Wíwo Ayé
Kíkú Léwe
Ìwé agbéròyìnjáde The Dallas Morning News ròyìn pé, ní ìfiwéra, ó ṣeé ṣe kí ìbọn pa àwọn ọmọdé ní United States ní ìlọ́po 12, kí ẹlòmíràn pa wọ́n ní ìlọ́po 5, kí wọ́n fúnra wọn pa ara wọn ní ìlọ́po méjì, ju ti àwọn ọmọdé ní àwọn orílẹ̀-èdè oníléeṣẹ́ ńláńlá 25 míràn lọ. Etienne Krug, olùṣekòkárí ìròyìn fún Àwọn Ibùdó fún Ìkáwọ́ Òkùnrùn ní Atlanta, Georgia, sọ pé: “A retí pé ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí yóò pọ̀ ní United States ju àwọn ibi yòó kù lọ, ṣùgbọ́n bí ìyàtọ̀ náà ṣe pọ̀ tó yà wá lẹ́nu.” Lára àwọn kókó abájọ tí ó tan mọ́ ikú oníwà ipá láàárín àwọn ọmọdé ni oògùn líle, ipò òṣì, ìdílé tí ó tú ká, àti àǹfààní ẹ̀kọ́ tó kéré jọjọ.
Àwọn Àrùn tí Oúnjẹ Ń Fà
Ìwé ìròyìn JAMA (The Journal of the American Medical Association) ròyìn pé ìbéèrè tí ó pọ̀ sí i láti ọ̀dọ̀ àwọn aláràjẹ tí ń fẹ́ “onírúurú ohun jíjẹ títutù yọ̀yọ̀ jálẹ̀ ọdún” àti “ọjà kan tí ó kárí ayé, tí ó lè kó oúnjẹ yí ká ayé lọ́sàn-án kan òru kan,” ń dá kún àwọn àrùn tuntun tí oúnjẹ ń fà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú ní United States. Ní gbígbé e karí àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, àwọn kòkòrò àrùn tí ń mú àrùn tí oúnjẹ ń fa wá “ń dààmú mílíọ̀nù 6.5 sí mílíọ̀nù 81 ènìyàn, wọ́n sì ń pa nǹkan bí 9000 ènìyàn ní United States lọ́dọọdún.” Àwọn ògbóǹkangí kan gbà gbọ́ pẹ̀lú pé jíjẹ tí a ń jẹ àwọn oúnjẹ tí a fi àwọn ìṣẹ̀fọ́-ìṣẹran gbìn (àwọn oúnjẹ tí a fi ìgbẹ́ ẹran ṣe ọ̀rá ilẹ̀ wọn) lè dá kún ìṣòro náà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn JAMA náà sọ, “kòkòrò àrùn E coli lè wà láàyè nínú ìgbẹ́ màlúù fún 70 ọjọ́, ó sì lè máa bí sí i nínú àwọn oúnjẹ tí a fi ìgbẹ́ màlúù ṣe ọ̀rá ilẹ̀ rẹ̀, àyàfi bí a bá fi ooru tàbí àwọn nǹkan àfikún bí iyọ̀ tàbí àwọn ohun ìpaǹkanmọ́ pa àwọn kòkòrò àrùn náà.”
Àwọn Ọ̀bọ “Mímọ́”—Amúnibínú
Onímọ̀ nípa àwọn ẹranko onípò gíga, Iqbal Malik, sọ pé àwọn ọ̀bọ rhesus ti wà ní Vrindavan, India, tipẹ́tipẹ́ gan-an. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ka àwọn ọ̀bọ náà sí ohun mímọ́, wọ́n sì ti wà lómìnira láti máa wọ́ ìgboro ìlú mímọ́ Híńdù náà láìfòyà pé a lè mú wọn—ìyẹn, títí di ìsinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ṣe sọ, iye àwọn ọ̀bọ rhesus náà ti pọ̀ rẹpẹtẹ níbẹ̀ ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, nítorí pé àwọn arìnrìn-àjò ìsìn tí ń bọ́ wọn ti pọ̀ sí i. Àwọn ènìyàn rò pé, bíbọ́ àwọn ọ̀bọ náà ń mú kí a níláárí. Bí ó ti wù kí ó rí, jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, àwọn ọ̀bọ náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dara dé àwọn ohun tí a ń fún wọn pátápátá, nítorí kò fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ewéko ìgbẹ́. “Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í jí àpò ìrajà, wọ́n sì ń já wọ àwọn ilé láti wá oúnjẹ.” Àwọn olùgbé ìlú náà ti fohùn ṣọ̀kan pé kí wọ́n mú iye tí ó pọ̀ tó ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀bọ náà, kí wọ́n sì kó wọn lọ sí àwọn àgbègbè àrọko. Malik wí pé: “Àwọn ọlọ́run ti di amúnibínú.”
Ó Fún Bí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn egungun ẹsẹ̀ wa kì í dàgbà mọ́ ní apá ìparí ìgbà ọ̀dọ́langba, àwọn ẹsẹ̀ wa ń yí pa dà jálẹ̀ ìgbésí ayé wa. Neil Koven, ààrẹ Ẹgbẹ́ Oníṣègùn Ìtọ́jú Ẹsẹ̀ Ènìyàn ní Kánádà, sọ pé: “Bí a ṣe ń dàgbà ni àwọn ẹsẹ̀ wa ń tẹ́ rẹrẹ díẹ̀ sí i, wọ́n sì ń nà tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń gùn tí wọ́n sì ń fẹ̀. Ó jẹ́ nítorí pé àwọn iṣan kèrékèré wa ń dẹ̀ níwọ̀nba tàbí wọn kò le gbagidi mọ́.” Àwọn ògbóǹkangí onímọ̀ nípa bàtà fojú bù ú pé ó tó ìdajì lára àwọn àgbàlagbà tí ń wọ bàtà tí kò bá wọn lẹ́sẹ̀ mu—tí bí ó ṣe fẹ̀ tó sì jẹ́ ìṣòro tí ó wọ́ pọ̀ jù lọ́—tí ń dá kún yíyọ kókó níbi ọmọ ìka ẹsẹ̀, awọ ẹsẹ̀ tó gíràn-án, wíwú tí ìṣẹ́po àkọ́kọ́ àtàǹpàkò ń wú, àti àwọn àbùkù ọmọ ìka ẹsẹ̀. Àwọn bàtà rẹ ha ti fún jù bí? Ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star sọ pé: “Fẹsẹ̀ lásán dúró lórí bébà kan, kí o sì ya bí ẹsẹ̀ rẹ méjèèjì ṣe rí sórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, kó àwọn bàtà rẹ lé orí bébà náà kí o sì yà wọ́n yí po. Nípa fífi àwọn àwòrán méjèèjì wéra, o lè rí bí o ṣe ń fún àwọn ẹsẹ̀ rẹ mọ́ inú bàtà rẹ tó.” Láti ra bàtà tí ó ṣeé ṣe kí ó bá ọ mu jù lọ, wọn ẹsẹ̀ rẹ nígbà kọ̀ọ̀kan tí o bá fẹ́ ra bàtà, sì máa ra bàtà ní ọ̀sán tàbí nírọ̀lẹ́ lẹ́yìn tí o ti rìn gan-an.
Dídọdẹ “Àwọn Ọ̀tá Tí A Kò Mọ̀”
Ìwé agbéròyìnjáde Corriere della Sera sọ pé ní 1997, àwọn èèwọ̀ ara àti àsín-ìnsíntán bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Róòmù, Ítálì, ní oṣù méjì ṣáájú ìgbà tó máa ń bẹ̀rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ẹnì kan tó ní èèwọ̀ ara rò pé ìkọlù òjijì eruku tí ó yára kánkán náà jẹ́ àbájáde “ìpíndọ́gba ìwọ̀n ìgbóná tó pọ̀ sí i nínú pílánẹ́ẹ̀tì, tí ó ti dín bí ìgbà òtútù ṣe ń gùn tó kù lọ́nà gígadabú.” Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé “àwọn ọjọ́ tí ojú ọjọ́ ti dára náà ti kó àwọn eruku tí a kò mọ̀ wá, èyí tí àwọn ògbóǹkangí nínú ìmọ̀ náà kò lè gbógun tì.” “Dídọdẹ okùnfà tí a kò mọ̀ náà” ti bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ní báyìí ná, “àwọn aláìsàn ń jìyà àwọn èèwọ̀ ara, tí a kò lè pinnu ohun tó fà wọ́n.”
Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Búrẹ́dì Aláìwú
Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti Charles Mímọ́ ní Picayune, Mississippi, ti bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn ẹ̀ṣọ́ láti rí i dájú pé kò sí ẹni tí ó jáde ní ṣọ́ọ̀ṣì náà láìjẹ búrẹ́dì aláìwú Ara Olúwa. Wọ́n gbé ìgbésẹ̀ yí lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mélòó kan nínú èyí tí àwọn ènìyàn ń mú búrẹ́dì aláìwú, tàbí Àkàrà Ara Olúwa, tí àwọn Kátólíìkì kà sí ohun mímọ́ ìsìn, jáde ní ṣọ́ọ̀ṣì. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Dallas Morning News ṣe sọ, àlùfáà John Noone sọ pé “àwọn olùjọsìn Sátánì ń fẹ́ láti mú àkàrà ara Olúwa náà,” kí wọ́n lè sọ ọ́ di “aláìmọ́.” Iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ Ara Olúwa náà ni láti máa ṣọ́ àwọn ọmọ ìjọ, kí ó sì wò ó bóyá wọ́n jẹ ẹ́ ní tòótọ́. Bí wọn kò bá jẹ ẹ́, a ó rọra rọ àwọn olùreṣọ́ọ̀ṣì náà láti jẹ Àkàrà Ara Olúwa náà tàbí kí wọ́n dá a pa dà.
Rírántí Ìran Fídíò ní Kedere
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ kan tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn Pediatrics ṣe sọ, “àwọn ìwádìí àṣedánrawò mélòó kan fi hàn pé àwọn fídíò orin lè nípa gidigidi lórí ìhùwàsí nípa sísọ àwọn tí ń wò wọ́n di aláìní-ìmọ̀lára-òdì nípa ìwà ipá àti nípa mímú kí àwọn ọ̀dọ́langba túbọ̀ fara mọ́ ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó.” Àwọn ọ̀rọ̀ inú orin onílù dídún kíkankíkan àti orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò elédè àwọn ìpàǹpá asùnta ní ń dààmú àwọn òbí jù lọ. “Fún àwùjọ kéréje àwọn ọ̀dọ́langba kan, irú orin tí wọ́n yàn láàyò lè jẹ́ ìtọ́ka pàtàkì kan. Ọ̀pọ̀ ìwádìí ti tọ́ka sí i pé yíyan orin onílù dídún kíkankíkan láàyò lè jẹ́ àmì ṣíṣe kókó kan fún ìyara-ẹni-sọ́tọ̀, lílo àwọn èròjà tí ń di bárakú nílòkulò, àwọn àrùn ọpọlọ, ewu pípa ara ẹni, fífọkànyàwòrán ipa ti ẹ̀yà kejì, tàbí àwọn ìwà ìfarawewu nígbà ọ̀dọ́langba.” Ìròyìn náà, tí àwọn dókítà mẹ́jọ kó jọ láàárín ọdún 1995 àti 1996, sọ pé: “Bí àwọn òǹwòran bá gbọ́ orin kan lẹ́yìn tí wọ́n ti wo fídíò rẹ̀, lọ́gán ni wọn ń ‘rántí’ ìran inú fídíò náà ‘ní kedere.’”
Bébà Tí A Fi Ìyàgbẹ́ Erin Ṣe
Nígbà tí àwọn aládùúgbò ṣàkíyèsí pé Mike Bugara ń se ìyàgbẹ́ erin nínú ọgbà ilé rẹ̀, a lè lóye rẹ̀ pé, ìdààmú bá wọn. Àwọn kan rò pé iṣẹ́ àjẹ́ ló ń ṣe, ṣùgbọ́n, ní gidi, bébà ló ń ṣe. Ọ̀gbẹ́ni Bugara ti kọ́kọ́ fi ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀, ewé àgbàdo, àti ewé eucalyptus ṣe bébà. Ṣùgbọ́n ìpèsè ìyàgbẹ́ erin tó ní fọ́nrán rẹpẹtẹ nínú lọ́pọ̀ yanturu ní Kenya mú kí onítara alágbàwí ààbò ẹ̀dá náà bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bí ó ṣe lè máa fi ṣe bébà. Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé, ó pinnu pé ìyẹn yóò jẹ́ ọ̀nà gbígbéṣẹ́ kan láti ta “ìmọ̀ àwọn ènìyàn nípa ìníyelórí dídáàbò bo irú ọ̀wọ́ erin náà” jí. Ní báyìí, bébà tí ó fi ìyàgbẹ́ erin ṣe ni a ń lò fún ìwé ìpè síbi ayẹyẹ 50 ọdún Ìpèsè Àbójútó Ẹran Ìgbẹ́ ní Kenya lọ́dún yìí.
Àwọn Àṣà Ìjẹun
Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé tẹlifíṣọ̀n ni “ìdójúlé ọ̀pọ̀ lára àwọn ìhùwà aláṣà ìgbàlódé.” Àpẹẹrẹ kan tí a fúnni ni àṣà jíjẹun nígbà tí a ń wo tẹlifíṣọ̀n—tí ó jẹ́ àṣà kan ní àwọn orílẹ̀-èdè yí ká ayé nísinsìnyí. Bí àpẹẹrẹ, ní Mexico, ọ̀pọ̀ ìdílé ní ń jẹun alẹ́ wọn níbi tí wọ́n ti ń wo àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n. Ìwádìí kan tí a ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ní ilẹ̀ Faransé fi hàn pé “a ń jẹ ìpín 62 nínú ọgọ́rùn-ún oúnjẹ nídìí tẹlifíṣọ̀n.” Ní China, àwọn òǹwòran máa ń gbádùn àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ àrà ọ̀tọ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n nígbà tí wọ́n bá ń jẹ hóró bàrà olómi tí wọ́n ti yan. Àwọn hóró dúdú wọ̀nyí tún wọ́pọ̀ láàárín àwọn òǹwòran tẹlifíṣọ̀n ní Ísírẹ́lì pa pọ̀ pẹ̀lú hóró abóòrùnyí àti èso pistachio. Àwọn ìpápánu tí a máa ń jẹ nígbà tí a bá ń wo tẹlifíṣọ̀n ní Philippines ní ẹsẹ̀ adìyẹ yíyan, etí ẹlẹ́dẹ̀ yíyan, àti ìfun adìyẹ tí a ti gún sí pọ̀pá. Ìwé agbéròyìnjáde Times sọ pé ìpápánu kan tí a yàn láàyò ni balut—“ọlẹ̀ pẹ́pẹ́yẹ tí a sè mọ́ èèpo, tí a wọ́n iyọ̀ sí, tí a sì ń jẹ láti inú kòròfo ẹyin.”
Ìdènà Tí Kò Náni Lówó fún Àrùn Onígbáméjì
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà gbọ́ pé àwọn ti rí ọ̀nà kan tí kò náni lówó fún dídènà àrùn onígbáméjì—fífi aṣọ sari sẹ́ omi mímu! Àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Maryland, ni United States, àti Ibùdó Àgbáyé fún Ìwádìí Lórí Àwọn Àrùn Tó Jẹ Mọ́ Ìgbẹ́ Gbuuru, ní Dacca, Bangladesh, ṣàwárí pé bakitéríà tí ń fa àrùn onígbáméjì ń gbé inú ìfun àwọn copepod, tí ó dà bí àwọn ohun alààyè ojú omi tí ń gbé inú omi. Nípa fífi ìṣẹ́po mẹ́rin aṣọ sari sẹ́ omi, a lè sẹ́ èyí tí ó lé ní ìpín 99 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn bakitéríà àrùn onígbáméjì kúrò. A lè mú ìdọ̀tí náà kúrò lára aṣọ sari náà nípa sísá a sóòrùn tààrà fún wákàtí méjì, tàbí ní àkókò òjò, nípa fífún egbòogi apakòkòrò tí kò wọ́nwó sí i. Ìwé agbéròyìnjáde The Independent ti London ròyìn pé àwọn àṣedánrawò ẹ̀yìn òde ibi ìwádìí yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́dún yìí, nígbà tí a óò fi bí a ti ń ṣe é kọ́ àwọn tí ń gbé àgbègbè tí ọ̀ràn kàn.
Ìtara Ọkàn Ọlọ́yàyà Tí America Ní fún Ìbọn
Ìwé agbéròyìnjáde Daily News ti New York ròyìn pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a ṣe ní America ṣe fi hàn, ìpín 4 nínú 10 àwọn àgbàlagbà ará America ń gbé nínú agboolé tó ní àwọn ìbọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn agboolé náà sì ní ìbọn méjì ní ìpíndọ́gba. Nínú ìwádìí náà, ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé àwọn ní ìbọn ìléwọ́, ìpín 27 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé àwọn ní ìbọn ṣakabùlà, ìpín 29 nínú ọgọ́rùn-ún sì sọ pé àwọn ní ìbọn àgbéléjìká.” Ọ̀pọ̀ agboolé ní ju oríṣi ìbọn kan ṣoṣo lọ.