Àjàkálẹ̀ Àrùn Black Death—Ó Gbo Yúróòpù ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú
Látọwọ́ akọ̀ròyìn Jí! ni ilẹ̀ Faransé
Ní ọdún 1347 ni. Àjàkálẹ̀ àrùn tí a ń wí yìí ti pa àwọn èèyàn lọ rẹ́kẹrẹ̀kẹ ní Ìkángun Ìlà Oòrùn ayé. Wàyí o, ó ti dé ààlà ìlà oòrùn Yúróòpù.
ÀWỌN ará Mongolia kógun ti ibùdó ìṣòwò àwọn ará Genoa tí wọ́n mọdi yí ká ní Kaffa, tó ń jẹ́ Feodosiya nísinsìnyí, ní Crimea. Nítorí pé abàmì àrùn náà ń pa àwọn ará Mongolia alára nípakúpa, wọ́n yáa kógun wọn padà. Àmọ́ kí wọ́n tó padà, àwọn náà já nǹkan sílẹ̀. Wọ́n fi àwọn àkàtàǹpó ńlá ju òkú àwọn tí àrùn náà ṣẹ̀ṣẹ̀ pa gba orí odi ìlú náà. Bí díẹ̀ lára àwọn ará Genoa tó ń gbèjà ìlú wọ́n ti kó sínú ọkọ̀ òkun wọn lẹ́yìn náà, tí wọ́n sì sá kúrò ní ìlú tí àrùn ti kọ lù náà, wọ́n kó àrùn náà ran àwọn èèyàn ní gbogbo èbúté tí wọ́n dé.
Láàárín oṣù mélòó kan, ńṣe ni òkú sùn lọ jákèjádò Yúróòpù. Kíá ó ti tàn dé Àríwá Áfíríkà, Ítálì, Sípéènì, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ilẹ̀ Faransé, Austria, Hungary, Switzerland, Jámánì, Scandinavia, àti àgbègbè Baltic. Nígbà tó lé díẹ̀ lọ́dún méjì, ó lé ní ìdá mẹ́rin lára gbogbo olùgbé Yúróòpù, ìyẹn jẹ́ nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n èèyàn, tó ti ṣòfò ẹ̀mí, ohun tí wọ́n pè ní “àjálù tó tíì pààyàn jù lọ”—àrùn Black Death, ti lù wọ́n pa.a
Bí Àgbákò Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀
Àjálù àrùn Black Death kò mọ sórí àrùn náà nìkan. Àwọn ohun bíi mélòó kan ló fà á tí àgbákò náà fi le gan-an, ọ̀kan lára wọn sì ni ìtara ìsìn. Àpẹẹrẹ kan ni ẹ̀kọ́ pọ́gátórì. Òpìtàn Jacques le Goff, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Nígbà tó fi máa di òpin ọ̀rúndún kẹtàlá, kò síbi tí ẹ̀kọ́ pọ́gátórì ò tíì dé.” Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìnlá, Dante ṣe ìwé rẹ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn gba tiẹ̀, èyí tó pè ní, The Divine Comedy, àwòrán ọ̀run àpáàdì àti pọ́gátórì sì wà níbẹ̀. Bó ṣe di pé àwọn èèyàn gbé ẹ̀sìn karí nìyẹn, tó mú kí wọ́n dágunlá sí àjàkálẹ̀ àrùn náà, láìjanpata, wọ́n sì kà á sí pé àmúwá Ọlọ́run ni. Bí a ó ṣe rí i, irú èrò burúkú bẹ́ẹ̀ ló wá mú kí àrùn náà tàn káàkiri bẹ́ẹ̀. Ìwé The Black Death, tí Philip Ziegler ṣe, sọ pé: “Kò sí ohun tó tún lè dẹlẹ̀ fún àjàkálẹ̀ àrùn jùyẹn lọ.”
Ìṣòro àwọn ohun ọ̀gbìn tí kò ṣe dáadáa tó ń wáyé léraléra ní Yúróòpù tún dá kún ọ̀ràn náà. Nítorí èyí, àwọn olùgbé ilẹ̀ náà, tí iye wọn ń pọ̀ sí i kò rí oúnjẹ tó dáa jẹ—ara wọn ò wá lè dènà àrùn mọ́.
Àrùn Náà Di Àjàkálẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn Guy de Chauliac, tó ń tọ́jú Póòpù Clement Kẹrin, ṣe sọ, oríṣi àrùn méjì ló kọlu ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn ni: òtútù àyà àti ọyún tó ń sun jáde látinú ara. Ó ṣàlàyé àwọn àrùn náà kínníkínní, ó ní: “Oṣù méjì ni èyí àkọ́kọ́ fi jà, ibà ò sì yé yọ àwọn tó ń ṣe lẹ́nu, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ń pọ ẹ̀jẹ̀, ó ń pa èèyàn láàárín ọjọ́ mẹ́ta. Ìkejì bá àwọn èèyàn fínra fún gbogbo sáà tí àwọn àrùn náà fi jà, ibà ò sì yé yọ àwọn tí ìyẹn náà ń ṣe lẹ́nu, ṣùgbọ́n àléfọ́ àti oówo tún bo gbogbo ara wọn, pàápàá ní abíyá àti odò abẹ́. Láàárín ọjọ́ márùn-ún lèyí ń pààyàn.” Àwọn dókítà ò rí nǹkan ṣe sí àrùn tó ń jà kálẹ̀ náà.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sá lọ nítorí ìbẹ̀rù—tí wọ́n já ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí àrùn náà ti ràn sílẹ̀. Ní ti gidi, àwọn ọ̀tọ̀kùlú àti àwọn amọṣẹ́dunjú ló kọ́kọ́ sá lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àlùfáà kan sá lọ, ọ̀pọ̀ lára àwùjọ àwọn onísìn ló sá pa mọ́ sínú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìsìn wọn, pẹ̀lú ìrètí pé àwọn ò ní kó àrùn náà.
Pákáǹleke yìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ nígbà tí póòpù kéde ọdún 1350 ní Ọdún Mímọ́. Ó ní tààràtà láìsí ìdádúró ni àwọn tó bá lè wá sí Róòmù á wọ párádísè, wọn ò sì ní gba pọ́gátórì kọjá! Ẹgbàágbèje èèyàn ló lọ síbẹ̀—wọ́n sì ń tan àrùn náà ká gbogbo ibi tí wọ́n dé.
Gbogbo Ìsapá Ló Já Sásán
Gbogbo ìsapá láti dáwọ́ àjàkálẹ̀ àrùn Black Death dúró ló já sásán nítorí pé kò sẹ́ni tó mọ bó ṣe ń tàn káàkiri. Ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé ó léwu láti fara kan ẹni tó lárùn náà—tàbí kéèyàn tiẹ̀ fara kan aṣọ ẹ̀ pàápàá. Àwọn kan tiẹ̀ ń bẹ̀rù tí ẹni tó lárùn náà bá wò wọ́n! Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tó ń gbé àgbègbè Florence ní Ítálì, ológbò àti ajá làwọ́n ń di ẹ̀bi ẹ̀ rù. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dúńbú àwọn ẹranko wọ̀nyẹn, wọn ò mọ̀ pé ńṣe làwọ́n ń máyé dẹrùn fún èkúté, tó jẹ́ pé òun gan-an ló ń tan àrùn náà kálẹ̀.
Bí àwọn tó ń kú ṣe ń pọ̀ sí i, làwọn kan bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Ọlọ́run. Tọkùnrin tobìnrin ló ń fi gbogbo ohun ìní wọn ta ṣọ́ọ̀ṣì lọ́rẹ, wọ́n rò pé Ọlọ́run á ràdọ̀ bo àwọn kí àrùn náà má bàa kọlù àwọn—tàbí kó kàn tiẹ̀ fi ìwàláàyè ní ọ̀run san àwọn lẹ́san bí àwọ́n bá kú. Èyí sì sọ ìjọ di ọlọ́rọ̀ rẹpẹtẹ. Àwúre àti ère Kristi àti ìṣọ́rí wà lára ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò bí ẹ̀rọ̀. Àwọn míì yíjú sí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, idán, àti awúrúju oògùn láti fi wo ara wọn sàn. Wọ́n ní àwọn lọ́fínńdà, ọtí kíkan, àti àwọn àkànṣe àgbo ń lé àrùn náà lọ. Títú ẹ̀jẹ̀ dà nù tún ni irú ìwòsàn mìíràn. Ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìṣègùn ní Yunifásítì Paris tiẹ̀ sọ pé àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó tò sórí ìlà kan náà ló fa àrùn náà! Síbẹ̀, oríṣiríṣi irọ́ àti awúrúju “oògùn” wọ̀nyí kò lè dá títàn tí àrùn panipani náà ń tàn kálẹ̀ dúró.
Àwọn Ohun Tó Dá Sílẹ̀ Kò Lọ Bọ̀rọ̀
Lẹ́yìn ọdún márùn-ún, ó jọ pé àrùn Black Death ti kásẹ̀ ńlẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ọ̀rúndún náà tó parí, ó kéré tán, ẹ̀ẹ̀mẹrin ló tún bẹ́ sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n ṣe fi àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àrùn Black Death jà wé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní. Ìwé The Black Death in England tí wọ́n ṣe lọ́dún 1996 sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí àríyànjiyàn láàárín àwọn òpìtàn òde òní pé láti òpin ọdún 1348, tí àrùn kan bá bẹ́ sílẹ̀, ó máa ń nípa burúkú lórí ètò ọrọ̀ ajé àti àwùjọ ẹ̀dá.” Àrùn náà pa ẹgbàágbèje èèyàn, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sì kọjá kí àwọn àgbègbè kan tó bọ́ nínú rẹ̀. Nítorí pé iye àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ti dín kù, iye owó táwọn òṣìṣẹ́ ń fẹ́ gbà pọ̀ sí i. Àwọn ọmọ onílẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nígbà kan wá di aláìní, bákan náà ni ètò sísan ìṣákọ́lẹ̀, tó wọ́pọ̀ ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, forí ṣánpọ́n.
Nítorí náà, àrùn náà súnná sí ìyípadà nínú ètò ìṣèlú, ọ̀ràn ẹ̀sìn, àti àwùjọ ẹ̀dá. Kí àrùn náà tó jà, èdè Faransé làwọn ọ̀mọ̀wé ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sábà máa ń sọ lágbo wọn. Ṣùgbọ́n ikú ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ èdè Faransé ló mú kí èdè Gẹ̀ẹ́sì gbẹ̀yẹ lọ́wọ́ èdè Faransé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn ìyípadà tún ṣẹlẹ̀ nínú agbo ìsìn pẹ̀lú. Òpìtàn Jacqueline Brossollet, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Faransé, sọ pé nítorí pé àwọn tó fẹ́ di àlùfáà kò pọ̀, “ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn aláìmọ̀kan, tí kò ka nǹkan sí ni Ṣọ́ọ̀ṣì ń gbà.” Brossollet sọ pé, “tìtorí pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí [ṣọ́ọ̀ṣì] dá sílẹ̀ ń dìdàkudà, tí ìgbàgbọ́ sì ń ṣákìí ni Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe fi yọjú.”
Dájúdájú àrùn Black Death ní ipa púpọ̀ lórí iṣẹ́ ìyàwòrán, ọ̀rọ̀ nípa ikú wá wọ́pọ̀ nínú àkọlé àwòrán yíyà. Àwòrán olókìkí nì, danse macabre [ijó ikú], tó sábà máa ń jẹ́ àwòrán eegun òkú àti òkú, wá di àmì tó gbajúmọ̀ nípa agbára ikú. Nítorí pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó yè bọ́ lọ́wọ́ àrùn náà kò mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣèṣekúṣe kiri. Ìwà rere sì tipa bẹ́ẹ̀ wọ̀ọ̀kùn. Nítorí pé ṣọ́ọ̀ṣì ò lè ṣe nǹkan kan sí àrùn Black Death, “àwọn èèyàn tó gbé ayé ní sànmánì ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀làjú ronú pé Ṣọ́ọ̀ṣì ti já àwọn kulẹ̀.” (The Black Death) Àwọn òpìtàn kan tún sọ pé àwọn ìyípadà tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àrùn Black Death jà ṣokùnfà ẹ̀mí kí kálukú máa gbọ́ bùkátà ara ẹ̀ àti ìtẹ̀síwájú nínú káràkátà, àti àfikún ìgbòkègbodò nínú àwùjọ ẹ̀dá àti ọrọ̀ ajé—èyí tó bí ìṣòwò bòńbàtà.
Àrùn Black Death náà tún sún àwọn ìjọba láti gbé àwọn ètò ìmọ́tótó kalẹ̀. Lẹ́yìn tí àrùn náà lọ, Venice ṣe àwọn ètò kan tó fi palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ kúrò ní àwọn òpópónà rẹ̀. Ọba ilẹ̀ Faransé, John Kejì, tí wọ́n ń pè ní Ẹniire, pẹ̀lú pàṣẹ pé kí àwọn èèyàn máa palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ kúrò ní àwọn òpópónà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbógun ti ewu àjàkálẹ̀ àrùn. Ọba náà gbégbèésẹ̀ yìí lẹ́yìn tó gbọ́ nípa dókítà kan láyé àtijọ́, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì, tí kò jẹ́ kí àrùn kan gbèèràn ní Áténì nítorí pé ó ní kí àwọn èèyàn gbá àwọn òpópónà kí wọ́n sì fọ̀ wọ́n mọ́ tónítóní. Ọ̀pọ̀ òpópónà tí ìdọ̀tí ń ṣàn gbà ní sànmánì agbedeméjì, ni wọ́n gbá mọ́ tónítóní.
Ohun Àtijọ́ Ha Ni Bí?
Ṣùgbọ́n ọdún 1894 ni onímọ̀ nípa bakitéríà náà, Alexandre Yersin, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Faransé, tóó ṣàwárí bakitéríà tó fa àrùn Black Death. Orúkọ ọ̀gbẹ́ni náà ni wọ́n sọ bakitéríà náà, ìyẹn Yersinia pestis. Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà, ọmọ ilẹ̀ Faransé mìíràn, Paul-Louis Simond, ṣàwárí ipa ti yọ̀rọ̀ (tó máa ń wà lára eku) kó nínú títan àrùn náà kálẹ̀. Láìpẹ́, wọ́n ṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára kan, àmọ́ agbára ẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ ká a.
Àrùn àtijọ́ ha ni bí? Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀. Nígbà òtútù ọdún 1910, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] èèyàn ni àrùn náà pa ní Manchuria. Àkọsílẹ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé sì fi hàn pé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn làrùn náà ń kọlù lọ́dọọdún—ńṣe ni wọ́n sì ń pọ̀ sí i. Wọ́n tiẹ̀ tún ṣẹ̀ṣẹ̀ rí oríṣi àrùn náà mìíràn—oògùn kì í ran àwọn yẹn. Dájúdájú, àrùn náà yóò ṣì máa bá àwọn èèyàn fínra àyàfi tí ètò ìmọ́tótó tó yẹ bá wà. Ìdí nìyẹn tí ìwé Pourquoi la peste? Le rat, la puce et le bubon (Kí Ló Fa Àrùn Náà? Eku, Yọ̀rọ̀, àti Ọyún), tí Jacqueline Brossollet àti Henri Mollaret ṣe, fi sọ pé, “ó dájú pé àrùn náà kì í ṣe ti Yúróòpù ìgbàanì ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, . . . ó bani nínú jẹ́ pé àrùn náà ṣì ń bọ̀ wá jà lọ́jọ́ iwájú.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn èèyàn ìgbà yẹn máa ń pè é ní àjàkálẹ̀ àrùn ńlá.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
Tọkùnrin tobìnrin fi gbogbo ohun ìní wọn ta ṣọ́ọ̀ṣì lọ́rẹ, wọ́n rò pé Ọlọ́run á ràdọ̀ bò àwọn kí àrùn náà má bàa kọ lù àwọn
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ẹ̀ya Ìsìn Àwọn Afìyàjẹra-Ẹni
Àwọn tó rò pé àmúwá Ọlọ́run ni àrùn yìí bẹ̀rẹ̀ sí na ara wọn ní pàṣán láti lè pẹ̀tù sí ìbínú Ọlọ́run. Ìsìn Àwọn Afìyàjẹra-ẹni, tí a gbọ́ pé ọmọ ìjọ wọ́n tó ogójì ọ̀kẹ́ [800,000], wá gbajúmọ̀ gan-an ní sáà tí àrùn Black Death jà. Àwọn òfin ẹ̀ya ìsìn náà ka bíbá obìnrin sọ̀rọ̀ léèwọ̀, èèyàn ò sì gbọ́dọ̀ fọṣọ, tàbí kó pààrọ̀ aṣọ. Ẹ̀ẹ̀mejì lójúmọ́ ni wọ́n máa ń na ara wọn ní gbangba.
Ìwé Medieval Heresy sọ pé: “Ìfìyàjẹra-ẹni jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà díẹ̀ tí àwọn èèyàn tí ìbẹ̀rù ti sọ dìdàkudà náà ń gbà tu ara wọn nínú.” Àwọn ẹlẹ́sìn yìí tún mú ipò iwájú nínú fífi àwùjọ àlùfáà onípò gíga ní ṣọ́ọ̀ṣì bú àti bíbẹnu àtẹ́ lu àṣà ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, tó ń mówó wọlé fún ṣọ́ọ̀ṣì. Abájọ tí póòpù ṣe bẹnu àtẹ́ lu ìsìn náà ní ọdún 1349. Àmọ́, níkẹyìn ìjọ náà bẹ̀rẹ̀ sí tú díẹ̀díẹ̀ lẹ́yìn tí àrùn Black Death jà kọjá.
[Àwòrán]
Ìsìn Àwọn Afìyàjẹra-ẹni wá ọ̀nà láti tu Ọlọ́run lójú
[Credit Line]
© Bibliothèque Royale de Belgique, Bruxelles
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àrùn náà jà ní Marseilles, nílẹ̀ Faransé
[Credit Line]
© Cliché Bibliothèque Nationale de France, Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Alexandre Yersin ṣàwárí bakitéríà tó ń fa àrùn náà
[Credit Line]
Culver Pictures