ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 5/8 ojú ìwé 26-27
  • Bí A Ṣe Lè Kápá Àìnírètí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí A Ṣe Lè Kápá Àìnírètí
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì Lè Ṣèrànwọ́
  • Eeṣe Ti Ainireti Pupọ Tobẹẹ Fi Wà?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Jèhófà Máa Ń gba Àwọn Tó Wà Nínú Ìpọ́njú Sílẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ireti Ṣẹgun Ainireti!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àbí Kí N Para Mi Ni?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 5/8 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Bí A Ṣe Lè Kápá Àìnírètí

KÒ SÉÈYÀN tí kì í sọ̀rètí nù, ó kéré tán dé ìwọ̀n kan. Bó ti wù kó rí, ìṣòro sísọ̀rètínù yìí máa ń ga fún àwọn kan débi tí wọ́n fi máa ń ronú pé kí àwọn kúkú kú sàn ju kí àwọn wà láàyè lọ.

Bíbélì fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ pàápàá kò ní àjẹsára tí ó lè lé ìṣòro àti pákáǹleke tó máa ń fa sísọ̀rètínù. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Èlíjà àti Jóòbù yẹ̀ wò—àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run rẹ́ gan-an ni. Lẹ́yìn tí Èlíjà sá lọ kí Jésíbẹ́lì Ayaba búburú náà má bàa pa á, ó ‘bẹ̀rẹ̀ sí béèrè pé kí Jèhófà jẹ́ kí ọkàn òun kú.’ (1 Àwọn Ọba 19:1-4) Oríṣiríṣi àjálù ló bá Jóòbù, ọkùnrin olódodo náà, àrùn burúkú kan kọ lù ú, àwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá sì tún kú. (Jóòbù 1:13-19; 2:7, 8) Nígbà tí gbogbo ẹ̀ tojú sú u, ó sọ pé: “Ó sàn kí n kú dípò gbogbo ìyà tó ń jẹ mí yìí.” (Jóòbù 7:15, The New English Bible) Ó ṣe kedere pé ọkàn àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ wọ̀nyí ti kó sókè.

Ní ti àwọn kan lónìí, wọ́n lè sọ̀rètí nù nítorí ìrora tí ọjọ́ ogbó ń mú wá bá wọn, nítorí ikú ìyàwó tàbí ọkọ, tàbí nítorí pé wọ́n ní ìṣòro ìṣúnná owó tó le gan-an. Àwọn kan ti wá rí i pé másùnmáwo tí kò yéé ṣeni, ìṣẹ̀lẹ̀ adanilórírú tí ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀ ò lọ bọ̀rọ̀, tàbí àwọn ìṣòro ìdílé ló ń mú káwọn máa nímọ̀lára bíi pé àwọn ń jà pàtàpàtà láàárín agbami òkun, tí ìjì òkun ń gbá àwọn káàkiri, tó sì ń mú kó túbọ̀ ṣòro fáwọn láti dé èbúté. Ọkùnrin kan sọ pé: “Ńṣe ló máa dà bíi pé o ò já mọ́ nǹkankan—bíi pé kò sẹ́ni tó tiẹ̀ máa mọ̀ tí o ò bá sí láyé mọ́. Ìmọ̀lára ìnìkanwà téèyàn máa ń ní nígbà mìíràn kì í ṣeé mú mọ́ra.”

Ní ti àwọn kan, ipò nǹkan máa ń yí padà sí dáadáa, pákáǹleke lílekoko yìí sì máa ń dín kù. Ṣùgbọ́n tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ipò nǹkan kò yí padà fún wa ńkọ́? Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti kápá àìnírètí?

Bíbélì Lè Ṣèrànwọ́

Jèhófà tóótun, ó sì lágbára láti mẹ́sẹ̀ Èlíjà àti Jóòbù dúró nígbà tí wọ́n wà nínú gbogbo ìṣòro wọn. (1 Àwọn Ọba 19:10-12; Jóòbù 42:1-6) Ìtùnú ńláǹlà ló jẹ́ fún wa lónìí láti mọ ìyẹn! Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.” (Sáàmù 46:1; 55:22) Bó tilẹ̀ jọ pé àìsírètí lè mú ọkàn wa pòrúurùu, Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo òun dì wá mú ṣinṣin. (Aísáyà 41:10) Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìrànlọ́wọ́ yìí?

Bíbélì ṣàlàyé pé nípasẹ̀ àdúrà “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà [wa] àti agbára èrò orí [wa] nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Nítorí ìrora ọkàn wa, a lè máà rí ojútùú sí ìṣòro wa. Bó ti wù kó rí, báa bá “ní ìforítì nínú àdúrà,” Jèhófà lè dáàbò bo ọkàn-àyà àti èrò orí wa, kó fún wa ní okun táa nílò láti forí tì í.—Róòmù 12:12; Aísáyà 40:28-31; 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; Fílípì 4:13.

A óò jàǹfààní nípa sísọ àwọn nǹkan pàtó nínú àdúrà wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣòro láti ṣàlàyé èrò ọkàn wa, kò yẹ ká lọ́ra láti sọ fún Jèhófà nípa ẹ̀dùn ọkàn wa àti ohun tí a wòye pé ó ń fa ìṣòro náà. A ní láti bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa lókun tí yóò máa mẹ́sẹ̀ wa dúró lójoojúmọ́. Ó mú un dá wa lójú pé: “Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ [Jèhófà] ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là.”—Sáàmù 145:19.

Ní àfikún sí gbígbàdúrà, a kò gbọ́dọ̀ máa ya ara wa sọ́tọ̀. (Òwe 18:1) Àwọn kan ti rí okun gbà nípa fífi tọkàntara ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíràn. (Òwe 19:17; Lúùkù 6:38) Gbé ọ̀ràn obìnrin kan tó ń jẹ́ Mariaa yẹ̀ wò, bí àrùn jẹjẹrẹ ti ń bá a fínra ni ẹni mẹ́jọ tún kú nínú ìdílé rẹ̀ láàárín ọdún kan. Nígbà yẹn, Maria máa ń tiraka dìde lórí ibùsùn láti ṣe àwọn nǹkan tó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ló ń jáde lọ kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. Nígbà tí Maria bá tún padà délé, ìrora ọkàn á tún fìdí pagbá sínú ọkàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n, nítorí pé Maria pọkàn pọ̀ sórí bó ṣe lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́, ìyẹn mú kó lè forí tì í.

Ṣùgbọ́n bó bá ṣẹlẹ̀ pé ó ṣòro fún wa láti gbàdúrà tàbí tó jọ pé ó ṣòro fún wa láti máa wà láàárín àwọn ènìyàn ńkọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ wá ìrànlọ́wọ́. Bíbélì fún wa níṣìírí láti yíjú sí “àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ.” (Jákọ́bù 5:13-16) Ọkùnrin kan tó ń ní ìsoríkọ́ tí kò dáwọ́ dúró sọ pé: “Nígbà míì, bíbá ẹnì kan tóo fọkàn tán sọ̀rọ̀ máa ń ṣèrànwọ́ láti mú ìtura bá èrò orí, ó sì ń mú kí ọkàn parọ́rọ́, tí èrò tó dáa á fi borí.” (Òwe 17:17) Lóòótọ́, tó bá jẹ́ àìlera ló ń fa àìnírètí tí ò lọ bọ̀rọ̀, tó sì le koko, èèyàn lè tún nílò ìrànlọ́wọ́ ẹni tó mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa.b—Mátíù 9:12.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ojútùú tó rọrùn, kò yẹ ká fojú kéré agbára tí Ọlọ́run yóò fi ràn wá lọ́wọ́ láti kápá àwọn ìṣòro wa. (2 Kọ́ríńtì 4:8) Títẹra mọ́ àdúrà, kí a má ya ara wa sọ́tọ̀, ká sì wá ìrànlọ́wọ́ tó mọ́yán lórí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti tún gbé ìrètí wa ró. Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run yóò mú ohun tí ń fa àìnírètí fún wa kúrò pátápátá. Àwọn Kristẹni ti pinnu láti gbẹ́kẹ̀ lé e bí wọ́n ti ń dúró de ọjọ́ náà tí àwọn ‘ohun àtijọ́ kì yóò wá sí ìrántí.’—Aísáyà 65:17; Ìṣípayá 21:4.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èyí kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gangan.

b Jí! kò fòté lé e pé irú ìtọ́jú kan pàtó ló dára jù lọ. Ó yẹ kí àwọn Kristẹni rí i dájú pé irú ìtọ́jú èyíkéyìí tí wọ́n bá fẹ́ gbà kò forí gbárí pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Láti rí ìsọfúnni sí i, wo Ilé-Ìṣọ́nà, October 15, 1988, ojú ìwé 25 sí 29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́