Wíwo Ayé
Sìgá Mímu Ń Náni Lówó Gọbọi
Ìwé ìròyìn Berner Oberländer sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn amusìgá ń dín kù ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, iye ti Switzerland kò yingin. Nǹkan bí ìdá mẹ́ta àwọn olùgbé ilẹ̀ náà ló ń mu sìgá. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ènìyàn tí ohun tó ń pa wọ́n lọ́dọọdún ò ṣẹ̀yìn sìgá—iye yẹn ju iye àwọn tí àpapọ̀ àrùn AIDS, oògùn líle heroin, kokéènì, ọtí líle, iná, jàǹbá mọ́tò, ìṣìkàpànìyàn, àti ìpara-ẹni ń pa lọ. Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Ilé Iṣẹ́ Tí Ń Bójú Tó Ìlera Ará Ìlú Ti Ìjọba Àpapọ̀ ní Switzerland sọ pé, iye tábà tí àwọn ènìyàn mu ní ọdún 1995 jẹ́ bílíọ̀nù mẹ́wàá owó franc ilẹ̀ Switzerland, iye tó pọ̀ ju bílíọ̀nù mẹ́fà dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ. Ìròyìn náà gbìyànjú láti mọ iye tí gbígba ìtọ́jú lọ́dọ̀ oníṣègùn àti àbójútó ilé ìwòsàn tó, bí agbára ìṣiṣẹ́ wọ́n ṣe ń dín kù sí, bí ìníyelórí ìgbésí ayé àwọn amusìgá tí àìsàn ti kọ lù àti àwọn tí wọ́n ń bọ́ ṣe ń dín kù, àti ìyà tí ń jẹ àwọn mẹ́ńbà ìdílé ẹni tó kú.
Dáàbò Bo Ọkàn-Àyà Rẹ
Dókítà Anthony Graham, onímọ̀ àrùn ọkàn-àyà, tó tún jẹ́ agbẹnusọ fún Àjọ Agbówókalẹ̀ fún Ìtọ́jú Àrùn Ọkàn-Àyà àti Àrùn Ẹ̀gbà ní Ontario, Kánádà, sọ pé: “A mọ̀ pé bí ooru bá ṣe mú gan-an tó ni ewu àrùn ọkàn-àyà ṣe ń pọ̀ sí i—ṣùgbọ́n nísinsìnyí a ti wá rí i pé ó máa ń ṣẹlẹ̀ bí òtútù bá ń mú pẹ̀lú.” Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú ìwé ìròyìn The Globe and Mail, ìwádìí kan tí a fi ọdún mẹ́wàá ṣe láàárín ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ [250,000] ọkùnrin ní ilẹ̀ Faransé fi hàn pé bí ìpíndọ́gba ooru ara bá fi ìwọ̀n mẹ́wàá lọ sókè tàbí sísàlẹ̀ “ó máa ń mú kí ewu níní àrùn ọkàn-àyà tó le gan-an fi ìpín mẹ́tàlá nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i.” Bí ìdíwọ̀n ooru ara bá lọ sílẹ̀, ọkàn-àyà yóò máa ṣiṣẹ́ kólekóle yóò sì máa yára sí i nítorí pé ẹ̀jẹ̀ yóò wọ́ kúrò nínú awọ ara lọ sí àwọn ibi tó jìn gan-an nínú ara láti pa ooru mọ́. Ewu náà máa ń pọ̀ sí i tí àwọn ènìyàn bá lo ara wọn lálòjù tàbí tí wọn kò bá wọ aṣọ tó yẹ. Dókítà Graham kìlọ̀ pé: “O kò lè jókòó tẹtẹrẹ fún oṣù márùn-ún kí o wá dìde lójijì lọ máa kó òjò dídì nínú òtútù. O ní láti máa ṣe é díẹ̀díẹ̀ tó fi máa mọ́ ẹ lára.”
A Fi Ohùn Orin Tó Ròkè Jù Yẹra fún Wàhálà
Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ilẹ̀ Poland náà, Przyjaciółka, sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn dókítà ń kìlọ̀ pé orin tí a yí ohùn rẹ̀ sókè jù, “ń ṣèpalára fún gbogbo ara lódindi,” ó jọ pé àwọn ọ̀dọ́ tí iye wọn ń pọ̀ sí i kò lè máà tẹ́tí sí ẹ̀rọ amìjìnjìn wọn. Kí ló fà á? Ìwé ìròyìn náà sọ pé, àwọn kan máa ń lo ẹ̀rọ amìjìnjìn wọn láti “gbọ́kàn wọn kúrò nínú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ láyìíká. Fún àpẹẹrẹ, bí ọ̀dọ́langba kan bá ti tẹ gbohùngbohùn àtẹ̀bọtí rẹ̀ bọtí, kò ní máa gbọ́ ẹjọ́ wẹ́wẹ́ àwọn òbí rẹ̀ tàbí kí ó máa dá wọn lóhùn bí wọ́n bá ní kó ṣe nǹkan.” Níwọ̀n bí ìwé ìròyìn Przyjaciółka ti ṣàkíyèsí pé bí ohùn orin bá ròkè jù, ó tún lè fa “àárẹ̀, ẹ̀fọ́rí, àìlèpọkànpọ̀ dáadáa, tàbí àìróorunsùntó,” kì í ṣe pé ó ń gba àwọn òbí nímọ̀ràn láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n lo ẹ̀rọ amìjìnjìn mọ́ ni ṣùgbọ́n ó ń dábàá pé kí àwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn láti ṣe é níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ìwé ìròyìn náà dábàá pé kí àwọn òbí “máa yá ẹ̀rọ amìjìnjìn àwọn ọmọ wọn lò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìyẹn yóò jẹ́ kí wọ́n gbé gbohùngbohùn àtẹ̀bọtí náà kúrò létí díẹ̀, ìwọ alára yóò sì lè mọ irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé.”
Èdè Tí Ń Kú Run
Olóyè Marie Smith Jones, ẹni tó sọ èdè Eyak, ti ilẹ̀ Alaska, kẹ́yìn láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀, sọ pé: “Nígbà mìíràn inú a kàn máa bí mi síra mi nítorí pé n kò kọ́ àwọn ọmọ mi ní èdè náà.” Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ fi hàn pé lára ẹgbẹ̀rún mẹ́fà èdè tí a ń sọ lágbàáyé, nǹkan bí ìpín ogójì sí ìpín àádọ́ta lára wọn lè pòórá láàárín ọ̀rúndún tí ń bọ̀. Nǹkan bí ogún èdè péré ni Ọsirélíà tó ti ní àádọ́talénígba èdè nígbà kan rí wá ní báyìí. Kí ló ń fa èyí? Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé ó lè jẹ́ pé àwọn èdè náà ti di “ìgbàgbé nítorí pé èdè Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn èdè ‘wíwọ́pọ̀’ mìíràn ń tàn kálẹ̀.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Stephen Wurm, olùyẹ̀wòṣàtúnṣe ìwé Atlas of the World’s Languages in Danger of Disappearing, tí Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe, fi kún un pé: “A sábà máa ń ní èrò pé ó yẹ ká gbàgbé àwọn èdè ‘tí kò wọ́pọ̀,’ àwọn èdè tí àwọn ènìyàn kéréje ń sọ, nítorí pé àwọn èdè náà kò wúlò.”
Máa Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀
Ìwé ìròyìn Daily Telegraph ti London sọ pé, bíbá àwọn ọmọ ọwọ́ sọ̀rọ̀ fún nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú péré lóòjọ́ lè mú kí làákàyè àti agbára àtikọ́ èdè wọn túbọ̀ gbéṣẹ́ dáadáa sí i. Àwọn olùwádìí ṣàyẹ̀wò ogóje ọmọ ọwọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́sàn-án. A gba àwọn òbí ìdajì lára wọn nímọ̀ràn lórí ọ̀nà tó dára jù lọ láti máa gbà bá àwọn ọmọ wọn jòjòló sọ̀rọ̀, a kò sì fún àwọn ìdajì yòókù nímọ̀ràn kankan nípa bí wọn ó ṣe ṣe é. Ìròyìn náà sọ pé, lẹ́yìn ọdún méje, “ìwọ̀n làákàyè ọ̀wọ́ àwọn ọmọ tí [a ń bá sọ̀rọ̀] fi ọdún kan àti oṣù mẹ́ta pọ̀ ju tí àwùjọ kejì lọ,” agbára àtikọ́ èdè wọn sì “ga gan-an.” Olùwádìí náà, Ọ̀mọ̀wé Sally Ward, gbàgbọ́ pé àwọn òbí kì í fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ lóde òní tó bí àwọn ènìyàn ṣe ń ṣe láyé àtijọ́ nítorí àwọn ìyípadà ńlá tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ ẹ̀dá. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ìyá púpọ̀ sí i ló ń lọ síbi iṣẹ́, fídíò sì ti rọ́pò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìdílé.
Yíyẹra fún Ìrunú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà
Enì kan tó ti pẹ́ lẹ́nu wíwakọ̀ sáre ìdíje, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé Fleet Maintenance & Safety Report, gbani nímọ̀ràn pé: “Kò yẹ kí a fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn awakọ̀ oníwàkuwà.” Fífarabalẹ̀ àti yíyẹra fún àwọn ipò tí kò báradé lè bá wa dín ewu ìrunú nídìí ọkọ̀ wíwà kù. Àwọn tí ń ṣalágbàwí ààbò dámọ̀ràn àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí:
◼ Máa wakọ̀ tìṣọ́ratìṣọ́ra nígbà gbogbo.
◼ Yà kúrò lọ́nà fún onímọ́tò tó ń wàwàkuwà tí o bá lè ṣe bẹ́ẹ̀ láìséwu.
◼ Má ṣe bá awakọ̀ mìíràn táákà nípa sísúnmọ́ ọkọ̀ rẹ̀ jù tàbí sísáré lé e.
◼ Má ṣe dáhùn sí àwọn ìṣesí tí ó léwu, sì yẹra fún ṣíṣe àwọn ohun tí a lè ṣì lóye.
◼ Má ṣe wo ojú awakọ̀ tí inú ń bí.
◼ Má ṣe gbé e yọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ awakọ̀ mìíràn láti bá a táákà.
Ìpalára àti Ikú Tí Oyún Ṣíṣẹ́ Ń Fà
Francisco Javier Serna Alvarado, ààrẹ Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Lórí Ìlera àti Iṣẹ́ Ìfẹ́dàáfẹ́re ní Ìlú Ńlá Mexico, sọ pé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500,000] oyún ni a ń ṣẹ́ lọ́dọọdún ní Mexico. Gẹ́gẹ́ bí a ti ròyìn rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn El Universal, èyí tó pọ̀ lára oyún tí a ń ṣẹ́ wọ̀nyí ló ń mú ẹ̀mí ìyá lọ, ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn sì ń yọrí sí ìṣòro lílekoko tó nílò ìtọ́jú oníṣègùn tàbí kí a tilẹ̀ dá wọn dúró sílé ìwòsàn pàápàá. Ṣíṣẹ́yún láṣìírí ló ṣìkẹ́ta lára ohun tí ń ṣokùnfà ikú àwọn obìnrin jù lọ ní Mexico. Ìròyìn náà sọ pé, nínú àwọn ọ̀ràn kan, a máa ń lo àwọn ìlànà ìṣẹ́yún tí kò dára—lílo àwọn nǹkan mímú tó rí ṣóṣóró, lílo oògùn tàbí àgbo ìṣẹ́yún, àti fífò lulẹ̀ láti orí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì pàápàá. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń yọrí sí ohun tí ìròyìn náà pè ní “ẹ̀jẹ̀ dídà lára gan-an, dídá ilé ọmọ lu, dídi ẹni tí kò lè bímọ mọ́, kíkó àrùn, àti bíba ilé ọmọ jẹ́.”
Sọ Ohun Tí O Ní Í Sọ
Ògbógi nípa ohùn, Ọ̀mọ̀wé Lillian Glass, sọ pé, láìka bí ohun tí o ní í sọ ti ṣe pàtàkì sí, ọ̀pọ̀ ènìyàn kò ní fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ bí wọn kò bá nífẹ̀ẹ́ sí bí o ṣe ń sọ̀rọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Citizen ti Gúúsù Áfíríkà ṣe sọ, fífọ̀rọ̀ ránu, sísọ̀rọ̀ lọ́nà tí kò dán mọ́rán, lílo ìró ohùn kan ṣáá, yíyánu sọ̀rọ̀, sísọ̀rọ̀ àlùfààṣá, àti àìfún ẹlòmíràn lọ́rọ̀ sọ máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹni tí ń gbọ́ni. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ènìyàn yóò máa tẹ́tí sí ọ bí o bá ń rẹ́rìn-ín músẹ́ láti mú kí ara wọ́n balẹ̀, bí o bá ń sọ̀rọ̀ ketekete láìyára, bí o bá ń wo ojú wọn tààràtà, bí o bá tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ní í sọ dáadáa láìjá lu ọ̀rọ̀ wọn. Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé: “Tí o bá ń ronú kí o tó sọ̀rọ̀, wàá lè fọkàn balẹ̀ ṣàlàyé ara rẹ.”
Àjẹjù Ń Mú Kí Ewu Jíjẹ Májèlé Inú Oúnjẹ Pọ̀ Sí I
Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Adolfo Chávez, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Oúnjẹ ti Ìjọba Àpapọ̀ ní Mexico, ṣe sọ, oúnjẹ àjẹjù ń mú kí ewu ṣíṣàìsàn nítorí jíjẹ oúnjẹ tó ní kòkòrò bakitéríà pọ̀ sí i. Ó sọ pé ásíìdì inú agbẹ̀du wa máa ń pa àwọn kòkòrò bakitéríà tó wà nínú oúnjẹ tí a ń jẹ. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí a bá ti jẹ àjẹjù, oúnjẹ tí a jẹ lẹ́yìn tí a yó tán yóò lágbára ju ìwọ̀n ásíìdì inú àgbẹ̀du lọ, yóò sì dín agbára ikùn láti pa kòkòrò bakitéríà kù. Dókítà Chávez wí fún Jí! pé: “Bí ẹnì kan bá jẹ kéèkì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí a kó èròjà sí láàárín, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀kan lára wọ́n ní kòkòrò bakitéríà nínú, ẹni náà lè kó bakitéríà nítorí iye tó jẹ. Ká ní ẹyọ kéèkì kan péré tí a kó èròjà sí láàárín, tí bakitéríà ti wọ̀ ló jẹ, ó lè máà ní ìṣòro kankan.”
Ẹ̀ẹ̀rín Rírín Ń Dín Kù
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi hàn nínú ẹ̀rí tí a gbé jáde níbi Ìpàdé Àgbáyé Lórí Ànímọ́ Ìdẹ́rìn-ínpani tí a ṣe ní Switzerland láìpẹ́ yìí, ní àwọn ọdún 1950 tí ètò ọrọ̀ ajé níṣòro, ènìyàn kan tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ máa ń fi ìṣẹ́jú méjìdínlógún rẹ́rìn-ín lóòjọ́, ṣùgbọ́n ó ń lo ìṣẹ́jú mẹ́fà lóòjọ́ ní àwọn ọdún 1990 tí nǹkan ń rọ̀ṣọ̀mù. Kí ló fa ìlọsílẹ̀ náà? Ìwé ìròyìn Sunday Times ti London ṣàlàyé pé: “Àwọn ògbógi di ẹ̀bi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ náà ru lílépa ọrọ̀ àlùmọ́nì lójoojúmọ́, lílépa ìyọrí ọlá àti aásìkí, èyí tó ti ìjótìítọ́ òwe àtijọ́ náà lẹ́yìn pé, a ò lè fi owó ra ayọ̀.” Ìdí nìyẹn tí òǹkọ̀wé Michael Argyle fi sọ pé: “Àwọn tí owó ń jẹ lọ́kàn jù kì í nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ọpọlọ wọn kì í sì í ṣiṣẹ́ dáadáa. Èyí lè jẹ́ nítorí pé ìtẹ́lọ́rùn tí kò jinlẹ̀ ni owó ń fúnni.”
A Dáàbò Bo Ẹ̀tọ́ Láti Gba Ìwòsàn
Láìpẹ́ yìí, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní El Salvador fagi lé òfin Ilé Ìwòsàn Ìfẹ́dàáfẹ́re kan tó béèrè pé kí àwọn aláìsàn fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ kí a tó lè tọ́jú wọn. Tẹ́lẹ̀ rí, àwọn ilé ìwòsàn máa ń béèrè pé kí olúkúlùkù aláìsàn mú ìwọ̀n méjì ẹ̀jẹ̀ wá kí a tó ṣe iṣẹ́ abẹ fún wọn. Nísinsìnyí, àwọn tí wọ́n bá fẹ́ kí a tọ́jú àwọn ní Ilé Ìwòsàn Ìfẹ́dàáfẹ́re ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti yàn láti má ṣe fi ẹ̀jẹ̀ tọrọ.