ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 2/8 ojú ìwé 29-30
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣe Ọmọdé Níṣekúṣe Wọ́pọ̀
  • “Baba Ńlá Tí Ọjọ́ Rẹ̀ Pẹ́ Jù Lọ” Kẹ̀?
  • Ẹ̀rọ Àfiṣènìyàn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Abẹ
  • Àwọn Tí Jàǹbá Ọkọ̀ Ń Pa Ń Pọ̀ Sí I
  • Orí Ibi Tó Dọ̀tí
  • Dídín Ewu Òkúta Inú Kíndìnrín Kù
  • Ohun Tí Wọ́n Ka Ọdún Àjíǹde Sí ní Ọsirélíà
  • Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè fún Àwọn Obìnrin
  • Sísọ Ọjà Rírà Di Bárakú
  • Ṣíṣọ́ Àwọn Ọmọdé
  • Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Nínú Ilé
    Jí!—1993
  • Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Ṣayẹyẹ Ọdún Àjíǹde?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Easter tàbí Ìṣe Ìrántí Èwo ni Ó Yẹ Kí O Ṣe?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọdún Àjíǹde?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 2/8 ojú ìwé 29-30

Wíwo Ayé

Ṣíṣe Ọmọdé Níṣekúṣe Wọ́pọ̀

Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Ìwádìí tuntun kan tí [Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà] ṣe nípa ìlera àwọn ọmọdékùnrin fi hàn pé ó lé ní ọ̀kan lára àwọn ọmọdékùnrin mẹ́jọ tí wọ́n ti tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tó sọ pé a ti fìyà jẹ àwọn, a sì ti bá àwọn ṣèṣekúṣe.” Ìwádìí náà fi hàn pé, “fífìyà jẹ àwọn ọmọdékùnrin wọ́pọ̀ ju bíbá wọn ṣèṣekúṣe lọ, àti pé ìdá méjì nínú mẹ́ta lára àwọn tí a fìyà jẹ náà ló jẹ́ àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn ló fìyà jẹ wọ́n nílé.” Àwọn ọmọdékùnrin ara Amẹ́ríkà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Éṣíà ni a bá ṣe ìṣekúṣe jù lọ, tí ìdá mẹ́sàn-án lára wọn sì sọ pé a ti fìyà jẹ àwọn rí. Lára àwọn ọmọdékùnrin ará Sípéènì, ìdá méje lára wọn sọ pé a ti bá àwọn ṣèṣekúṣe rí, nígbà tí ìdá mẹ́ta lára àwọn adúláwọ̀ àti òyìnbó sọ pé a ti bá àwọn ṣèṣekúṣe rí. Ìwé ìbéèrè náà kò ṣàlàyé irú ṣíṣeni níṣekúṣe tó jẹ́. Ó wulẹ̀ béèrè bóyá a ti fìyà jẹ ẹni tó dáhùn ìbéèrè náà rí tàbí a ti bá a ṣèṣekúṣe rí ni.

“Baba Ńlá Tí Ọjọ́ Rẹ̀ Pẹ́ Jù Lọ” Kẹ̀?

Àwọn bíṣọ́ọ̀bù jákèjádò Éṣíà ṣèpàdé láìpẹ́ yìí ní Ìlú Ibùjókòó Ìjọba Póòpù láti jíròrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà mú ẹ̀sìn Kátólíìkì dé àwọn ilẹ̀ Éṣíà. Bíṣọ́ọ̀bù Oswald Gomis láti Sri Lanka sọ pé: “Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Éṣíà, ìsìn Kristẹni jẹ́ ẹ̀sìn àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé tó bá ètò ìtẹ̀lúdó wá.” Ìwé ìròyìn Associated Press sọ pé, nípa bẹ́ẹ̀, ìpèníjà náà jẹ́ láti “fi Jésù hàn bí ará Éṣíà. Àwọn bíṣọ́ọ̀bù náà sọ̀rọ̀ nípa mímú ìjọ Róòmù náà bá àṣà àdúgbò àti èdè mu tàbí kí a má mú un bá a mu.” Àpẹẹrẹ kan tí a fúnni ni ti àṣà jíjọ́sìn àwọn baba ńlá. Láti fa àwọn tí ń tẹ̀ lé àṣà àtijọ́ náà lọ́kàn mọ́ra, Bíṣọ́ọ̀bù John Tong Hon láti Hong Kong dábàá pé kí àwọn Kátólíìkì rọra máa mú èrò náà wọlé pé Jésù tí í ṣe ọlọ́run àwọn “Kristẹni” jẹ́ “baba ńlá tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ.”

Ẹ̀rọ Àfiṣènìyàn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Abẹ

Ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, Le Figaro, sọ pé àwọn oníṣẹ́ abẹ́ méjì ní ilé ìwòsàn kan ní Paris ti ṣiṣẹ́ abẹ ọkàn-àyà tí a kọ́kọ́ fi ẹ̀rọ àfiṣènìyàn tí kọ̀ǹpútà ń darí ṣe, tí ó kẹ́sẹ járí. Iṣẹ́ abẹ mẹ́fà ni wọ́n ṣe, tí iṣẹ́ abẹ tí a fi ń ṣẹ̀dá iṣan òpójẹ̀ wà lára wọn. Ojú ibì kan tí wọ́n là ní sẹ̀ǹtímítà mẹ́rin ni wọ́n gbà ṣe iṣẹ́ abẹ náà. Àwọn oníṣẹ́ abẹ́ náà jókòó níbi ìdarí ẹ̀rọ náà tí ó wà ní mítà mélòó kan sí aláìsàn náà, wọ́n ń fi kámẹ́rà kan wo inú ara aláìsàn náà, wọ́n sì ń fi ọ̀pá rubutu méjì darí àwọn ọwọ́ ẹ̀rọ àfiṣènìyàn náà. Nítorí pé kọ̀ǹpútà náà dín lílọ àti bíbọ̀ àwọn oníṣẹ́ abẹ náà kù sí nǹkan bí ìgbà mẹ́ta sí márùn-ún, iṣẹ́ abẹ náà kò lábùkù, kò sì gba líla ara jù. Àǹfààní mìíràn ni pé ìrora aláìsàn náà túbọ̀ máa ń dín kù nígbà tí ara bá ń yá.

Àwọn Tí Jàǹbá Ọkọ̀ Ń Pa Ń Pọ̀ Sí I

Ìwé ìròyìn Fleet Maintenance & Safety Report ròyìn pé, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] ènìyàn tí ń kú lọ́dọọdún lójú pópó jákèjádò ayé àti pé àwọn tí jàǹbá ọkọ̀ ń pa ń pọ̀ sí i jákèjádò ayé. Báwo ni o ṣe lè ní ìjàǹbá ọkọ̀ bíburújáì? Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ti sọ, “ní àwọn orílẹ̀-èdè ‘tí ọkọ̀ ti pọ̀,’ ó kéré tán ẹnì kan lára ogún ènìyàn ló ń kú tàbí ló ń fara pa nínú jàǹbá ojú pópó lọ́dọọdún, bákan náà, ẹnì kan lára àwọn méjì ni a ń gbà sí ilé ìwòsàn nítorí fífarapa nínú jàǹbá ọkọ̀, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan ní gbogbo ìgbà tí wọ́n lò láyé.”

Orí Ibi Tó Dọ̀tí

Ó lè dà bí ohun ìyàlẹ́nu pé ibi tí o ń jókòó lé lórí ṣáláńgá aláwo ilé rẹ lè mọ́ ju pátákó tí o ń gé nǹkan lórí rẹ̀ ní ilé ìdáná rẹ lọ. Ohun tí àwọn olùwádìí láti Yunifásítì Arizona sọ nìyẹn lẹ́yìn tí wọ́n lo ọgbọ̀n ọ̀sẹ̀ nídìí ṣíṣàyẹ̀wò àwọn kòkòrò bakitéríà tí wọ́n rí ní ilé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Agbo àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣàyẹ̀wò ohun mẹ́rìnlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ilé kọ̀ọ̀kan, ìwọ̀nyí ní nínú ọwọ́ ẹ̀rọ omi, inú ibi ìfọǹkan, pátákó tí a ń gé nǹkan lórí rẹ̀, aṣọ àgbékọ́rùn gbọ́únjẹ, àti ibi tí a ń jókòó lé lórí ṣáláńgá aláwo. Kí ni wọ́n rí? Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Kòkòrò bakitéríà tí àwọn olùwádìí rí nínú omi tí wọ́n fún jáde lára aṣọ àgbékọ́rùn gbọ́únjẹ fi ìlọ́po àádọ́ta ọ̀kẹ́ pọ̀ ju èyí tó wà ní ibi tí a ń jókòó lé lórí ṣáláńgá aláwo lọ. Kódà, àwọn pátákó tí a ń gé nǹkan lórí wọn ní kòkòrò bakitéríà tí ó fi ìlọ́po mẹ́ta ju ìyẹn lọ.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé, agbẹnusọ nínú ìwádìí náà, Pat Rusin, sọ èrò rẹ̀ pé, “ibi tí a ń jókòó lé lórí ṣáláńgá aláwo wulẹ̀ ti gbẹ gan-an débi pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn kòkòrò bakitéríà tí wọ́n máa ń wá àyíká tó lọ́rinrin kò lè fi ibẹ̀ ṣe ilé.” Rusin dámọ̀ràn fífọ àwọn aṣọ àgbékọ́rùn gbọ́únjẹ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti túbọ̀ ṣe ìmọ́tótó sí i. Ó fi kún un pé: “Kí a wulẹ̀ da ife àpòpọ̀ ìbóǹkan sínú omi tó kún ibi ìfọǹkan, kí a sì rẹ ẹ́ fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá kí a tó jẹ́ kí ó ṣàn lọ.”

Dídín Ewu Òkúta Inú Kíndìnrín Kù

Ìwé ìròyìn Science News sọ pé, àwọn olùwádìí tí ń ṣọ́ irú oúnjẹ tí àwọn nọ́ọ̀sì tí iye wọ́n lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rin ń jẹ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà láàárín 1986 sí 1994 ṣàwárí pé ó lè jẹ́ pé àwọn ohun mímu kan ń ṣèrànwọ́ ju àwọn mìíràn lọ láti má jẹ́ kí òkúta wọ inú kíndìnrín ẹnì kan. Lára àwọn ohun mímu mẹ́tàdínlógún tí a lò fún ìwádìí, tíì ń dín ewu níní òkúta nínú kíndìnrín kù ní ìpín mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún, nígbà tí kọfí wíwọ́pọ̀ tàbí èyí tí a yọ èròjà kaféènì inú rẹ̀ kúrò ń dín ewu náà kù ní nǹkan bí ìpín mẹ́sàn-án nínú ọgọ́rùn-ún. Ọtí wáìnì tí a mu níwọ̀nba ń dín ewu níní òkúta nínú kíndìnrín kù ní ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwádìí náà fi hàn pé: “Ó yani lẹ́nu pé mímu ife omi ọsàn àjàrà kan lóòjọ́ ń mú kí ewu òkúta pọ̀ sí i ní ìpín mẹ́rìnlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún. Kò sí ohun mímu mìíràn tó ní ipa bíburú bẹ́ẹ̀.” A fa ọ̀rọ̀ Dókítà Gary Curhan, onímọ̀ nípa kíndìnrín, tí ó tún jẹ́ onímọ̀ nípa àrùn tí ń ṣe aráàlú ní Boston, yọ pé: “Dídín ìwọ̀n ohun tí a ń mu kù díẹ̀ lè mú ìyàtọ̀ wá,” àmọ́, kìkì bí apá kan ọ̀nà ìtọ́jú tó wọ́pọ̀.

Ohun Tí Wọ́n Ka Ọdún Àjíǹde Sí ní Ọsirélíà

Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ọsirélíà náà, Sun-Herald, béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn nípa ohun tí wọ́n ka ọdún Àjíǹde sí. Bí èsì tí a tẹ̀ jáde náà ṣe lọ nìyí: ẹyin ọdún Àjíǹde oníṣokoléètì (ìpín mẹ́rìnléláàádọ́ta), ìsinmi gígùn lópin ọ̀sẹ̀ (ìpín mọ́kàndínlógójì), Eré Ọdún Àjíǹde Ọba (ìpín mọ́kànlélógún), àkókò ayẹyẹ ìsìn (ìpín ogún). David Milikan, àlùfáà kan láti Ìjọ Ìparapọ̀ Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì, sọ pé kò ya òun lẹ́nu pé iye àwọn ènìyàn Sydney tó so ọdún Àjíǹde mọ́ ẹ̀sìn kéré tó bẹ́ẹ̀. Ó fi kún un pé: “Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń tán lọ . . . Gbogbo àwọn ẹ̀ya ìsìn pàtàkì-pàtàkì ń pàdánù àwọn ọmọ ìjọ púpọ̀.” Bíṣọ́ọ̀bù àgbà Ìjọ Roman Kátólíìkì tó wà ní Sydney kédàárò pé: “Ọdún Àjíǹde kò ní ìjẹ́pàtàkì ìsìn rárá lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn; àjọyọ̀ ayé mìíràn lásán ni wọ́n kà á sí.”

Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè fún Àwọn Obìnrin

Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Àwọn obìnrin ti ń lé àwọn ọkùnrin bá ní ti lílọ́kàn-ìfẹ́ sí àwọn ìsọfúnni nípa ìbálòpọ̀ tí a kò fi bò, tí a ń tàtagbà rẹ̀ lórí kọ̀ǹpútà.” Àwọn ibi bíi mélòó kan bẹ́ẹ̀ tí a ṣètò fún àwọn obìnrin ní “àwọn àwòrán àpèjúwe nípa ìbálòpọ̀ tí a ti fi ọ̀rọ̀ díẹ̀ bò . . . àti dídúnàádúrà.” Lẹ́yìn tí apá ibi kan tí a ṣe ní pàtàkì fún àwọn obìnrin abẹ́yà-kejì-lòpọ̀ kọ́kọ́ jáde, ìwé ìròyìn Times sọ pé, “apa ibi tí a yà sọ́tọ̀ yìí wulẹ̀ jẹ apá kékeré kan lára àwọn ìṣekúṣe jàá-ǹ-rẹrẹ tó kún inú àwọn ìsokọ́ra alátagbà lílókìkí.”

Sísọ Ọjà Rírà Di Bárakú

Ìwé ìròyìn Grafschafter Nachrichten sọ pé: “Àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ sí i ló ń ní ìṣòro sísọ ọjà rírà di bárakú ní Germany.” Bí afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá nídìí òwò ṣíṣe náà, Alfred Gebert, ti sọ, àwọn tí wọ́n ti sọ ọjà rírà di bárakú máa ní ìmọ̀lára ayọ̀ tí kì í pẹ́ pòórá lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sanwó ọjà tí wọ́n rà. Gebert sọ pé, a tilẹ̀ máa ń rí àwọn àmì ìfàsẹ́yìn lára wọn. “Wọ́n máa ń wárìrì, wọ́n máa ń làágùn, inú sì máa ń run wọ́n.” Nítorí èyí, àwọn tí owó gọbọi ń wọlé fún, tí wọ́n sì rí ṣe ló wà nínú ewu ju àwọn tálákà lọ. Wọ́n sọ pé lára àwọn ohun tó lè fa ìsọdibárakú náà ni ‘ìdáwà, iyì ara ẹni tí kò tó, àìfararọ, àti àwọn ìṣòro tí a ń kò níbi iṣẹ́.’ Láti kápá ìsọdibárakú náà, Gebert dámọ̀ràn níní ìgbòkègbodò àfipawọ́ kan. Gebert sọ pé, lílọ síbi àpéjọ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ṣe pàtàkì. Ó sọ pé: “Tí a kò bá rẹ́ni sọ fúnni, ìgbà tí pańpẹ́ gbèsè bá múni, tí a sì ná owó tó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ ẹni tán nìkan ni a máa tó mọ̀ pé a ní àṣà bárakú náà.”

Ṣíṣọ́ Àwọn Ọmọdé

Àwọn òbí kan ní Japan ti bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àdáni láti máa ṣọ́ àwọn ọmọ wọn láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn abúmọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Daily Yomiuri ṣe sọ, ọ̀jọ̀gbọ́n kan láti Yunifásítì Ìlú Ńlá Osaka tí ó ṣèwádìí lórí ẹgbàáta akẹ́kọ̀ọ́ sọ pé: “Lápapọ̀, àwọn ọmọ tí a bú mọ́ máa ń fẹ́ láti fi òkodoro ọ̀rọ̀ náà pa mọ́ fún ìdílé wọn, wọ́n máa ń bẹ̀rù pé a óò bá àwọn wí nítorí pé àwọn kò lè jà padà tàbí kí àwọn kọ̀ ọ́.” Àwọn òbí kan tí wọ́n fura pé a ń fìtínà àwọn ọmọ àwọn ti fàbọ̀ sórí títọ́jú ohun atú-ǹkan-fó tí ń lo agbára mànàmánà sára àwọn ọmọ náà kí wọ́n lè máa gbọ́ ìjíròrò tí wọ́n ń ní. Àwọn mìíràn ti gba àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àdáni láti máa tẹ̀ lé “ọmọ náà láìsún mọ́ ọn jù, kí wọ́n máa gba ẹ̀rí tí a lè fi mú àwọn adánilóró sílẹ̀, kí wọ́n sì máa yọ sí wọn láti gbà ọmọ kan tí ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ewu sílẹ̀ bí àwọn áńgẹ́lì tí ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ ti máa ń ṣe.” Àmọ́, ìwé ìròyìn náà sọ pé, àwọn tí ń jà fún ààbò ọmọdé “bu ẹnu àtẹ́ lu ṣíṣọ́ tí àwọn òbí ń ṣọ́ àwọn ọmọ, wọ́n sọ pé ó jẹ́ ìgbésẹ̀ amúnifòyà tí ó lè túbọ̀ sọ ọmọdé kan di àjèjì sí àgbàlagbà tí ó yẹ kí ó gbẹ́kẹ̀ lé, kí ó sì finú tán.” Àmọ́, àwọn òbí sọ pé ó jẹ́ ọ̀nà àtiran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ nínú ìṣòro nígbà tí àwọn ọmọ náà kò bá lè bá àwọn sọ̀rọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́