Àwọn Nọ́ọ̀sì—Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Jẹ́ Kòṣeémánìí?
“Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe tó ṣòro jù lọ ni iṣẹ́ nọ́ọ̀sì jẹ́. Ìyọ́nú lè sún wa láti ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ìmọ̀ nìkan ló ń fún wa lágbára àtiṣiṣẹ́ wa.”—Mary Adelaide Nutting, 1925, ẹni tó kọ́kọ́ gba oyè ọ̀jọ̀gbọ́n nínú iṣẹ́ nọ́ọ̀sì lágbàáyé.
ORÍṢI iṣẹ́ nọ́ọ̀sì lọ́nà tó rọrùn jù lọ ti wà láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn—kódà ó wà ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì. (1 Àwọn Ọba 1:2-4) Nínú gbogbo ìtàn, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó ta yọ ló ṣètọ́jú àwọn aláìsàn. Fún àpẹẹrẹ, ẹ wo ọ̀ràn ti Elizabeth ọmọ ilẹ̀ Hungary (ọdún 1207 sí 1231), tó jẹ́ ọmọ Andrew Ọba Kejì. Ó ṣètò pípín oúnjẹ kiri nígbà ìyàn kan tó bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1226. Lẹ́yìn náà, ó ṣètò pé kí wọ́n kọ́ àwọn ilé ìwòsàn, ó sì ṣètọ́jú àwọn adẹ́tẹ̀ níbẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún péré ni Elizabeth nígbà tó kú, àwọn aláìsàn ló sì fi èyí tó pọ̀ jù lára ọdún díẹ̀ tó lò láyé tọ́jú.
A ò lè sọ̀rọ̀ nípa ìtàn iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ká máà dárúkọ Florence Nightingale. Obìnrin onígboyà, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yìí àti àwùjọ àwọn nọ́ọ̀sì tí iye wọ́n jẹ́ méjìdínlógójì ṣàtúnṣe ilé ìwòsàn ológun tó wà ní Scutari, tí kò jìnnà sí ìlú Constantinople, nígbà Ogun Crimea tó jà láti ọdún 1853 sí 1856. Nígbà tó dé ibẹ̀, bí àwọn èèyàn ṣe ń kú pọ̀ gan-an, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún. Ṣùgbọ́n nígbà tó fi máa fi ibẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún 1856, àwọn tí ń kú kò tó ìpín méjì nínú ọgọ́rùn-ún mọ́.—Wo àpótí tó wà lójú ìwé 6.
Ohun mìíràn tó tún ní ipa ńlá lórí iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ni Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Obìnrin Tí Ń Ran Àlùfáà Ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì Lọ́wọ́, èyí tó wà ní Kaiserswerth, ní Jámánì, níbi tí Nightingale ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kó tó lọ sí Crimea. Bí àkókò ti ń lọ, àwùjọ àwọn nọ́ọ̀sì mìíràn tó ta yọ bẹ̀rẹ̀ sí yọjú. Fún àpẹẹrẹ, lọ́dún 1903, Agnes Karll sé ìdásílẹ̀ Àjọ Àwọn Ògbóǹkangí Nọ́ọ̀sì ní Ilẹ̀ Jámánì.
Lónìí, agbo àwọn nọ́ọ̀sì la kà sí ẹgbẹ́ àwọn ògbóǹkangí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó tóbi jù lọ nínú àwọn elétò ìlera. Àjọ Ìlera Àgbáyé ròyìn pé ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án nọ́ọ̀sì àti agbẹ̀bí tó ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè mọ́kànlélógóje. Iṣẹ́ ńlá gbáà sì ni wọ́n ń ṣe! Ìwé ìròyìn The Atlantic Monthly sọ pé àwọn nọ́ọ̀sì “pa ìtọ́jú, ìmọ̀, àti ìgbọ́kànlé pọ̀, gbogbo èyí sì ṣe pàtàkì bí aláìsàn kan yóò bá là á já.” Nípa bẹ́ẹ̀, ó tọ̀nà tí a bá béèrè nípa àwọn nọ́ọ̀sì pé, Kí la lè ṣe láìsí àwọn nọ́ọ̀sì?
Ipa Táwọn Nọ́ọ̀sì Ń Kó Nínú Ìkọ́fẹpadà
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan túmọ̀ iṣẹ́ nọ́ọ̀sì sí “ìgbésẹ̀ kan nínú èyí tí nọ́ọ̀sì kan ti ń ran aláìsàn lọ́wọ́ láti kọ́fẹ padà nínú àìsàn kan tàbí ìpalára, tàbí láti lómìnira bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.”
Lóòótọ́, ìgbésẹ̀ yẹn ní ohun púpọ̀ nínú. Ó ju ká wulẹ̀ máa ṣe àwọn àyẹ̀wò látìgbàdégbà lọ, irú bíi yíyẹ ìwọ̀n ìlùkìkì ọkàn-àyà àti ìfúnpá wò. Nọ́ọ̀sì ń kó ipa pàtàkì nínú ìkọ́fẹpadà aláìsàn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The American Medical Association Encyclopedia of Medicine ti sọ, “nọ́ọ̀sì túbọ̀ máa ń ṣàníyàn nípa ìṣesí aláìsàn kan nípa àìsàn rẹ̀ ju bó ṣe ń ṣe nípa àìsàn náà gan-an lọ, ó sì ń ṣiṣẹ́ kára láti wá nǹkan ṣe tí yóò fi dín ìrora àti ìdààmú ọpọlọ kù, nígbà tí ó bá sì ṣeé ṣe, kí ó dènà àwọn ìṣòro tó lè di ńlá.” Ní àfikún sí i, nọ́ọ̀sì máa ń pèsè “ìtọ́jú àfòyeṣe, tó kan fífi sùúrù tẹ́tí sí àwọn àníyàn àti ìbẹ̀rù aláìsàn, àti pípèsè ìṣírí àti ìtùnú.” Ìwé náà tún sọ pé, nígbà tí aláìsàn kan bá ń kú lọ, ojúṣe nọ́ọ̀sì ni “láti ran aláìsàn náà lọ́wọ́ láti kojú ikú náà pẹ̀lú ìrora ọkàn díẹ̀ àti iyì púpọ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.”
Ọ̀pọ̀ àwọn nọ́ọ̀sì máa ń ṣiṣẹ́ kọjá àkókò tó yẹ kí wọ́n fi ṣiṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, Ellen D. Baer kọ̀wé nípa ìrírí rẹ̀ ní Ilé Ìwòsàn Montefiore ní Ìlú New York. Obìnrin náà kò fẹ́ sáré ṣe iṣẹ́ òwúrọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe pẹ̀lú àwùjọ àwọn dókítà oníṣẹ́ abẹ. Ó kọ̀wé pé: “Mo fẹ́ dúró ti àwọn aláìsàn. Mo fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń mí, mo fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa rírìn káàkiri, kí n pààrọ̀ aṣọ ọgbẹ́ wọn dáadáa, kí n dáhùn àwọn ìbéèrè wọn, kí n ṣàlàyé àwọn nǹkan fún wọn, kí n sì tù wọ́n nínú díẹ̀. Mo fẹ́ràn láti máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn aláìsàn kí n sì jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́.”
Láìsí àní-àní, ẹnikẹ́ni tó bá ti jẹ́ aláìsàn rí ní ilé ìwòsàn lè rántí nọ́ọ̀sì kan tó jẹ́ olùgbatẹnirò, tó ní irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ kan náà yẹn. Ṣùgbọ́n kí ni èèyàn ní láti ṣe kó lè di nọ́ọ̀sì tó dáńgájíá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Florence Nightingale
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure National Library of Medicine