Ecuador—Orílẹ̀-Èdè Tí Ó Wà Lórí Ìlà Agbedeméjì Ayé
GẸ́GẸ́ bí àlejò láti ilẹ̀ Yúróòpù, ohun tí èmi àti aya mi kọ́kọ́ ṣàkíyèsí nípa Ecuador ni ìlà agbedeméjì ayé. Lótìítọ́, ìlà kan tí a kò lè rí ni, àmọ́ ipa tí ó ní lórí Ecuador ṣe kedere.
Orúkọ náà Ecuador jẹ́ “equator” lédè Sípéènì. Àwọn kan lè ronú pé ìlà agbedeméjì ayé ló ń darí ipò ojú ọjọ́ ní Ecuador. Bí ó ti wù kí ó rí, láìpẹ́ lẹ́yìn tí a dé ibẹ̀, a rí i pé ipò ojú ọjọ́ mímóoru tàbí títutù ní púpọ̀ láti ṣe pẹ̀lú ojú ilẹ̀ tó ga ju kàlẹ́ńdà lọ. Níwọ̀n bí oòrùn ti wà níbi tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ wà ní ọ̀gangan orí jálẹ̀ ọdún ní igun wọ̀nyí, ibi tí ó ga ju ìtẹ́jú òkun lọ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn atọ́nà dídárajùlọ láti mọ iye aṣọ tí a ní láti wọ̀.
Bí ìlà agbedeméjì ayé ti jẹ́ àpẹẹrẹ Ecuador, àwọn òkè ńlá Andes fún orílẹ̀-èdè náà ní àbùdá. Bí àwọn òkè ńláńlá wọ̀nyí ti la ibẹ̀ kọjá bí egungun ẹ̀yìn, wọ́n mú onírúurú ipò ìrísí ojú ilẹ̀ tí kò lópin wá.
Onírúurú Àwọ̀
Àwọ̀ jẹ́ ohun kejì tó wọ̀ wá lọ́kàn nípa Ecuador. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, láìpẹ́ lẹ́yìn tí a dé ibẹ̀, a jókòó sí ìbòjì àwọn igi ńláńlá kan. Orin àwọn ẹyẹ oriole tí ó dà bíi dùrù, ariwo lemọ́lemọ́ àwọn ẹyẹ wren, àti orin híhantí tí àwọn ẹyẹ antpitta aláfojúdi ń kọ pọ̀, ló kí wa káàbọ̀. Àmọ́ àwọn àwọ̀ wọn tilẹ̀ túbọ̀ wuni ju àwọn ìró wọn lọ.
Ẹyẹ ajẹkòkòrò kan tí ó ní àwọ̀ pupa mọ́ elése fò fìrì jáde láti inú ìtẹ́ rẹ̀ láti mú ẹ̀fọn kan. Ọ̀wọ́ àwọn ẹyẹ ayékòótọ́ parakeet aláwọ̀ ewé títàn ń pariwo lemọ́lemọ́ láti gba àfiyèsí bí wọ́n ṣe ń bá igún turkey kan tí ń fò lókè láìlo ìyẹ́ wí. Ẹyẹ oriole aláwọ̀ ìyeyè òun dúdú tí ó jojú ní gbèsè àti àwọn labalábá morpho aláwọ̀ búlúù bíbì náà fi àwọn àwọ̀ tí a fi wọ̀ wọ́n kún ìran mánìígbàgbé náà.
Bí a ti ń káàkiri orílẹ̀-èdè náà, a ṣàkíyèsí pé àwọn àwọ̀ títàn tí àwọn ẹyẹ àti àwọn labalábá náà ní tún wà lára aṣọ àti àwọn iṣẹ́ ọnà Ecuador. Fún àpẹẹrẹ, yẹ̀rì aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti àwọn obìnrin Àmẹ́ríńdíà ẹ̀yà Cañar bá àwọ̀ pupa mọ́ elése àlùkò ti ẹyẹ ajẹkòkòrò náà mu. Ó sì jọ pé àwọn àwọ̀ títàn ara aṣọ àwọn Àmẹ́ríńdíà ẹ̀yà Otavalo kó gbogbo àwọ̀ tí ó wà ní Ecuador mọ́ra.
Onírúurú Ipò Ojú Ọjọ́
Ìlà agbedeméjì ayé àti àwọn òkè ńlá Andes ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti mú kí onírúurú ipò ojú ọjọ́ wà ní Ecuador. Láàárín kìlómítà mélòó kan—ní gbọnrangandan bí igún òyìnbó ti ń fò—ipò ojú ọjọ́ lè yí pa dà láti ipò ọ̀rinrin inú igbó kìjikìji Amazon sí àwọn òjò dídì orí àwọn òkè náà.
Lọ́jọ́ kan, a gbéra láti àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ ibi olókè nítòsí àárín igbó kìjikìji Amazon lọ sí àwọn òkè ńláńlá ìtòsí Quito. Bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa ti ń pọ́nkè, a ṣàkíyèsí bí igbó kìjikìji náà ṣe ń yí pa dà di igbó kékeré díẹ̀díẹ̀, tí ó wá yí pa dà di pápá ẹgàn, tàbí paramo níkẹyìn. Àwọn ìyípadà agbàfiyèsí tí ń ṣẹlẹ̀ lójú ilẹ̀ náà tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé a ti rìnrìn àjò láti ibi ìlà agbedeméjì òbìrí ayé ti Áfíríkà dé àwọn ibi olókè ti Scotland láàárín wákàtí mélòó kan.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìlú àti ìlú ńlá tí ó wà ní Ecuador wà ní àwọn àfonífojì àárín àwọn òkè ńláńlá, níbi tí ipò ojú ọjọ́ ti rí bíi ti ìgbà ìrúwé jálẹ̀ ọdún. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èyíkéyìí lára àwọn ìgbà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló lè wáyé nígbàkugbà ní àwọn ìlú tí wọ́n wà ní àwọn òkè ńlá Andes—mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì lè wáyé lọ́jọ́ kan ṣoṣo! Bí arìnrìn-àjò onírìírí kan ti sọ ọ́, “ohun tí ó dájú jù lọ nípa ipò ojú ọjọ́ ní Ecuador ni pé a kò lè sàsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀.”
Àwọn Ẹyẹ Akùnyùnmù àti Àwọn Igún Òyìnbó
Onírúurú ipò ojú ọjọ́ ń mú kí ọ̀pọ̀ ẹranko àti ohun ọ̀gbìn wà. Ecuador ní irú ọ̀wọ́ ẹyẹ tí ó lé ní 1,500, tí ó jẹ́ ìlọ́po méjì àpapọ̀ àwọn tó wà ní United States àti Kánádà, tí ó sì jẹ́ ìdá mẹ́fà gbogbo irú ọ̀wọ́ tí a mọ̀ lágbàáyé. Gbogbo wọn ni a rí ní orílẹ̀-èdè kan tí ó kéré sí Ítálì.
Àwọn ẹyẹ akùnyùnmù kéékèèké ni a fún láfiyèsí jù lọ—nǹkan bí 120 irú ọ̀wọ́ wọn ló wà ní Ecuador. Inú àwọn ọgbà ìlú ńlá náà ni a ti kọ́kọ́ rí wọn, tí wọ́n ń lọ, tí wọ́n ń bọ̀ nídìí àwọn igi kéékèèké tí ó ní òdòdó lórí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù. Wọ́n wà ní àáríngbùngbùn igbó kìjikìji Amazon, wọ́n tilẹ̀ wà ní àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tí ó jọ pé afẹ́fẹ́ ń gbá ní àwọn òkè ńlá Andes.
Ní ìlú Baños, a fi wákàtí kan gbáko wo ẹyẹ akùnyùnmù kan tí wọ́n ń pè ní violet-ear adábírà tí ń jẹun níbi ìṣùjọ òdòdó ilá abilà pupa kan. Bí ó ti ń fò lófegè láti ìdí òdòdó kan dé òmíràn, tí ó ń fi ọgbọ́n fa omiídùn òdòdó ṣíṣeyebíye, abánidíje kan dé, ìyẹn túbọ̀ fara balẹ̀. Ẹyẹ trainbearer onírù dúdú kan ni, tí a fún ní orúkọ rẹ̀ nítorí ìrù rẹ̀ dúdú tí ó gùn, tí ó mú kí ó jọ ìràwọ̀ onírù dúdú tí ó bá ń kùn yùnmù yíká àgbègbè rẹ̀, tí ó sì ń lé àwọn abánidíje dà nù. Dípò fífò lófegè, ńṣe ni ẹyẹ akùnyùnmù yí bà sórí ìtì òdòdó náà, ó sì ń dá òdòdó náà lu láti ẹ̀yìn, kí ó lè fa omiídùn rẹ̀ mu.
Kì í ṣe gbogbo àwọn ẹyẹ ilẹ̀ Ecuador ló kéré bẹ́ẹ̀. Igún òyìnbó bàgùjẹ̀, tí ó tóbi jù lọ nínú àwọn ẹyẹ apẹranjẹ, ṣì ń fò lókè láìlo ìyẹ́ gba orí àwọn òkè ńlá Andes, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye rẹ̀ ti dín kù gan-an. Léraléra ni a ń bojú wo orí àwọn òkè gíga fíofío náà, ní fífojúsọ́nà láti rí tinútẹ̀yìn rẹ̀, àmọ́ pàbó ló já sí. Ní àgbègbè Amazon, idì happy—ẹyẹ apẹranjẹ tí ó lágbára jù lọ lágbàáyé—ṣòro gan-an láti rí. Ní àkókò púpọ̀ jù lọ nínú ọjọ́, ó máa ń bà sórí ẹ̀ka igi ràbàtà kan lọ́nà tí a kò fi ní rí i nínú igbó kìjikìji tí kò nídààmú náà, bí ó ti ń dúró láti ki ẹranko sloth tàbí ọ̀bọ tí kò fura mọ́lẹ̀.
Àwọn Irúgbìn Awonisàn
Púpọ̀ lára àwọn irúgbìn tí ó wà ní Ecuador ni a ń lò bí egbòogi tí a sì ń fi ṣe ọ̀ṣọ́. Nígbà ìbẹ̀wò wa sí Ọgbà Ẹ̀dá ti Orílẹ̀-Èdè ní Podocarpus, ní ìhà gúúsù orílẹ̀-èdè náà, afinimọlẹ̀ wa fi igi kékeré kan tí ó ní àwọn àgbáyun pupa hàn wá. Ó ṣàlàyé pé: “Igi cascarilla nìyẹn. Èèpo rẹ̀ ti jẹ́ orísun èròjà quinine fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.” Ní igba ọdún sẹ́yìn, ní Loja tí kò jìnnà sí wa, èròjà quinine gba ẹ̀mí obìnrin ọlọ́lá ará Sípéènì kan tí ibà fẹ́ pa là. Kò pẹ́ tí òkìkí rẹ̀, tí àwọn ará Inca ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́, kàn káyé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò jọ pé igi cascarilla já mọ́ nǹkan kan tí a bá kọ́kọ́ rí i, oògùn tí a ń rí mú jáde lára èèpo rẹ̀ ti gba ẹ̀mí púpọ̀ là.
Igbó kékeré níbi tí igi yẹn ti ń hù gan-an tún jẹ́ ilé fún ọ̀pọ̀ àwọn igi àtijọ́, tí àwọn irúgbìn bromeliad ẹlẹ́gùn-ún sòlẹ̀kẹ̀ sára àwọn ẹ̀ka wọn oníkókó, tí díẹ̀ lára wọn yọ àwọn yẹtuyẹtu òdòdó pupa rẹ́súrẹ́sú. Igbó jíjìnnà réré wọ̀nyí tún jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn béárì alámì lójú, ẹranko ocelot, àti puma, àti onírúurú ọ̀wọ́ irúgbìn tí kò lóǹkà tí àwọn onímọ̀ nípa ewéko ṣì ń gbìyànjú láti ṣàkọsílẹ̀ wọn sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣèwádìí fínnífínní nípa àkèré kékeré kan láti Ecuador, pẹ̀lú ìrètí àtirí àwọn oògùn apàrora tí ó dára jù. Awọ ara àkèré ayára-pọ-májèlé yìí ń tú èròjà apàrora kan tí wọ́n sọ pé ó fi ìlọ́po 200 lágbára ju èròjà morphine lọ jáde.
Ní àwọn òkè ńlá Andes, a rí àwọn irúgbìn kan tí kò jọ èyí tí a rí rí. Irúgbìn puya, ẹ̀yà irúgbìn aláìnígi, tí ó máa ń fa àwọn ẹyẹ akùnyùnmù mọ́ra, rán wa létí ìgbálẹ̀ ńlá àtijọ́ kan, tí ń dúró kí ẹnì kan mú òun, kí ó sì fi gbá ilẹ̀ tí ó wà láyìíká náà. Àwọn igbó kéékèèké tí ó ní igi quinua, igi lílágbára kan tí ó ga bí àwọn igi ahóyaya ti Himalaya, wà nínú àwọn ihò tí a dáábò bò nínú ẹgàn paramo tí ó jẹ́ ahoro. Àwọn igi tí ewé pọ̀ gan-an lórí wọn, tí wọ́n ga ní kìkì mítà méjì sí mẹ́ta, ni wọ́n di igbó dídí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé wọ̀ tí wọ́n jẹ́ ibi ààbò tí ó gba àwọn ẹyẹ àti ẹranko tọwọ́tẹsẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn igi inú igbó kìjikìji Amazon ga, wọ́n sì ń gbèrú gan-an. Nígbà ìbẹ̀wò kan sí Ibùdó Ẹ̀kọ́ Nípa Ohun Alààyè ti Jatun Sacha, a dúró sábẹ́ igi gíga fíofío kan tí ó ga ju 30 mítà lọ nínú igbó náà. Lójijì, ohun kan tí ó rọra rìn kọjá nítòsí àwọn gbòǹgbò ńláńlá tí ó gbé e ró mú wa ta gìrì. Lẹ́yìn náà ni a wá mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ẹ̀là inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀ ni ìdílé àwọn àdán kékeré kan fi ṣe ilé. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn rán wa létí pé igbó náà nílò ọ̀pọ̀ irú ipò ìbátan alájọṣepọ̀ báyìí. Àwọn àdán, tí wọ́n jẹ́ olórí olùṣèpínkiri hóró èso àti ẹni tí ń fún àwọn òdòdó inú igbó kìjikìji náà lákọ, jẹ́ alájọṣepọ̀ pàtàkì fún àwọn igi tí ń dáàbò bò wọ́n.
Àwọn Ọjà ní Àwọn Òkè Ńlá Náà
Nǹkan bí ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ń gbé Ecuador ni wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Àmẹ́ríńdíà. Onírúurú ẹ̀yà ìran—tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọ̀nà ìmúra tirẹ̀ tí ó yàtọ̀—jẹ́ ohun kan tí a máa ń rí ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àfonífojì òkè ńlá Andes. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń rí àwọn obìnrin Àmẹ́ríńdíà tí wọ́n ń pọ́nkè ní gbígba ojú àwọn ipa ẹsẹ̀ gíga ní àwọn ibi dídàgẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ńlá náà, tí wọ́n sì ń rànwú bí wọ́n ṣe ń rìn lọ. Ó jọ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi dídàgẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ èyíkéyìí tí ó ga jù fún wọn láti dáko sí. A yẹ oko àgbàdo kan wò, tí a ṣírò pé ó kéré tán, ó dagun tó ìwọ̀n 45!
Òkìkí àwọn ọjà Ecuador, irú ti Otavalo, ti kàn káàkiri. Wọ́n jẹ́ àwọn ojúkò ibi tí àwọn ènìyàn àdúgbò ti lè rà tàbí tí wọ́n ta àwọn ẹranko àti àwọn ohun tí ó ti oko jáde àti àwọn ohun èlò ìbílẹ̀ tí wọ́n hun tàbí àwọn iṣẹ́ ọnà míràn. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ irú àwọn aṣọ pàtó kan ni àwọn ènìyàn àdúgbò náà máa ń wọ̀ lọ sọ́jà, àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ohun àfiṣèranwò tí ó fa ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ mọ́ra. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú ń lo àǹfààní ọjọ́ ọjà náà láti ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ènìyàn.
Ohun fífanimọ́ra kan nínú ohun tí ẹni kan ń hun ni ìlọ́jọ́lórí nǹkan náà àti bí wọ́n ṣe lo àwọn àwọ̀ àti bátànì ọnà dáradára nínú híhun ún. Àwọn ènìyàn tí ń gbé àárín àwọn òkè ńlá Andes ti ń hun agbádá wọn lílókìkí tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí àwọn ará Sípéènì tó dé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti sọ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é di ti ìgbàlódé, àwọn Àmẹ́ríńdíà aṣiṣẹ́kára wọ̀nyí ṣì ń ṣe aṣọ híhun àti aṣọ ọlọ́nà dáradára.
Àwọn Òkè Ńlá Inú Ìkùukùu
Ẹni tí ó ní ìṣòro ṣíṣàárẹ̀ lórí ìrìn àjò kò lè wakọ̀ kọjá láàárín àwọn òkè ńlá Andes. Àwọn ọ̀nà náà rí kọ́lọkọ̀lọ; wọ́n jẹ́ olókè, wọ́n sì da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, bí wọ́n ti sún mọ́ ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àwọn àfonífojì lílọ́ kọ́lọkọ̀lọ náà. Arìnrìn-àjò tí ó ní ìforítì ń gbádùn àwọn oríṣiríṣi ìran tí ń yí pa dà, tí a wulẹ̀ lè ṣàpèjúwe bí amúnikúnfún-ìbẹ̀rù.
Bí a ṣe ń wakọ̀ lọ síbi àwọn òkè ńlá Andes ní ìgbà àkọ́kọ́, ìkùukùu—ohun kan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìgbà kan tí kò sí—bo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa. Nígbà míràn, tí a bá jáde kúrò nínú ìkùukùu náà, a ṣì ń rí ìṣẹ́wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ àwọn àfonífojì ti ìkùukùu bò. Nígbà tí a ń gba àárín ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá Andes kọjá, ńṣe ló jọ pé ìkùukùu náà ń bá wa ṣeré ọwọ́. Kí á tó pajú pẹ́, yóò ti bo abúlé kan tí a gbà kọjá mọ́lẹ̀. Ní ìṣẹ́jú mélòó kan lẹ́yìn náà, oòrùn yóò máa ràn ní abúlé tí ó tẹ̀ lé e.
Nígbà míràn, ìkùukùu náà yóò dóbìrìpó wá láti ìsàlẹ̀; nígbà míràn yóò fẹ́ wá sísàlẹ̀ láti orí àwọn òkè ńlá náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń mú inú bíni bí ohun kan bá díni lójú rírí ìran ẹlẹ́wà kan, ìkùukùu náà fi orí fún àwọn òkè gíga fíofío náà tí ó yọ lókè rẹ̀, ó sì fi hàn pé ó jẹ́ àwámáàrídìí. Èyí tí ó tún ṣe pàtàkì jù ni pé ó ń mú kí igbó kékeré náà ní ìṣẹ̀dá nínú, èyí tí ń rí ọ̀rinrin ṣíṣeyebíye nínú rẹ̀.
Ní òwúrọ̀ tí a lò kẹ́yìn ní Ecuador, ìkùukùu náà ká nílẹ̀. Fún wákàtí mélòó kan, a rí ìkàmàmà òkè ńlá Cotopaxi—òkè ayọnáyèéfín onírìísí òkòtó tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ní àbùkù, tí òjò dídì bo orí rẹ̀. Wọ́n ti sọ òkè ayọnáyèéfín tí ó máa ń bú gbàù déédéé, tí ó ga jù lọ lágbàáyé yìí di èyí tí ó gba ipò pàtàkì nínú ọgbà ẹ̀dá ti orílẹ̀-èdè kan. Nígbà tí a sún mọ́ òkè náà, a ṣe kàyéfì láti rí ìṣàn òkìtì yìnyín kan tí ń ṣan ọ̀kan lára àwọn ìdàgẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó wà lókè dànù díẹ̀díẹ̀. Pẹ̀lú bí gíga rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 6,000 mítà, ó ń ṣe àṣeyọrí pípe oòrùn kíkọyọyọ àgbègbè agbedeméjì ayé níjà.
Lọ́jọ́ kejì, bí ọkọ̀ òfuurufú wa ṣe fi Quito sílẹ̀ tí a dorí kọ ilé, a wo Ecuador fìrí fún ìgbà tó kẹ́yìn. Nínú ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ kùtùkùtù, a rí òkè Cayambe, òkè ayọnáyèéfín mìíràn tí òjò dídì bo orí rẹ̀, tí ó yọrí jáde láàárín ìkùukùu náà, tí ó sì ń dán gbinrin bíi wúrà tí ó wà nínú oòrùn. Ó jọ pé òkè ayọnáyèéfín yìí, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé orí ìlà agbedeméjì ayé ni òkè rẹ̀ wà, jẹ́ àmì ìdágbére yíyẹ kan ti orílẹ̀-èdè fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí a bẹ̀ wò náà. Bíi ti òkè ayọnáyèéfín Cayambe, Ecuador wà lórí ìlà agbedeméjì ayé.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìrísí ojú ilẹ̀ àwọn òkè Andes, pẹ̀lú òkè ayọnáyèéfín Cotopaxi lẹ́yìn
Àmẹ́ríńdíà tí ń ta òdòdó
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
1. Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà ẹgàn
2. Ẹyẹ “toucan” alágòógó ńlá
[Credit Line]
Fọ́tò: Zoo de Baños