Ìnàkí ọlọ́dún mẹ́jọ náà, Binti Jua—èdè Swahili tí ó túmọ̀ sí “ọmọbìnrin ìtànṣan oòrùn”—rìn lọ síbẹ̀, ó sì rọra gbé ọmọ tí ó ṣèṣe náà. Bí Binti ti pọn ọmọ tirẹ̀ gan-an sẹ́yìn, ó gbé ọmọ náà mọ́ra gẹ̀gẹ̀, ó sì gbé e lọ sí ẹnu ọ̀nà ibi iṣẹ́ àwọn olùtọ́jú ọgbà ẹranko náà, ní gbígbé e síbi tí àwọn olùtọ́jú náà yóò ti rí i. Ìwé agbéròyìnjáde Daily News ti New York ròyìn pé, “àwọn olùtọ́jú ọgbà ti kọ́” Binti, tí ìyá tirẹ̀ gan-an ti pa tì, “lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀nà tí ìyá fi ń tọ́ ọmọ, nípa fífún un ní àwọn ọmọláńgidi ìṣeré ọmọdé láti tọ́ àti láti bójú tó,” kí ó tóó bí ọmọ tirẹ̀. Láti ìgbà náà wá ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ti ṣèbẹ̀wò sí ibẹ̀, tí wọ́n sì fi ẹ̀bùn èso san oore fún un. Ọmọdékùnrin náà, tí ara rẹ̀ bó, tí ó sì fi ara ha nǹkan, kọ́fẹ pa dà.

Yà Mú Tìrẹ

Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn New Scientist béèrè pé: “O ha bẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun lọ́nà kan tí kò dùn mọ́ ọ bí? Má ṣèyọnu, ó kéré tán, ó ku ọdún tuntun 14 fún ọ lágbàáyé láti yàn lára wọn.” Ní tòótọ́, àwọn orílẹ̀-èdè tí ń lo kàlẹ́ńdà ti Gregory nìkan ní ń ṣírò January 1 bí ọjọ́ kìíní nínú ọdún. Julius Caesar ló pinnu pé ọdún kàlẹ́ńdà náà yóò máa bẹ̀rẹ̀ ní January 1, ní ọdún 46 ṣáájú Sànmánì Tiwa, tí wọn kò sì yí i pa dà nígbà tí Póòpù Gregory ń ṣàtúnyẹ̀wò kàlẹ́ńdà ní ọdún 1582. Bí àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe ń ṣàgbékalẹ̀ kàlẹ́ńdà tiwọn, àwọn Ọjọ́ Ọdún Tuntun tí ó jẹ yọ kò dín sí 26. Lára àwọn tí ó kù lónìí, èyí ti àwọn ará China gbé kalẹ̀ ni ó lọ́jọ́ lórí jù lọ. Ní tiwọn, Ọdún Tuntun bẹ̀rẹ̀ ní February 7 ọdún yìí. Ọdún Tuntun Àwọn Júù yóò bẹ̀rẹ̀ ní October 2. Kàlẹ́ńdà àwọn Mùsùlùmí, tí ó gbára lé oṣù ojú ọ̀run pátápátá, yóò ní ọjọ́ tirẹ̀ pẹ̀lú—May 8.

A So Sìgá Mímu Pọ̀ Mọ́ Ikú Àwọn Ọmọdé

Àwọn olùwádìí ará Britain sọ pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èéfín tábà kan àwọn ọmọdé àti àwọn aboyún rárá. Ìwádìí ọlọ́dún méjì tí Ilé Ìwòsàn Aláyélúwà fún Àwọn Abirùn Ọmọ, ní Bristol, ṣe, ṣàyẹ̀wò gbogbo ọ̀ràn ikú òjijì àwọn ọmọdé (SIDS), tí a tún mọ̀ sí ikú àwọn ọmọdé, ní ẹkùn ilẹ̀ mẹ́ta ní England. Ní bíbéèrè ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn òbí àwọn ọmọ 195 tí ó kú àti àwọn òbí àwọn 780 ọmọ tí ó yè, wọ́n rí i pé, lára àwọn ìyá tí àwọn ọmọ wọn kú, ìpín 62 nínú ọgọ́rùn-ún ní ń mu sìgá, ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún tí ń mu sìgá lára àwọn ìyá tí ọmọ wọn yè. Joyce Epstein, ti Àjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ikú Ọmọ Ọwọ́, sọ pé: “Ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ mú un ṣe kedere pé, àwọn bàbá tí ń mu sìgá pẹ̀lú jẹ́ ìṣòro kan. Bí a bá lè mú gbogbo ọ̀ràn sìgá mímu kúrò láyìíká ọmọdé, a fojú díwọ̀n pé ikú àwọn ọmọdé [àwọn ọ̀ràn ìṣẹ̀lẹ̀ SIDS] yóò dín kù ní ìwọ̀n ìpín 61 nínú ọgọ́rùn-ún.”

Ìwádìí Lórí Ẹ̀jẹ̀ Tú Àṣírí

A ti ṣèwádìí fínnífínní lórí èròjà hemoglobin fún iye ọdún tí ó lé ní 60, a sì ti gbọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ èròjà protein tí a ṣèwádìí lé lórí jù lọ nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè. Ó ti pẹ́ tí a ti mọ̀ pé ó máa ń gbé afẹ́fẹ́ oxygen láti inú ẹ̀dọ̀fóró lọ sínú àwọn ìṣù ẹran ara, ó sì máa ń dá carbon dioxide àti nitric oxide pa dà. Síbẹ̀, ó ya àwọn oníṣègùn àti àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lẹ́nu nígbà tí àwọn àwárí lọ́ọ́lọ́ọ́ tọ́ka sí i pé ó ní àfikún iṣẹ́ tó ń ṣe—ti gbígbé oríṣi ìdìpọ̀ èròjà nitric oxide yíyàtọ̀ kan, tí a ń pè ní nitric oxide àrà ọ̀tọ̀, lọ sí gbogbo ara. Èròjà nitric oxide àrà ọ̀tọ̀ ń kó ipa pàtàkì kan ní gidi nínú ìlera àti mímú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì àti àwọn ìṣù ẹran ara máa wà láàyè nìṣó, títí kan bíbójú tó agbára ìrántí àti agbára ìkẹ́kọ̀ọ́, ìmárale fún ìbálòpọ̀, àti ìwọ̀n ìfúnpá. Nípa dídíwọ̀n èròjà nitric oxide tí ń wọnú òpó ẹ̀jẹ̀ ara, èròjà hemoglobin lè mú kí àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ fẹ̀ tàbí sún kì. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé: “Ó ṣeé ṣe kí àwárí náà nípa ṣíṣe kókó lórí ọ̀nà ìtọ́jú ìwọ̀n ìfúnpá àti ìṣèmújáde ẹ̀jẹ̀ àtọwọ́dá.” Ní báyìí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àfidípò ẹ̀jẹ̀ máa ń mú kí ìwọ̀n ìfúnpá ga sókè. Àwọn olùwádìí náà sọ pé, èyí lè jẹ́ nítorí pé wọn kò ní èròjà nitric oxide àrà ọ̀tọ̀ nínú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́