Ìsapá Wa Lórí Ẹ̀tọ́ Láti Wàásù
Gẹ́gẹ́ bí Grace Marsh ṣe sọ ọ́
Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, Ọ̀jọ̀gbọ́n Newton, tí a mọ̀ mọ́ Kọ́lẹ́ẹ̀jì Huntingdon ní Montgomery, Alabama, fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní èyí tó lé ní 50 ọdún sẹ́yìn. Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ ní United States ṣe ìdájọ́ kan tó kan àwọn ìgbòkègbodò mi gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ní 1946. Ọkàn ìfẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Newton nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ mú kí n rántí ọ̀pọ̀ nǹkan. Ẹ jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí mo wà lọ́mọdé.
ABÍ mi ní 1906, ní Randolph, Alabama, U.S.A., mo jẹ́ ìran kẹrin Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ti mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà náà. Baba baba mi àgbà, Lewis Waldrop, àti baba mi àgbà, Sim Waldrop ti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní apá ìparí àwọn ọdún 1800.
Joseph ọmọ Sim Waldrop ni baba mi. Joseph wọ ọmọbìnrin kan tí ń jẹ́ Belle lọ́kàn nípa fífún un ní ìwé kékeré kan tó tú àṣírí ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni. Ohun tí Belle ka mú inú rẹ̀ dùn tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fún baba rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ náà tún wọ̀ lọ́kàn, ní ìwé kékeré náà kà. Lẹ́yìn náà, Joseph gbé Belle níyàwó, wọ́n sì bí ọmọ mẹ́fà. Èmi ni wọ́n bí ṣìkejì.
Lálaalẹ́, Baba yóò kó ìdílé náà jọ yí ibi ìdáná ká, yóò sì ka Bíbélì àti ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sókè ketekete. Nígbà tí ó bá kà á tán, gbogbo wa yóò kúnlẹ̀ nígbà tí Baba yóò gba àdúrà àtọkànwá kan. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a ń rìnrìn àjò ọlọ́pọ̀-kìlómítà nínú kẹ̀kẹ́ àfẹṣinfà lọ sí ilé Baba Àgbà Sim láti ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹlẹgbẹ́ wa.
Nílé ẹ̀kọ́, àwọn ọmọ kíláàsì wa máa ń pẹ̀gàn wa, wọ́n ń pè wá ní ọmọlẹ́yìn Russell. Ìyẹn kì í ṣe ìpẹ̀gàn tí wọ́n pète pé kí ó jẹ́, nítorí pé mo bọ̀wọ̀ gidigidi fún Charles Taze Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ fún Watch Tower Bible and Tract Society. Ẹ wo bí inú mi ti dùn gan-an tó láti rí i ní àpéjọ kan ní Birmingham, Alabama, ní 1914! Mo sì lè rántí bí ó ṣe dúró lórí pèpéle, tó ń ṣàlàyé àfihàn àwòrán tí a pè ní “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá.”
Ní 1920, ìdílé wa kó lọ sí Robertsdale, ìlú kékeré kan níhà ìlà oòrùn Mobile, Alabama. Ní ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, mo fẹ́ Herbert Marsh. Èmi àti Herbert kó lọ sí Chicago, Illinois, a sì bí ọmọkùnrin wa, Joseph Harold, níbẹ̀ láìpẹ́. Ó bani nínú jẹ́ pé mo sú lọ kúrò nínú ìsìn ìgbà ọmọdé mi, ṣùgbọ́n ó wà lọ́kàn mi síbẹ̀.
Mímú Ìdúró Mi fún Òtítọ́ Bíbélì
Lọ́jọ́ kan ní 1930, orí mi fapo padà nígbà tí mo rí i tí onílé wa ti Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣubú lórí àtẹ̀gùn. Inú bí mi, mo sì bá onílé wa sọ̀rọ̀ nípa ìwà rẹ̀. O sọ fún mi pé bí mo bá jẹ́ kí ọkùnrin yìí wọ ilé wa, èmi àti ọkọ mi kò ní lè gbé ibẹ̀ mọ́. Bí a ti lè retí, mo pe Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà wọlé, mo sì fún un ní ife tíì kan.
Èmi àti ọkọ mi lọ sí ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sunday tó tẹ̀ lé e, a sì láyọ̀ pé a bá Joseph F. Rutherford, tí ó ti di ààrẹ Watch Tower Society lẹ́yìn ikú Russell, pàdé níbẹ̀. Ńṣe ni Rutherford ń ṣèbẹ̀wò sí Chicago nígbà náà. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ru mí sókè láti tún di akíkanjú lẹ́ẹ̀kan sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, a tún padà lọ sí Robertsdale, Alabama.
Ní àpéjọpọ̀ kan ní Columbus, Ohio, ní 1937, mo pinnu láti di aṣáájú ọ̀nà, bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àkókò ti ń lọ, ọkọ mi, Herbert, ṣèrìbọmi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sìn bí alábòójútó olùṣalága Ìjọ Robertsdale láìpẹ́. Ọmọkùnrin wa, Harold, ni ó sábà máa ń jẹ́ alájọṣiṣẹ́ mi lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé.
Ní 1941, mo rí ìkésíni gbà láti ṣiṣẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní Brookhaven, Mississippi. Violet Babin, Kristẹni arábìnrin kan láti New Orleans, ni alájọṣiṣẹ́ mi. A tẹ́wọ́ gba ìpèníjà náà, a sì gbé ọkọ̀ àfiṣelé wa àti àwọn ọmọ wa lọ pẹ̀lú wa láti fìdí kalẹ̀ sí Brookhaven. Àwọn ọkọ wa yóò wá dara pọ̀ mọ́ wa lẹ́yìn náà.
Lákọ̀ọ́kọ́, a ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, Harold àti ọmọbìnrin Violet sì ń ṣe dáradára nílé ẹ̀kọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn tí àwọn ará Japan ju bọ́ǹbù lu Pearl Harbor ní December 1941, tí United States si kéde ogun, ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn yí padà sí iṣẹ́ wa lọ́nà yíyanilẹ́nu. Ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè lọ́nà àṣejù àti ìbẹ̀rù ìdìtẹ̀ wà. Nítorí àìdásí-tọ̀túntòsì wa nínú ìṣèlú, àwọn ènìyàn ń fura sí wa, kódà, wọ́n ń fẹ̀sùn kàn wá pé a jẹ́ amí ilẹ̀ Germany.
Wọ́n lé Harold kúrò nílé ẹ̀kọ́ nítorí pé ó kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ayẹyẹ kíkí àsíá. Olùkọ́ rẹ̀ sọ fún mi pé Harold ní làákàyè, ó sì níwà rere, ṣùgbọ́n ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ rò pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ búburú nítorí pé kò kí àsíá. Ìpinnu ọ̀gá náà àti ìgbìmọ̀ alákòóso ilé ẹ̀kọ́ náà lórí ọ̀rọ̀ yìí bí alábòójútó àwọn ilé ẹ̀kọ́ nínú tó bẹ́ẹ̀ tó kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀, tó sì gbà láti máa san owó ilé ẹ̀kọ́ Harold nílé ẹ̀kọ́ aládàáni!
Ojoojúmọ́ ni àwùjọ àwọn ènìyànkénìyàn ń halẹ̀ mọ́ wa. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan, àwọn ọlọ́pàá tì wá jáde lẹ́nu ọ̀nà ilé obìnrin kan, wọ́n fọ́ àwọn ohun èlò agbóhùnjáde wa mọ́ igi, wọ́n fọ́ àwọn àwo tí a fi gba àwíyé Bíbélì sí, wọ́n fa àwọn Bíbélì àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ya, wọ́n sì dáná sun gbogbo ohun tí wọ́n gbà lọ́wọ́ wa níkẹyìn. Wọ́n sọ pé kí a fi ìlú sílẹ̀ kí alẹ́ tó lẹ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwùjọ àwọn ènìyànkénìyàn kan yóò lé wa lọ. A yára kọ̀wé sí àwọn aláṣẹ ìlú láti dáàbò bò wá, a sì fọwọ́ mú un lọ fún wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti pèsè ààbò. Mo tilẹ̀ kàn sí Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ ní Jackson, Mississippi, mo sì béèrè ìrànwọ́. Àwọn pẹ̀lú gbà wá nímọ̀ràn pé kí a kúrò nílùú.
Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, àwọn ọkùnrin tí ń bínú, tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún yí ọkọ̀ àfiṣelé wa po. Àwa obìnrin méjì pẹ̀lú àwọn ọmọ wa la wà níbẹ̀. A ti àwọn ilẹ̀kùn, a pa àwọn iná, a sì gbàdúrà sí Jèhófà tìtaratìtara. Níkẹyìn, àwùjọ ènìyàn náà tú ká láìṣewá-níjàǹbá.
Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, Herbert pinnu láti dara pọ̀ mọ́ wa ní Brookhaven lọ́gán. A mú Harold padà lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ àgbà ní Robertsdale, níbi tí ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ àdúgbò ti fún wa ní ìdánilójú pé wọn yóò kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí a padà dé Brookhaven, wọ́n ti ba ọkọ̀ àfiṣelé náà jẹ́, wọ́n sì ti lẹ ìwé àṣẹ láti mú wa mọ́ ẹ̀gbẹ́ kan ara rẹ̀ nínú. Láìka àtakò yìí sí, a dúró ṣinṣin, a sì ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ.
Wọ́n Fàṣẹ Mú Wa, Wọ́n sì Jẹ Wá Níyà
Ní February 1942, wọ́n mú èmi àti Herbert nígbà tí a ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé kékeré kan. Bí wọ́n ṣe hùwà sí wa bí ọkùnrin onílé náà nínú tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi lọ gbé ìbọn rẹ̀ lára ògiri, tí ó sì halẹ̀ pé òun yóò yìnbọn fún ọlọ́pàá náà! Wọ́n fẹ̀sùn kàn wá pé a wọ ibi tí kò yẹ ká wọ̀, wọ́n sì dá wa lẹ́bi níbi ìgbẹ́jọ́ tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ kejì.
Wọ́n fi wá sí àhámọ́ olótùútù kan tí ó dọ̀tí púpọ̀ fún ọjọ́ 11. Òjíṣẹ́ ìjọ Onítẹ̀bọmi kan ládùúgbò wá bẹ̀ wá wò níbẹ̀, ó sì mú un dá wa lójú pé bí a bá gbà láti fi ìlú náà sílẹ̀, òun yóò lo agbára òun láti dá wa sílẹ̀. A rò pé ẹ̀dà ọ̀rọ̀ ni èyí, nítorí agbára rẹ̀ náà ló jẹ́ ká débẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Igun kan nínú iyàrá àhámọ́ wa ti jẹ́ ibi ìgbọ̀nsẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àwọn ìdun pọ̀ níbẹ̀. Àwọn àwo onípáànù dídọ̀tí, tí a kò fọ̀, ni wọ́n fi ń fún wa lóúnjẹ. Nítorí àwọn ipò wọ̀nyí, mo ní àrùn òtútù àyà. Wọ́n ké sí dókítà kan pé kó wá yẹ̀ mí wò, wọ́n sì dá wa sílẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, àwùjọ àwọn ènìyànkénìyàn kan tún wá síbi ọkọ̀ àfiṣelé wa, nítorí náà, a padà sílé ní Robertsdale títí di ìgbà ìgbẹ́jọ́ wa.
Ìgbẹ́jọ́ Náà
Àwọn ọmọ ìjọ Onítẹ̀bọmi jákèjádò ìpínlẹ̀ náà wá sí Brookhaven nítorí ìgbẹ́jọ́ wa, láti ṣètìlẹ́yìn fún òjíṣẹ́ ìjọ Onítẹ̀bọmi tí wọ́n torí rẹ̀ mú wa. Èyí mú kí n kọ lẹ́tà kan sí ọkọ àbúrò mi, Oscar Skooglund, tó jẹ́ díákónì kan nínú ìjọ Onítẹ̀bọmi. Ìgbónára ni mo fi kọ ọ́, n kò sì fi bẹ́ẹ̀ lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ nínú kíkọ ọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwà tí wọ́n ti hù sí mi àti ohun tí mo kọ gbọ́dọ̀ ti nípa lórí Oscar lọ́nà tó ṣàǹfààní, nítorí pé kò pẹ́ lẹ́yìn náà tó fi di onítara Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà.
Ó dá àwọn agbẹjọ́rò wa, G. C. Clark àti Victor Blackwell, tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ẹlẹ́gbẹ́ wa, lójú pé a kò lè rí ìgbẹ́jọ́ aláìṣègbè ní Brookhaven. Nítorí náà, wọ́n pinnu láti máa ṣàtakò gbogbo ọ̀ràn ẹjọ́ náà títí ilé ẹjọ́ yóò fi tú u ká. Ní gbogbo ìgbà tí olùpẹ̀jọ́ bá ti sọ nǹkan kan, ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò wa yóò ṣàtakò. Ó kéré tán, wọ́n ṣàtakò ní ìgbà 50. Níkẹyìn, adájọ́ tú ẹjọ́ náà ká.
Iṣẹ́ Ìwàásù Níbòmíràn
Lẹ́yìn tí mo sinmi tí mo sì lera padà, mo tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, pẹ̀lú ọmọ mi, Harold. Ní 1943, wọ́n fún wa ní ibòmíràn nítòsí ilé láti wàásù, Whistler àti Chickasaw, àwọn àwùjọ kéékèèké nítòsí Mobile, Alabama. Mo lérò pé àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀ tuntun wọ̀nyí kì yóò léwu tó bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ ní United States ti ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwọn ìdájọ́ mélòó kan tó dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre, tí ìhùwà àwọn aráàlú sí iṣẹ́ wa sì ti bẹ̀rẹ̀ sí yí padà.
Láìpẹ́, a ní àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ní Whistler, a sì nílò ibi ìpàdé tiwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti lè kan ìṣó ló ṣiṣẹ́ níbi kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wa kékeré, ènìyàn 16 ló sì wá sí ìpàdé wa àkọ́kọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan yàtọ̀ ní Chickasaw, nítorí pé ìlú tó jẹ́ ti ilé iṣẹ́ kan ni, ilé iṣẹ́ Gulf Shipbuilding Corporation ló ni ín. Síbẹ̀, ó dà bí ìlú kékeré èyíkéyìí mìíràn, tó ní àgbègbè iṣẹ́, ilé ìfìwéránṣẹ́, àti ibùdó ìnájà tirẹ̀.
Lọ́jọ́ kan ní December 1943, èmi àti Aileen Stephens, aṣáájú ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ mi kan, ń fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn tí ń kọjá lọ ní Chickasaw, nígbà tí Aṣòfin Chatham sọ fún wa pé a kò ní ẹ̀tọ́ láti wàásù nítorí orí ilẹ̀ àdáni la wà. A ṣàlàyé pé ọjà kọ́ la ń tà àti pé iṣẹ́ wa jẹ́ ti ìsìn, ó sì ní ìtìlẹ́yìn nínú Àtúnṣe Kìíní sí Àkọsílẹ̀ Òfin United States.
Àfikún Ìfàṣẹmúni àti Ìfinisẹ́wọ̀n
Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, èmi àti Aileen pàdé E. B. Peebles, igbákejì ààrẹ ilé iṣẹ́ Gulf Shipbuilding, a sì ṣàlàyé bí ìgbòkègbodò ìsìn wa ti ṣe pàtàkì tó fún un. Ó kìlọ̀ fún wa pé àwọn kò ní fàyè gba iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Chickasaw. A ṣàlàyé pé àwọn ènìyàn ti gbà wá sílé wọn tayọ̀tayọ̀. Yóò ha dù wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí? Ó mú ojú koko, ó sì halẹ̀ pé òun yóò sọ wá sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé a wọ ibi tí kò yẹ ká wọ̀.
Mo padà lọ sí Chickasaw léraléra, wọ́n sì ń fàṣẹ mú mi nígbà kọ̀ọ̀kan tí mo bá lọ. Ṣùgbọ́n, nígbà kọ̀ọ̀kan náà ni wọ́n ń dá mi sílẹ̀ bí wọ́n bá ti gba owó ìdúró lọ́wọ́ mi. Níkẹyìn, wọ́n fi kún owó ìdúró náà gan-an, mo sì ń pẹ́ lẹ́wọ̀n sí i títí di ìgbà tí a bá rí owó tí a nílò san. Ipò inú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kò bójú mu ní ti ìmọ́tótó—kò sí ibi ìyàgbẹ́, àwọn tìmùtìmù ibùsùn dọ̀tí, kò sì sí aṣọ tí a ń tẹ́ lé wọn lórí, kúbùsù dídọ̀tí kan ló sì wà láti fi bora. Ó yọrí sí pé, àìlera mi tún padà wá.
Ní January 27, 1944, wọ́n ṣe ìgbẹ́jọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́fà tí wọ́n fàṣẹ mú ní December 24, 1943 papọ̀, wọ́n sì gba ẹ̀rí mi bí ọ̀kan náà pẹ̀lú ti àwọn olùjẹ́jọ́ tó kù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbẹ́jọ́ náà fi hàn pé a ń ya Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ́tọ̀ ní kedere ni, wọ́n dá mi lẹ́bi. A pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.
Ní January 15, 1945, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn gbé ìdájọ́ rẹ̀ jáde pé: mo jẹ̀bi ẹ̀sùn wíwọ ibi tí kò yẹ kí n wọ̀. Síwájú sí i, Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ ní Alabama kọ̀ láti gbọ́ ẹjọ́ mi. Ní May 3, 1945, Hayden Covington, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó sì jẹ́ onígboyà àti akíkanjú agbẹjọ́rò, gbé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ ní United States.
Nígbà tí èmi àti Aileen ṣì ń dúró de ohun tí Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ náà yóò ṣe, a yí ọ̀ràn náà sórí àwọn olùfisùn wa nípa pípe E. B. Peebles àti àwọn alájọṣe rẹ̀ lẹ́jọ́ ọ̀ràn ara ẹni lábẹ́ òfin sí ẹ̀ka iṣẹ́ òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ, tí a sì béèrè fún owó ìtanràn. Àwọn olùfisùn wa gbìyànjú láti yí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá padà kúrò ní pé a wọ ibi tí kò yẹ ká wọ̀ sí pé a ń dí ètò ìrìnnà lọ́wọ́, ṣùgbọ́n nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, mo ti yọ́ mú ẹ̀dà ìwé kan tí Aṣòfin Chatham fọwọ́ sí, tí n fi wa sùn pé a wọ ibi tí kò yẹ ká wọ̀, jáde. Nígbà tí mo mú ẹ̀rí yìí jáde nílé ẹjọ́, Òṣìṣẹ́ Amúdàájọ́ṣẹ Holcombe yára dìde dúró, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ gbé sìgá rẹ̀ mì! Ìgbẹ́jọ́ náà parí ní February 1945, pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ tí wọ́n pín sí méjì lọ́gbọọgba.
Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ Dájọ́
Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ ní United States lọ́kàn-ìfẹ́ nínú ẹjọ́ mi nítorí pé wíwọ ibi tí kò yẹ kí a wọ̀ lórí ilẹ̀ àdáni mú apá mìíràn wọ ọ̀ràn òmìnira ìsìn. Covington fẹ̀rí hàn pé òmìnira àwọn olùjẹ́jọ́ nìkan kọ́ ni àwọn òfin Chickasaw tẹ̀ lójú, ṣùgbọ́n ó tún tẹ ti àwùjọ náà lójú lápapọ̀.
Ní January 7, 1946, Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ ní United States yí ìdájọ́ ilé ẹjọ kékeré padà, ó sì ṣe ìdájọ́ gbígbàfiyèsí kan nínú ìtàn tó fi dá wa láre. Adájọ́ Black ṣe ìdájọ́ náà, tó ní àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nínú pé: “Níwọ̀n bí Ìpínlẹ̀ [Alabama] ti gbìdánwò láti gbé ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀daràn karí olùpẹ̀jọ́-kòtẹ́milọ́rùn [Grace Marsh] nítorí pé ó dáwọ́ lé pípín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìsìn nínú ìlú tó jẹ́ ti ilé iṣẹ́ kan, ìgbésẹ̀ ìpínlẹ̀ náà kò lè fẹsẹ̀ múlẹ̀.”
Ìsapá Tí Ń Bá A Lọ
Níkẹyìn, èmi àti Herbert fìdí kalẹ̀ sí Fairhope, Alabama, a sì ń tẹ̀ síwájú láti ṣiṣẹ́ fún ire Ìjọba náà jálẹ̀jálẹ̀ àwọn ọdún náà. Herbert kú ní 1981, ṣùgbọ́n mo ní àwọn ìrántí aláyọ̀ nípa àkókò tí a fi wà pọ̀. Ọmọkùnrin mi, Harold, ṣíwọ́ sísin Jèhófà nígbà tó dàgbà, ó sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ní 1984. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó bà mí nínú jẹ́ jù nínú ìgbésí ayé mi.
Síbẹ̀síbẹ̀, mo dúpẹ́ pé mo ní àwọn ọmọ-ọmọ mẹ́ta, obìnrin, tí Harold àti ìyàwó rẹ̀, Elsie, bí, mo sì ní àwọn ọmọ ọmọ-ọmọ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi nísinsìnyí. Mẹ́ta lára àwọn àbúrò mi obìnrin, Margaret, Ellen Jo, àti Crystal ṣì wà láàyè, wọ́n sì ń bá a lọ bí olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Crystal fẹ́ Lyman Swingle, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ń gbé ní orílé iṣẹ́ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní Brooklyn, New York. Láìka àwọn àìsàn lílekoko láàárín àwọn ọdún mélòó kan láìpẹ́ yìí sí, Crystal ti jẹ́ àpẹẹrẹ àgbàyanu àti ìṣírí fún mi.
Láàárín èyí tó lé ní 90 ọdún, mo ti kọ́ láti má bẹ̀rù ohun tí ènìyàn lè ṣe láé, nítorí pé Jèhófà lágbára ju òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ èyíkéyìí, adájọ́ èyíkéyìí, àti ènìyàn èyíkéyìí lọ. Bí mo ti ń ronú lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣẹ̀ sẹ́yìn wọ̀nyí, mo ń fojú pàtàkì wo àǹfààní ti pé mo ti nípìn-ín nínú ‘gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin’!—Fílípì 1:7.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Wọ́n Fi Àkọsílẹ̀ Òfin Dìhámọ́ra
Ní 1995, Merlin Owen Newton kọ iwé Armed With the Constitution, tó ṣàkọsílẹ̀ ipa tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó nínú mímú ìlò Àtúnṣe Kìíní sí Àkọsílẹ̀ Òfin United States ṣe kedere. Nígbà yẹn, aya Newton jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn àti ẹ̀kọ́ ìṣèlú ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì Huntingdon, ní Montgomery, Alabama. Ìwé rẹ̀ tí ó fara balẹ̀ ṣèwádìí lé lórí, tí ó sì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ dáradára ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ méjì tí wọ́n ṣe nílé ẹjọ́ Alabama, tí wọ́n sì gbé dé Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ ti United States kẹẹrẹkẹ.
Ọ̀kan lára àwọn ẹjọ́ Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ wọ̀nyí jẹ́ ti Grace Marsh, tí ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ wà nínú àpilẹ̀kọ tó wà pẹ̀lú àpótí yìí. Ẹjọ́ kejì láàárín Jones àti Ìlú Ńla Opelika, ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ láti tan ìgbàgbọ́ ìsìn kálẹ̀ nípa pípín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kiri. Rosco àti Thelma Jones, àwọn tọkọtaya adúláwọ̀ kan, jẹ́ àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Nígbà tó ń múra ìwé rẹ̀ sílẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Newton lo àwọn ìwé agbéròyìnjáde àtìgbàdégbà àti àwọn ìwé àtìgbàdégbà ti ètò òfin ti lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn àkọsílẹ̀ ìránnilétí àti lẹ́tà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí kọ, ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn ìtẹ̀jáde Àwọn Ẹlẹ́rìí fúnra wọn, àti àwọn ìwádìí tí àwọn ọ̀mọ̀wé ṣe lórí ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wíwọnilọ́kàn àti àwọn èrò lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tí àwọn olùjẹ́jọ́, àwọn agbẹjọ́rò, àti àwọn adájọ́ náà sọ nínú ìwé Armed With the Constitution ti mú apá kan ìtàn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́nà ti òfin wá sí ojútáyé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Èmi àti baba mi àgbà, Sim Waldrop
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Grace Marsh lónìí