Ọmọ Tí A Sọ ní Òtòṣì
NÍ ABÚLÉ kékeré kan ní Áfíríkà, ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Okot àti ìyàwó rẹ̀, Matina, láyọ̀ nígbà tí wọ́n bí bẹ́ẹ́rẹ̀ wọn. Àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wá sí abúlé náà láti fún wọn lẹ́bùn, kí wọ́n sì wúre pé kí ẹ̀mí ọmọ náà gùn, kí ayé rẹ̀ sì lóyin.
Ìgbésí ayé kò rọrùn fún tọkọtaya náà. Ilẹ̀ kékeré kan ni wọ́n fi dáko, amọ̀ ni wọ́n fi kọ́ ilé wọn, tí Matina bímọ sí, kóóko ni wọ́n sì fi bò ó. Wọ́n múra tán láti ṣiṣẹ́ kára kí nǹkan lè rọrùn fún àkọ́bí wọn ju bí ó ti rí fún wọn lọ. Láti máa rán ara wọn létí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí, wọ́n sọ ọmọbìnrin wọn ní Acan, tó túmọ̀ sí “Òtòṣì Ni Mí.”
Kí ló wà fún Acan lọ́jọ́ iwájú? Bí ìgbésí ayé rẹ̀ bá rí bí ti ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó máà kọ́ ìwé láé. Nígbà tó bá dàgbà, bí ó bá lè ríṣẹ́ ṣe, nǹkan bí 190 dọ́là péré ni ó lè máa wọlé fún un lọ́dún. Bẹ́ẹ̀, ní orílẹ̀-èdè rẹ̀, kò sí ìrètí pé ẹ̀mí ẹnì kan lè gùn ju ọdún 42 péré lọ.
Acan nìkan kọ́ ló wà ní ipò yìí. Nínú iye ènìyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù 6 tó wà láyé, owó tó ń wọlé lọ́dún fún nǹkan bí bílíọ̀nù 1.3 kò tó 370 dọ́là. Ìpíndọ́gba owó tí ń wọlé lọ́dún fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ jẹ́ 21,598 dọ́là. Lójoojúmọ́ ni 67,000 ènìyàn, nǹkan bí mílíọ̀nù 25 lọ́dọọdún ń kún àwọn tálákà. Iye tó pọ̀ jù lára wọn ń gbé àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà—ní Áfíríkà, Éṣíà, àti Latin America. Àmọ́, ní àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ pàápàá, kò ṣàìsí àwọn tálákà. Ìpín 7 nínú 10 àwọn òtòṣì lágbàáyé sì jẹ́ obìnrin.
Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò rọ́nà jà bọ́ lọ́wọ́ òṣì. Kò jẹ́ kí wọ́n ní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé—oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé. Ó lè ṣàìjẹ́ kí wọ́n ní òmìnira, iyì, ẹ̀kọ́ ìwé, àti ìlera. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Òṣì ń lo agbára apanirun rẹ̀ ní gbogbo ìpele ìgbésí ayé ènìyàn, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí a bá lóyún rẹ̀ sí ìgbà tí a bá sìnkú rẹ̀. Ó ń bá àwọn àrùn aṣekúpani jù lọ àti aronilára jù lọ dìmọ̀ lù láti mú kí ìwàláàyè gbogbo àwọn tí ó ń pọ́n lójú burú jáì.”
Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé kò ti ń sunwọ̀n sí i ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà? Ó rí bẹ́ẹ̀ ní àwọn ibi mélòó kan. Ní ibi púpọ̀, kò rí bẹ́ẹ̀. Ìwé ìròyìn Choices tí ń sọ nípa ìtẹ̀síwájú ènìyàn ṣàpèjúwe èrò pé “ìgbésí ayé àwọn tálákà ti ń dára sí i” gẹ́gẹ́ bí ‘èrò èké tó léwu.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí pé: “A ń gbé inú ayé kan tí ó ti túbọ̀ pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní gidi ní ti ọrọ̀ ajé, láàárín orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn àti nínú orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan.”
Ṣé ìran ènìyàn yóò máa bá òṣì yí títí láé ni? Nínú àwọn àpilẹ̀kọ méjì tí ó kàn, Jí! ṣàyẹ̀wò kókó ọ̀rọ̀ tó díjú yìí, ó sì sọ ohun tí yóò jẹ́ ojútùú náà.