“Àwọn Ìwé Ìròyìn Tó Dáa Jù Lọ”
LẸ́NU àìpẹ́ yìí, àwọn olóòtú Jí! rí lẹ́tà kan gbà látọ̀dọ̀ Lisel, ọmọ iléèwé gíga kan tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún láti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó kọ̀wé pé:
“Ẹ̀kọ́ nípa ìtàn ni mo ń kọ́. Iṣẹ́ ìwádìí rẹpẹtẹ kan wà tí wọ́n ní ká ṣe, ohun tí mo sì yàn láti kọ̀wé lé lórí ni ìdúrógbọn-in àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòdì sí ìjọba Násì ní Jámánì nígbà tí Hitler ń ṣèjọba. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún mi ní orísun àwọn ìsọfúnni tẹ́ẹ tọ́ka sí ní ìparí àpilẹ̀kọ inú Jí! tẹ́ẹ pe àkọlé rẹ̀ ní ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Àwọn Onígboyà Lójú Ewu Nazi,’ tó wà nínú ìtẹ̀jáde July 8, 1998. Ẹ̀kọ́ gidi wà nínú àpilẹ̀kọ náà, ọgbọ́n ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yín sì gún régé débi pé bó bá tiẹ̀ jẹ́ ìdajì irú ìmọ̀lára àti òtítọ́ kan náà ni mo gbé kalẹ̀, ohun tí mo bá kọ á ṣì jẹ́ ẹ̀rí ńláǹlà fáwọn tí yóò yẹ iṣẹ́ mi wò.
“Ẹ ṣeun tí ẹ ò yé tẹ àwọn ìwé ìròyìn tó dáa jù lọ jáde. Nínú ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan, mo máa ń kọ́ ‘ẹ̀kọ́ nípa ìwé kíkọ,’ tí kì í ṣẹgbẹ́ ohun tí mo ń kọ́ níléèwé, èyí sì máa ń jẹ́ kí n sapá láti ṣe dáadáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nínú gbogbo kókó tí mo bá ń kọ̀wé lé lórí. Ẹ jọ̀wọ́ mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé mo mọrírì ìsapá yín.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]
Fọ́tò àárín: Państwowe Muzeum Oświęcim-Brzezinka, nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda USHMM Photo Archives