ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/8 ojú ìwé 11-15
  • Kíkó Àwọn Ọmọdé Nífà Ìbálòpọ̀—Ìṣòro Kan Tí Ó Kárí Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkó Àwọn Ọmọdé Nífà Ìbálòpọ̀—Ìṣòro Kan Tí Ó Kárí Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Okùnfà Díẹ̀
  • Àwọn Wo Ni?
  • Ó Kan Ìsìn
  • Kí La Lè Ṣe?
  • Ojútùú Kan Ṣoṣo Náà
  • Ta Ni Yóò Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ wa?
    Jí!—1999
  • Ìṣòro náà Kárí Ayé
    Jí!—1999
  • Kí Ló Dé Tí Ìṣòro Yìí Fi Ń peléke Sí I?
    Jí!—2003
  • Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Nínú Ilé
    Jí!—1993
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 4/8 ojú ìwé 11-15

Kíkó Àwọn Ọmọdé Nífà Ìbálòpọ̀—Ìṣòro Kan Tí Ó Kárí Ayé

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SWEDEN

Oríṣi ọ̀nà bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe tí ń dáni níjì kan, tí irú rẹ̀ àti bí ó ṣe ń gbalẹ̀ kan kò wọ́pọ̀ ṣáájú àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, ń mi àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tìtì. Láti mọ ohun tí a lè ṣe nípa rẹ̀, àwọn aṣojú láti 130 orílẹ̀-èdè pàdé pọ̀ ní Stockholm, Sweden, níbi Ìpàdé Ìjíròrò Àgbáyé Lòdì sí Ìṣòwò Kíkó Àwọn Ọmọdé Nífà Ìbálòpọ̀, àkọ́kọ́ irú rẹ̀. Aṣojúkọ̀ròyìn Jí! kan ní Sweden wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

NÍGBÀ tí Magdalen jẹ́ ọmọ ọdún 14, wọ́n fẹ̀tàn mú un gba iṣẹ́ “obìnrin agbàlejò” ní ilé ọtí kan ní Manila, Philippines. Ní ti gidi, iṣẹ́ rẹ̀ ní mímú àwọn àlejò ọkùnrin lọ sínú iyàrá kótópó kan, kí ó sì tú ara rẹ̀ síhòhò fún wọn láti bá a ṣèṣekúṣe nínú—ìpíndọ́gba ọkùnrin 15 lóru kọ̀ọ̀kan, àti 30 ọkùnrin ní àwọn ọjọ́ Saturday. Nígbà míràn, tí ó bá sọ pé òun kò lè fara dà á mọ́, ọ̀gá rẹ̀ yóò fipá mú un láti máa báṣẹ́ lọ. Ó sábà máa ń parí iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ ní aago mẹ́rin ìdájí, pẹ̀lú àárẹ̀, ìsoríkọ́, àti àìláyọ̀, lọ́nà lílé kenkà.

Ní Phnom Penh, Cambodia, Sareoun jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin asùnta kan, tí àwọn òbí rẹ̀ ti kú. Ó ní àrùn rẹ́kórẹ́kó, a sì mọ̀ pé ó ti bá àwọn àjèjì ọkùnrin ‘ròde.’ Wọ́n fún un ní ilé kan láti máa gbé nínú pagoda kan, níbi tí a ti retí pé kí ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé nígbà kan rí kan máa ‘bójú tó’ o. Bí ó ti wù kí ó rí, ńṣe ni ọkùnrin yìí ń bá ọmọkùnrin náà ṣèṣekúṣe, tí ó sì ń lò ó fún ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn àjèjì. Nígbà tí wọ́n wó apá ibi tí Sareoun ń gbé nínú pagoda náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ̀dọ̀ obìnrin kan tí ó jẹ́ ìbátan àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n síbẹ̀, a fipá mú un láti máa ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó ọkùnrin.

Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ méjì péré nípa ìṣòro lílé kenkà tí a bá fínra lápá ìparí ọdún tó kọjá, níbi Ìpàdé Ìjíròrò Àgbáyé Lòdì sí Ìṣòwò Kíkó Àwọn Ọmọdé Nífà Ìbálòpọ̀ ni. Báwo ni àṣà yí ṣe gbilẹ̀ tó? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọdé ló ń kàn—ní gidi, àwọn kan sọ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ni wọ́n. Aṣojú kan ṣàkópọ̀ ìṣòro náà báyìí pé: “A ń ra àwọn ọmọdé, a sì ń tà wọ́n bí ọjà ìbálòpọ̀ àti ti ìṣòwò. A ń kó wọn kiri bi ẹrù fàyàwọ́ láàárín orílẹ̀-èdè àti ré kọjá ẹnubodè, a ń há wọn mọ́ sílé aṣẹ́wó, a sì ń fipá mú wọn juwọ́ sílẹ̀ fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn akóninífà-ìbálòpọ̀.”

Nínú ọ̀rọ̀ ìṣípàdé tí olórí ìjọba Sweden, Göran Persson, sọ fún àwọn tó pé jọ náà, ó pe irú ìkóninífà yí ní “ìsọ̀rí ìwà ọ̀daràn àìlọ́làjú, tí ó rorò, tí ó sì ń ríni lára jù lọ.” Ẹnì kan tí ó ṣojú fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé ó “jẹ́ ìfipákọluni tí ń wá láti ìhà gbogbo lòdì sí àwọn ọmọdé . . . , ó ń ríni lára pátápátá, ó sì jẹ́ títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú lọ́nà búburú jù lọ, tí a lè ronú kàn.” Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ jíjọra, tí ń fìbínú hàn sí kíkó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀ ni a sọ jáde láti orí pèpéle jálẹ̀jálẹ̀ ìpàdé ìjíròrò náà, bí a ṣe ń ṣàgbéyẹ̀wò bí ó ṣe gbilẹ̀ tó, bí ó ṣe rí, àwọn ohun tí ń fà á, àti ipa tí ó ń ní.

Ìwé ìtọ́kasí pàtàkì kan sọ pé: “Ó gbilẹ̀ ré kọjá orílẹ̀-èdè kan, ó sì nípa lórí àtìrandíran ju ẹyọ kan lọ.” Òmíràn sọ pé: “A gbà gbọ́ pé àfojúbù nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé ń wọnú iṣẹ́ òwò ìbálòpọ̀ tí kò bófin mu, tí ń mú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là wọlé lọ́dọọdún.” Ipa wo ló ń ní? “Ó ń jin ìmọ̀lára iyì, ìjámọ́ǹkan, àti ìdára-ẹni-lójú àwọn ọmọdé lẹ́sẹ̀, ó sì ń mú kí agbára wọn láti gbẹ́kẹ̀ léni pòkúdu. Ó ń wu ìlera ti ara àti ti ìmọ̀lára wọn léwu, ó ń tẹ ẹ̀tọ́ wọn lójú, ó sì ń ba ọjọ́ ọ̀la wọn jẹ́.”

Àwọn Okùnfà Díẹ̀

Kí ni díẹ̀ lára àwọn okùnfà ìbúrẹ́kẹ ìṣòro yìí? Wọ́n ti mẹ́nu bà á pé àwọn ọmọdé kan “ń kó wọṣẹ́ aṣẹ́wó nítorí ipò tó yí wọn ká, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti la ipò òṣì wọn já, kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti ti ìdílé wọn lẹ́yìn, tàbí láti rówó ra aṣọ àti àwọn ohun mìíràn. Àìlóǹkà àwọn ènìyàn tí a ń fi hàn pé wọ́n ń gbádùn nítorí tí wọ́n ní ohun ìní nígbà ìpolówó tí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń ṣe, ló ń tan àwọn ẹlòmíràn sí i.” Síbẹ̀, a ń jí àwọn kan gbé, tí a sì ń fipá mú wọn ṣe aṣẹ́wó. Lára àwọn okùnfà tí a tún mẹ́nu bà ni ìníyelórí ìwà rere tí ń yára yìnrìn, àti ìmọ̀lára àìnírètí tí àwọn ènìyàn ń ní ní gbogbogbòò.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin ń fi ìbálòpọ̀ ṣòwò nítorí ìfìyàjẹni lábẹ́lé—ìwà ipá àti àwọn ìbátan tí ń báni ṣèṣekúṣe ń lé wọn kúrò nílé. Níbẹ̀, wọ́n wà nínú ewu àwọn tí ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe àti àwọn mìíràn, kódà, ó jọ pé àwọn ọlọ́pàá mélòó kan pẹ̀lú wà níbẹ̀, tí ń bá wọn ṣèṣekúṣe. Ìròyìn kan nípa ìṣòro náà tí a pè ní Kids for Hire sọ nípa Katia, ọmọ ọdún mẹ́fà, ní Brazil. Nígbà tí ọlọ́pàá kan mú un, ó fipá mú un ṣe àwọn ohun tí kò tọ́, ó sì halẹ̀ mọ́ ọn pé òun yóò pa ìdílé rẹ̀, bí ó bá sọ fún ọ̀gá òun. Lọ́jọ́ kejì, ó kó àwọn ọkùnrin márùn-ún mìíràn wá, tí gbogbo wọn ń fẹ́ kí Katia bá àwọn ṣe ìṣe ìbálòpọ̀ kan náà.

Children’s Ombudsman, ìgbìmọ̀ tí ìjọba ilẹ̀ Sweden gbé kalẹ̀, sọ fún àwọn aṣojú náà pé: “Nígbà tí a ṣe ìwádìí lórí ohun tí ń fa iṣẹ́ aṣẹ́wó àwọn ọmọdé, kò sí iyè méjì pé ìrìn àjò afẹ́ [nítorí ìbálòpọ̀] jẹ́ ọ̀kan lára àwọn okùnfà pàtàkì náà.” Ìròyìn kan sọ pé: “Òwò ìrìn àjò afẹ́ ló fa ìlọsókè kíkàmàmà nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó àwọn ọmọdé láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá ní tààràtà. Ìfàmọ́ra tuntun jù lọ tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ń fúnni ni iṣẹ́ aṣẹ́wó àwọn ọmọdé.” “Ìrìn àjò afẹ́ nítorí ìbálòpọ̀” láti Europe, United States, Japan, àti ibòmíràn ló fa kí àwọn ènìyàn máa béèrè fún àwọn ọmọdé aṣẹ́wó jákèjádò ayé. Ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ilẹ Europe kan lo àwòrán ọmọdé kan tí ó múra tán fún ìbálòpọ̀ láti gbé ìrìn àjò afẹ́ nítorí ìbálòpọ̀ lárugẹ. Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ni àwọn ilé iṣẹ́ ìrìn àjò afẹ́ ń ṣètò ìrìn àjò nítorí ìbálòpọ̀ fún.

Lára àwọn okùnfà tí a tò rẹrẹẹrẹ náà ni gbígbé tí ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun ń gbé ìbọ́mọdélòpọ̀ lárugẹ jákèjádò ayé. A ti gbọ́ pé ìmọ̀ ẹ̀rọ Internet, pa pọ̀ mọ́ àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tí ó fara jọ ọ́ mìíràn, jẹ́ olórí orísun títóbi jù lọ tí àwọn ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè ti ń wá. Lọ́nà kan náà, àwọn ohun ìṣiṣẹ́ fídíò olówó pọ́ọ́kú ti mú kí ó rọrùn láti ṣe àmújáde àwọn ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè ti ọmọdé.

Àwọn Wo Ni?

Ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbàlagbà tí ń bọ́mọdé lò pọ̀ ló jẹ́ abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe. Abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe kan ń ní òòfà ìbálòpọ̀ lọ́nà òdì sí àwọn ọmọdé. Gẹ́gẹ́ bí Children’s Ombudsman ti Sweden ṣe wí, “wọn kò fi dandan jẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti ń darúgbó, onírìísí wúruwùru, tí ń wọ aṣọ òjò kiri, tàbí òǹrorò oníjàgídíjàgan. Àfiṣàpẹẹrẹ abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe kan ni ọkùnrin ọlọ́jọ́ orí 40 sí 60 ọdún, tó kàwé dáadáa, lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọdé bí olùkọ́, dókítà, òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re, tàbí àlùfáà kan.”

Àwùjọ tí ó wá láti Sweden náà mú àpẹẹrẹ ti Rosario wá, ọmọbìnrin ọlọ́dún 12, ará Filipino kan, tí arìnrìn-àjò afẹ́ nítorí ìbálòpọ̀ kan láti Austria, tí ó jẹ́ dókítà kan, bá ṣèṣekúṣe. Bíbá tí ó bá a ṣèṣekúṣe yọrí sí ikú ọmọbìnrin náà.

Carol Bellamy, olùdarí àgbà fún àjọ UNICEF (Àjọ Àkànlò Owó ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé) ní Geneva, sọ àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí nípa ọmọbìnrin ọlọ́dún 12, ará Filipino náà, pé: “Ó sábà máa ń jẹ́ àwọn àgbàlagbà náà gan-an tí a fi ìtọ́jú àti ààbò àwọn ọmọ náà sí níkàáwọ́ ni wọ́n ń yọ̀ǹda fún àṣàkaṣà yí, tí wọ́n sì ń ṣe é. Wọ́n máa ń jẹ́ àwọn olùkọ́, òṣìṣẹ́ ìlera, ọlọ́pàá, òṣèlú, àti àwọn mẹ́ńbà àwùjọ àlùfáà, tí ń lo ipò àti ọlá àṣẹ wọn láti kó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀.”

Ó Kan Ìsìn

Ẹnì kan tí ń ṣojú Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì níbi ìpàdé ìjíròrò náà ní Stockholm polongo pé, kíkó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀ jẹ́ “ìwà ọ̀daràn ẹlẹ́gbin jù lọ,” ó sì jẹ́ “ìyọrísí ìyísódì jinlẹ̀jinlẹ̀ àti ìwólulẹ̀ ìlànà tí a kà sí pàtàkì.” Síbẹ̀, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti fara gbá irú àṣàkaṣà bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn àwùjọ àlùfáà rẹ̀.

Nínú ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn Newsweek, August 16, 1993, àpilẹ̀kọ tí ó ní àkọlé náà, “Àwọn Àlùfáà àti Ìṣekúṣe,” ròyìn “ẹ̀gàn búburú jù lọ tí ó dé bá àwùjọ àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ní United States.” Ó wí pé: “Nígbà tí wọ́n ti fẹ̀sùn kan àwọn àlùfáà tí a fojú díwọ̀n sí 400 láti 1982 wá, àwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì mélòó kan méfò pé àwọn àlùfáà tí ó pọ̀ tó 2,500 ti fìtínà àwọn ọmọdé tàbí àwọn ọ̀dọ́langba. . . . Ní àfikún sí owó tí ṣọ́ọ̀ṣì ti ná nítorí ẹ̀gàn náà, ó tún ti kótìjú bá a gidigidi—ó sì kótìjú bá àwọn aláṣẹ lórí ìwà rere rẹ̀ mélòó kan pẹ̀lú.” Àwọn ìsìn míràn jákèjádò àgbáyé wà nínú ipò kan náà.

Ray Wyre, onímọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn ìbálòpọ̀ kan, tí ó wá láti United Kingdom, sọ fún ìpàdé àpérò náà ní Stockholm nípa àwọn ọmọkùnrin méjì tí àlùfáà kan bá ṣèṣekúṣe lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́. Ní báyìí, ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin náà ń ṣàbójútó ẹ̀ka kan fún àwọn òjìyà tí àwọn àlùfáà bá ṣèṣekúṣe, èkejì fúnra rẹ̀ sì jẹ́ oníṣekúṣe kan.

Mettanando Bhikkhu, ọ̀mọ̀wé ẹlẹ́sìn Búdà kan láti Thailand, ròyìn pé, “àwọn oríṣi àṣà ẹ̀sìn Búdà kan báyìí pín nínú ẹ̀bi ìṣòwò kíkó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀ ní Thailand ní ìpele mélòó kan. Ní àwọn abúléko Thailand, lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti jàǹfààní láti inú owó tí àwọn ọmọdé tí wọ́n fipá sọ di aṣẹ́wó ń san fún ìlú.”

Kí La Lè Ṣe?

Dókítà Julia O’Connell Davidson, láti Yunifásítì Leicester ní United Kingdom, ké sí ìpàdé ìjíròrò náà láti pe àwáwí tí àwọn akóninífà náà máa ń ṣe láti dá ìhùwàsí wọn láre níjà. Àwọn oníṣekúṣe sábà máa ń pàfiyèsí sí èròǹgbà náà pé ọmọdé náà ni kò ní ìkóra-ẹni-níjàánu, tí ó sì jẹ́ oníwà pálapàla, pẹ̀lú àlàyé pé ọmọ náà ti jẹ́ oníwà àìmọ́, ó sì ti bà jẹ́ fúnra rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àwọn akóninífà míràn ń lo àlàyé èké tí a lọ́ lọ́rùn náà pé kò sí ìjàǹbá kankan tí ìwà àwọn lè mú wá, àti pé ọmọdé náà jàǹfààní láti inú rẹ̀.

Ìgbìmọ̀ kan tí ń rí sí ọ̀ràn ìrìn àjò afẹ́ nítorí ìbálòpọ̀ dábàá pé kí a gbógun tì í nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ nílé ẹ̀kọ́. Ní àfikún, ìsọfúnni lòdì sí kíkó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀ gbọ́dọ̀ máa kan àwọn arìnrìn-àjò lára jálẹ̀jálẹ̀ gbogbo ìrìn àjò náà—kí wọ́n tó gbéra, nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò lọ́wọ́, àti níbi tí wọ́n ń lọ.

Nípa ti àwọn ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tuntun, ìgbìmọ̀ kan dábàá pé kí a fún àwọn orílẹ̀-èdè ní ìlànà bí wọ́n ṣe lè yọ àwọn apá tí ó bá ń kó àwọn ọmọdé nífà kúrò. Wọ́n ṣàgbéyẹ̀wò bí ó ṣe lè ṣeé ṣe láti ṣàgbékalẹ̀ ẹ̀ka iṣẹ́ ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè kan láti ṣe kòkárí àwọn ìgbòkègbodò apá yìí. Ìgbìmọ̀ míràn dábàá pé kí a ka àwọn ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè tí a ń fi kọ̀ǹpútà ṣe àti níní àwọn ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè lọ́wọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀daràn, kí a sì fi òfin gbé ìjìyà kalẹ̀ fún un ní gbogbo orílẹ̀-èdè.

Kí ni àwọn òbí lè ṣe? Ìgbìmọ̀ kan tí ó ṣiṣẹ́ lórí ipa ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde dábàá pé kí àwọn òbí gba ẹrù iṣẹ́ láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Ó wí pé: “Àwọn òbí kò gbọ́dọ̀ wulẹ̀ máa tọ́ àwọn ọmọ sọ́nà lásán bí wọ́n ṣe ń dàgbà di ẹni tí ń lo àwọn ohun agbéròyìnjáde, ṣùgbọ́n wọ́n tún gbọ́dọ̀ máa pèsè ìsọfúnni, àlàyé àti onírúurú orísun ìsọfúnni láti kojú ipa tí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń ní, kí wọ́n sì ran ọmọ náà lọ́wọ́ láti ní òye púpọ̀.”

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n ilẹ̀ Sweden kan, tí ń ròyìn nípa ìpàdé ìjíròrò náà, tẹnu mọ́ bí ó ṣe pọn dandan tó fún àwọn òbí láti túbọ̀ máa bójú tó àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ewu tó wà. Bí ó ti wù kí ó rí, ó gbani nímọ̀ràn pé: “Má wulẹ̀ kìlọ̀ fún àwọn ọmọdé nípa ‘àwọn àgbàlagbà ọkùnrin oníwà àìmọ́’ lásán, nítorí àwọn ọmọdé . . . ń tipa bẹ́ẹ̀ rò pé kìkì àwọn ọkùnrin àgbàlagbà, onírìísí wúruwùru, ni àwọn ní láti máa ṣọ́ra fún, nígbà tí ẹni tí ń hu irú ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ lè wọ aṣọ iṣẹ́ tàbí aṣọ àmúròde mímọ́ tónítóní pàápàá. Nítorí náà, kìlọ̀ fún wọn lòdì sí àwọn àjèjì tí ń fi ìfẹ́ ọkàn tí kò wọ́pọ̀ hàn sí wọn.” Dájúdájú, a tún gbọ́dọ̀ kìlọ̀ fún àwọn ọmọdé lòdì sí ẹnikẹ́ni tí ń fi ìlọ̀kilọ̀ lọ̀ wọ́n, títí kan àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ̀ pàápàá—kí a sì rọ̀ wọ́n láti fẹjọ́ sun àwọn aláṣẹ.

Ojútùú Kan Ṣoṣo Náà

Ohun tí ìpàdé ìjíròrò ti Stockholm náà kò lè dábàá ni ọ̀nà láti ṣẹ́pá àwọn okùnfà kíkó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀. Ìwọ̀nyí ní nínú, àwọn ohun tí a kà sí ìwà rere tí ó yára ń pa rẹ́ lọ níbi gbogbo; ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìyánhànhàn fún ohun ìní tí ń pọ̀ sí i; àìlọ́wọ̀ tí ń pọ̀ sí i fún àwọn òfin tí a ṣe láti dáàbò bo àwọn ènìyàn lọ́wọ́ àìṣẹ̀tọ́; àìkìíka ire, iyì, àti ìwàláàyè àwọn ẹlòmíràn sí tí ń pọ̀ sí i; ìwólulẹ̀ yíyára kánkán nínú ìṣètò ìdílé; ipò òṣì tí ó gbilẹ̀ rẹpẹtẹ nítorí àpọ̀jù iye ènìyàn, àìríṣẹ́ṣe, sísọ àrọko dìlú ńlá, àti ìṣíkiri; ìmọ̀lára ìran tèmi lọ̀gá tí ń pọ̀ sí i lòdì sí àwọn àjèjì àti àwọn olùwá-ibi-ìsádi; ìṣèmújáde àti ìkókiri oògùn olóró lọ́nà tí ń pọ̀ sí i; àti àwọn èròǹgbà ìsìn, àṣà ìsìn, àti ìṣe ìsìn, tí ó ti díbàjẹ́.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kíkó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀ ń dáni níjì, irú ìwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ kò ya àwọn oníṣọ̀ọ́ra tí ń ka Bíbélì lẹ́nu. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? Nítorí pé nísinsìnyí, a ń gbé nínú ohun tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ṣe sọ, “àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò” wà níhìn-ín. (Tímótì Kejì 3:1-5, 13) Nítorí náà, ó ha yani lẹ́nu pé ìwà búburú ń tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù bí?

Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì tọ́ka sí ojútùú kan ṣoṣo sí àwọn ìṣòro títóbi tí ayé dojú kọ—ìwẹ̀nù pátápátá láti ọwọ́ Ọlọ́run Olódùmarè. Láìpẹ́, òun yóò fagbára rẹ̀ hàn, yóò sì mú gbogbo àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé, tí kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà àti òfin òdodo rẹ̀ kúrò: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.”—Òwe 2:21, 22, NW; Tẹsalóníkà Kejì 1:6-9.

Àwọn ‘tí a ké kúrò’ náà yóò ní gbogbo àwọn tí ń sọ àwọn ọmọdé di aṣẹ́wó àti àwọn oníbàjẹ́ ènìyàn tí ń bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe nínú. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Kì í ṣe àwọn àgbèrè, . . . tàbí àwọn panṣágà, . . . tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin [tàbí ọmọkùnrin] dà pọ̀, . . . ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Kọ́ríńtì Kíní 6:9, 10) Ó fi kún un pé, “àwọn wọnnì tí ń ríni lára nínú èérí ẹ̀gbin wọn . . . àti àwọn àgbèrè” yóò ní ipa tiwọn nínú “ikú kejì”—ìparun ayérayé.—Ìṣípayá 21:8

Ọlọ́run yóò wẹ ilẹ̀ ayé nù, yóò sì mú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tuntun pátápátá tí ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ wọlé wá, “àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” (Pétérù Kejì 3:13) Nígbà náà, nínú ayé tuntun tí òun ṣe yẹn, àwọn ènìyàn oníwà ìbàjẹ́, oníwà òdì, kì yóò tún kó àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ nífà mọ́ láé. Àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kò sì ní bẹ̀rù pé a lè fìyà jẹ wọ́n mọ́ láé nítorí pé, “kì yóò . . . sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà 4:4, NW.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

“Ìsọ̀rí ìwà ọ̀daràn àìlọ́làjú, tí ó sì ń ríni lára jù lọ.”—Olórí ìjọba Sweden

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

“Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, mílíọ̀nù 10 sí 12 ọkùnrin ń lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ aṣẹ́wó.”—The Economist, London

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Ìrìn àjò afẹ́ nítorí ìbálòpọ̀ jẹ́ okùnfà pàtàkì kan fún kíkó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìrìn Àjò Afẹ́ Nítorí Ìbálòpọ̀—Èé Ṣe?

(Àwọn ìdí mélòó kan tí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ fi ń bá àwọn ọmọdé lò pọ̀)

(1) Àìdánimọ̀ tí arìnrìn-àjò afẹ́ náà ń gbádùn yọ ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìdíwọ́ tí àwùjọ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà gbé karí rẹ̀ nílé

(2) Nítorí àìgbọ́ èdè àdúgbò yanjú, tàbí àìgbọ́ ọ rárá, a lè fìrọ̀rùn ṣi àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ lọ́nà láti gbà gbọ́ pé sísan owó fún bíbá ọmọdé kan lò pọ̀ ṣètẹ́wọ́gbà, tàbí pé ó jẹ́ ọ̀nà kan láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ kúrò nínú ipò òṣì

(3) Ìhùwàsí ìran tèmi lọ̀gá ń mú kí àwọn olùṣèbẹ̀wò máa kó àwọn mìíràn tí wọ́n kà sí ẹni rírẹlẹ̀ nífà

(4) Àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ń ka ara wọn sí ọlọ́lá nígbà tí wọ́n bá rí i pé iye owó ìbálòpọ̀ kéré gan-an ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]

Bí Ìṣòro Náà Ṣe Gbilẹ̀ Tó Kárí Ayé

(Ìwọ̀nyí ni ìdíyelé tí onírúurú àwọn aláṣẹ ìjọba àti àwọn àjọ mìíràn ṣe)

Brazil: Ó kéré tán, 250,000 ọmọdé ń ṣe aṣẹ́wó

Kánádà: Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́langba ọmọbìnrin ni àwùjọ àwọn ọkùnrin tí ń wá oníbàárà fún aṣẹ́wó ń sọ di aṣẹ́wó

China: Láàárín 200,000 sí 500,000 ọmọdé jẹ́ aṣẹ́wó. Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, nǹkan bí 5,000 ọmọbìnrin ará China ni a ti tàn jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, tí a sì ti tà bí aṣẹ́wó ní Myanmar

Colombia: Iye àwọn ọmọdé tí a ti kó nífà ìbálòpọ̀ ní àwọn òpópó Bogotá ti di ìlọ́po mẹ́rin láàárín ọdún méje tó kọjá

Ìlà Oòrùn Europe: 100,000 ọmọdé jẹ́ asùnta. A ń kó púpọ̀ ránṣẹ́ sí ilé aṣẹ́wó ní Ìwọ̀ Oòrùn Europe

Íńdíà: 400,000 ọmọdé ń fi ìbálòpọ̀ ṣiṣẹ́ ṣe

Mòsáńbíìkì: Àwọn ẹ̀ka ìpèsè ìrànwọ́ ń fẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ogun apẹ̀tùsíjà àjọ UN pé wọ́n ń kó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀

Myanmar: 10,000 ọmọbìnrin àti àgbàlagbà obìnrin ni wọ́n ń kó lọ sílé aṣẹ́wó ní Thailand lọ́dọọdún

Philippines: 40,000 ọmọdé ló kàn

Sri Lanka: 10,000 ọmọdé ọlọ́dún 6 sí 14 wà lóko ẹrú ní àwọn ilé aṣẹ́wó, 5,000 ọmọdé ọlọ́dún 10 sí 18 ń dá ṣiṣẹ́ ní àwọn ibi ìnàjú àwọn arìnrìn-àjò afẹ́

Taiwan: 30,000 ọmọdé ló kàn

Thailand: 300,000 ọmọdé ló kàn

United States: Ìsọfúnni láti ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ sọ pé 100,000 ọmọdé ló kàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́