ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 3/8 ojú ìwé 16
  • Kò Gbàgbé Orin Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kò Gbàgbé Orin Náà
  • Jí!—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Mo Ṣe Sapá Láti Ṣe Yíyàn Tó Bọ́gbọ́n Mu
    Jí!—2000
  • Jèhófà Ń hùwà Lọ́nà Ìdúróṣinṣin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • A Rí Ohun Míì Tó Sàn Jù Tá A Fi Ìgbésí Ayé Wa Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Fi Orin Yin Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 3/8 ojú ìwé 16

Kò Gbàgbé Orin Náà

“NÍGBÀ tí mo wà nílé ẹ̀kọ́, mo máa ń kọrin tó ní àwọn ọ̀rọ̀ náà, ‘Jèhófà ńlá gúnwà nínú ògo rẹ̀.’ Mo sì sábà máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni Jèhófà yìí?’”

Ọ̀rọ̀ yẹn, tó jáde lẹ́nu Gwen Gooch, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, táa kọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ sínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́, rí bákan náà lára òǹkàwé kan.a Vera tó wá láti ìlú Seattle, ìpínlẹ̀ Washington, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ pé, “ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí mi nígbà tí mo wà nílé ìwé gíga.”

Bíi ti Gwen, lẹ́yìn tí Vera gbọ́ orin kan báyìí tán, òun náà fẹ́ mọ ẹni tí Jèhófà yìí jẹ́. Vera rí ìdáhùn sí èrò ọkàn rẹ̀ ní ọdún 1949 nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kọ́kọ́ sọ fún un nípa Jèhófà, tí í ṣe orúkọ tí Bíbélì pe Ọlọ́run.

Ó ti lé ní àádọ́ta ọdún báyìí tí Vera ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n kò gbàgbé orin ìyìn tó kọ nígbà tó wà nílé ìwé gíga. Ó wí pé: “Mo ti gbìyànjú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti mọ ibi tí orin náà ti wá.” Níkẹyìn, àwọn kan tí ń ta àwo orin ràn án lọ́wọ́ láti mọ orísun orin náà. Franz Schubert ló kọ ọ́ ní ọdún 1825. Lóòótọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ inú orin náà fìyìn fún Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ orin náà ló wà nísàlẹ̀ yìí:

“Atóbilọ́lá ni Jèhófà, Olúwa! nítorí Ọ̀run àti Ayé ń kókìkí agbára ńlá rẹ̀. . . . Àwọn ọ̀dàn, ìjì líle, òkun tó ń ru gùdù ń fagbára rẹ̀ hàn . . . Àwọn igi àti igbó tí atẹ́gùn ń fẹ́, ọwọ́ ewé àgbàdo tí ń fẹ́ lẹ́lẹ́; àwọn òdòdó olóòórùn dídùn tó tanná, àwọn ìràwọ̀ tó kún ojú Ọ̀run ń fi agbára rẹ̀ hàn . . . Sísán ààrá Rẹ̀ ń múni wá rìrì, mànàmáná Rẹ̀ sì ń kọ mànà lójú òfuurufú. Ṣùgbọ́n èyí tó wá pabanbarì ni ọkàn-àyà rẹ tó ń lù kìkì tí òun pẹ̀lú ń pòkìkí agbára Jèhófà, . . . Olúwa Ọlọ́run ayérayé. Gbójú sókè sí I lókè Ọ̀run, kí o sì dúró de oore ọ̀fẹ́ àti àánú rẹ̀. . . . Atóbilọ́lá ni Jèhófà, Olúwa!”

Vera sọ pé: “Mo máa ń ka àwọn ọ̀rọ̀ orin yẹn fún àwọn èèyàn láti fi hàn wọ́n pé àwọn tó mọ orúkọ Ọlọ́run wà ní àwọn ọdún 1800, wọ́n sì ń yìn ín.” Òótọ́ ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ ni pé láti ọjọ́ táláyé ti dáyé ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó nígbàgbọ́ ti máa ń fẹ́ fi orin yin Jèhófà. Àṣà náà kò sì lè parẹ́ láé, nítorí ìdí fún yíyin Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé ò lópin.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé Ìṣọ́, March 1, 1998.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Vera

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́