Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Àmódi Ìrìn Àjò Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mí, mo sì fẹ́ẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún kókó náà, “Àmódi Ìrìn Àjò,” nínú “Wíwo Ayé.” (January 22, 1996) Mo dán àwọn ìdámọ̀ràn inú àpilẹ̀kọ náà wò, wọ́n sì gbéṣẹ́! Ẹ jọ̀wọ́, ẹ máa tẹ irú àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ jáde sí i.
J. C. S., Brazil
Bèbè Ikú Mo ń kọ̀wé nípa àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Dókítà Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Bèbè Ikú Tí Mo Sún Mọ́.” (December 22, 1995) A kò ha ń lo ìwọ̀n ìpín ọrún èròjà albumin, potéènì ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ nínú omi ìsúnniṣe inú kíndìnrín tí ń mú sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa pọ̀ sí i bí?
R. P., United States
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, bẹ́ẹ̀ ni, Kristẹni kọ̀ọ̀kan sì ní láti fúnra rẹ̀ pinnu yálà láti gba ìtọ́jú ìṣègùn tí ó ní ìwọ̀n èròjà “albumin” díẹ̀ nínú, tàbí láti má ṣe gbà á. Fún kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé, jọ̀wọ́ wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú àwọn ìtẹ̀jáde “Ilé-Ìṣọ́nà,” October 1, 1994, àti June 1, 1990.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ìsẹ̀lẹ̀ Mo ka àpilẹ̀kọ náà, “Ìjábá Òjijì ní Ilẹ̀ Japan—Bí Àwọn Ènìyàn Ṣe Kojú Rẹ̀.” (August 22, 1995) Yóò wù mí láti mọ ìdí tí ẹ ṣe fi àwọn ìsapá yín láti ṣètò ìrànwọ́ mọ sọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí nìkan? Ẹnì kan ti lè rò pé àwọn Ẹlẹ́rìí ì bá ti nawọ́ ìfẹ́ sí àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bákan náà.
V. C. E., Nàìjíríà
Ní ti gidi, a ran ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, pípín ìṣètò ìrànwọ́ nípasẹ̀ àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ ọ̀nà tí ó yá kánkán jù lọ láti jẹ́ kí ìpèsè náà dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó nílò rẹ̀. Nínú ọ̀ràn kan, a fi ọkọ̀ méjì tí ó kún fún ìpèsè oúnjẹ ránṣẹ́ sí ibùdó àwọn olùwá ibi ìsádi kan ládùúgbò. A lè mẹ́nu ba ọ̀pọ̀ irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀. Lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn Ẹlẹ́rìí fi ojúṣe èkíní fún àwọn mẹ́ḿbà ìjọ, níwọ̀n bí a ti rọ̀ wá nínú Bíbélì pé: “Kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn wọnnì tí wọ́n bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10)—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ìbáradíje Nínú Eré Ìdárayá Àpilẹ̀kọ yín, “Ìbáradíje Nínú Eré Ìdárayá Ha Burú Bí?” (December 8, 1995), rú mi lójú gan-an, ní ti pé ó lo Gálátíà 5:26. Kí ló kan ìwé Gálátíà pẹ̀lú eré ìdárayá àti eré àṣedárayá? Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí ní ìyàtọ̀ sí ẹran ara àti òmìnira ní ìyàtọ̀ sí ẹrú. Ìtumọ̀ King James Version túmọ̀ ẹsẹ yẹn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa ṣògo asán, kí a máà mú ọmọnìkejì wa bínú.”
P. O., United States
Òtítọ́ ni pé àpọ́sítélì náà kò ní ìdíje eré ìje lọ́kàn ní pàtó nígbà tí ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni kan ń ṣe àfiwé tí kò dára láàárín ẹnì kíní kejì. Èyí yọrí sí àwọn ìṣarasíhùwà ‘ti ara’ bí ‘ìṣọ̀tá, gbọ́nmisi-omi-ò-to, owú, asọ̀, àti ìpínyà.’ (Gálátíà 5:20, 21; 6:3, 4) Pọ́ọ̀lù tipa bẹ́ẹ̀ kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni láti má ṣe máa “ru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wọn lẹ́nìkíní kejì.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, “The New Thayer’s Greek-English Lexicon,” ṣe wí, ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “ìdíje” túmọ̀ sí “láti pè níjà sí ìdojúùjàkọ tàbí láti bá wọ̀yáàjà.” Dájúdájú, ìlànà yìí yóò kan àwọn ìgbòkègbodò eré ìdárayá tàbí ìgbòkègbodò èyíkéyìí tí ó lè mú kí àwọn Kristẹni máa bá ara wọn díje lọ́nà tí kò gbámúṣé.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ìmọ̀ọ́kàmáfẹ̀ẹ́kà Mo ka àpilẹ̀kọ náà, “Ṣọ́ra fún Ìmọ̀ọ́kàmáfẹ̀ẹ́kà” (January 22, 1996), mo sì gbádùn rẹ̀ púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi sún mi kọ̀wé dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ohun kíkà tí ó kún fún ìsọfúnni tí ẹ ń pèsè. Ìwé kíkà ń fún wa ní àǹfààní láti mọ Ẹlẹ́dàá àgbáyé nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣíṣeyebíye, Bíbélì. Nípa bẹ́ẹ̀, àìlera tẹ̀mí àti ìmọ̀ọ́kàmáfẹ̀ẹ́kà bá ara wọn tan.
R. R., United States
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti jẹ́ Kristẹni tí a batisí fún ọdún 28, tí mo sì jẹ́ olùka àwọn ìtẹ̀jáde Society déédéé, mo ń fòní dónìí, fọ̀la dọ́la, mo sì rò pé mo ń pàdánù ìfẹ́ ọkàn láti kàwé. Àpilẹ̀kọ yín sọ ìṣòro mi ní ṣàkó! Àlàyé yín lórí kókó yìí fún mi ní ìsúnniṣe láti kàwé kí n lè ṣe ara mi láǹfààní.
A. O., Kánádà