Fífomijé Fúnrúgbìn, Fífìdùnnú Kórè
“GBÁDÙN àkókò ìfẹ̀yìntì rẹ ní Sípéènì tí oòrùn ti máa ń ràn gan-an!” Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ará Europe ti tẹ́wọ́ gba ìpè fífanimọ́ra yìí, wọ́n sì ti kó lọ síbẹ̀. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún 59, èmi pẹ̀lú pinnu láti ta ohun gbogbo, kí n sì kó kúrò ní ilẹ̀ England lọ sí Sípéènì, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wá ju ìtànṣán oòrùn àti fàájì lọ.
Mo yàn láti lọ sí Santiago de Compostela—ọ̀kan nínú àwọn ìlú tí òjò ti ń rọ̀ jù lọ ní Sípéènì—níwọ̀n bí góńgó mi ti jẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan dípò kí n wulẹ̀ máa yáàrùn. Ọdún 22 lẹ́yìn náà, àwọn àyíká ipò ti fipá mú kí n pa iṣẹ́ ìsìn ìjíhìnrere mi ní Sípéènì tì, níbi tí mo ti lọ nítorí àìní fún iṣẹ́ ìsìn yẹn pọ̀ níbẹ̀. Ó ti jẹ́ ìpinnu mi láti pa dà lọ, mo sì ti ṣàṣeyọrí níkẹyìn nísinsìnyí.
Ṣùgbọ́n mímú ara bá ipò náà mu kò rọrùn tó bí mo ṣe rò pé yóò rí. Oṣù àkọ́kọ́ dẹ́rù bà mí! N kò lè rántí ìgbà kankan tí ó rẹ̀ mí tó bẹ́ẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi. Mo ń gbé ilé gbéetán kan ní àjà kẹrin, láìsí ẹ̀rọ agbéniròkè. Lójoojúmọ́, mo máa ń ròkè rodò ní àwọn òpópó olókè ti Santiago, ní gígun àìlóǹkà àkàsọ̀ ilé, bí mo ti ń gbìyànjú láti wàásù ìhìn rere náà fún ọ̀pọ̀ ènìyàn bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Lẹ́yìn oṣù atánnilókun yẹn, iyè méjì bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun tì mí. Ǹjẹ́ ìpinnu títọ̀nà ni mo ṣe bí? Mo ha ti dàgbà jù fún irú ìgbòkègbodò yìí ni bí?
Bí ó ti wù kí ó rí, ní oṣù kejì, okun mi bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bí agbára ọ̀tun tí asáré ẹlẹ́mìí ẹṣin kan ń ní. Ní gidi, mo bọ́ sí ọ̀kan lára àwọn sáà aláyọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ìdùnnú kíkórè lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí mo ti fomijé fúnrúgbìn. (Orin Dáfídì 126:5) Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.
Àkókò Ìdùnnú
Èmi àti ìyàwó mi, Pat, kó lọ sí Sípéènì ní 1961. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ìjọba kò fàṣẹ sí ìgbòkègbodò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ìlú ńlá Seville, níbi tí nǹkan bí ènìyàn 25 ti ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà ni ibi iṣẹ́ àyànfúnni ìwàásù wa.
Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ́jọ́ kan, mo bá ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Faransé tí ń kun ilé kan sọ̀rọ̀. Lọ́jọ́ kejì, obìnrin kan wáá bá èmi àti ìyàwó mi, ó sì béèrè bóyá a ti bá ọkùnrin kunlékunlé kan sọ̀rọ̀ lánàá. Ó sọ pé ọkọ òun, Francisco, ni. Ọkùnrin náà ti fún un ní àpèjúwe tí ó péye tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi lè dá wa mọ̀ lọ́gán tí ó rí wa. Ó sọ fún wa pé: “Ó wà nílé nísinsìnyí, bí ẹ óò bá fẹ́ láti bẹ̀ ẹ́ wò.”
Láìfi àkókò ṣòfò, a tẹ́wọ́ gba ìkésíni yìí, láìpẹ́, ìdílé náà lódindi sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wa. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí Francisco fi pa dà sí ilẹ̀ Faransé nítorí ètò ọrọ̀ ajé. Ó mú wa dààmú. Yóò ha wá Àwọn Ẹlẹ́rìí kàn bí? Bí ó ti wù kí ó rí, láìpẹ́ lẹ́yìn tí ó lọ, a rí lẹ́tà tí ó fi ọkàn wa balẹ̀ gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé ọ̀gá òun tuntun ti béèrè lọ́wọ́ òun nípa iye ìsìn tí ń bẹ ní Sípéènì.
Francisco fìṣọ́ra ṣàlàyé pé: “Tóò, méjì ló wà, Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì.” Níwọ̀n bí iṣẹ́ wa kò tí ì ní ìtìlẹ́yìn òfin, ó rò pé kò níí bọ́gbọ́n mu láti sọ jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀gá rẹ̀ béèrè pé: “Ṣé ó dá ọ lójú?”
Francisco dáhùn pé: “Tóò, mẹ́ta ló wà ní ti gidi, mo sì wà lára ẹ̀kẹ́ta—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Ọ̀gá rẹ̀ fèsì pé: “Ó dùn mọ́ mi láti gbọ́ bẹ́ẹ̀. Mo jẹ́ ìránṣẹ́ kan nínú ìjọ rẹ!” Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an, Francisco lọ sí ìpàdé ìjọ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
A gbé wa kúrò ní Seville lọ sí Valencia ní 1963, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí a tún fi gbé wa lọ sí Barcelona. Níbẹ̀ ni mo ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò. Lẹ́yìn náà, a rán wa pa dà sí Valencia láti ṣiṣẹ́ sìn nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò ní àgbègbè yẹn. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mélòó kan lẹ́nu ìgbòkègbodò dídùnmọ́ni jọjọ yìí, Pat bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìṣòro àìlèmú ara rẹ̀ dúró. Láìpẹ́, kò lè rìn. Bẹ́ẹ̀ ni àkókò tí a ‘fomijé fúnrúgbìn’ ṣe bẹ̀rẹ̀.—Orin Dáfídì 126:5.
Àkókò Omijé
Tìlọ́ratìlọ́ra, a fi Sípéènì sílẹ̀, a lọ gba ìwòsàn ní ilẹ̀ England. Kí ló fa àwọn àmì àrùn tí Pat ní? Ó jẹ́ àrùn ìlegbagidi iṣan inú ọpọlọ tàbí ti ògóró ẹ̀yìn, àrùn abanilárajẹ́ kan tí ó máa ń sọni di abirùn díẹ̀díẹ̀. Bí àkókò ti ń lọ, nítorí àwọn ohun mìíràn tí ó ń fà àti àwọn ìṣòro tí ó tan mọ́ ọn, ó lè yọrí sí ikú.
A ní ìṣòro gidigidi láti mú ìgbésí ayé wa bá àrùn yí mu, kí a sì gbà á bó ṣe rí. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀, a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ onísáàmù náà pé: “Olúwa yóò gbà á [ẹnikẹ́ni tí ń ro ti àwọn aláìní] ní ìyànjú lórí ẹní àrùn.”—Orin Dáfídì 41:3.
Fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá, a ń kó kúrò ní ilé kan bọ́ sí òmíràn. Ariwo kò bá Pat lára mu rárá, a sì ń gbìyànjú láti rí ibi tí ó dára tó fún un láti máa gbé—èyí tí a wáá mọ̀ lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ pé kò ṣeé ṣe. Pat ní láti fi lílo kẹ̀kẹ́ arọ kọ́ra. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè gbọ́únjẹ, kí ó sì ṣe àwọn nǹkan mìíràn yọrí, àìlèrìnkiri rẹ̀ mú un sorí kọ́. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ẹni tí ó máa ń lọ síhìn-ín, lọ sọ́hùn-ún tẹ́lẹ̀, àìlera yìí jẹ́ orísun másùnmáwo ti èrò ìmọ̀lára fún un.
Okun Àtomijé
Mo kọ́ bí mo ṣe lè ran Pat lọ́wọ́ láti dìde, kí ó jókòó, kí ó wọṣọ, kí ó wẹ̀, kí ó bọ́ sórí bẹ́ẹ̀dì, kí ó sì sọ̀ kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì. Lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé tún jẹ́ ìpèníjà kan. Ó gba ìsapá gidigidi láti múra wa sílẹ̀. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí ó wà fún wa láti máa lókun tẹ̀mí nìṣó ni kí a máa bá àwọn Kristẹni arákùnrin wa kẹ́gbẹ́.
Ọdún 11 ni mo fi tọ́jú Pat nílé, tí mo sì ń ṣe iṣẹ́ ayàwòrán ilé lọ́sàn-án. Níkẹyìn, a rí i pé, nítorí ìlera rẹ̀ tí ń jó rẹ̀yìn, ó nílò àkànṣe ìtọ́jú tí n kò lè fún un. Nítorí náà, ó ń gbé ilé ìwòsàn kan láàárín ọ̀sẹ̀, mo sì ń tọ́jú rẹ̀ nílé ní ìparí ọ̀sẹ̀.
Lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán lọ́jọọjọ́ Sunday, mo máa ń gbé Pat lọ sí Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, tí ó jẹ́ gbogbo ìpàdé tí ó ṣeé ṣe fún un láti lọ ní àkókò náà. Lẹ́yìn náà, mo ń gbé e pa dà lọ sílé ìwòsàn. Ọ̀nà ìgbàṣeǹkan tí kò yí pa dà náà máa ń mú mi káàárẹ̀, ṣùgbọ́n ó tóyeyẹ, nítorí tí ó ń mú kí Pat ní okun tẹ̀mí. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń ṣe kàyéfì nípa bí mo ṣe lè forí tì í pẹ́ tó, ṣùgbọ́n Jèhófà fún mi lókun láti máa bá a nìṣó. Ní àràárọ̀ ọjọ́ Saturday, mo máa ń ṣáájú fún àwùjọ kan nínú iṣẹ́ ìwàásù kí n tóó lọ gbé Pat nílé ìwòsàn. Mo rí i pé ìgbòkègbodò Kristẹni mi ń mú kí n lè máa bá a lọ ní gbogbo àkókò pákáǹleke yìí.
Láàárín àkókò náà, Pat ń ṣe ohun tí ó lè ṣe láti wàásù ìhìn rere náà. Ní ilé ìwòsàn, ó ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì pẹ̀lú àwọn nọ́ọ̀sì tí ń tọ́jú rẹ̀. Ọ̀kan tí ń jẹ́ Hazel tẹ̀ síwájú dé orí yíya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó bani nínú jẹ́ pé Pat kò lè lọ síbi ìrìbọmi Hazel, nítorí pé ó kú ní àkókò díẹ̀ ṣáájú, ní July 8, 1987.
Ikú Pat jẹ́ àkókò fún ìtura òun ìbànújẹ́ lápapọ̀. Ó jẹ́ ìtura láti rí i pé ìrora rẹ̀ dópin, ṣùgbọ́n mo ní ìbànújẹ́ jíjinlẹ̀ nítorí pípàdánù alábàákẹ́gbẹ́ mi. Ikú rẹ̀ fi ìmọ̀lára òfo ńláǹlà kan sílẹ̀.
Ìdùnnú Lákọ̀tun
Bí ó tilẹ̀ dà bí nǹkan tí kì í sábà ṣẹlẹ̀, èmi àti Pat ti pinnu ohun tí mo gbọ́dọ̀ ṣe lẹ́yìn náà. Níwọ̀n bí a ti jọ mọ̀ pé ìgbésí ayé rẹ̀ ń sún mọ́ òpin, a sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà dídára jù lọ tí mo lè gbà ṣiṣẹ́ sin Jèhófà lẹ́yìn ikú rẹ̀. Ìpinnu àjùmọ̀ṣe wa ni pé, kí n pa dà sí Sípéènì, sídìí iṣẹ́ àyànfúnni tí a ti pa tì tipátipá.
Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí Pat kú, mo rìnrìn àjò lọ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Sípéènì láti mọ ibi tí mo ti lè ṣiṣẹ́ sìn dáradára jù lọ. Mo gba iṣẹ́ àyànfúnni gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, a sì yàn mí síṣẹ́ ní ìlú ńlá ìgbàanì, tí òjò ti máa ń rọ̀ gan-an, Santiago de Compostela.
Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, mo gba lẹ́tà kan láti ọ́fíìsì ẹ̀ka, tí ń fún mi ní àdírẹ́sì olùfìfẹ́hàn kan tí ń jẹ́ Maximino. Lẹ́yìn tí mo ti gbìyànjú láti rí i nílé fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, mo bá a pàdé níkẹyìn. Maximino, tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìtọ́jú àyíká nílé ìwòsàn àdúgbò kan, ti gba ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Igbesi-aye ninu Aye Titun alalaafia kan, ó sì ti béèrè fún ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.a Nígbà tí mo ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ti ka ìwé náà nígbà mẹ́ta. Ó tọrọ àforíjì pé òun kò ka Bíbélì tó bẹ́ẹ̀ rí—‘apá ògbólógbòó’ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré, àti ‘apá tuntun’ lẹ́ẹ̀mejì. Ó ṣe gbogbo èyí nígbà tí ó ń retí pé kí ẹnì kan bẹ̀ ẹ́ wò.
Ó tún sọ fún mi pé òun ti lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kí òun lè wà ní ọ̀kan nínú àwọn ìpàdé wa. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí pé ojú ń tì í gidigidi, kò wọ ibi ìpàdé náà. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì lọ sí àwọn ìpàdé lọ́sẹ̀ kan náà. Ó fi ìháragàgà tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣòro fún un gan-an láti jáwọ́ lára àṣà tábà mímu. Pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún un níkẹyìn láti fi ìsọdibárakú tábà mímu náà sílẹ̀, ó sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí a ti batisí nísinsìnyí.
Ìdùnnú Púpọ̀ Sí I, Omijé Púpọ̀ Sí I
Ní ọdún kan péré lẹ́yìn tí mo pa dà sí Sípéènì, a ké sí mi pé kí n wáá ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣùgbọ́n kí n tóó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àyànfúnni yẹn, ìgbésí ayé mi tún yí pa dà láìròtẹ́lẹ̀. Mo bá aṣáájú ọ̀nà kan tí ń jẹ́ Paquita, tí ń ṣiṣẹ́ sìn nítòsí Santiago pàdé. Opó tí ó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni. Láìpẹ́, a rí i pé a bá ara wa dọ́gba lọ́nà púpọ̀. Ní 1990, ní oṣù mẹ́fà péré lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ arìnrìn-àjò náà, a ṣègbéyàwó—ìdùnnú lẹ́ẹ̀kan sí i.
Bíi tèmi, Paquita ti ‘ń fomijé fúnrúgbìn.’ Ọ̀ràn ìbànújẹ́ ló ba iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe jẹ́. Ọkọ rẹ̀ kú nínú ìjàǹbá ọkọ̀ kan nígbà tí ó ń kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ilé lọ sí ilé wọn tuntun ní Orense—ọkọ̀ akẹ́rù kan tí ń bọ̀ yà bàrà sí ojú ọ̀nà tí òun ń gbà lọ. Paquita àti ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́wàá ti wà ní Orense nígbà tí wọ́n fi gbọ́ ìròyìn ikú rẹ̀. Láìka àdánù ńlá náà sí, Paquita bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ bí ó ṣe wéwèé rẹ̀ ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn ìsìnkú náà.
Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyẹn, Paquita ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nìṣó. Lẹ́yìn náà ni ọ̀ràn ìbànújẹ́ tún ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìjàǹbá ọkọ̀ míràn tún pa ọmọbìnrin rẹ̀, tí ó ti di ọmọ ọdún 23 nígbà náà. Ìrora náà kàmàmà, ẹ̀dùn ọkàn náà sì gba àkókò gígùn. Bíi ti tẹ́lẹ̀, ìgbòkègbodò Kristẹni rẹ̀, àti ìtìlẹ́yìn tí ó rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe kókó fún ìkọ́fẹpadà rẹ̀. Mo di ojúlùmọ̀ Paquita ní 1989, ọdún méjì péré lẹ́yìn ikú ọmọbìnrin rẹ̀.
Láti ìgbà tí a ti ṣègbéyàwó ní 1990, a ti ń ṣiṣẹ́ sìn nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò ní Sípéènì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọdún díẹ̀ tí ó kọjá wọ̀nyí ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn sáà tí ń tẹ́ni lọ́rùn nínú ìgbésí ayé wa, a kò kábàámọ̀ pé a ti fojú winá àwọn àdánwò. Ó dá wa lójú pé, wọ́n ti mú wa gbára dì lọ́nà rere.—Jákọ́bù 1:2-4.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí Mo Ti Kọ́
Mo gbà gbọ́ pé, kódà, àwọn àdánwò tí ó le koko jù lọ ní apá ṣíṣàǹfààní tiwọn, nítorí pé wọ́n ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn àdánwò kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ ìjẹ́pàtàkì ẹ̀mí ìfọ̀rànrora-ẹni-wò, ànímọ́ pàtàkì kan fún Kristẹni alábòójútó. Bí àpẹẹrẹ, láìpẹ́ yìí, mo bá Kristẹni arákùnrin kan, tí ó ní ọmọkùnrin abirùn kan sọ̀rọ̀. Mo lóye dáadáa nípa ìsapá ńláǹlà tí ó ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní gbígbé ọmọkùnrin rẹ̀ lọ sí gbogbo ìpàdé. Lẹ́yìn ìjíròrò wa, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ mi, ó sì sọ pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí ẹnì kankan tí ì lóye àwọn ìṣòro tí òun àti ìyàwó òun ń dojú kọ ní ti gidi.
Ẹ̀kọ́ pàtàkì míràn tí mo kọ́ ni pé, kí n máa gbára lé Jèhófà. Nígbà tí gbogbo nǹkan bá ń lọ déédéé, a lè nítẹ̀sí láti gbára lé okun àti agbára tiwa fúnra wa. Ṣùgbọ́n nígbà tí àdánwò líle koko kan bá ń bá a lọ láti ọdún dé ọdún, tí a kò sì lè fi okun tiwa fúnra wa kápá rẹ̀, a ń kọ́ láti gbára lé Jèhófà. (Orin Dáfídì 55:22) Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run mú kí n lè máa bá a nìṣó.
Dájúdájú, èyí kò túmọ̀ sí pé ó sábà máa ń rọrùn fún mi. Mo gbọ́dọ̀ gbà pé nígbà àìlera ìyàwó mi àkọ́kọ́, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, inú máa ń bí mi, tí mo sì máa ń bọ́hùn nítorí ipò mi, pàápàá, nígbà tí ó bá rẹ̀ mí. Lẹ́yìn náà, mo ń dá ara mi lẹ́bi fún ìmọ̀lára mi. Mo bá alàgbà aláàánú kan, tí ó ní ìrírí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa títọ́jú àwọn aláìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ, sọ̀rọ̀. Ó mú un dá mi lójú pé mo ń ṣe dáradára lábẹ́ ipò tí mo wà, àti pé, ó wọ́pọ̀ gan-an pé kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé máa ṣe àṣìṣe lọ́nà yí nígbà tí wọ́n bá ń kojú pákáǹleke èrò ìmọ̀lára fún ìgbà pípẹ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi àti Paquita ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wa gan-an nísinsìnyí, n kò rò pé a jẹ́ fojú yẹpẹrẹ wo àwọn ìbùkún wa láé. Jèhófà ti san èrè fún wa lọ́nà púpọ̀, ó sì ti fún wa ní iṣẹ́ kan tí ń tẹ́ni lọ́rùn ṣe, ọ̀kan tí a lè jùmọ̀ máa ṣe. Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyẹn, àwa méjèèjì fomijé fúnrúgbìn, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé a ń fìdùnnú kórè.—Gẹ́gẹ́ bí Raymond Kirkup ṣe sọ ọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Èmi àti Paquita jùmọ̀ ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa