ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/8 ojú ìwé 24-25
  • Wo Ẹyẹ Tí Ó Ní Ìpéǹpéjú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wo Ẹyẹ Tí Ó Ní Ìpéǹpéjú
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwo Ẹyẹ—Ìgbòkègbodò Àfipawọ́ Tí Gbogbo Ènìyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí Ni Bí?
    Jí!—1998
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìrísí Tàn Ọ́ Jẹ
    Jí!—1996
Jí!—1998
g98 1/8 ojú ìwé 24-25

Wo Ẹyẹ Tí Ó Ní Ìpéǹpéjú

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ

“Ó ṢEÉ ṣe kí o máà tí ì rí wa rí. Ẹyẹ ni wá, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn sì mọ̀ wá sí ẹyẹ àkàlà ti Áfíríkà.

“Yàtọ̀ sí ìrísí wa tí ó fani mọ́ra, àwọn ohun pàtàkì gbígbádùnmọ́ni mìíràn wà nípa wa tí a óò fẹ́ láti sọ fún ọ. Lọ́nà kan ṣá, a ń lo èyí tí ó pọ̀ jù nínú àkókò wa lórí ilẹ̀. A fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó tòlótòló, a kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ fò bíi ti tòlótòló.

“Bí a ti sanra jọ̀bọ̀tọ̀, a ń rìn hẹ́bẹ́hẹ́bẹ́ kiri àgbègbè àárín gbùngbùn àti gúúsù ìlà oòrùn Áfíríkà. Bí a bá bá ọ pàdé níbikíbi, o kò ní ṣàìdáwamọ̀ nítorí àwọn gẹ̀gẹ̀ ọrùn wa tí ó jẹ́ aláwọ̀ elésè àlùkò, àti pàápàá, àwọn ìpéǹpéjú wa gígùn, tí ń ṣeni ní kàyéfì!

“Àwa ẹyẹ àkàlà jẹ́ onítìjú ẹyẹ atọ́mọ—ní ìpíndọ́gba, a máa ń fi ọdún mẹ́fà tọ́jú ọmọ kan dìgbà tí yóò hùyẹ́ tó láti fò. Láàárín ìgbà tí a ń tọ́ ọmọ náà, àwọn akọ wa máa ń pèsè ewé gbígbẹ tí ó pọ̀ láti fi tẹ́ inú àwọn ìtẹ́ wa, tí ó sábà máa ń wà nínú àwọn ihò ara igi tàbí ihò àpáta. Àwọn abo sì máa ń fi ìṣọ́ra bójú tó àwọn ẹyin fún 40 ọjọ́. Pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà míràn nínú agbo ìdílé wa, a máa ń rìn hẹ́bẹ́hẹ́bẹ́ káàkiri, tí a sì ń wá ekòló, ìdin, àti àwọn ohun jíjẹ gbígbádùnmọ́ni mìíràn wá fún ‘ìyá tí ń retí ọmọ’ náà láìdábọ̀. Inú gbogbo wa máa ń dùn gan-an nígbà tí àwọn ọmọ tuntun náà bá jáde nínú ìtẹ́ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn yòó kù ní agbo ìdílé wa ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí a bí i.

“A kì í tètè dàgbà—ó kéré tán, ó máa ń tó ọdún mẹ́fà kí a tó dàgbà dáadáa. Ó sì tilẹ̀ lè pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ kí ọ̀kan lára wa tó lè gbé ìdílé tirẹ̀ kalẹ̀. Ní gidi, òtítọ́ náà pé a máa ń pẹ́ láyé (púpọ̀ lára wa máa ń tó 30 ọdún láyé) ń fún wa ní àkókò tó láti tàtaré apilẹ̀ àbùdá wa sí àwọn ìrandíran ọmọ wa.

“Bí o ti lè rí i, arìnmẹ́bí ni wá, a máa ń gbé ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí ọ̀wọ́ kan kì í ní ju ẹyẹ mẹ́jọ lọ, a sì jùmọ̀ ń ṣiṣẹ́. Ìdílé kọ̀ọ̀kan máa ń ṣiṣẹ́ nínú àwọn ọ̀dàn, igbó ńláńlá, àti àwọn pápá oníkoríko Áfíríkà tí ó fẹ̀ tó 100 kìlómítà níbùú lóròó. Ní àwọn apá ibì kan ní ìhà gúúsù Áfíríkà, iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ibùgbé àwọn ènìyàn ti gba èyí tí ó tó ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ibùgbé wa.

“A máa ń dáàbò bo àwọn ibi tí a máa ń jẹ̀ sí, a sì máa ń ṣọ́ àwọn ààlà wa déédéé. A kì í fún ẹnikẹ́ni lára oúnjẹ wa—ejò, ìdin, ìjàpá, àti àwọn kòkòrò—a kì í fún àwọn ẹyẹ àkàlà láti àwọn ìdílé mìíràn pàápàá. Nígbà míràn tí a bá ń gbìyànjú láti fi ìwà jàgídíjàgan lé àwọn olùyọjúràn dà nù, a máa ń ṣe àwọn ohun tí kò mọ́gbọ́n dání. Lọ́nà wo? Tí a bá rí òjìji ara wa lára fèrèsé kan, a máa ń ṣàṣìṣe ní fífi òjìji náà pe olùyọjúràn kan, a óò sì pa kuuruku mọ́ fèrèsé náà. Lọ́nà tí kò ṣe é yẹ̀ sílẹ̀, bí àgógó gígùn tí ó lágbára náà ṣe fi gbogbo agbára rọ́ lu fèrèsé náà máa ń fọ́ ọ. Nítorí ọ̀pọ̀ fèrèsé tí ó ti fọ́, àwọn ènìyàn kan ti fi wáyà híhun sójú àwọn fèrèsé, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún ìyẹn!

“Lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, àwọn ewu tí ń ṣekú pani wà tí a ní láti dààmú nípa wọn. Àwọn ènìyàn kan máa ń lé wa tipátipá kúrò ní ibùgbé wa. Àwọn kan ń yìnbọn fún wa. Àwọn àgbẹ̀ sábà máa ń gbé ìdẹ tí wọ́n fi májèlé dẹ fún àwọn ọ̀wàwà àti àwọn ẹranko mìíràn tí wọn kò nífẹ̀ẹ́ sí sílẹ̀. Ṣùgbọ́n báwo ni àwa ṣe máa mọ̀ pé wọ́n fi májèlé sí i? Ó dájú pé nítorí ààbò wa ni àwọn àgbẹ̀ náà ṣe máa ń bo májèlé náà mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n nítorí pé a sábà máa ń fi àgógó wa gígùn walẹ̀ láti rí oúnjẹ, ó máa ń já sí pé ńṣe ni a ń gbẹ́ sàréè wa fúnra wa, bí a bá wa oúnjẹ tí wọ́n ti fi májèlé sí jáde.

“Àwọn ènìyàn kan ń ṣiṣẹ́ kárakára láti dáàbò bò wa lọ́wọ́ ewu wọ̀nyí. A lérò pé ọ̀ràn tiwa kò ní rí bí i ti ẹyẹ ẹlẹgbẹ́ wa náà, ẹyẹ dodo—tí ó ti kú àkúrun. Nítorí náà, ìgbàkígbà tí o bá wà ní àgbègbè wa, tí o sì gbọ́ igbe wa gbígbalẹ̀kan náà, du-du-dududu du-du-dududu, gbìyànjú láti bẹ̀ wá wò. A óò yára ṣẹ́ ìpéǹpéjú wa gígùn náà pékúpékú, a óò sì kí ọ káàbọ̀ sí ibùgbé ẹyẹ àkàlà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́