Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìrísí Tàn Ọ́ Jẹ
A WÀ ní ilé ìnàjú tí ọ̀rẹ́ kan kọ́ sínú igbó dídí kan, a sì sùn ní ibùgbé ìsàlẹ̀ tí kò wọlẹ̀ tán. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn fèrèsé wà ní déédéé ojú wa nínú ilé, wọ́n sì wà ní déédéé ilẹ̀ níta. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ àkọ́kọ́, ní nǹkan bí aago mẹ́fà, ìró ìgbálẹ̀kùn pẹ́pẹ́ méjì, tí ó jọ pé ó ń dún láti onírúurú ìhà inú ibùgbé náà, ni ó jí mi. Bí ó ti ru ìfẹ́ ìtọpinpin mi sókè, mo dìde, mo sì fẹsẹ̀ palẹ̀ lọ sí ilé ìdáná láti wò bóyá ẹ̀rọ amúǹkantutù tàbí amúǹkangbóná ní ń pariwo bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe ọ̀kankan nínú wọn. Ó yà mí lẹ́nu, lójijì, mo gbúròó náà tí ń wá láti iyàrá ìnàjú. Mo yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wọ ibẹ̀, sí ìyàlẹ́nu mi, mo rí ẹyẹ pípọ́n fòò kan níta, ẹyẹ cardinal, ó ń bá gíláàsì ojú fèrèsé jà! Ó ń ti ibi fèrèsé kan dé ibi òmíràn yí ilé náà ká—iyàrá ibùsùn, ilé ìwẹ̀, iyàrá ẹ̀rọ tẹlifíṣọ̀n—ibikíbi tí fèrèsé tí ó wà ní déédéé ilẹ̀ bá ti wà. Ó dà mí lọ́kàn rú.
Bí mo ti rọra sún mọ́ fèrèsé náà sí i, mo rí amọ̀nà kan sí àdììtú náà—abo ẹyẹ cardinal kan tí ń ṣá èso jẹ, ní ìwọ̀n sẹ̀ǹtímítà díẹ̀ níwájú. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí akọ náà fi ń bá àwọn fèrèsé jà? Ní kedere, òjìji ara rẹ̀ tí ó ń rí lára fèrèsé ni ó ń kà sí ẹyẹ cardinal abánidíje kan, ó sì ń gbìyànjú láti lé e lọ! Ìrísí tàn án jẹ.
Mo fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé ète àjèjì ìhùwàsí ẹyẹ náà nìyí. Nínú ìwé rẹ̀, The Cardinal, June Osborne sọ pé akọ ẹyẹ cardinal “máa ń ṣe gbogbo ohun tí ó bá pọn dandan láti rí sí i pé àwọn ọ̀yọjúràn akọ mìíràn nínú irú ọ̀wọ́ náà kò wọ ìpínlẹ̀ rẹ̀. . . . Kì í ṣe pé [ó] máa ń lé àwọn ọ̀yọjúràn nìkan ni, a ti mọ̀ pé ó máa . . . ń gbógun ti òjìji ara rẹ̀ nínú ìdérí táyà ọkọ̀, dígí ọkọ̀, tàbí fèrèsé tí ń fòjìji hàn àti àwọn ilẹ̀kùn onígíláàsì.” Ó wáá fi àlàyé kan tí a lè fara mọ́ kún un pé: “Èyí lè ṣèdíwọ́ fún àlàáfíà onílé.” A rí ìyẹn bẹ́ẹ̀, ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
Kí ni a lè ṣe láti dẹ́kun ìwà àìlèkóra-ẹni-níjàánu akọ ẹyẹ yìí? Òǹkọ̀wé Osborne dámọ̀ràn pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ń di dandan láti bojú àwọn ohun tí ń dán gbinrin láti dá àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ padà . . . , èyí yóò sì tún ran ẹyẹ náà lọ́wọ́ láti má ṣe ara rẹ̀ léṣe nínú ìgbóguntì tí ó jọ ìṣekúpara-ẹni yìí.”—A kọ ọ́ ránṣẹ́.