Eeṣe Ti Ainireti Pupọ Tobẹẹ Fi Wà?
IRETI fun igbesi-aye kan ti ó sànjù—ọwọ́ tẹ̀ ẹ́ nigbẹhin-gbẹhin! Ọpọlọpọ eniyan tí ń gbé ní ibi ti a ń pè ni Ila-oorun Germany nigba naa gba eyi gbọ́ nigba ti Ogiri Berlin wólulẹ̀ ni November 1989. Bi o ti wu ki o ri, ni ohun ti o fi diẹ ju ọdun kan lọ lẹhin naa, wọn ṣaroye nipa “rírí ayé lilekoko ti ijọba dẹmọ oniṣowo bombata bí eyi tí o nira jù lati dojukọ ju igbesi-aye ti a fi Ogiri Berlin daabobo lọ.” Ki ni iyọrisi rẹ̀? Otitọ tí kòbákùngbé ati ainireti tí ń ga sii.
Ìwà-ipá abẹ́lé ati ti awujọ lè fi ipá mú awọn eniyan lati sá kuro ni ile ni wíwá aabo, ṣugbọn iwọnba ni awọn ti ń rí i. Awọn kan tilẹ lè pari rẹ̀ si wíwà lara awọn alainilelori tí wọn ń pàgọ́ kiri awọn opopona ilu-nla. Ni awọn ilẹ kan ọpọ ninu awọn wọnyi ni wọn ń pari rẹ̀ si didi ẹni ti ó tarabọ ilana iṣe nǹkan didiju ti awọn alaṣẹ. Wọn kò lè ni ile kan nitori pe wọn kò niṣẹ lọwọ, wọn kò sì lè rí iṣẹ ṣe nitori pe wọn kò ni adirẹsi ile. Awọn eleto ire alaafia ijọba gbiyanju lati ṣeranlọwọ, ṣugbọn o ń gba akoko lati kásẹ̀ iṣoro naa kuro nilẹ. Nipa bẹẹ imujakulẹ ati ainireti wọlé dé.
Ọpọ awọn obinrin ni ainireti ń sún lati ṣe awọn nǹkan tí ń dẹ́rùbani. Ninu irohin Women and Crime in the 1990’s, olukọni nipa ofin Dr. Susan Edwards ṣalaye pe: “Ìlọ́wọ́ [ninu ìwà aṣẹwo] awọn ọ̀ṣọ́rọ́ obinrin ní taarata jẹ́ nitori awọn ohun pipọndandan niti eto ọrọ̀ ajé, kì í ṣe nitori aini ìbára-ẹni-wí tabi ipilẹ idile.” Bakan naa, awọn ọdọkunrin ti wọn fi ile silẹ ni wíwá iṣẹ lọ kì í sábà rí ọ̀kan. Awọn kan, ninu ainireti, pari rẹ̀ si didi ‘awọn kárùwà ọkunrin,’ ni mimu araawọn wà larọọwọto fun ìbẹ́yà-kan-naa-lopọ lati lè gba ounjẹ ati ile gbigbe, ni didi ohun eelo ni ọwọ awọn ọdaran oniwa ibajẹ.
Awọn otitọ gidi nipa ipo oṣelu lilekoko, ìwà-ipá, awọn isoro ọrọ ajé, gbogbo wọn lè ru ìwọ̀n ainireti rẹpẹtẹ soke. Kódà awọn eniyan ti iṣẹ wọn jẹ́ ti ìmọ̀-ẹ̀kọ́ iwe giga paapaa kò ní àjẹsára bi wọn ti ń wá ọ̀nà lati maa bá àṣà igbesi-aye alaasiki wọn lọ lẹsẹ kan-naa nigba ti wọn sì ń kojú awọn iṣoro iṣunna-owo ti ń ga sii. Ki ni iyọrisi rẹ̀? Gẹgẹ bi Ọba Solomoni igbaani ti sọ, “Inilara mú ọlọgbọn eniyan sínwín”!a (Oniwasu 7:7) Nitootọ, ainireti ń sún iye ti ń ga sii lati yan ọ̀nà abajade lilekoko julọ—ifọwọ ara-ẹni pa ara-ẹni.
Ọ̀nà Abajade Lilekoko Julọ Naa
Ọpọ ọ̀ràn ifọwọ ara-ẹni pa ara-ẹni laaarin awọn ọ̀dọ́ fihan pe awọn paapaa ní ìyọnu ainireti kan. Akọwe irohin ara Britain kan beere pe: “Ki ni ohun naa nipa akoko wa ti o ń fa ainireti pupọ tobẹẹ fun awọn ọdọlangba?” Ninu iwadii kan nipa awọn ọmọde ti ọjọ-ori wọn wà laaarin ọdun 8 si 16 ti a ti gba si ile iwosan lẹhin gbigbiyanju lati gbé majele jẹ, Dr. Eric Taylor ti London’s Institute of Psychiatry rohin pe: “Ohun agbafiyesi kan ni bi iye awọn ọmọ ti wọn jẹ́ alainireti ati alailekẹsẹjari nipa awọn nǹkan ti pọ̀ tó.” Britain ṣakọsilẹ 100,000 awọn ipo ọ̀ràn ti kò la ikú lọ ti a fojudiwọn ṣugbọn ti wọn jẹ́ awọn ipo ọ̀ràn mímọ̀ọ́mọ̀ gbé majele jẹ lọdọọdun lọna kan ti ń fi bi awọn eniyan ti ń sọ aini kanjukanju wọn fun iranlọwọ di mímọ̀ tó hàn.
Eto ọrẹ-àánú kan ni ilẹ Britain ṣe ìfilọ́lẹ̀ igbetaasi kan lati maa fetisilẹ pẹlu ìyọ́nú si awọn alainireti. Ni ọ̀nà yii awọn olugbaninimọran rẹ̀ jẹwọ lati funni ni “awọn ohun afidipo ikú.” Sibẹ, wọn gbà pe awọn kò lè yanju iṣoro naa ti o ń fa ainireti fun awọn eniyan.
Ìwọ̀n ifọwọ ara-ẹni pa ara-ẹni fi “ipele ipinya ati aisi ifaramọra ẹgbẹ-oun-ọgba ninu ẹgbẹ awujọ” hàn, ni iwe irohin The Sunday Correspondent ṣalaye. Eeṣe ti ifọwọ ara-ẹni pa ara-ẹni fi gasoke lonii? Iwe irohin naa tọkasi “airilegbe, iye ti ń ga sii ninu ọti mimu, ihalẹmọni ti àrùn Aids ati títi awọn ile iwosan ọpọlọ pa” gẹgẹ bi okunfa ti ń ti ẹnikọọkan sinu ipo ainireti jijinlẹ bẹẹ ti wọn fi ro pe fifopin si iwalaaye araawọn ni ojutuu kanṣoṣo si awọn iṣoro wọn.
Ireti kankan ha wà lati lé ainireti kuro bi? Bẹẹni! “Ẹ wo oke, ki ẹ si gbé ori yin soke” ni igbe afunnilokun Jesu! (Luku 21:28) Ki ni ohun ti oun nilọkan? Ireti wo ni o wà nibẹ?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹgẹ bi iwe Theological Wordbook of the Old Testament, ti a tẹ̀ lati ọwọ Harris, Archer, ati Waltke ti sọ, orisun ede ipilẹṣẹ ọrọ naa ti a tumọ si “inilara” tan mọ́ “ẹrù-inira, ìtẹ̀mọ́lẹ̀, ati ìtẹ̀látẹ̀rẹ́ awọn wọnni ti wọn wà ni ipo rirẹlẹ.”