Àwọn Òléwájú Nínú Iṣẹ́ Ìṣègùn
ẸNI ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta ni José, ará Belgium, ọmọ abúlé Oupeye jẹ́ nígbà tí wọ́n sọ fún un pé wọ́n gbọ́dọ̀ pààrọ̀ ẹ̀dọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ̀rù ò bà mí bẹ́ẹ̀ rí láyé mi.” Ní ogójì ọdún péré sẹ́yìn, pípààrọ̀ ẹ̀dọ̀ ò tiẹ̀ ṣeé ṣe ni. Lẹ́yìn ọdún 1970 pàápàá, kìkì ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ abẹ yẹn fún ló ń rù ú là. Àmọ́ lónìí, pípààrọ̀ ẹ̀dọ̀ kì í ṣe nǹkan bàbàrà mọ́ o, wẹ́rẹ́ ni wọ́n ń ṣe é.
Ṣùgbọ́n ìṣòro ńlá kan ṣì wà ńlẹ̀ o. Níwọ̀n bí ẹ̀jẹ̀ ti máa ń dà gan-an nígbà tí wọ́n bá ń pààrọ̀ ẹ̀dọ̀, àwọn dókítà máa ń fa ẹ̀jẹ̀ síni lára nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ abẹ náà. Ṣùgbọ́n nítorí ohun tí José gbà gbọ́, kò fẹ́ gba ẹ̀jẹ̀. Àmọ́, ó fẹ́ kí wọ́n pààrọ̀ ẹ̀dọ̀ òun. Ǹjẹ́ ìyẹn lè ṣeé ṣe? Àwọn kan lè rò pé kò ṣeé ṣe. Àmọ́ ọ̀gá pátápátá tó fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ náà sọ pé òun àtàwọn ẹlẹgbẹ́ òun á ṣe é láìlo ẹ̀jẹ̀. Wọ́n mà ṣe é tí nǹkan ò mà sì yíwọ́ lóòótọ́! Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n péré tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún José ló padà sílé, tó ń gbádùn ayé ẹ̀ pẹ̀lú aya àtọmọbìnrin ẹ̀.a
Ọpẹ́lọpẹ́ ìmọ̀ táwọn èèyàn tí ìwé ìròyìn Time pè ní “akọni nínú iṣẹ́ ìṣègùn” ní, àwọn ló sọ ìtọ́jú àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ di èyí tó wá tàn kálẹ̀ báyìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Àmọ́ kí nìdí táwọn èèyàn fi ń gba tiẹ̀ gan-an báyìí? Ká lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká yẹ onírúurú àgbákò táwọn èèyàn ti kò nídìí gbígbẹ̀jẹ̀ sára wò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èrò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ọ̀ràn iṣẹ́ abẹ pípààrọ̀ ẹ̀yà ara ni pé kí kálùkù ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá sọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Kárí ayé, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rin ààbọ̀ [90,000] dókítà tó ti sọ báyìí pé àwọn ti ṣe tán láti máa tọ́jú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìlo ẹ̀jẹ̀