Àjàkálẹ̀ Àrùn Black Death Kì Í Ṣe Òpin Ayé
NÍ OCTOBER ọdún 1347, àwọn ọkọ̀ òkun olówò láti Ìlà Oòrùn gúnlẹ̀ sí èbúté Messina, ní Sicily. Àrùn ti mú àwọn atukọ̀ náà, wọ́n sì ń kú lọ. Ẹ̀jẹ̀ àti ọyún ń yọ níbi tí ó wú káàkiri ara wọn, tí ó tóbi tó ẹyin, tí ó sì dúdú. Àwọn atukọ̀ náà ń jẹ̀rora púpọ̀ jọjọ, wọ́n sì ń kú láàárín ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí àmì àrùn náà.
Àwọn èkúté inú ọkọ̀ náà yára dara pọ̀ mọ́ àwọn èkúté tí ó wà nílùú náà. Àwọn èkúté náà ní eégbọn tí ó ní bakitéríà bacillus, tí ó lè ṣekú pa ènìyàn, lára. Bẹ́ẹ̀ ni àjàkálẹ̀ àrùn tí a mọ̀ sí ìyọnu àjàkálẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn Black Death, àjàkálẹ̀ àrùn bíburújáì tí ó tí ì ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ilẹ̀ Yúróòpù títí di ìgbà yẹn, ṣe tàn kálẹ̀.
Ìyọnu àjàkálẹ̀ náà pín sí ọ̀nà méjì. Èyí àkọ́kọ́, tí ó máa ń ranni, bí eégbọn alárùn kan bá buni jẹ́, máa ń tan àrùn náà ká inú ìṣàn ẹ̀jẹ̀, ó sì ń fa ara wíwú àti ìṣẹ̀jẹ̀sínú. Èkejì, tí àwọn ẹlòmíràn máa ń kó láti inú ikọ́ tàbí sísín, máa ń kó àrùn bá ẹ̀dọ̀fóró. Nítorí pé irú àwọn méjèèjì ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, àrùn náà ń yára gbèèràn, lọ́nà tí ó burú jáì. Láàárín ọdún mẹ́ta péré, ó ti pa ìdá mẹ́rin àwọn olùgbé ilẹ̀ Yúróòpù; bóyá mílíọ̀nù 25 ènìyàn ló kú.
Nígbà náà, kò sí ẹni tí ó mọ bí àrùn náà ṣe ń gbèèràn láti ara ẹnì kan dé ara ẹlòmíràn. Àwọn kan gbà gbọ́ pé ńṣe ni májèlé dà sáfẹ́fẹ́, bóyá nítorí ìsẹ̀lẹ̀ kan tàbí ìmúbáramu àwọn pílánẹ́ẹ̀tì lọ́nà ṣíṣàjèjì kan. Àwọn mìíràn rò pé àwọn ènìyàn ń kó àrùn náà bí wọ́n bá wo ẹni tí àrùn náà ń ṣe lásán. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò àwọn ènìyàn yàtọ̀ síra, ó dájú pé àrùn náà ń gbèèràn gan-an. Oníṣègùn kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé ṣàlàyé pé, ńṣe ló jọ pé ẹnì kan tí ó ní àrùn náà “lè kó o ran gbogbo aráyé.”
Àwọn ènìyàn kò mọ ọ̀nà àtidènà rẹ̀, wọn kò sì mọ ọ̀nà ìwòsàn kankan. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ronú lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì bí èyí tí ó wà nínú Lúùkù 21:11, tí ó sàsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn àjàkálẹ̀ àrùn ní àkókò òpin. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé owó ń wọlé fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ìyọnu àjàkálẹ̀ náà ń bá a lọ. Ọmọ ilẹ̀ Ítálì kan kọ̀wé nígbà náà pé: “Wọn kò lu agogo ṣọ́ọ̀ṣì láti kéde ikú ẹnì kankan mọ́, ẹnikẹ́ni kì í sì í sunkún bí ó ti wù kí àdánù rẹ̀ pọ̀ tó nítorí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ló ń retí ikú . . . àwọn ènìyàn gbà gbọ́, wọ́n sì ń sọ pé, ‘Òpin ayé lèyí.’”
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe òpin ayé. Ní ìparí ọ̀rúndún kẹrìnlá, ìyọnu àjàkálẹ̀ yẹn kò jà mọ́. Ayé ṣì wà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Archive Photos