Ìdí Tí Àwọn Ọmọdé Fi Dára Fún Ogun Jíjà
ṢÉ O PÀNÌYÀN? “Rárá.”
ṢÉ O NÍ ÌBỌN? “Bẹ́ẹ̀ ni.”
ṢÉ O NA ÌBỌN NÁÀ SÍ ÈNÌYÀN? “Bẹ́ẹ̀ ni.”
ṢÉ O YÌN ÍN? “Bẹ́ẹ̀ ni.”
KÍ LÓ WÁ ṢẸLẸ̀? “Wọ́n kàn ń ṣubú lulẹ̀ ni.”—World Press Review, January 1996.
ÌJÍRÒRÒ amúniwárìrì yí tó wáyé láàárín òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan àti ọmọdé sójà kan ní Áfíríkà fi ìdàrúdàpọ̀ tó wà lọ́kàn ọmọdé kan tí ń làkàkà láti ṣàtúnṣe ìgbésí ayé rẹ̀ àtẹ̀yìnwá hàn.
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ọmọdé tí wọn kò tí ì pé ọmọ ọdún 16 ti ń kópa nínú ìjà ní àwọn orílẹ̀-èdè 25. Láàárín 1988 nìkan, nǹkan bí 200,000 ọmọdé ní ń kópa nínú ogun. Nítorí pé àwọn àgbàlagbà ti mú àwọn ọmọdé sìn gẹ́gẹ́ bíi jagunjagun, àwọn pẹ̀lú jẹ́ òjìyà ìpalára.
Ìdí Tí A Fi Fẹ́ Wọn Gẹ́gẹ́ Bíi Sójà
Nígbà kan rí, nígbà tí àwọn ológun ń fi ọ̀kọ̀ àti idà jà, ọmọdé kan kì í fi bẹ́ẹ̀ lè là á já ní kíkọjúùjàsí àgbàlagbà kan tó gbé irú ohun ìjà kan náà. Àmọ́ sànmánì olóhun-ìjà fífúyẹ́ la wà yí. Lónìí, ọmọdé kan tí ó ní ìbọn àgbétèjìká kan—ìbọn àgbétèjìká AK-47 tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Soviet tàbí ìbọn àgbétèjìká M16 kan tí wọ́n ṣe ní America—lè kojú àgbàlagbà kan.
Kì í ṣe pé àwọn ohun ìjà wọ̀nyí fúyẹ́ nìkan ni àmọ́ wọ́n tún rọrùn láti lò àti láti ṣètọ́jú. Ọmọ ọdún mẹ́wàá lè tú ìbọn àgbétèjìká AK-47 kan palẹ̀ kí ó sì tò ó pa dà. Àwọn ìbọn àgbétèjìká wọ̀nyí wà lọ́pọ̀ yanturu pẹ̀lú. Nǹkan bíi mílíọ̀nù 55 ìbọn àgbétèjìká AK-47 ni a ti tà. Ní orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, iye tí wọ́n ń tà á kò ju dọ́là mẹ́fà (ti U.S.) lọ. Àwọn ìbọn àgbétèjìká M16 pẹ̀lú wà lọ́pọ̀ yanturu, wọn kò sì wọ́n.
Yàtọ̀ sí pé wọ́n lè lo àwọn ìbọn àgbétèjìká, àwọn ọmọdé jẹ́ sójà tí a nífẹ̀ẹ́ sí nítorí àwọn ìdí mìíràn. Wọn kì í béèrè fún owó oṣù, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ sá fiṣẹ́ ológun sílẹ̀. Ní àfikún sí i, àwọn ọmọdé ní ìyánhànhàn gidigidi láti tẹ́ àwọn tí wọ́n dàgbà jù wọ́n lọ lọ́rùn. Ìfẹ́ ọkàn láti jẹ́ ẹni tí ẹgbẹ́ adáninídè tàbí ẹgbẹ́ ológun agbábẹ́lẹ̀jagun èyíkéyìí tó bá ti di “ẹbí” wọn tẹ́wọ́ gbà máa ń bo agbára ìrònú wọn láti mọ ire yàtọ̀ sí ibi mọ́lẹ̀.
Ó tún ń ṣẹlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ lára wọn kì í bẹ̀rù. Alálàyé kan nípa ogun ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ṣàlàyé pé: “Níwọ̀n bí ó ti jọ pé [àwọn ọmọdé] kò ní òye kan náà tí àwọn àgbàlagbà sójà ní nípa ikú, kò jọ pé wọ́n óò juwọ́ sílẹ̀ nínú ipò tí kò ti sí ìrètí.” Ọmọdékùnrin ará Liberia kan, tí ń jẹ́ orúkọ náà, Ọ̀gágun Ẹ̀rọ Ìpànìyàn, yangàn pé: “Nígbà tí àwọn àgbàlagbà bá yíjú pa dà, tí wọ́n sì sá lọ, àwa ọmọdékùnrin kéékèèké ni a ń dúró láti jà.”
Lọ́nà títakora, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdékùnrin dára bíi sójà, a sábà máa ń wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni tí a lè tètè fi òmíràn rọ́pò. Nígbà ogun kan ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, wọ́n pàṣẹ fún ẹgbẹ́ ogun àwọn ọmọdé sójà láti ṣíwájú ní líla àwọn pápá tí ohun abúgbàù wà kọjá.
Ìgbanisíṣẹ́-Ológun àti Ìfinisípòoṣẹ́ Ara Yíyẹ
Àwọn ọmọdé kan dara pọ̀ mọ́ àwọn ológun tàbí àjọ àwọn aṣòdìsíjọba nítorí pé wọ́n ń fẹ́ ṣe ojúmìító ipò eléwu. Bákan náà, nígbà tí ohun eléwu bá ń halẹ̀, tí àwọn ìdílé kò sì rójú ráyè, ẹ̀ka ẹgbẹ́ ológun kan yóò pèsè ìmọ̀lára ààbò fún wọn, yóò sì di àfirọ́pò ẹbí. Àjọ Àkànlò Owó ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé sọ pé: “Àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà sáàárín ìwà ipá rí èyí bí ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó wà títí lọ. Bí wọ́n ti dá wà, tí wọ́n jẹ́ aláìlóbìí, tí jìnnìjìnnì bá wọn, tí nǹkan sú wọn, tí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bò wọ́n, wọn óò sábà yàn láti jagun níkẹyìn.”
Àwọn ọmọdé mìíràn ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ ológun nítorí ó lè jọ pé kò sí yíyàn tó sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà míràn, tí oúnjẹ bá ṣọ̀wọ́n, tí ohun eléwu sì ń halẹ̀, ó lè jọ pé dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ológun kan ni ọ̀nà kan ṣoṣo láti là á já.
Nígbà míràn, àwọn ọmọdé lè rí ara wọn bí ẹni tí ń jà fún ìdájọ́ òdodo ti àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn, àwọn èrò ìgbàgbọ́ ìsìn, tàbí àwọn ìdánimọ̀ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní Peru, àwọn ọmọdé tí a ti fipá mú láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ agbábẹ́lẹ̀jagun ń gba ìtọ́ni olóṣèlú fún àkókò gígùn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà ni ìyẹn kò pọn dandan. Brian Milne, onímọ̀ nípa ìṣesí ẹ̀dá ènìyàn tí ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọmọdé sójà ní Gúúsù ìlà oòrùn Éṣíà, sọ pé: “Àwọn ọmọdé kò ní àwọn àbá èrò orí ìrítẹ́lẹ̀. A wulẹ̀ ń fà wọ́n láti ìhà kan tàbí òmíràn, a sì ń mú wọn ṣiṣẹ́.”
Síbẹ̀, ipá ni wọ́n fi mú àwọn ọmọdé mìíràn láti dara pọ̀. Nínú àwọn ogun kan ní Áfíríkà, àwọn ẹ̀ka ẹgbẹ́ ológun kan ń kógun wọ àwọn abúlé kan láti lọ kó àwọn ọmọdé, tí wọ́n wá ń mú kí wọ́n wo ìdálóró àti pípa àwọn ìdílé wọn tàbí kí wọ́n tilẹ̀ lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Nígbà míràn, wọ́n ń fipá mú wọn láti yìnbọn fún àwọn òbí wọn tàbí láti dúńbú wọn. Níwọ̀n bí a ti kó ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bá àwọn ọmọdékùnrin náà, a sún wọn láti kó ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bá àwọn ẹlòmíràn. Àwọn ọ̀dọ́mọdé tí a hùwà òǹrorò sí wọ̀nyí sábà máa ń hu àwọn ìwà òǹrorò tí àwọn àgbà sójà onírìírí yóò kọ̀ láti hù.
Pípadà sí Ìgbésí Ayé Tó Wà Déédéé
Kò rọrùn fún irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ láti mú ara bá ìgbésí ayé aláìníwà-ipá mu. Olùdarí ibùdó àbójútó àwọn ọmọdé kan ní orílẹ̀-èdè kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà sọ pé: “Gbogbo àwọn ọmọ tí a ti tọ́jú ni wọ́n ti dààmú agbára èrò orí wọn dé ìwọ̀n oríṣiríṣi. Wọ́n ti fipá báni lò, wọ́n ti pànìyàn, wọ́n sì ti dáni lóró. Wọ́n ti fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ní ọtí tàbí oògùn líle mu, lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ, igbó, àmọ́ nígbà míràn heroin. . . . O lè finú wòye ipa búburú tí irú ohun bẹ́ẹ̀ ń ní lórí èrò inú àwọn ọmọdé, tí àwọn kan lára wọn kò ju ọmọ ọdún mẹ́jọ tàbí mẹ́sàn-án lọ.”
Ipò náà rí bákan náà ní Liberia tí kò jìnnà síbẹ̀, níbi tí ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn ọmọdé ti lo ìgbà ọmọdé wọn ní kíkó ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bá àwọn ará àgbègbè àrọko. Kò rọrùn fún àwọn ọ̀dọ́langba tí a fi joyè aṣáájú ogun àti ọ̀gágun láti jọ̀wọ́ ipò àti agbára tí ìbọn àgbétèjìká AK-47 gbé lé wọn lọ́wọ́. Ẹnì kan tí ń gbé Somalia sọ pé: “Bí o bá ní ìbọn, ni o máa wà láàyè. Bí o kò bá ní ìbọn, ikú pa ọ́.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọdé tí ń jagun kò lè pa dà sílé nítorí ìforóyaró tàbí nítorí pé ìdílé wọn yóò kọ̀ wọ́n. Olùgba-ọmọdé-nímọ̀ràn kan ní Liberia sọ pé: “Àwọn ìyá máa ń wí fún wa pé, ‘ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín. A kò fẹ́ ewèlè yí nínú ilé wa.’”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ti mú ara bá ipò gbígbé ìgbésí ayé alálàáfíà mu, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń béèrè ìfẹ́, ìtìlẹ́yìn, àti òye púpọ̀ jọjọ láti ọ̀dọ̀ àwọn tó yí wọn ká. Bí kò ṣe rọrùn fún àwọn ọmọ náà ni kò rọrùn fún àwọn ìdílé wọn. Òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan ní Mòsáḿbíìkì ṣàlàyé pé: “Fi ìgbésí ayé níní àǹfààní láti mú ohunkóhun tí o bá fẹ́, láti pàṣẹ fún àwọn ẹlòmíràn, wé ìgbésí ayé rẹ nígbà tí o bá pa dà sí abúlé. Ní pàtàkì, tí o bá jẹ́ ọmọ ọdún 17, tí o jẹ́ púrúǹtù, tí o kò sì mọ iṣẹ́ kankan. A ti ṣá ọ tì sínú ìgbésí ayé tí ń súni. Ó ṣòro gan-an láti pa dà síbi tí àwọn ẹlòmíràn yóò ti máa pàṣẹ fún ọ, kí o sì pa dà lọ bẹ̀rẹ̀ ìpele ẹ̀kọ́ kìíní.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Anwar, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 13, ń gbé ní Afghanistan. Ó ti ja ogun mẹ́fà, ìgbà àkọ́kọ́ tí yóò pànìyàn ni ìgbà tó lọ lẹ́ẹ̀keje. Ó yìnbọn pa àwọn sójà méjì kan tí wọn kò jìnnà sí i, ó sì fi ìdí ìbọn àgbétèjìká rẹ̀ gún ara wọn láti rí i dájú pé wọ́n ti kú. Nígbà tí a béèrè èrò rẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó jọ pé ó ṣòro fún Anwar láti dáhùn ìbéèrè náà. Ó sọ pé: “Inú mi dùn nítorí pé mo pa wọ́n.”
Nínú ogun kan náà, àwọn sójà ẹlẹgbẹ́ Anwar mú àwọn sójà ọ̀tá mẹ́rin kan. Wọ́n dè àwọn tí wọ́n mú náà, wọ́n fi nǹkan bò wọ́n lójú, wọ́n sì yìnbọn pa wọ́n. Kí ni èrò Anwar nípa ìyẹn? Ọ̀dọ́mọdé jagunjagun náà sejú, ó fara balẹ̀, ó sì rọra dáhùn, bíi pé ẹnì kan tí kò ní làákàyè ló ń bá sọ̀rọ̀. “Inú mi dùn.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sọ́wọ́ ẹlẹ́wọ̀n kan tí a óò tú sílẹ̀ láìpẹ́ ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, àmọ́ ọ̀gágun náà ti sọ kọ́kọ́rọ́ nù. Ọ̀gágun náà yanjú ìṣòro náà nípa pípàṣẹ fún ọmọdékùnrin sójà kan láti gé ọwọ́ ẹlẹ́wọ̀n náà. Ọmọdékùnrin náà sọ pé: “Mo ṣì máa ń gbọ́ igbe ọkùnrin yẹn nínú àlá mi. Gbogbo ìgbà tí mo bá ronú kan án, ni mo máa ń kábàámọ̀ nípa rẹ̀.”