ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 10/8 ojú ìwé 29-30
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Eré Orí Kọ̀ǹpútà Tí Ń Ṣèpalára
  • Àwọn Òkun Tí A Sọ Dìbàjẹ́
  • Gbàrọgùdù Egbòogi
  • Ìbọn Di Ohun Fífẹ́ ní United States
  • Afárá Alásorọ̀ Tó Gùn Jù Lágbàáyé
  • Àwọn Irúgbìn Tí A Ń Wu Léwu
  • Àwọn Àrùn Tí A Ń Kó ní Ilé Ìwòsàn
  • Bẹ́líìtì Ààbò Gba Ẹ̀mí Là Nínú Ọkọ̀ Òfuurufú
  • Dín Iná Mànàmáná Tí O Ń Lò Kù
  • Òkun Òkú Ń Gbẹ
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1996
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Àwọn Àlùmọ́ọ́nì Ilẹ̀ Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Run Tán
    Jí!—2005
  • Fọgbọ́n Lo Oògùn
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 10/8 ojú ìwé 29-30

Wíwo Ayé

Àwọn Eré Orí Kọ̀ǹpútà Tí Ń Ṣèpalára

Ìròyìn Reuters kan sọ pé, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Ilẹ̀ Brazil “ti fòfin de títa eré orí kọ̀ǹpútà kan tí ń fa awuyewuye, tí àwọn tí ń ṣe é ti máa ń gba máàkì bí wọ́n bá jí ọkọ̀ gbé àti tí wọ́n pa àwọn ọlọ́pàá.” Wọ́n ka eré náà sí “eléwu nítorí ó fi olè jíjà àti ìpànìyàn hàn bí ohun tí kò ṣe bàbàrà, ó sì lè sún àwọn èwe tí ń ṣe eré náà hùwà ipá.” Ní 1997, ilé iṣẹ́ náà fòfin de eré orí kọ̀ǹpútà tí “ń fún àwọn tí ń ṣe eré náà ní máàkì tí wọ́n bá pa àwọn ènìyàn tí ń fẹsẹ̀ rìn, títí kan àwọn arúgbó obìnrin àti àwọn aboyún.” Agbẹnusọ kan fún ẹgbẹ́ Procon, ẹgbẹ́ tí ń jà fún ẹ̀tọ́ aláràlò, sọ pé: “Irú àwọn eré wọ̀nyí léwu, wọ́n sì lè ṣèpalára nítorí pé wọ́n ń dá ìwà ipá sílẹ̀. Àwọn ọmọdé yóò máa rò pé kò sí ohun tó burú nínú irú nǹkan bẹ́ẹ̀.”

Àwọn Òkun Tí A Sọ Dìbàjẹ́

Ìwé ìròyìn Nassauische Neue Presse sọ pé: “Fífi ìwà àìláàánú pẹja lápajù, àwọn kẹ́míkà olóró, àti pàǹtírí onítànṣán olóró tí ń dénú àwọn òkun ń wu ìpìlẹ̀ ìwàláàyè gbogbo àgbáyé léwu.” Bí ìwé ìròyìn Kieler Nachrichten ṣe sọ, Òkun Dúdú ni èyí ń ṣẹlẹ̀ sí jù. A kà á sí ọ̀kan lára ibi tí ó léwu jù lọ nínú ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn lágbàáyé, tí kò ti sí ẹ̀dá abẹ̀mí kankan nínú ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún rẹ̀. Pàǹtí tí a kò bójú tó ti sọ ìgbì omi tí ń rọ́ wá sí àwọn etíkun ilẹ̀ Ukraine di omi eléèérí tí ó láwọ̀ ewé mọ́ àwọ̀ ilẹ̀, wọ́n sì ṣí etíkun tí ó yí Odessa ká sílẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan péré ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tó kọjá. Ààrẹ ilẹ̀ Romania, Emil Constantinescu, sọ pé: “A ti ba Òkun Dúdú jẹ́ jù. Bí a bá jẹ́ kí ó gbẹ, aburú tí ó ju èyí tí a lè finú rò ni yóò ṣẹlẹ̀ sí wa.” Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti kéde pé 1998 ni “Ọdún Òkun Àgbáyé.”

Gbàrọgùdù Egbòogi

Ìwé ìròyìn Le Figaro Magazine sọ pé: “Nǹkan bí ìpín 8 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn egbòogi tí a ń tà láyé ló jẹ́ gbàrọgùdù.” Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ti sọ, a fojú bù ú pé ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún gbàrọgùdù egbòogi ló wà ní Brazil, a sì rò pé ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún ló wà ní Nàìjíríà. Ìròyìn sọ pé títa gbàrọgùdù egbòogi jẹ́ òwò tí ń mú 300 bílíọ̀nù dọ́là wọlé, tí ìwà ọ̀daràn tí a ṣètò sì kó ipa tí ó gba iwájú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilé iṣẹ́ apòògùn ń sapá láti fòpin sí òwò yìí, àwọn ọlọ́pàá àti àwọn àjọ àgbáyé kò tí ì rí ojútùú sí ìṣòro náà. Ire tí gbàrọgùdù egbòogi lè ṣe ni pé ó lè fi ọkàn aláìsàn balẹ̀ dípò wíwò ó sàn; aburú tí ó lè ṣe ni pé ó lè pani. Ìwé ìròyìn Le Figaro Magazine sọ pé: “Gbàrọgùdù egbòogi jẹ́ mímọ̀ọ́mọ̀ wu ìlera àwọn aláìsàn léwu.”

Ìbọn Di Ohun Fífẹ́ ní United States

Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé: “Amẹ́ríkà [United States] yàtọ̀ gédégédé sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Ní 1996, àwọn tí wọ́n fi ìbọn ìléwọ́ pa ní New Zealand jẹ́ méjì, 15 ní Japan, 30 ní Britain, 106 ní Kánádà, 211 ní Germany, ti United States sì jẹ́ 9,390.” Ìbọn kò gbẹ́yìn nínú nǹkan bí ìdajì mílíọ̀nù ìwà ọ̀daràn àti nǹkan bí 35,000 ènìyàn tí ó kú, títí kan ìpara ẹni àti èèṣì tí ń ṣẹlẹ̀ ní United States lọ́dọọdún. Síbẹ̀síbẹ̀, ìwé ìròyìn náà sọ pé àwọn tí wọ́n ní ìbọn ní United States “kò fẹ́ dẹ̀yìn lẹ́yìn ìbọn, láìbìkítà nípa iye ènìyàn tí ń kú. Dípò gbígbégbèésẹ̀ tí ó túbọ̀ le láti dín in kù, bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ti ṣe, ńṣe ni púpọ̀púpọ̀ wọn ń lépa rẹ̀.” Ní báyìí, ìpínlẹ̀ 31 ti ṣàgbéjáde ìwé àṣẹ tí ń gba àwọn ènìyàn láyè láti máa gbé ìbọn ìléwọ́ tí a fi pa mọ́ kiri.

Afárá Alásorọ̀ Tó Gùn Jù Lágbàáyé

Afárá Akashi Kaikyo tó wà ní Japan, tó so Erékùṣù Awaji pọ̀ mọ́ ìlú ńlá Kobe, ni wọ́n ṣí ní April, tí orúkọ rẹ̀ sí wọ ìwé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé òun ni afárá alásorọ̀ tí ó gùn jù lágbàáyé. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Nígbà tí iṣẹ́ náà ń lọ lọ́wọ́ láàárín ọdún mẹ́wàá tí wọ́n fi ṣe é, afárá tí wọ́n fi 7.7 bílíọ̀nù dọ́là ṣe náà gùn ní ẹsẹ̀ bàtà 6,532 (ibùsọ̀ 1.2) [1,991 mítà]—tí ó jẹ́ ìṣirò bí àwọn ilé gogoro méjèèjì náà ṣe jìnnà síra. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ilé gogoro náà, tí ó ga ju ilé alájà 90 lọ, ní 20 ẹ̀rọ tí ń darí ìgbọ̀nrìrì; bí afẹ́fẹ́ bá sún ilé náà, àwọn irin àsorọ̀ kẹ̀ǹdùkẹ̀ǹdù yóò fa àwọn ilé gogoro náà padà sípò.” Wọ́n tún ṣe afárá náà kí ìsẹ̀lẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ ga tó 8.0 lórí òṣùwọ̀n Richter má lè rí i gbé ṣe. Bí a bá na àwọn irin tí wọ́n fi ṣe é, wọ́n lè ká ilẹ̀ ayé ní ìlọ́po méje.

Àwọn Irúgbìn Tí A Ń Wu Léwu

Lẹ́yìn 20 ọdún tí àwọn onímọ̀ nípa ewéko àti àwọn alágbàwí ààbò ẹ̀dá yíká ayé fi ṣe iṣẹ́ náà, wọ́n parí èrò sí pé ìpín 12.5 nínú ọgọ́rùn-ún lára 270,000 irú ọ̀wọ́ irúgbìn tí a mọ̀ tó wà lágbàáyé—ọ̀kan nínú 8—ni a ń wu léwu àkúrun. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Mẹ́sàn-án lára irúgbìn 10 tí a to orúkọ wọn ni a ń gbìn ní orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo péré, tí èyí sì ń mú kí ìṣòro ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè tàbí ti ìbílẹ̀ àti àwọn ìṣòro tí ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ ẹ̀dá lè tètè wu wọ́n léwu.” Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ ìdí pàtàkì méjì tí àwọn irúgbìn fi ń wà nínú ewu: (1) ṣíṣá igbó agbègbè àrọko lulẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ilé kíkọ́, gígé gẹdú, àti iṣẹ́ àgbẹ̀ àti (2) gbígbalẹ̀ tí àwọn irúgbìn tí a kì í gbìn ládùúgbò gbalẹ̀ kan, tí wọ́n sì kún bo àwọn irú ọ̀wọ́ tí a ń gbìn ládùúgbò. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé, àwọn irúgbìn “ń ṣe àyíká ẹ̀dá láǹfààní gan-an” ju àwọn ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú àti àwọn ẹyẹ lọ. Ó sọ síwájú sí i nípa àwọn irúgbìn pé: “Wọ́n ń ṣètìlẹyìn fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára ìyóókù àwọn ohun alààyè, àti ènìyàn, nípa yíyí ìtànṣán oòrùn padà di oúnjẹ. Wọ́n ń ṣèmújáde àwọn èròjà tí a fi ń ṣe egbòogi àti orísun apilẹ̀ àbùdá tí a fi ń ṣèmújáde oríṣiríṣi irúgbìn. Wọ́n sì jẹ́ ìpìlẹ̀ àdánidá ti ìrísí ojú ilẹ̀, ohun tí gbogbo ohun mìíràn ń ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀.”

Àwọn Àrùn Tí A Ń Kó ní Ilé Ìwòsàn

Ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, Le Figaro, kéde pé: “Àwọn àrùn tí a ń kó ní ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n bá tọ́jú ẹni tàbí tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fúnni tán jẹ́ ìṣòro pàtàkì kan tí àwọn ará ìlú ń ní.” Ní ilẹ̀ Faransé nìkan, 800,000 ènìyàn ní ń kó irú àrùn bẹ́ẹ̀ lọ́dọọdún, a sì fojú díwọ̀n iye àwọn tí ń kú sí 10,000. Onírúurú ìgbésẹ̀ ni a lè gbé láti dín ewu àkóràn kù: fífọ àwọn iyàrá aláìsàn kí aláìsàn mìíràn tó dé síbẹ̀, yíyẹ àwọn ìgbésẹ̀ ìpakòkòrò wò, àti fífọ ọwọ́ dáadáa kí a tó tọ́jú aláìsàn. Ó hàn kedere pé púpọ̀ lára àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí ni a kì í sábà kà sí. Ìwádìí kan tí a ṣe ní ilé ìwòsàn kan ní Paris fi hàn pé ìpín 72 péré nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn òṣìṣẹ́ abáni-múgbá-máwo nílé ìwòsàn ló sọ pé àwọn máa ń fi ara balẹ̀ fọ ọwọ́ àwọn lẹ́yìn fífọwọ́ kan aláìsàn kọ̀ọ̀kan. Ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn wọ̀nyí ni kì í fọ ọwọ́ wọn tó ìwọ̀n àkókò tí ó yẹ. Ìwé ìròyìn náà parí ọ̀rọ̀ pé, pẹ̀lú bí iye náà ti pọ̀ tó báyìí, “ó jọ pé a ṣì ní púpọ̀ láti ṣe.”

Bẹ́líìtì Ààbò Gba Ẹ̀mí Là Nínú Ọkọ̀ Òfuurufú

Bí olúkúlùkù ẹni tí ó ti ń rin ìrìn àjò tipẹ́ ti mọ̀, àwọn ọkọ̀ òfuurufú lè ní ìṣòro àìdára ojú ọjọ́ lójijì, tí ó lè ṣèpalára fún àwọn èrò inú ọkọ̀ tàbí kí ó tilẹ̀ pa wọ́n. Àwọn ògbógi sọ pé, ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ kan ṣoṣo tí a lè lò ni kí bẹ́líìtì ààbò ẹni wà ní dídè ní gbogbo ìgbà tí a bá ti jókòó nínú ọkọ̀ òfuurufú. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Ìṣòro àìdára ojú ọjọ́ tí ń ṣẹlẹ̀ lójú òfuurufú ṣòro láti mọ̀ tẹ́lẹ̀, láti rí tẹ́lẹ̀, kò sì dùn sá fún tẹ́lẹ̀.” Bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ronú nípa ṣíṣe àwọn ẹ̀rọ tí ń fi irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ hàn kí a tó rọ́ lù ú, ọ̀pọ̀ jù lọ ọkọ̀ òfuurufú ló jẹ́ pé àwọn ìròyìn tí wọ́n ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkọ̀ òfuurufú tí ó ti gba ọ̀nà kan náà kọjá ṣáájú wọn ni wọ́n ń gbẹ́kẹ̀ lé. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn tí ó fara pa nínú àwọn ìṣòro yìí ni kò de bẹ́líìtì ààbò wọn. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Àmọ́, àwọn ilé iṣẹ́ ọlọ́kọ̀ òfuurufú kò tíì mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà mú kí àwọn èrò ọkọ̀ máa de bẹ́líìtì ààbò wọn lọ́ràn-anyàn.”

Dín Iná Mànàmáná Tí O Ń Lò Kù

Lẹ́tà ìròyìn Apotheken Umschau sọ pé: “Ìpín 11 nínú ọgọ́rùn-ún iná mànàmáná tí àwọn ènìyàn ń lò nínú ilé àti ọ́fíìsì wọn ní ilẹ̀ Germany ló jẹ́ àwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ tí a kò lò, àmọ́ tí a tanná rẹ̀ sílẹ̀ ní ń lò ó.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí a fojú bù fún ilẹ̀ Germany, ẹ̀rọ tẹlifíṣọ̀n, ẹ̀rọ amìjìnjìn, kọ̀ǹpútà, àti àwọn ohun abánáṣiṣẹ́ mìíràn tí a tanná wọn sílẹ̀ ń lo nǹkan bí 20.5 bílíọ̀nù kilowatt-hour iná mànàmáná lọ́dọọdún. Èyí pọ̀ ju iye iná mànàmáná tí Berlin, ìlú ńlá tí ó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà, ń lò lọ́dọọdún. Bí o bá ń pa àwọn ohun abánáṣiṣẹ́ kan pátápátá dípò títàn wọ́n sílẹ̀, ó ṣeé ṣe kí iná mànàmáná tí o ń lò má pọ̀ jù, kí o má sì náwó jù.

Òkun Òkú Ń Gbẹ

Òkun Òkú, tí ó jìn jù, tí ó sì níyọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé, ń yára gbẹ. Ní 1965, Òkun Òkú jìn ní 395 mítà sísàlẹ̀ ìtẹ́jú òkun. Ó ti di 413 mítà sí ìsàlẹ̀ òkun báyìí, ilẹ̀ ṣóńṣó kan sì ti yọrí láàárín rẹ̀, tí ó pín in sí méjì. Àwọn òtẹ́ẹ̀lì tí a kọ́ sí ibi tí òkun náà fẹnu kan ti wà lórí ilẹ̀ gedegbe báyìí. Ìwé ìròyìn The Dallas Morning News sọ pé: “Ó hàn kekere pé jíjìn omi rẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ bàtà 2.5 [80 sẹ̀ǹtímítà] dín kù lọ́dọọdún, omi tí ń ṣàn wọ inú òkun náà kò tó nítorí bí àwọn ènìyàn ṣe ń lo omi tó àti nítorí ìṣèlú. Ìparun tí ń bọ̀ kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ sórí Òkun Òkú náà ń tọ́ka bí ọ̀ràn àìtó omi ní àwọn àgbègbè kan ṣe le tó, tí àwọn ìdènà sí ojútùú kan sì fi bí omi ti ṣe pàtàkì tó kí àlàáfíà tó wà ní Àáríngbùngbùn Ìlà Oòrùn gbígbẹ táútáú náà hàn. . . . Lónìí, ilẹ̀ Ísírẹ́lì, Síríà àti Jọ́dánì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ darí Odò Jọ́dánì tí ó jẹ́ olórí orísun Òkun Òkú gba ibòmíràn tán.” Àpilẹ̀kọ náà sọ nípa ìtàn Òkun Òkú pé: “Ìtàn tí ó dájú jù lọ ni èyí tí Bíbélì sọ nípa bí àwọn Ìlú Ńlá Pẹ̀tẹ́lẹ̀ ṣe fìdí sọlẹ̀ sí àgbègbè ilẹ̀ ọlọ́ràá kan títí tí ìwà wọn fi bí Ọlọ́run nínú, tí ó sì ‘fi rọ òjò imí ọjọ́ àti iná sórí Sódómù àti Gòmórà’ láti sọ ọ́ di ilẹ̀ tí kò wúlò.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́