Ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ Àtọkànwá Kan
JÍ!, May 8, 1996, gbé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan jáde lórí ọ̀ràn ìgbàṣọmọ. Tìyanutìyanu, ó dùn mọ́ wa láti rí àwọn ìdáhùnpadà àwọn òǹkàwé tí a ń rí gbà kárí ayé. Lẹ́tà tí ó tẹ̀ lé e yìí wọni lọ́kàn ní pàtàkì.
“Mo rò pé ó pọn dandan fún mi láti tọ́ka sí i pé ọ̀pọ̀ nínú àwa tí a ń gbé ọmọ wa sílẹ̀ fún ìgbàṣọmọ ń fẹ́ láti tọ́ àwọn ọmọ náà fúnra wa ní ti gidi. Mo jẹ́ ọ̀dọ́langba kan tí kò tí ì ṣègbéyàwó, tí ó ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ nígbà náà. Gbàrà tí àwọn òbí mi mọ̀ pé mo lóyún, wọ́n sọ fún mi pé mo gbọ́dọ̀ fi ire ọmọ náà ṣíwájú tèmi, kí n sì gbé e kalẹ̀ fún ìgbàṣọmọ. Wọ́n sọ fún mi pé, ‘ọmọ kan nílò ìyá kan àti bàbá kan lápapọ̀,’ èyí tí èmi kò lè pèsè. Àwọn òbí mi kò fẹ́ kí n dá tọ́ ọmọ náà—kò sí àyè fún mi nínú ilé wọn bí mo bá ń tọ́mọ. Kí ni mo lè ṣe? Wọ́n ṣàlàyé pé: ‘Ìwọ yóò fìbínú kórìíra ọmọ rẹ pé ó gba òmìnira rẹ dà nù.’
“Kété tí oyún náà bẹ̀rẹ̀ sí í hàn, wọ́n mú mi kúrò nílé ẹ̀kọ́, wọ́n sì fi mí ṣọwọ́ sí ìbátan kan pé kí n máa gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí mo ń kúrò nílé, mo mọ̀ pé, wọn kì yóò gbà mí pa dà síbẹ̀ títí tí mo bá fi bímọ, tí mo sì ti gbé e sílẹ̀ fún ìgbàṣọmọ.
“Wọ́n fi mí sílé àwọn ìyá tí ko lọ́kọ. Nígbà tí òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re náà ń bi mí bóyá ó dá mi lójú pé ìpinnu mi ni láti gbé ọmọ náà sílẹ̀ fún ìgbàṣọmọ, mo mọ̀ pé kò mọ̀ pé n kò ní yíyàn míràn ni. MO FẸ́ LÁTI TỌ́ ỌMỌ MI FÚNRA MI! Mo ti fìgbà gbogbo ń yán hànhàn láti rí i bí ó ṣe ń rẹ́rìn-ín, tí ó sì láyọ̀. Ó yẹ kí àwọn òǹkàwé yín mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìyá tí ó bímọ gan-an ní ìmọ̀lára kan náà tí mo ní.
“Wọn kò fún mi ní yíyàn kankan tí ó jẹ́ gidi. Nítorí náà, mo ṣe ohun tí wọ́n sọ fún mi pé ó jẹ́ fún ‘ire dídára jù lọ’ ọmọ náà. Láti ìgbà náà wá ni mo sì ti ní ìpalára jíjinlẹ̀ ní ti ìmọ̀lára. Mo ń dààmú pé ọmọkùnrin mi lè rò pé n kò fìgbà kankan bìkítà nípa òun, àti pé n kò fẹ́ òun.
“Ní báyìí, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kan, mo sábà máa ń mọrírì àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì nípa àwọn ipò tí ó túbọ̀ ṣòro tí a máa ń fa ara wa sí nítorí àìkò lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé wa. Ó ń fi àwọn ipa lílọ jìnnà tí ó sì jẹ́ onírora tí ríronú lọ́nà ti ayé ń ní hàn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí a gbà ṣọmọ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé, gbígbé wọn kalẹ̀ lásán fún ìgbàṣọmọ kò túmọ̀ sí pé a kò fẹ́ láti ní wọn. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀!”