ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 8/8 ojú ìwé 29-30
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Òkun Wà Nínú Ewu
  • Àwọn Tí Ń Fi Ẹ̀yà Ara Tọrọ
  • Ọdún Burúkú fún Àwọn Alásọtẹ́lẹ̀
  • Ìbálòpọ̀ Eléwu-Ńlá
  • Ìbátan Àárín Ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ àti Àrùn Ọkàn-Àyà
  • Àwọn Igbó Tí Ń Pòórá
  • A Sàsọtẹ́lẹ̀ Àìtó Oúnjẹ Lágbàáyé
  • Ẹlẹ́gungùn Inú Odò Orinoco Ń Pòórá
  • Agbára Ìràwọ̀ Kíkàmàmà
  • Wíwakọ̀ àti Títẹniláago —Àkànpọ̀ Tó Léwu
  • Ṣé Ìṣòro Ni Pé Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀?
    Jí!—2004
  • Sísanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Ǹjẹ́ Kò Ti Ń di Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Kárí Ayé Báyìí?
    Jí!—2003
  • Kí Ló Ń Jẹ́ Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀?
    Jí!—2004
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 8/8 ojú ìwé 29-30

Wíwo Ayé

Àwọn Òkun Wà Nínú Ewu

Ìwé ìròyìn The Journal of Commerce sọ pé, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa òkun àti àwọn onímọ̀ nípa ààbò ohun alààyè tó ti fọwọ́ sí “ìpè láti gbégbèésẹ̀” láti dáàbò bo àwọn òkun lọ́wọ́ ìbàjẹ́ síwájú sí i ti lé ní 1,600 láti orílẹ̀-èdè 65. Onímọ̀ ìbátan láàárín àwọn ohun alààyè inú òkun àti ibùgbé wọn, Elliot Norse, sọ pé: “Ìjàngbọ̀n ti so lókun, ìjàngbọ̀n ọ̀hún ju bí a ti ń rò tẹ́lẹ̀ lọ.” Àpẹẹrẹ kan tí wọ́n mẹ́nu bà ni ti òkun tó jẹ́ 18,000 kìlómítà níbùú lóròó níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Mexico, tí a mọ̀ sí àgbègbè òkú. Bí orúkọ rẹ̀ ti fi hàn, àgbègbè òkú kò ní ẹja, edé, àti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ohun alààyè inú omi tí a kò fi dọ́sìn mìíràn nínú. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèhọ̀n tí ń jẹun létí Odò Mississippi tó ní ọ̀pọ̀ èròjà aṣaralóore ló fà á. Nígbà tí àwọn èèhọ̀n náà bá kú, wọ́n ń lọ sísàlẹ̀ òkun náà. Bí àwọn bakitéríà ti ń ṣiṣẹ́ láti jẹ́ kí òkú èèhọ̀n náà jẹrà ni afẹ́fẹ́ oxygen ń dín kù nísàlẹ̀ òkun náà. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa òkun, Ọ̀mọ̀wé Nancy Rabalais, sọ pé: “Ohunkóhun tí kò bá lè sá kúrò níbẹ̀ ń kú nígbẹ̀yìngbẹ́yín.”

Àwọn Tí Ń Fi Ẹ̀yà Ara Tọrọ

Ṣé o fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn lo àwọn ẹ̀yà ara rẹ lẹ́yìn tí o bá kú? Ìbéèrè tí ń kojú ọ̀pọ̀ ará Brazil láti ìgbà tí òfin tuntun kan ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní January 1, 1998 nìyí. Òfin náà sọ pé, a óò fi ẹ̀yà ara gbogbo ará Brazil tó bá ti lé lọ́mọ ọdún 18 tọrọ láìsí pé a ń gbàṣẹ, àyàfi bí ó bá ti fọwọ́ sí ìwé tó fi béèrè pé kí a má fi tòun tọrọ. Ṣùgbọ́n, ìwé ìròyìn The Miami Herald sọ pé, “ẹ̀rí púpọ̀ ló wà pé ọ̀pọ̀ jù lọ ará Brazil yóò yàn láti wà lódindi lẹ́yìn tí wọ́n bá kú. Láàárín oṣù mẹ́fà tó kọjá, lára ènìyàn mẹ́rin tí ó bá lọ gba ìwé àṣẹ ìwakọ̀, mẹ́ta ń kọ̀ láti fi ẹ̀yà ara wọn tọrọ.” Èé ṣe? Àwọn ènìyàn kan ń bẹ̀rù pé, ó lè mú kí àwọn dókítà máa polongo pé ọpọlọ àwọn aláìsàn ti kú láìtíìkú, kí wọ́n lè yọ àwọn ẹ̀yà ara wọn.

Ọdún Burúkú fún Àwọn Alásọtẹ́lẹ̀

Ìwé ìròyìn Nassauische Neue Presse ti Frankfurt sọ pé gbogbo àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ní Germany ni “ìfọ́jú” bù lù ní 1997. Kò sí ọ̀kankan tó ṣẹ lára nǹkan bí 70 àsọtẹ́lẹ̀ tí Àjọ Aṣèwádìí Lọ́nà ti Sáyẹ́ǹsì Lórí Àwọn Ọ̀ràn Afarajọ-Sáyẹ́ǹsì (GWUP) ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ wọn. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbàfiyèsí jù ní 1997 kò hàn rárá sí àwọn aríran náà. Bí àpẹẹrẹ, kò sí ọ̀kankan tó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú Diana, ìyàwó ọmọ ọba ilẹ̀ Britain. Ọ̀pọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ ti di oníṣọ̀ọ́ra tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo ìgbìyànjú wọn wulẹ̀ ń dá lórí bí àwọn nǹkan ṣe ń lọ sí, bí àwọn ọ̀ràn ètò ọrọ̀ ajé àti wàhálà ìṣèlú. Edgar Wunder, òṣìṣẹ́ àjọ GWUP, sọ pé, ìwọ̀nyí jẹ́ “àwọn ohun tí ẹni kan tó wulẹ̀ ń ka ìwé ìròyìn lásán ti lè sọ.”

Ìbálòpọ̀ Eléwu-Ńlá

Láàárín 1994 sí 1996, àwọn olùwádìí ní Ilé Ìwòsàn Rhode Island àti Ilé Ìwòsàn Boston City, ní United States, fi ọ̀rọ̀ wá 203 aláìsàn tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV lẹ́nu wò nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀ nínú ìgbésí ayé wọn. Kí ni ìwádìí yẹn fi hàn? Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Mẹ́rin nínú àwọn ènìyàn mẹ́wàá tó ní fáírọ́ọ̀sì H.I.V. kò sọ fún àwọn tí wọn ń bá lò pọ̀ pé àwọn ní fáírọ́ọ̀sì náà, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méjì nínú mẹ́ta wọn tí kì í sábà lo kọ́ńdọ̀mù.” Àwọn olùwádìí sọ pé, kí ẹni tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV má sọ fún ẹlòmíràn wọ́pọ̀. Dókítà Michael Stein, láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ti Yunifásítì Brown, ní Providence, Rhode Island, sọ pé: “Èyí kì í ṣe ọ̀ràn àìmọ̀. Àwọn ènìyàn mọ̀ pé ewu títàtaré fáírọ́ọ̀sì H.I.V. láti ọ̀dọ̀ àwọn wà. [Wọn] kò ṣàìmọ àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ọ̀ràn ṣíṣe ojúṣe ẹni ni èyí.”

Ìbátan Àárín Ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ àti Àrùn Ọkàn-Àyà

Ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ pé: “Ọ̀nà tó dára jù lọ láti dènà àrùn CAD [àrùn inú òpó tí ń gbẹ́jẹ̀ jáde láti inú ọkàn-àyà] nígbà tí a bá dàgbà ni kí a dènà ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ nígbà ọmọdé.” Ó pẹ́ tí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ti mọ̀ pé sísanrajọ̀kọ̀tọ̀ nígbà ọmọdé ń mú kí ewu níní ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn àtọ̀gbẹ, àpọ̀jù ọ̀rá inú ẹ̀jẹ̀, àrùn iṣan ẹ̀jẹ̀ ọkàn-àyà, àti àwọn àrùn eléwu mìíràn, pọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n láìka àwọn ìkìlọ̀ tí àwọn dókítà ń ṣe pé kí a pààlà sí bí a ṣe ń jẹ nǹkan ọlọ́ràá tó, kí a sì máa ṣe eré ìmárale sí, a gbọ́ pé ìdámẹ́ta gbogbo àwọn ará Àríwá Amẹ́ríkà ló sanra jù tàbí tí wọ́n sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Linda Van Horn, láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ti Yunifásítì Northwestern ní Chicago, béèrè pé: “Báwo ni a ṣe fẹ́ kí àkọsílẹ̀ oníṣirò wa pọ̀ tó kí a tó mú kí àwùjọ ènìyàn wa gbé ìgbésẹ̀ láti dènà ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ nípa kíkọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́ àṣà ìjẹun àti eré ìmárale tí a mú sunwọ̀n sí i? Àwọn àǹfààní tó lè ṣe kò mọ níwọ̀n. Bí a kò bá dín ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ kù, àbájáde rẹ̀ lórí ọkàn-àyà àti àwọn òpójẹ̀ ṣeé sọ dájú, wọ́n ń sọni daláàbọ̀ ara, wọ́n sì ń náni lówó.” Bí ó ti wù kí ó rí, àbájáde ìwádìí kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe láìpẹ́, tí ìwé ìròyìn The New England Journal of Medicine gbé jáde, sọ pé, ewu tí ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ ń fà fún ìlera ẹni mọ níwọ̀n. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé, ìwádìí náà rí i pé ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ “ń mú kí kíkúláìtọ́jọ́ túbọ̀ ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n kò tó bí ọ̀pọ̀ ògbógi onímọ̀ ìṣègùn ṣe rò ó sí tẹ́lẹ̀.”

Àwọn Igbó Tí Ń Pòórá

Àjọ Ààbò Ẹ̀dá Lágbàáyé (WWF) sọ pé, ìwọ̀n tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn igbó tó wà lójú ilẹ̀ ayé kí ọ̀làjú ènìyàn tó bẹ̀rẹ̀ sí tọwọ́ bọ̀ wọ́n lójú ti pòórá báyìí. Láìka àwọn ìsapá takuntakun tí ènìyàn ń ṣe láti mú kí a mọ ìṣòro náà sí, pípa igbó run ní ọ̀rúndún yìí ti pọ̀ dé àyè tí ó fi ṣeé ṣe kí àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan máà ní igbó àdánidá mọ́ láìpẹ́. Gígé igbó nítorí igi gẹdú àti láti fi dáko ń pa àwọn irú ọ̀wọ́ igi àti ti ẹranko run. Síwájú sí i, dídánásungi ń tú gáàsì carbon dioxide dà sínú afẹ́fẹ́, èyí tí ọ̀pọ̀ ń bẹ̀rù pé ó lè yọrí sí mímú kí ilẹ̀ ayé máa móoru. Ìwé ìròyìn Guardian ti London sọ pé, àjọ WWF ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé, ó kéré tán, kí a dáàbò bo ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo oríṣi igbó lágbàáyé nígbà tí ó bá fi di ọdún 2000.

A Sàsọtẹ́lẹ̀ Àìtó Oúnjẹ Lágbàáyé

Ìròyìn àjọ akóròyìnjọ Associated Press sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí Yunifásítì Johns Hopkins ṣe ṣe fi hàn, “bí kò bá jẹ́ pé bí iye ènìyàn ṣe ń pọ̀ sí i dín kù, kí irè oko sì pọ̀ sí i lọ́nà kíkọyọyọ, nígbà tí ó bá fi di ọdún 2025, kò ní sí oúnjẹ púpọ̀ tó fún àwọn olùgbé ayé, tí a fojú bù pé yóò tó bílíọ̀nù 8, tí yóò fẹ́ jẹun.” Àwọn olùwádìí náà sọ tẹ́lẹ̀ pé, “bí ìwọ̀n ìbímọ kò bá dín kù sí nǹkan bí ọmọ méjì fún obìnrin kan,” a gbọ́dọ̀ sọ ìwọ̀n oúnjẹ tí a ń pèsè ní báyìí di ìlọ́po méjì nígbà tí ó bá fi di ọdún 2025 kí “oúnjẹ gbígbámúṣé, tó sì lè ṣara lóore lè wà” fún àwọn ènìyàn, kí ara wọn lè dá ṣáṣá. Àwọn ìṣòro tó tún wà ni àìtó omi, bíba ilẹ̀ jẹ́, bí ọ̀gbàrá àti afẹ́fẹ́ ṣe ń gbá ilẹ̀dú lọ déédéé, àti àwọn ìyípadà ojú ọjọ́. Kódà ní báyìí, nǹkan bí mílíọ̀nù 18 ènìyàn ni ebi ń pa kú lọ́dọọdún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń pèsè ìwọ̀n oúnjẹ púpọ̀ tó fún iye ènìyàn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù 6 tó wà láyé.

Ẹlẹ́gungùn Inú Odò Orinoco Ń Pòórá

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Estampas ti Caracas ṣe sọ, àwọn ẹlẹ́gungùn inú Odò Orinoco ní Venezuela wà nínú ewu. A ti ń dọdẹ àwọn ẹ̀dá náà láti 1930 wá, nítorí awọ wọn. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, nígbà yẹn, “iye ẹlẹ́gungùn tó wà ní Venezuela pọ̀ ju iye ènìyàn lọ.” Ṣùgbọ́n láàárín 1931 sí 1934, a ti ta awọ ẹlẹ́gungùn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ̀n tó mílíọ̀nù 1.5 kìlógíráàmù, sí ilẹ̀ òkèèrè, ó kéré tán, ó jẹ́ awọ mílíọ̀nù 4.5 ẹlẹ́gungùn. Nígbà tí ó fi di ọdún 1950, “lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí a ti ń dọdẹ wọn láìṣíwọ́,” iye àwọn ẹlẹ́gungùn ti dín kù tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ́ pé ìwọ̀n 30,000 kìlógíráàmù “péré” la rí tà sílẹ̀ òkèèrè. Lónìí, àwọn ẹlẹ́gungùn tó kù lódò Orinoco kò pé 3,000 mọ́, àwọn ògbógi sì sọ pé àwọn ènìyàn ń wu àwọn ẹlẹ́gungùn náà àti àwọn irú ọ̀wọ́ 312 ẹranko ilẹ̀ Venezuela mìíràn léwu àkúrun.

Agbára Ìràwọ̀ Kíkàmàmà

Ìran kan tí a fi awò awọ̀nàjíjìn Hubble wò láìpẹ́ yìí fi ẹ̀rí hàn síwájú sí i pé ìràwọ̀ kan nínú ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ wa jẹ́ oríṣi tó ṣọ̀wọ́n gan-an tí a ń pè ní “oríṣi atànyanran aláwọ̀-búlúù.” Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀dá inú sánmà ṣe sọ, ìràwọ̀ mímọ́lẹ̀yòò náà àti àwọn gáàsì eléruku tó yí i ká rí bí ìbọn, nítorí náà, wọ́n sọ orúkọ rẹ̀ ní Pistol. Wọ́n fojú bù ú pé, ó kéré tán, ìràwọ̀ Pistol náà tóbi tó Oòrùn wa ní ìlọ́po 60, ó sì lágbára tó o ní ìlọ́po mílíọ̀nù 10. Ìwé ìròyìn Science News sọ pé ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ “ìràwọ̀ tó lágbára jù lọ́run.” Ṣùgbọ́n nítorí eruku tó wà láàárín wa sí ìràwọ̀ náà, àwọn ohun èlò àwárí tí ó lágbára láti rí ìmọ́lẹ̀ tí ojú lásán kò tó nìkan ni a lè fi rí i. Ìyẹn ni ìdí tí a kò fi rí ìràwọ̀ Pistol, tó wà ní 25,000 ọdún ìmọ́lẹ̀ sí Ayé, títí di ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990. Oríṣi ìràwọ̀ yìí mìíràn mẹ́fà péré ni a tíì rí nínú ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ wa.

Wíwakọ̀ àti Títẹniláago —Àkànpọ̀ Tó Léwu

Àwọn awakọ̀ tí ń tẹni láago nígbà tí wọ́n ń wakọ̀ lọ́wọ́ lè ṣe àwọn àṣìṣe tó léwu láìmọ̀ rárá. Èyí ni àbájáde àyẹ̀wò kan tí wọ́n ṣe lórúkọ Ẹgbẹ́ Onímọ́tò Àpapọ̀ Ilẹ̀ Germany. Wọ́n ní kí àwọn awakọ̀ wa ọkọ̀ fi dánra wò nígbà mẹ́ta. Nígbà àkọ́kọ́, wọn kò lo fóònù. Nígbà kejì, wọn lo fóònù tí wọn kì í gbé sọ́wọ́; nígbà kẹta, wọ́n lo tẹlifóònù tí wọ́n ń gbé sọ́wọ́. Báwo ni àwọn awakọ̀ tó ṣe ìdánrawò náà ti ṣe sí? Ní ìpíndọ́gba, láìlo fóònù, àwọn awakọ̀ ṣe 0.5 àṣìṣe nínú kíkó ìjánu ọkọ̀ àti dídúró sórí ọwọ́ wọn, àwọn tó lo fóònù tí wọn kò gbé sọ́wọ́ ṣe àṣìṣe 5.9, àwọn awakọ̀ tó lo fóònù tí wọ́n gbé sọ́wọ́ sì ṣe àṣìṣe 14.6. Nítorí náà, ìwé ìròyìn Süddeutsche Zeitung ròyìn pé, ìwádìí náà parí sí pé lílo fóònù tí a ń gbé sọ́wọ́ nígbà tí a bá ń wakọ̀ “léwu nínú púpọ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́