ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 4/8 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Ọmọdé Wà Nínú Ewu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọmọdé Wà Nínú Ewu
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọmọdé Tó Jẹ́ Sójà àti Ilé Ìtọ́jú Àwọn Ọmọ Òrukàn
  • Láti Inú Òógùn Àwọn Ọmọdé
    Jí!—1999
  • Kíkó Àwọn Ọmọdé Nífà Ìbálòpọ̀—Ìṣòro Kan Tí Ó Kárí Ayé
    Jí!—1997
  • Yíya Àwọn Obìnrin Sọ́tọ̀
    Jí!—1998
  • Ìdí Tí Àwọn Ọmọdé Fi Dára Fún Ogun Jíjà
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 4/8 ojú ìwé 3-4

Àwọn Ọmọdé Wà Nínú Ewu

“Bí a kò bá fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọdé, kí a sì lo ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá lé wọn lórí, a kò lè bọ́ nínú gbogbo ìṣòro ńláńlá tí ó le jù lọ tí aráyé ti ń bá jà láti ìgbà pípẹ́.”—Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé.

GBOGBO ọmọdé jákèjádò ayé ló wà nínú ewu. A fi ẹ̀rí tó dájú nípa bí ọ̀ràn ìbìnújẹ́ náà ṣe burú tó hàn níbi Àpéjọ Àgbáyé Tí Ń Gbéjà Ko Lílo Àwọn Ọmọdé fún Iṣẹ́ Aṣẹ́wó tí wọ́n ṣe ní Stockholm, Sweden, ní ọdún 1996, tí àwọn aṣojú láti àádóje orílẹ̀-èdè sì pésẹ̀ síbẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó wà nínú àkọsílẹ̀ pe, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin kéékèèké, tí àwọn kan lára wọn kò ju ọmọ ọdún mẹ́wàá lọ pàápàá, ni a ti fi ipá mú láti ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó ní àwọn apá ibi púpọ̀ lágbàáyé.

Ìwé ìròyìn Melbourne University Law Review ti ilẹ̀ Ọsirélíà sọ pé a ti pe irú ìfipámúni ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó bẹ́ẹ̀ ní “ọ̀kan nínú èyí tó burú jù lọ lára àwọn ohun tó dàbí òwò ẹrú ti lọ́wọ́lọ́wọ́.” Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún ìfìyàjẹni, ìdanilórírú, àti ìbanilọ́kànjẹ́, àwọn ọmọdébìnrin wọ̀nyí máa ń wà ní ipò ìbànújẹ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà máa ń fara sílẹ̀ fún ìwà òkú òǹrorò yìí nítorí àtijẹun kí wọ́n má bàa kú. Àyàfi tí wọ́n bá fẹ́ kí ebi pa àwọn kú. Ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọdé wọ̀nyí ni àwọn òbí wọn tí ìyà ti pá àwọn alára lórí ló fipá tì wọ́n sẹ́nu iṣẹ́ aṣẹ́wó nípa títà wọ́n nítorí owó.

Ohun tó sábà máa ń fa àríyànjiyàn lílekoko tó sì tún máa ń dá kún ìṣòro bíbaninínújẹ́ tí àwọn ọmọdé ní yìí ni ọ̀ràn nípa kíkó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́. A ń fipá mú àwọn ọmọdé tí àwọn kan lára wọn kò tilẹ̀ ju ọmọ ọdún márùn-ún lọ láti ṣe ohun tí a ń pè ní “iṣẹ́ ẹrú” ní Éṣíà, Gúúsù Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ní àwọn ibòmíràn àti láàárín àwọn ẹgbẹ́ kan tí ń kó káàkiri ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ bí ẹ̀rọ kéékèèké tí a ń darí lábẹ́ ipò tí ń dáyà foni tó sì ń sọ ẹran ara àti èrò inú wọn tó jẹ́ tọmọdé dìbàjẹ́. Ọ̀pọ̀ nínú wọn kò kàwé, wọn ò lóbìí tó nífẹ̀ẹ́ wọn, wọn ò nílé kankan tí wọ́n lè forí pa mọ́ sí, kò sí ohun ìṣeré fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àwọn ọgbà ohun alààyè tí wọ́n ti lè lọ ṣeré. Ọ̀pọ̀ ni àwọn òbí wọ́n ń fi ọmọdé yàn jẹ lọ́nà àìgbatẹnirò.

Àwọn Ọmọdé Tó Jẹ́ Sójà àti Ilé Ìtọ́jú Àwọn Ọmọ Òrukàn

Ohun tó mú kí ọ̀ràn ìbìnújẹ́ náà túbọ̀ burú sí i ni pé àwọn ọmọdé tí a ń lò fún iṣẹ́ sójà ti ń pọ̀ sí i nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun agbábẹ́lẹ̀jagun. Wọ́n lè jí àwọn ọmọdé gbé tàbí kí wọ́n rà wọ́n ní ọjà ẹrú, lẹ́yìn náà kí wọ́n wá máa hùwà òǹrorò sí wọn díẹ̀díẹ̀, ó lè jẹ́ nípa mímú kí wọ́n máa wo ìṣìkàpànìyàn nígbà mìíràn. Kódà wọ́n ti pàṣẹ fún àwọn kan láti pa àwọn òbí tiwọn alára tàbí láti lo oògùn líle kí òòfà ọkàn wọn láti pànìyàn lè pọ̀ sí i.

Ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí jẹ́ àpẹẹrẹ kan lára àwọn àbájáde ìyíniléròpadà tí a ti ṣe fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọdé tó jẹ́ sójà ní Áfíríkà. Ìjíròrò amúniwárìrì yìí wáyé láàárín òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan àti ọmọdékùnrin kan tó jẹ́ sójà tó hàn gbangba pé ó ń gbìyànjú láti fi hàn pé òun kò jẹ̀bi:

“Ṣé o pànìyàn? ‘Rárá.’

Ṣé o níbọn? ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’

Ṣé o na ìbọn náà sí ènìyàn? ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’

Ṣé o yìn ín? ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’

Kí ló wá ṣẹlẹ̀? ‘Wọ́n kàn ṣubú lulẹ̀ ni.’”

Abájọ tí ẹnì kan fi sọ pé, díẹ̀ ni àwọn kan lára àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí fi ju “ọmọ ọwọ́” lọ nígbà tí a bá ń wo àwọn sójà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà sókè. Ìròyìn fi hàn pé láti nǹkan bí ọdún 1988 sẹ́yìn ni iye àwọn ọmọdé tó jẹ́ sójà ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba káàkiri àgbáyé.

A gbọ́ pé àwọn ọmọdé tí wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́ta, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọ́n jẹ́ obìnrin, ni a yà sọ́tọ̀ láti fi ebi pa kú ní ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn kan ní orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà láàárín ọdún 1988 sí ọdún 1992. Dókítà kan ròyìn pé: “Àwọn ọmọ òrukàn wọ̀nyẹn kò rí oògùn lò láti pa ìrora wọn. Kódà ṣe ni a dè wọ́n mọ́ bẹ́ẹ̀dì wọn nígbà tí wọ́n ń joró ikú lọ́wọ́.”

Báwo ni ọ̀ràn náà ṣe rí ní ilẹ̀ Yúróòpù? Akutupu hu ní orílẹ̀-èdè kan níbẹ̀ nígbà tí a ṣàwárí ẹgbẹ́ kárí ayé ti arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lára àwọn ọmọdé tí wọ́n ń fipá gbé àwọn ọmọbìnrin sá lọ láti bá wọn lòpọ̀. Àwọn kan tó kàgbákò lára àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà ni wọ́n ṣe ìkà pa tàbí kí wọ́n febi pa wọ́n kú.

Àwọn ìròyìn wọ̀nyí fi hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ní ìṣòro gidi pẹ̀lú híhùwà àìdáa sí àwọn ọmọdé àti fífi ọmọdé yàn wọ́n jẹ. Àmọ́, ṣé àsọdùn ni láti sọ pé èyí jẹ́ ìṣòro tó kárí ayé? Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ọmọdé tó jẹ́ sójà ní Liberia

[Credit Line]

John Gunston/Sipa Press

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ní ilé iṣẹ́ bíríkì kan ní Colombia, àwọn ọmọdé ń kẹ́rù bí ọmọlanke

[Credit Line]

FỌ́TÒ UN 148000/Jean Pierre Laffont

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Fọ́tò FAO/F. Botts

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́