Ìbẹ̀wò sí “Ìlú Tọ́jọ́ Rẹ̀ Pẹ́ Jù Lọ ní Rọ́ṣíà”
ÈMI àti Linda, aya mi dé Moscow ní July 1998, níbi tí wọ́n rán wa lọ ṣe iṣẹ́ kan. A ò tíì dé ilẹ̀ Rọ́ṣíà rí, a sì ń hára gàgà láti mọ̀ nípa orílẹ̀-èdè náà, kí a gbọ́ èdè ibẹ̀, kí a sì mọ̀ nípa àwọn èèyàn ibẹ̀.
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí a débẹ̀, mo rí àwòrán kan tó fani mọ́ra, tó wà lẹ́yìn ruble márùn-ún, ìyẹn owó bébà aláwọ̀ ewé, tó jẹ́ ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Ó dà bí odi alágbára tí wọ́n fi bíríkì kọ́, tó ga lókè omi, tí erékùṣù àti adágún kan sì wà lẹ́yìn rẹ̀. Wọ́n wá kọ orúkọ ibẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan pé: Novgorod.
Mo bi àwọn tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Moscow léèrè nípa rẹ̀. Gbogbo wọn ló mọ̀ nípa Novgorod, ṣùgbọ́n nínú gbogbo àwọn tí mo bi léèrè, ẹnì kan ṣoṣo ló tíì débẹ̀ rí. Wọ́n sọ fún mi pé kò tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àbọ̀ kìlómítà sí ìlú Moscow, tó jẹ́ ìrìn àjò alẹ́ nínú ọkọ̀ ojú irin tó forí lé ọ̀nà St. Petersburg. Èmi àti aya mi pinnu láti lọ síbẹ̀.
Ìrìn Àjò wa sí Novgorod
Níwọ̀n bí mo ti ra tíkẹ́ẹ̀tì tí mo lè fi wọkọ̀ lọ sí St. Petersburg tẹ́lẹ̀ rí, mo mọ ibi tí mo ti lè rí ti ibẹ̀ rà. Wọ́n kọ nọ́ńbà ọkọ̀ ojú irin wa àti ibi tí a máa wà nínú rẹ̀ sí orí tíkẹ́ẹ̀tì wa. A dé sí ibùdó ọkọ̀ ojú irin ní agogo mẹ́sàn-án kọjá díẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ kan nínú oṣù September tó kọjá, a sì wọ inú iyàrá àdáni inú ọkọ̀, tí nọ́ńbà rẹ̀ jẹ́ aárùn-ún nínú ọkọ̀ ojú irin náà.
Ọkọ̀ ojú irin yìí rọ́, ó sì ṣe jìgì, ló bá wá gbéra. Bí a ṣe máa ṣe ní gbogbo òru yẹn nìyí níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọkọ̀ ojú irin tí yóò máa já àwọn èèyàn lójú ọ̀nà la wọ̀. Ọkọ̀ wa yóò dúró, lẹ́yìn ìṣẹ́jú mélòó kan, ọkọ̀ ojú irin mìíràn á wọ́ kọjá. Ní òru tí gbogbo nǹkan pa lọ́lọ́ yẹn, ìṣẹ́jú mélòó kan á tún kọjá sí i bí ọkọ̀ wa ti ń dúró ní ibi tí ọkọ̀ ojú irin ti máa ń dúró. Awakọ̀ yóò tún dẹ ìjánu ọkọ̀, ọkọ̀ wa á tún ṣe jìgì, á rọ́, á sì han gooro, bó bá sì yá, á tún bẹ̀rẹ̀ sí wọ́ tọ àwọn yòókù lẹ́yìn. Ìgbà yẹn loorun sì tún tó máa gbé mi lọ.
Bó ṣe kù díẹ̀ ká dé Novgorod, obìnrin tó jẹ́ olùtọ́jú èrò nínú ọkọ̀ ojú irin tiwa kan ilẹ̀kùn wa. Ibùdó ọkọ̀ ojú irin yẹn kún fún èrò bó tilẹ̀ jẹ́ pé agogo méje òwúrọ̀ kùtùkùtù ni. Ní ibì kan tí wọ́n ti ń ta ìwé ìròyìn, a rí àwòrán-ilẹ̀ ti ìlú náà, a sì tún béèrè lọ́wọ́ òǹtajà kan nípa iye tí a óò wọkọ̀ dé òtẹ́ẹ̀lì tí a fẹ́ dé sí. Ogún ruble (nǹkan bíi àádọ́rin sẹ́ǹtì) ni iye owó tí awakọ̀ takisí tó fi ọkọ̀ Lada rẹ̀ ti wọ́n ṣe ní Rọ́ṣíà gbé wa gbà dé òtẹ́ẹ̀lì wa tó wà lódìkejì Odò Volkhov—odò tó wà nínú àwòrán yẹn.
Awakọ̀ yẹn sọ fún wa pé òun kì í ṣe ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ṣùgbọ́n ọmọ ibẹ̀ ni ìyàwó òun. Ìdí nìyẹn tí òun fi ń gbé ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Olùgbàlejò tó wà ní òtẹ́ẹ̀lì náà gbà wá tọwọ́ tẹsẹ̀, kódà ó jẹ́ kí a wọlé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé agogo méje àbọ̀ òwúrọ̀ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ lù nígbà náà. Ó dámọ̀ràn ibi tí a lè lọ fún wa. A rìn lọ sí ibi odò náà, a sì jẹ oúnjẹ òwúrọ̀.
A rí ọgbà ìtura kan tó ní àwọn koríko tí wọ́n gé dáadáa àti àwọn igi tí wọ́n rẹ́ ọwọ́ wọn dáadáa. Àwọn òdòdó tí wọ́n fi ń ṣe ọ̀ṣọ́, tí wọ́n gbìn síbẹ̀ mú kí ibi tí èèyàn máa ń rin ìrìn gbẹ̀fẹ́ gbà léteetí odò náà lẹ́wà gidigidi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ wá síbẹ̀, nítorí pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkọ̀ bọ́ọ̀sì tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Kòríà máa ń kó àwọn èèyàn wá láti ṣèbẹ̀wò, síbẹ̀ Novgorod kì í ṣe ìlú tí àwọn èèyàn sábà máa ń rìnrìn àjò afẹ́ lọ. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí a rí ló jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà.
Àwọn kan tó ń gbé níbẹ̀ sọ fún wa pé Novgorod ni ìlú tọ́jọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Wọ́n sọ pé ó ti wà fún ohun tí ó ju ẹgbẹ̀rún ọdún ó lé ọgọ́rùn-ún lọ. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ògbólógbòó ṣọ́ọ̀ṣì tó wà káàkiri ìlú yẹn fi hàn pé ó pẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn níbẹ̀. Lórí àwòrán ilẹ̀ kan, mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wọn ni Linda kà ní àgbègbè òtẹ́ẹ̀lì wa nìkan.
A rí ilé gogoro kan ní kremlin, kì í ṣe Kremlin tó wà ní Moscow ni mo ń sọ o; “kremlin” ni àwọn ará Rọ́ṣíà máa ń pe “odi ìlú.” Èèyàn lè gun ilé gogoro yẹn dé òkè pátápátá. A san ruble márùn-ún (kò tó ogún sẹ́ǹtì), wọ́n sì gbà pé kí a gun àtẹ̀gùn tó yípoyípo náà dé òkè. Mo fi bí ibẹ̀ ṣe rí wé àwòrán tó wà lórí owó bébà ruble márùn-ún náà. Àwọn igi tó wà níbẹ̀ ti dàgbà, wọ́n sì ti fi nǹkan kan bo orí ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ tó wà níbi ògiri odi alágbára náà. Ṣùgbọ́n, Odò Volkhov ṣì wà níbẹ̀, odò kan náà àti erékùṣù àti adágún kan náà tó wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn rẹ̀. Ẹ̀rọ ńlá tí wọ́n fi máa ń gbẹ́ odò náà nìkan ni kò sí nínú àwòrán yẹn.
A ṣàkíyèsí ohun kan tó jẹ́ arabaríbí ní ọjọ́ kejì tí a lò ní Novgorod. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Rọ́ṣíà ń wo ìlú náà pé ó kéré, bẹ́ẹ̀ àwọn tó ń gbé ibẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé àádọ́ta, síbẹ̀ àwọn èèyàn ibẹ̀ rántí wa, wọ́n sì tún rántí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa wa! Obìnrin tó ń gbé oúnjẹ fún àwọn èèyàn ní òtẹ́ẹ̀lì náà rántí pé àná la débẹ̀. Ó rántí pé a fẹ́ràn kọfí, òun ló sì ń gbé wá fún wa. Ó tún rántí pé a kò fẹ́ràn omi èso, nítorí náà, kò béèrè lọ́wọ́ wa lọ́jọ́ kejì bóyá a fẹ́ ẹ. Mo rántí pé Olga ni orúkọ rẹ̀, nígbà tí mo bi í pé èló ni owó wa, o rẹ́rìn-ín, ó wo ojú mi ó sì sọ pé, “Iyàrá 356 ni, àbí?”
Lọ́jọ́ Sunday, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ya bo ibi odi náà, wọ́n wá sí ibi afárá tí ẹlẹ́sẹ̀ ń gbà tó gba orí Odò Volkhov kọjá, wọ́n ya bo òpópónà, wọ́n sì ń rìn níbi eteetí odò náà. Linda lọ ra gbúgbúrú lọ́dọ̀ ẹni tó ń tà á ní òpópónà nítòsí afárá tí ẹlẹ́sẹ̀ ń gbà, tí ẹ̀yin náà bá rántí, ẹni tí a rí lánàá ni, òun náà sì dá ìyàwó mi mọ̀!
Nígbà tí a padà lọ láti gun ilé gogoro náà kí a lè tún wo bí àyíká yẹn ṣe rí, ọmọbìnrin tó ń gba owó ìwọlé rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wa, ó sì wí pé: “Ẹ̀yin lẹ wá síbí lánàá, àbí ẹ̀yin kọ́ ni? Ṣé ẹ rí i, ẹ ti sanwó lánàá, ẹ kò tún ni sanwó mọ́.”
A pàdé David, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ wa kan tí a ti mọ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ní New York. Ó ti fẹ́ Alyona, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ará Rọ́ṣíà, Novgorod ni wọ́n sì ń gbé báyìí, wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ nínú ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Iwájú Ilé Àrójẹ Detinets, tí wọ́n kọ́ mọ́ ara ògiri lókè ibi odi yẹn la ti pàdé wọn. Níbẹ̀, wọ́n fún wa ní oúnjẹ àwọn ará Rọ́ṣíà tó dára jù lọ tí a kò jẹ rí. Gbogbo oúnjẹ ọ̀hún lápapọ̀ (sàláàdì, ọbẹ̀, pàtàkì nínú oúnjẹ ọ̀hún, kọfí, àti èso) kò ná wa lówó tó nǹkan.
Novgorod jẹ́ ìlú kan tí àwọn èèyàn ibẹ̀ yá mọ́ni, tí wọ́n rántí wa, ó sì ní oúnjẹ tó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, bákan náà ni ìtàn nípa ibẹ̀ àti oríṣiríṣi nǹkan tó wà níbẹ̀ mú kí ibẹ̀ gbádùn mọ́ni. A ṣì máa padà lọ.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
Owó bébà ruble márùn-ún ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà, àti fọ́tò Novgorod
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ibi odi yẹn, láti Odò Volkhov
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Gbígba orí afárá ẹlẹ́sẹ̀ kọjá lórí Odò Volkhov
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ẹ̀sìn pọ̀ gan-an ní Novgorod fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún