Gbígbẹ́ Ọnà Ọ̀pá Ìtẹ̀lẹ̀
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Britain
AMỌṢẸ́DUNJÚ kan nínú gbígbẹ́ ọnà náà sọ pé: “Ó sábà máa ń yà mí lẹ́nu láti gbọ́ pé àwọn àgbègbè kan wà ní àwọn Erékùṣù ilẹ̀ Britain tí kò sí ẹni tó lóye ohun tí o ní lọ́kàn nígbà tí o bá sọ pé gbígbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ ni ìgbòkègbodò àfipawọ́ rẹ.”
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló mọ ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ tàbí ọ̀pá darandaran dunjú. Gbígbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ máa ń sọ àwọn ohun èlò lásán wọ̀nyí di iṣẹ́ ọnà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn darandaran àti àwọn òṣìṣẹ́ oko ti rí i pé iṣẹ́ ọwọ́ fífanimọ́ra yìí gba òye iṣẹ́ gidigidi—àti ọ̀pọ̀ sùúrù pẹ̀lú. Àmọ́ kí ló wà nínú gbígbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀?
Yìyan Igi Náà
Ìgbésẹ̀ kìíní ni yíyan igi náà. Igi èyíkéyìí tó bá ní ìrísí yíyẹ la lè lò—igi blackthorn, igi ápù, tàbí igi píà. Àwọn kókó tó yọ dáadáa tó sì fani mọ́ra lára igi Holly mú kí a máa yàn án láàyò lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ ló ń yan igi hazel láàyò. Nígbà mìíràn, igi kan ń pẹ̀ka tí kò fẹ̀ lára ẹ̀ka tàbí gbòǹgbò kan. Èyí ń mú kí ó rọrùn láti gbẹ́ gbogbo ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ náà—torítara—láti ara igi kan náà.
Ìgbà wo ló dára jù láti gé igi títọ́ kan? Ó sábà máa ń jẹ́ ìgbà tí àwọn ìgbòkègbodò igi náà bá dáwọ́ dúró, tí àwọn oje ara rẹ̀ kò sì ṣàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan tí ń gbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ ń sọ pé ìgbà tó dára jù jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí a rí i—kí ẹlòmíràn tó rí i! Èyí tó wù kó jẹ́, ní kété tó bá ti tẹ́ ẹni tí ń gbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ náà lọ́rùn pé òun ti gé igi wíwúlò kan, ó gbọ́dọ̀ fi gírísì tàbí ọ̀dà kun orí àti ìdí tó ti gé igi náà, kí ìpórì igi náà má bàa sán. Ó wá gbọ́dọ̀ tọ́jú igi náà títí yóò fi gbẹ, ìgbésẹ̀ kan tó lè gbà tó ọdún méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà yẹn nìkan ni ẹni tí ń gbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ náà tó lè bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́ ẹ.
Gbígbẹ́ Orí Rẹ̀
Nígbà tí igi kan kò bá ní ibi tí a lè fọwọ́ mú, tàbí orí kan, lọ́nà àdánidá, ẹni tí ń gbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ náà lè fi ìwo màlúù, ti àgùntàn, tàbí ti ewúrẹ́, ṣe ọ̀kan. A gbọ́dọ̀ tọ́jú ìwo náà títí yóò fi gbẹ, tí ó sábà máa ń gba ọdún kan. Lẹ́yìn náà, ẹni tí ń gbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ náà yóò wá fi ẹ̀mú gbẹ́ ìwo náà sí bí ó ṣe fẹ́ kí ó rí. Láti ìrandíran ni àwọn darandaran ti ń lo iná alágbẹ̀dẹ, omi híhó, koríko gbígbẹ tí ń jó lọ́wọ́, tàbí ooru orí àtùpà olóròóró karosín pàápàá láti sọ ìwo náà di èyí tí ó ṣeé tẹ̀. Yóò wá ṣeé sọ dí ohunkóhun tí ó wu darandaran náà, tàbí tí òye iṣẹ́ rẹ̀ bá lè mú jáde. Bí àpẹẹrẹ, ó lè ṣe ibi àfọwọ́mú tó rí bí ajá collie, bí ẹyẹ, bí ẹja trout aláwọ̀ ilẹ̀, bí orí ẹyẹ pheasant, tàbí bí ẹranko kékeré kan.
Bí ẹni tí ń gbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ náà ṣe ń gbẹ́ ìwo náà, yóò máa fara balẹ̀ fiyè sí àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó rọ̀ mọ́ ọn. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ ẹja trout kan ló ń gbẹ́, yóò fi irin gbígbóná kan yọ ìrù àti lẹbẹ rẹ̀, yóò sì fi òòlu róbótó kan yọ ìpẹ́ kọ̀ọ̀kan. Ó lè fi ìwo ẹfọ̀n dúdú ṣe ojú. Dípò ọ̀dà, yóò fi yíǹkì ṣe àwọ̀ ara. Yóò fi yíǹkì náà kùn ún ju ẹ̀ẹ̀kan lọ, fífi yíǹkì sí ara tí a dán náà sì lè súni. Apá tó kẹ́yìn ni láti fi nǹkan olómi tí ń dán gbinrin kun ìwo náà.
Iṣẹ́ Ọnà Tí A Ṣe Parí
A ń fi ìdè onírin, tàbí ìṣó, tàbí èèkàn onígi lẹ ìwo náà mọ́ ọ̀pá náà. Ẹni tí ń gbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ náà yóò wá lo òye iṣẹ́ láti fi òwú onírin múlọ́múlọ́ nu ara iṣẹ́ ọnà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóò dán an, yóò sì fi nǹkan olómi tí ń dán gbinrin bo ọ̀pá rẹ̀. Ẹnì kan tó ti pẹ́ lẹ́nu gbígbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ kọ̀wé pé: “Yóò gbà mí ní nǹkan bí 100 wákàtí láti gbẹ́ ẹja trout kan, kí n gbẹ́ àwọn lẹbẹ rẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, kí n sì gbẹ́ àwọn ìpẹ́ ara ẹja trout náà, kí n kùn ún, kí n sì fi nǹkan olómi tí ń dán gbinrin kùn ún, kí ó dára tó láti gbapò nínú ìdíje kan.”
Ó dájú pé gbígbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ kan tí ń súni. Ṣùgbọ́n ohun tí a ń mú jáde níkẹyìn lè jẹ́ iṣẹ́ ọnà gidi kan, tí a sì ń fi àwọn kan ṣe ìdíje. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnì kan tí ń gbẹ́ ọnà ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ ń ka iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí ìránnilétí sáà ìfọkànbalẹ̀ kan, tí ń pẹ̀rọ̀ sí àwọn másùnmáwo àti pákáǹleke inú ìgbésí ayé òde òní.