Ipò Òṣì ‘Ọ̀ràn Ìṣòro Tí A Kò Fiyè Sí’
OLÙDÁMỌ̀RÀN fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, Ọ̀mọ̀wé Mahbub Ul-Haq, sọ pé: “A ń gbọ́ igbe ìdágìrì kíkankíkan nípa mímóoru ilẹ̀ ayé àti ìsọdìbàjẹ́ ìpele ozone òun agbami òkun,” ṣùgbọ́n ó fi kún un pé: “Mímóoru ilẹ̀ ayé àti àwọn ọ̀ràn ìṣòro mìíràn tí ń gbàfiyèsí kò tí ì pa ẹnikẹ́ni [nígbà tí] àwọn ọ̀ràn ìṣòro tí a kò fiyè sí ń fa ikú ọ̀pọ̀ ènìyàn lójoojúmọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.” Ọ̀mọ̀wé Ul-Haq sọ̀rọ̀ lórí ọ̀kan lára àwọn ọ̀ràn ìṣòro tí a kò fiyè sí wọ̀nyí. Ó sọ pé: “Ipò òṣì ni panipani títóbi jù lọ.” Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
Fún ọ̀pọ̀ lára bílíọ̀nù 1.3 ènìyàn lágbàáyé tí dọ́là kan tàbí iye tí kò tó bẹ́ẹ̀ ń wọlé fún lójúmọ́, dájúdájú, ipò òṣì ti di ìjábá aṣekúpani. Ìwé ìròyìn UN Chronicle ròyìn pé, “àwọn okùnfà tí ó tan mọ́ ipò òṣì” ń pa iye ènìyàn tí ó tó mílíọ̀nù 18 lọ́dọọdún. Iye náà ń múni kọ háà! Ronú lórí àwọn kókó ìròyìn “agbàfiyèsí” tí à bá gbé jáde ká ní, bí àpẹẹrẹ, gbogbo ènìyàn tí ń gbé ní Australia, nǹkan bíi mílíọ̀nù 18, ni ebi ń pa lọ́dún kan! Síbẹ̀, ètò kan lórí Rédíò UN sọ pé, “a kì í sọ púpọ̀” nípa ikú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tálákà wọ̀nyí. Ní tòótọ́, èyí jẹ́ ‘ìjábá tí a kò fiyè sí’ kan.
Láti fòpin sí àìfiyè-síǹkan náà, àwọn aṣojú láti orílẹ̀-èdè 117 tí wọ́n pé jọ síbi Àpérò Àgbáyé fún Ìdàgbàsókè Àwùjọ Ẹ̀dá Ènìyàn, àkọ́kọ́ irú rẹ̀, sọ nípa àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbógun ti ìṣòro ipò òṣì lágbàáyé náà. James Gustave Speth, alákòóso Ìwéwèé Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè fún Ìdàgbàsókè, ránni létí pé: “Ní 150 ọdún sẹ́yìn, ayé ṣàfilọ́lẹ̀ gbígbógun ti òwò ẹrú. Lónìí, ó yẹ kí a ṣàfilọ́lẹ̀ gbígbógun ti ipò òṣì ọlọ́pọ̀ èrò rẹpẹtẹ.” Èrèdí àníyàn náà? Ó ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé, ipò òṣì “ń fa àìnírètí àti àìfẹsẹ̀múlẹ̀, [ó sì] ń wu àgbáyé wa léwu.”
Bí ó ti wù kí ó rí, bí àwọn aṣojú náà ṣe ń jíròrò ọ̀nà láti fòpin sí ipò òṣì lọ́wọ́ pàápàá, ‘agogo ipò òṣì,’ tí ń ṣírò iye ọmọ tí a ń bí sínú àwọn ìdílé òtòṣì lójoojúmọ́, fi hàn pé ọ̀ràn ipò òṣì náà túbọ̀ ń burú sí i lágbàáyé ni. Agogo náà, tí a gbé kalẹ̀ sí ibi àpérò náà, fi hàn pé láàárín ọ̀sẹ̀ kan tí wọ́n fi ṣe àpérò náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 600,000 àwọn ìkókó tí a tún fi kún iye àwọn òtòṣì tí ń fìgbà gbogbo pọ̀ sí i náà. Ní ìparí ọjọ́ tó kẹ́yìn àpérò náà, wọ́n pa agogo náà; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Speth ṣe kíyè sí i, “agogo náà ń báṣẹ́ lọ” ní ti gidi. Ìbéèrè náà nísinsìnyí ni pé, A óò ha fiyè sí i bí?