Gbin Àwọn Èèhù Tìrẹ Fúnra Rẹ
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ HAWAII
O HA máa ń wá ẹ̀fọ́ tútù, tí ń bẹ́ sèrésèré lẹ́nu, tí ó sì ń ṣara lóore, tì ní ọjà àdúgbò rẹ bí? Tóò, máà wá a kiri mọ́! Nípa lílo àkókò àti ìsapá mímọníwọ̀n, o lè gbin ẹ̀fọ́ ní ilé tàbí ibùgbé tìrẹ fúnra rẹ. Báwo? Nípa gbígbin àwọn èèhù!
Ó rọrùn láti bójú tó àwọn èèhù débi pé ọmọdé kan lè ṣe é. Ó gba ìwọ̀nba àyè díẹ̀, láìsí ilẹ̀ gbígbẹ́, oko ríro, àti fífi àwọn kẹ́míkà da ara ẹni láàmú. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, o lè jẹ irè rẹ láàárín ọjọ́ mẹ́rin tàbí márùn-ún péré lẹ́yìn tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í hù! Ṣùgbọ́n àwọn àǹfààní ibẹ̀ ju ti ìmúǹkanrọrùn lásán lọ.
Ohun kan ni pé, àwọn èèhù ń ṣara lóore—bóyá, wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ju ẹ̀wà tàbí hóró irúgbìn lásán lọ. Ìwé The Beansprout Book, tí Gay Courter kọ, sọ pé: “Bí àwọn hóró irúgbìn náà ṣe ń bẹ̀rẹ̀ sí í hù ni àwọn èròjà fítámì wọn pẹ̀lú ń bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà. Nínú ìwádìí kan tí a ṣe ní Yunifásítì Pennsylvania, a rí i pé àtètèyọ ẹ̀wà sóyà (nínú hóró irúgbìn ìwọ̀n 100 gíráàmù [nǹkan bí ounce 4]) tí ó kọ́kọ́ yọ jáde ń ní èròjà fítámì C ní ìwọ̀n mílígíráàmù 108 péré. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn wákàtí 72, ìwọ̀n èròjà fítámì C inú rẹ̀ ti lọ sókè sí 706 mílígíráàmù!”
Àwọn èèhù kì í náni lówó gọbọi pẹ̀lú. Ní gidi, ó ṣeé ṣe kí o ti ní gbogbo irinṣẹ́ tí o máa nílò.
Bíbẹ̀rẹ̀
Lákọ̀ọ́kọ́, o nílò ohun ìkóǹkansí kan. Ì báà jẹ́ ìgò tàbí ike ìkóǹkansí, ìkòkò tí kì í ṣe onímẹ́táàlì, ìsúnsẹ̀ onígò tàbí alámọ̀, tàbí àwo kan tí ó jinnú ti dára tó. Ó tilẹ̀ tún ṣeé ṣe láti lo àwo kan tí kò jinnú, ní fífún ìpele hóró irúgbìn kan sí àárín ìpele ìdànǹdán tàbí pépà ìnuǹkan méjì tí wọ́n tutù, kí wọ́n má baà gbẹ. Ohun ìkóǹkansí yòó wù kí o yàn, rí i dájú pé ó fẹ̀ tó láti gba àwọn hóró irúgbìn náà láyè àtidàgbà, kí afẹ́fẹ́ díẹ̀ sì lè máa fẹ́ sí wọn. Mo ti rí i pé ìgò ìkóǹkansí kan dára púpọ̀ fún àwọn hóró irúgbìn tí ó wẹ́ wuuru bí alfalfa. Àwọn hóró irúgbìn tí ó túbọ̀ tóbi, irú bí ẹ̀wà mung, lè ṣe dáradára sí i nínú àwo tàbí ìkòkò tí ó jinnú gan-an. Èyí ń pèsè àfikún àyè tí wọ́n nílò, ó sì ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ jíjẹrà tàbí kíkan.
Ìwọ yóò nílò ìbòrí kan fún ohun ìkóǹkansí rẹ. Ìbòrí oníke kan, abala ìdànǹdán kan, tàbí ògbólógbòó ìbọ̀sẹ̀ oníláílọ́ọ̀nù kan ti dára tó. Gbogbo ohun tí ó gbà láti fi dì í mọ́ ẹnu ohun ìkóǹkansí náà ni ìdiǹkan onírọ́bà kan tí ó lágbára tàbí okùn. Dájúdájú, níwọ̀n bí o ti gbọ́dọ̀ máa ṣan hóró irúgbìn náà lẹ́ẹ̀mejì lóòjọ́, ó kéré tán, ìwọ yóò tún nílò omi, àti bóyá, asẹ́ kan láti máa fi sẹ́ omi kúrò nínú ohun ìkóǹkansí náà.
Níkẹyìn, ìwọ yóò nílò àwọn hóró irúgbìn. A lè fi hóró irúgbìn èyíkéyìí tí o ṣeé jẹ ṣe èèhù. (Bí ó ti wù kí ó rí, èmi máa ń ṣọ́ra láti yẹra fún àwọn hóró irúgbìn tí a ti po kẹ́míkà mọ́.) Hóró irúgbìn ẹ̀wà mung tàbí ti alfalfa ni ó dára jù fún ẹnì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Ó rọrùn láti gbìn wọ́n, wọ́n sì ń dùn gan-an! Ní báyìí, jẹ́ kí n wáá sọ bí a ṣe ń ṣe é fún ọ.
Gbígbin Èèhù Tìrẹ Fúnra Rẹ
ỌJỌ́ KÌÍNÍ: Bu omi kún inú ohun ìkóǹkansí rẹ títí tí yóò fi bo hóró irúgbìn tàbí ẹ̀wà náà ní nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà márùn-ún. Rẹ hóró irúgbìn náà fún wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́wàá, ó kéré tán. O lè rẹ hóró irúgbìn náà sómi kí o tóó lọ sùn. Nígbà tí ojú ọjọ́ bá tutù, rẹ hóró irúgbìn náà sínú omi lílọ́ wọ́ọ́rọ́. Lẹ́yìn wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́wàá, hóró irúgbìn náà yóò wú, àwọn èèpo ara rẹ̀ yóò sì rọra lanu díẹ̀. Wọ́n ti ṣe tán láti hù nìyẹn.
ỌJỌ́ KEJÌ: Ní òwúrọ̀, bo orí rẹ̀, kí o sì jo omi inú ohun ìkóǹkansí náà dà nù. (Níwọ̀n bí omi náà ti ní àwọn fítámì nínú, mo sábà máa ń mu ún—tàbí kí n fi fọ́n àwọn irúgbìn mi.) Nísinsìnyí, tún bomi kún inú ohun ìkóǹkansí náà. Mì ín jìgìjìgì níye ìgbà mélòó kan, kí o sì dorí rẹ̀ kodò, kí omi tí kò bá fà mu lè jò dà nù. Tún bomi kún inú ohun ìkóǹkansí náà léraléra, kí o máa ṣan hóró irúgbìn náà, kí o sì máa jo omi inú rẹ̀ dà nù ní àpapọ̀ ìgbà mẹ́ta. Bí o bá ti pa ipò àwọn hóró irúgbìn tí o rẹ náà dà sínú àwo tí kò jinnú, rọra da omi sórí ìdànǹdán náà, kí o sì jò ó dà nù nípa gbígbé àwo náà sórí ibi dídagun kan. Lẹ́yìn náà, tún ìgbésẹ̀ ṣíṣan hóró irúgbìn náà ṣe lẹ́ẹ̀kan sí i, kí àwọn hóró irúgbìn náà lè máa wà ní ṣíṣàn dáradára lẹ́ẹ̀mejì lóòjọ́.
ỌJỌ́ KẸTA: Ní báyìí, ó yẹ kí o ti máa rí bí hóró irúgbìn rẹ ṣe ń hù. Máa bá ṣíṣàn án lẹ́ẹ̀mejì lóòjọ́ lọ.
ỌJỌ́ KẸRIN: O lè bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àwọn èèhù rẹ! O lè jẹ́ kí àwọn èèhù ẹ̀wà mung náà ga dáradára láìsí pé wọ́n ní ìtọ́wò kíkorò nínú. Ṣáà ti rí i pé o ń ṣan àwọn èèhù náà lẹ́ẹ̀mejì lóòjọ́. O tún lè gbé àwọn èèhù rẹ sínú oòrùn fún nǹkan bíi wákàtí kan, kí o sì gbé wọn sínú fìríìjì lẹ́yìn náà. Àwọn ewé tíntìntín náà yóò yí pa dà di àwọ̀ ewé rírẹwà—tí ń dáni lọ́fun tòló gan-an!
Lẹ́yìn tí o ti ṣe àṣeyọrí èyí, o lè wáá fẹ́ láti fi oríṣi àwọn ọkà àti hóró irúgbìn míràn ṣe àṣeyẹ̀wò. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìtọ́wò àti àkókò tí ó fi ń hù, tí ó yàtọ̀ díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè gbìyànjú láti gbin hóró irúgbìn sunflower tí a bó léèpo. Àwọn èèhù wọ̀nyí dára jù lọ fún jíjẹ láàárín ọjọ́ méjì péré, nígbà tí wọ́n ṣì ga ní ìlàjì íǹṣì. Bí wọ́n bá ga jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í korò.
Bí A Ṣe Lè Sọ Àwọn Èèhù Di Oúnjẹ
Èèhù púpọ̀ jù lọ ni a lè jẹ ní tútù nínú sàláàdì, ìpápánu, tàbí ọbẹ̀ èyíkéyìí tí a bá ti lo ẹ̀wà àti hóró èso. Bí ó ti wù kí ó rí, o lè se èèhù ẹ̀wà fún ìṣẹ́jú 10 sí 15 kí o tóó jẹ ẹ́. Tàbí, o lè dín in pẹ̀lú òróró díẹ̀, aáyù, àti iyọ̀. Oúnjẹ aládùn kan nìyí! Èèhù ọkà wheat àti ti ọkà rye máa ń dùn gan-an, wọ́n sì dára láti fi jẹ búrẹ́dì àti búrẹ́dì ẹlẹ́yin.
Nípa báyìí, ṣíṣọ̀gbìn èèhù jẹ́ ìgbòkègbodò àfipawọ́ dídọ́ṣọ̀ tí kì í sì í náni lówó gọbọi. O lè rí i pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń gbádùn mọ́ni, ó sì ṣàǹfààní gan-an. Ó ṣe tán, àṣeyọrí rẹ̀ pọ̀, àbájáde rẹ̀ sì ládùn!—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
Japanese Stencil Designs
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
ỌJỌ́ KÌÍNÍ: Kó àwọn hóró irúgbìn jọ, kí o sì rẹ wọ́n somi fún wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́wàá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
ỌJỌ́ KEJÌ ÀTI ÌKẸTA: Máa ṣan àwọn hóró irúgbìn náà dáadáa lẹ́ẹ̀mejì lóòjọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
ỌJỌ́ KẸRIN: Àwọn èèhù náà (a rí wọn níhìn-ín láti ẹ̀gbẹ́, lórí ìtẹ́lẹ̀ ìdànǹdán) ti tóó jẹ!