ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 11/8 ojú ìwé 5-11
  • Ipa Pàtàkì Tí Àwọn Nọ́ọ̀sì Ń Kó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ipa Pàtàkì Tí Àwọn Nọ́ọ̀sì Ń Kó
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ́ Olùtọ́jú Tí Nọ́ọ̀sì Ń Ṣe
  • Kí Ló Mú Kí Wọ́n Di Nọ́ọ̀sì?
  • Ayọ̀ Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Nọ́ọ̀sì
  • Kíkojú Àwọn Ìpèníjà Ibẹ̀
  • Ohun Tó Wà Nípamọ́ fún Àwọn Nọ́ọ̀sì
  • Àwọn Nọ́ọ̀sì—Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Jẹ́ Kòṣeémánìí?
    Jí!—2000
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2000
  • ‘Obìnrin Náà Kọ́ Wa Láti Ṣe Ohun Tó Bá Ìgbàgbọ́ Rẹ̀ Mu’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Wọn Ò Sí Láàárín Wa Àmọ́ A Kò Gbàgbé Wọn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 11/8 ojú ìwé 5-11

Ipa Pàtàkì Tí Àwọn Nọ́ọ̀sì Ń Kó

“Nọ́ọ̀sì ni ẹnì kan tó ń lọ́wọ́ nínú ìdàgbàsókè ẹni, tó ń fúnni níṣìírí, tó sì ń dáàbò boni—ẹnì kan tó ṣe tán láti tọ́jú aláìsàn, ẹni tó fara pá, àti arúgbó.”—Nursing in Today’s World—Challenges, Issues, and Trends.

ÀÌMỌTARA-ẸNI-NÌKAN kò tó láti mú kí ẹnì kan jẹ́ nọ́ọ̀sì tó dáńgájíá bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì. Àwọn nọ́ọ̀sì tó dára pẹ̀lú nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó kún rẹ́rẹ́ àti ìrírí tó pọ̀. Ohun pàtàkì kan tó ń béèrè láti ṣe iṣẹ́ náà ni kíkàwé nípa iṣẹ́ náà àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà láàárín ọdún kan sí mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n àwọn ànímọ́ wo ló ń sọ ẹnì kan di nọ́ọ̀sì tó dára? Díẹ̀ lára ohun tí àwọn nọ́ọ̀sì tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà sọ nígbà tí Jí! béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn la kọ sísàlẹ̀ yìí.

“Dókítà máa ń wo aláìsàn sàn, ṣùgbọ́n nọ́ọ̀sì ló ń tọ́jú aláìsàn. Èyí sábà ń béèrè fún gbígbé aláìsàn tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí àìsàn sì ti sọ ara rẹ̀ di hẹ́gẹhẹ̀gẹ ró, fún àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n bá ti sọ fún wọn pé wọ́n ní àrùn bára kú kan lára tàbí pé ikú ló máa gbẹ̀yìn àìsàn tó ń ṣe wọ́n. O ní láti fi ara rẹ ṣe ìyá fún ẹni tó ń ṣàìsàn náà.”—Carmen Gilmartín, Sípéènì.

“Ó pọndandan láti lè mọ bí ara ṣe ń ni aláìsàn náà àti bí nǹkan ṣe ṣòro fún un tó kí a sì fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́. Inú rere àti ìpamọ́ra la nílò. Ìgbà gbogbo ni o gbọ́dọ̀ fẹ́ láti mọ ohun púpọ̀ sí i nípa iṣẹ́ nọ́ọ̀sì àti ìṣègùn.”—Tadashi Hatano, Japan.

“Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó ti di dandan pé kí àwọn nọ́ọ̀sì mọ iṣẹ́ wọn lámọ̀dunjú gan-an. Nítorí náà, ìfẹ́ àtọkànwá láti kẹ́kọ̀ọ́ àti agbára láti lóye ohun tí a kọ́ ṣe pàtàkì. Bákan náà, àwọn nọ́ọ̀sì ní láti lè tètè ṣèpinnu nípa nǹkan, kí wọ́n sì gbégbèésẹ̀ ní kíá mọ́sá nígbà tí ipò nǹkan bá béèrè fún un.”—Keiko Kawane, Japan.

“Gẹ́gẹ́ bíi nọ́ọ̀sì, o ní láti fi ìfẹ́ hàn. O gbọ́dọ̀ ní àmúmọ́ra kí o sì fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò hàn.”—Araceli García Padilla, Mẹ́síkò.

“Nọ́ọ̀sì tó dára gbọ́dọ̀ ní aápọn, kó jẹ́ alákìíyèsí, kó sì mọ iṣẹ́ rẹ̀ lámọ̀dunjú. Bí nọ́ọ̀sì kan kò bá ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ—bó bá ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tàbí tí kì í gbọ́ ìmọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn tí ipò wọn ga ju tirẹ̀ lọ nínú iṣẹ́ ìṣègùn—nọ́ọ̀sì yẹn kò ní lè tọ́jú àwọn aláìsàn, bákan náà ni kò ní jẹ́ ẹni yíyẹ lójú àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.”—Rosângela Santos, Brazil.

“Àwọn ànímọ́ bíi mélòó kan kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn: àìkì í rin kinkin, níní àmúmọ́ra, àti sùúrù. Bákan náà ni o ní láti máa fi ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ṣọgbọ́n, kí o ní agbára láti lè máa ní àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ àti àwọn ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ìṣègùn. O ní láti tètè máa lóye àwọn ìlànà tuntun nínú iṣẹ́ yìí kí o lè máa jẹ́ ọ̀jáfáfá nígbà gbogbo.”—Marc Koehler, ilẹ̀ Faransé.

“O gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn kí o sì fẹ́ràn láti máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ó yẹ kí o lè fara da àìfararọ nítorí pé ní agbo àwọn nọ́ọ̀sì, tí o kò bá ṣe iṣẹ́ rẹ dáadáa, nǹkan burúkú lè ṣẹlẹ̀. O gbọ́dọ̀ lè mú ara rẹ bá onírúurú ipò mu kí o lè ṣe irú iṣẹ́ kan náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí iye àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ kò bá pé—láìṣe àjàǹbàkù iṣẹ́.”—Claudia Rijker-Baker, Netherlands.

Iṣẹ́ Olùtọ́jú Tí Nọ́ọ̀sì Ń Ṣe

Ìwé Nursing in Today’s World sọ pé, “iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ní í ṣe pẹ̀lú títọ́jú ẹni tó ń ṣàìsàn lóríṣiríṣi ọ̀nà tó bá jẹ mọ́ ọ̀ràn ìlera. Nípa bẹ́ẹ̀, a ń wo iṣẹ́ ìṣègùn bí èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú mímú aláìsàn lára dá, a sì ń wo iṣẹ́ nọ́ọ̀sì bí èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú títọ́jú aláìsàn náà.”

Nítorí náà, olùtọ́jú ni nọ́ọ̀sì kan jẹ́. Nítorí náà, ó hàn gbangba pé nọ́ọ̀sì ní láti ṣètọ́jú. Nígbà kan, wọ́n bi ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba nọ́ọ̀sì tí ìjọba fún níwèé ẹ̀rí léèrè pé, “Kí ló ṣe pàtàkì jù lọ fún ọ nínú iṣẹ́ nọ́ọ̀sì tí o ń ṣe?” Ìpín méjìdínlọ́gọ́rùn-ún nínú wọn ló fèsì pé títọ́jú aláìsàn dáadáa ni.

Nígbà mìíràn, àwọn nọ́ọ̀sì máa ń fojú kéré bí wọ́n ṣe jẹ àwọn aláìsàn lógún tó. Carmen Gilmartín, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú, tó ti ń ṣe iṣẹ́ nọ́ọ̀sì láti ọdún méjìlá sẹ́yìn, sọ fún Jí! pé: “Nígbà kan, mo jẹ́wọ́ fún ọ̀rẹ́ mi kan pé mo máa ń ronú pé n kò lè ṣe púpọ̀ tó nígbà tí mo bá ń tọ́jú àwọn tí àìsàn wọn le gan-an. Mo rí ara mi bí ẹni tí ń ṣe ìrànwọ́ tí kò tó nǹkan. Ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ mi fèsì pé: ‘Ẹni tó ń ṣèrànwọ́ tí kò tó nǹkan nígbà tí ẹnì kan bá ń ṣàìsàn ṣùgbọ́n tí a mọyì rẹ̀ ni ọ́, ohun tí a nílò ju ohunkóhun mìíràn lọ ni ọ́—nọ́ọ̀sì tó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn.’”

A kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní láti máa sọ ọ́, ṣíṣe irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ lè fa àìfararọ fún nọ́ọ̀sì kan tó ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lójúmọ́! Kí ló mú kí àwọn olùtọ́jú tó lẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ wọ̀nyí di nọ́ọ̀sì?

Kí Ló Mú Kí Wọ́n Di Nọ́ọ̀sì?

Jí! fọ̀rọ̀ wá àwọn nọ́ọ̀sì lẹ́nu wò jákèjádò ayé, ó sì bi olúkúlùkù wọn léèrè pé, “Kí ló mú kí o di nọ́ọ̀sì?” Díẹ̀ lára ìdáhùn wọn nìyí.

Terry Weatherson ti ń ṣiṣẹ́ nọ́ọ̀sì fún ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta. Ní bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi nọ́ọ̀sì ní ẹ̀ka ìtọ́jú pàtó kan ní Ẹ̀ka Ìtọ́jú Àìsàn Inú Àwọn Ẹ̀yà Ara Àfitọ̀ ní ilé ìwòsàn kan ní Manchester, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ó sọ pé: “Inú ìdílé Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn Kátólíìkì dá sílẹ̀ ni mo si ti kàwé. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́bìnrin kan, mo pinnu pé iṣẹ́ obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tàbí iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ni mo máa ṣe. Mo ní ìfẹ́ àtọkànwá láti sin àwọn ẹlòmíràn. Ẹ lè pè é ní iṣẹ́ ìgbésí ayé o. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti lè rí i, iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ni mo wá yàn.”

Chiwa Matsunaga láti Saitama, Japan, ti dá ilé ìtọ́jú aláboyún ti ara rẹ̀ sílẹ̀ láti ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn. Ó wí pé: “Mo tẹ̀ lé irú ìrònú tí bàbá mi ní pé ‘ohun tó dára jù ni kí èèyàn kọ́ iṣẹ́ kan tí yóò lè máa ṣe ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ.’ Nítorí náà, mo yan iṣẹ́ nọ́ọ̀sì.”

Etsuko Kotani láti Tokyo, Japan, tí í ṣe ọ̀gá nọ́ọ̀sì kan tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ náà fún ọdún méjìdínlógójì, sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì ń lọ sí ilé ìwé, bàbá mi ṣubú, ẹ̀jẹ̀ tó dà nù lára rẹ̀ sì pọ̀ gan-an. Nígbà tí mo lọ dúró ti bàbá mi ní ilé ìwòsàn, mo pinnu pé iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ni mo máa ṣe kí ń lè ran àwọn aláìsàn lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú.”

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn mìíràn nígbà tí wọ́n ṣàìsàn ló mú kí wọ́n di nọ́ọ̀sì. Eneida Vieyra, tí í ṣe nọ́ọ̀sì kan ní Mẹ́síkò, sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà, wọ́n dá mi dúró sílé ìwòsàn fún ọ̀sẹ̀ méjì nítorí àrùn gbọ̀fungbọ̀fun, ìgbà yẹn gan-an ni mo sì pinnu pé iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ni mo máa ṣe.”

Ó ṣe kedere pé èèyàn ní láti ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ gidigidi láti lè di nọ́ọ̀sì. Ẹ jẹ́ ká wá wo àwọn ìpèníjà àti èrè tó wà nídìí iṣẹ́ tó gbayì yìí.

Ayọ̀ Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Nọ́ọ̀sì

Ayọ̀ wo ló wà nínú iṣẹ́ nọ́ọ̀sì? Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn yóò sinmi lórí ẹ̀ka iṣẹ́ nọ́ọ̀sì tí èèyàn wà. Fún àpẹẹrẹ, àwọn olùtọ́jú aboyún máa ń láyọ̀ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbẹ̀bí, tí ọmọ ké, tí ìyá sì fọhùn. Ẹnì kan tó jẹ́ agbẹ̀bí ní Netherlands sọ pé: “Ohun ìdùnnú ńlá ni tí a bá gbẹ̀bí ọmọ kan tí ara rẹ̀ le, tó sì jẹ́ pé ìwọ lo bójú tó bó ṣe ń dàgbà ní inú.” Jolanda Gielen-Van Hooft, tí òun pẹ̀lú wá láti Netherlands, sọ pé: “Ìgbẹ̀bí ni ọ̀kan lára ìrírí tó dára jù lọ tí tọkọtaya kan—àti olùtọ́jú aláìsàn kan—lè ní. Iṣẹ́ ìyanu ni!”

Rachid Assam láti Dreux, ní ilẹ̀ Faransé, jẹ́ nọ́ọ̀sì ní ẹ̀ka ìpàmọ̀lára, tí Ìjọba fún níwèé ẹ̀rí, ó sì ti lé díẹ̀ ní ẹni ogójì ọdún. Kí ló mú kó máa gbádùn iṣẹ́ nọ́ọ̀sì? Ó sọ pé ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni “ìtẹ́lọ́rùn tó wà nínú lílọ́wọ́ nínú àṣeyọrí iṣẹ́ abẹ kan àti jíjẹ́ ọ̀kan lára agbo àwọn oníṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe kan tó ń fani lọ́kàn mọ́ra tó sì ń tẹ̀ síwájú déédéé.” Isaac Bangili, tí òun pẹ̀lú wá láti ilẹ̀ Faransé, sọ pé: “Bí àwọn aláìsàn àti àwọn ìdílé wọ́n ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa ń ṣí mi lórí, pàápàá jù lọ nínú àwọn ọ̀ràn pàjáwìrì nígbà tí a bá jàjà mú aláìsàn kan tí a ti ronú pé kò ní yè é lára dá.”

Wọ́n dúpẹ́ lọ́nà kan náà lọ́wọ́ Terry Weatherson, tí a mẹ́nu kàn níṣàájú. Opó kan kọ̀wé pé: “Mi ò jẹ́ gbàgbé láti tún tọ́ka sí bí ọkàn wa ṣe balẹ̀ tó látàrí ìfọ̀kànbalẹ̀ rẹ tó ki wá láyà ní gbogbo àkókò tí Charles fi ṣàìsàn. Ìfẹ́ tí o fi hàn lé ìbànújẹ́ jìnnà sí wa, ó sì wá di ohun ìtìlẹ́yìn tí ń fún wa lókun.”

Kíkojú Àwọn Ìpèníjà Ibẹ̀

Ṣùgbọ́n bí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nọ́ọ̀sì ṣe ń láyọ̀ náà ni wọ́n ń kojú ìpèníjà. Kò sí àyè fún àṣìṣe nínú iṣẹ́ nọ́ọ̀sì o! Yálà nọ́ọ̀sì kan ń fún èèyàn ní oògùn tàbí pé ó ń fa ẹ̀jẹ̀ tàbí pé ó ń ki ohun èlò kan bọnú iṣan ara tàbí pé ó wulẹ̀ ń gbé aláìsàn kan láti ibì kan sí ibòmíràn, ó gbọ́dọ̀ fẹ̀sọ̀ ṣe é ni. Kò gbọ́dọ̀ ṣe àṣìṣe—èyí sì rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti sábà máa ń peni lẹ́jọ́. Síbẹ̀, láwọn ìgbà mìíràn nọ́ọ̀sì máa ń ko ìṣòro. Fún àpẹẹrẹ, ká ní nọ́ọ̀sì ronú pé oògùn tó yẹ kí dókítà kan kọ fún aláìsàn kọ́ ló kọ tàbí pé dókítà ní kí ó ṣe ohun tí kò ní ṣe aláìsàn náà lóore. Kí ló yẹ kí nọ́ọ̀sì yẹn ṣe? Ṣé kó lọ ko dókítà náà lójú ni? Ìyẹn ń béèrè ìgboyà, ìgbọ́nféfé, àti ọgbọ́n mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀—ṣùgbọ́n ó léwu o. Ó ṣeni láàánú pé àwọn dókítà kan kì í gbà lẹ́rọ̀ bí àwọn tí wọ́n ń wò bí ọmọ iṣẹ́ wọn bá gbà wọ́n nímọ̀ràn.

Àkíyèsí wo ni àwọn nọ́ọ̀sì kan ti ṣe nínú irú ọ̀ràn yìí? Barbara Reineke láti Wisconsin, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tí ìjọba ti fún níwèé ẹ̀rí iṣẹ́ nọ́ọ̀sì láti ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n sẹ́yìn, sọ fún Jí! pé: “Nọ́ọ̀sì gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, lábẹ́ òfin, òun ni yóò dáhùn fún oògùn èyíkéyìí tó bá lò tàbí ìtọ́jú èyíkéyìí tó bá ṣe fún aláìsàn àti fún ìpalára èyíkéyìí tí wọ́n bá fà. Ó gbọ́dọ̀ lè kọ̀ bí dókítà bá ní kó ṣe ohun kan ṣùgbọ́n tí òun rò pé yóò jẹ́ ìkọjá-àyè fún òun gẹ́gẹ́ bíi nọ́ọ̀sì tàbí tó bá mọ̀ pé ohun tí dókítà ní kí òun ṣe náà kò tọ̀nà. Kì í ṣe bí iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ṣe rí nígbà ayé Florence Nightingale tàbí ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn ló rí lónìí. Nísinsìnyí, nọ́ọ̀sì kan ní láti mọ ìgbà tó yẹ kí òun má gbà pẹ̀lú oníṣègùn àti ìgbà tó yẹ kí òun rin kinkin pé kí dókítà lọ yẹ aláìsàn wò, kódà tó bá jẹ́ láàárín òru pàápàá. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé o kò tọ̀nà, má ṣe jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ èyíkéyìí tí dókítà bá fi ọ ṣe dùn ọ́.”

Ìṣòro mìíràn tí àwọn nọ́ọ̀sì ní láti kojú ni ìwà ṣíṣèpalára fúnni lẹ́nu iṣẹ́. Ìròyìn kan láti Gúúsù Áfíríkà sọ pé àwọn nọ́ọ̀sì “wà nínú ewu púpọ̀ gan-an, ewu kí wọ́n hùwà àìdáa sí wọn àti kí wọ́n ṣèpalára fún wọn níbi iṣẹ́. Ní tòótọ́, àwọn èèyàn lè gbógun ti àwọn nọ́ọ̀sì níbi iṣẹ́ ju àwọn wọ́dà tàbí àwọn ọlọ́pàá lọ, àti pé ìpín méjìléláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn nọ́ọ̀sì ni ọkàn wọn kò balẹ̀ látàrí pé wọ́n lè fipá kọ lu àwọn.” Wọ́n ní ó ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, níbi tí ìpín mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn nọ́ọ̀sì tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nínú ìwádìí kan láìpẹ́ yìí ti sọ pé àwọn ti rí i tí wọ́n fipá kọ lu nọ́ọ̀sì kan ní ọdún kan sẹ́yìn. Kí ló ń fa ìwà ipá yìí? Lọ́pọ̀ ìgbà, ìṣòro náà ń wá láti ọ̀dọ̀ àwọn aláìsàn tó joògùn yó tàbí tí wọ́n ti mutí yó tàbí tí wọ́n wà nínú ipò másùnmáwo tàbí tí wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn.

Àwọn nọ́ọ̀sì tún ní láti bá ìṣòro kí nǹkan máa súni jà, èyí tí másùnmáwo ń fà. Ọ̀kan lára okùnfà rẹ̀ ni àìtó àwọn òṣìṣẹ́. Nígbà tí nọ́ọ̀sì tó ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ kò bá lè tọ́jú aláìsàn kan dáadáa nítorí pé iṣẹ́ tí òun nìkan ń ṣe ti pọ̀ jù, másùnmáwo kò ní pẹ́ wọnú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó jọ pé gbígbìyànjú láti kojú ìṣòro náà nípa àìsinmi lákòókò tó yẹ ká sinmi àti àìṣíwọ́ lákòókò tó yẹ ká ṣíwọ́ wulẹ̀ ń mú kí nǹkan túbọ̀ súni ni.

Jákèjádò ayé, ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn ni kò ní òṣìṣẹ́ tó pọ̀ tó. Ìwé ìròyìn kan ní Madrid, tó ń jẹ́ Mundo Sanitario sọ pé: “A kò ní àwọn nọ́ọ̀sì ní àwọn ilé ìwòsàn wa. Ẹni tó bá ti ṣàìsàn rí tó sì nílò ìtọ́jú yóò mọ ìjẹ́pàtàkì àwọn nọ́ọ̀sì.” Kí ni wọ́n sọ pé ó fa àìtó àwọn nọ́ọ̀sì? Wọn kò fẹ́ náwó ni! Ìròyìn kan náà yẹn sọ pé iye nọ́ọ̀sì tí àwọn ilé ìwòsàn ní Madrid ní fi ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá dín sí iye tó yẹ kí wọ́n ní!

Ìdí mìíràn tí a gbọ́ pé ó máa ń fa másùnmáwo ni pé àkókò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n gba iṣẹ́ lọ́wọ́ ẹlòmíràn sábà máa ń gùn gan-an ṣùgbọ́n owó oṣù wọn kò tó nǹkan. Ìwé The Scotsman sọ pé: “Ó lé ní ọ̀kan lára àwọn nọ́ọ̀sì márùn-ún ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ìdá mẹ́rin lára àwọn olùrànlọ́wọ́ nọ́ọ̀sì tó ní iṣẹ́ mìíràn tí wọ́n ń ṣe kí wọ́n lè máa gbọ́ bùkátà ara wọn, gẹ́gẹ́ bí àjọ òṣìṣẹ́ ìjọba tó ń jẹ́ Unison ti sọ.” Mẹ́ta lára nọ́ọ̀sì mẹ́rin ló ń rò pé owó tí wọ́n ń fún àwọn kò tó. Àbájáde rẹ̀ ni pé púpọ̀ wọn ló ti ronú nípa fífi iṣẹ́ náà sílẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ìdí mìíràn ló wà tó ń dá kún másùnmáwo tó ń bá àwọn nọ́ọ̀sì. Tí a bá fi ojú ọ̀rọ̀ tí Jí! gbà sílẹ̀ lẹ́nu àwọn nọ́ọ̀sì jákèjádò ayé wò ó, ikú àwọn aláìsàn lè kó ìdààmú ọkàn bá wọn. Magda Souang, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì, ń ṣiṣẹ́ ní Brooklyn, New York. Nígbà tí a bi í léèrè ohun tó mú kí iṣẹ́ rẹ̀ le gan-an, ó dáhùn pé: “Rírí i tí nǹkan bí ọgbọ̀n àwọn tí mo ń tọ́jú, tí àìsàn wọ́n la ikú lọ, ń kú léraléra láàárín ọdún mẹ́wàá. Èèyàn á kàn joro ṣáá ni.” Abájọ tí ìwé kan fi sọ pé: “Fífi gbogbo agbára ẹni tọ́jú àwọn aláìsàn tó sì jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kú níkẹyìn lè kó ìbànújẹ́ báni.”

Ohun Tó Wà Nípamọ́ fún Àwọn Nọ́ọ̀sì

Àṣeyọrí àti ipa tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ń ní ń mú kí pákáǹleke tó wà nínú iṣẹ́ nọ́ọ̀sì pọ̀ sí i. Ìpèníjà náà jẹ́ láti mú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ìgbatẹnirò, ìyẹn bí a ṣe ń ṣe dáadáa sí aláìsàn, bára dọ́gba. Kò sí ẹ̀rọ tó lè rọ́pò bí nọ́ọ̀sì ṣe ń káàánú aláìsàn tó sì ń yọ́nú sí i.

Ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà kan sọ pé: “Iṣẹ́ tí kò nípẹ̀kun ni iṣẹ́ nọ́ọ̀sì jẹ́. . . . Níwọ̀n bí èèyàn bá ṣì wà láàyè, ìdí yóò ṣì máa wà fún ìtọ́jú, ìyọ́nú, àti òye.” Iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ló ń pèsè àwọn nǹkan yẹn. Ṣùgbọ́n ìdí tó túbọ̀ lágbára wà láti fojú sọ́nà fún rere nínú ọ̀ràn bíbójú tó ìlera. Bíbélì fi hàn pé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní sí ẹni tí yóò sọ pé, “àìsàn ń ṣe mí.” (Aísáyà 33:24) A kò ní nílò àwọn dókítà, nọ́ọ̀sì, àti àwọn ilé ìwòsàn nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.—Aísáyà 65:17; 2 Pétérù 3:13.

Bíbélì tún ṣèlérí pé “Ọlọ́run . . . yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Ṣùgbọ́n kó tó di ìgbà yẹn, ó yẹ ká fi ìmọrírì hàn fún gbogbo àfiyèsí àti ìfara-ẹni-rúbọ tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì tó wà jákèjádò ayé ń fún wa, tó jẹ́ pé láìsí àwọn nọ́ọ̀sì, èèyàn á kàn wà nílé ìwòsàn ṣáá ni tàbí kí èèyàn má tilẹ̀ lè dúró síbẹ̀ rárá! Ìbéèrè náà mà dẹ̀ bá a mu wẹ́kú o, pé, “Àwọn nọ́ọ̀sì—kí la lè ṣe láìsí wọn?”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Florence Nightingale—Ẹni Tó Pilẹ̀ Iṣẹ́ Nọ́ọ̀sì Ìgbàlódé

Ọdún 1820 ni wọ́n bí Florence Nightingale ní Ítálì, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó lọ́rọ̀ ni àwọn òbí rẹ̀, wọ́n sì kẹ́ ẹ gan-an. Ọ̀dọ́mọdé Florence kọ̀ láti lọ́kọ, ó sì kàwé nípa ìlera àti ìtọ́jú àwọn aláìní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí Florence lòdì sí i, ó gba iṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn nọ́ọ̀sì níṣẹ́ ní Kaiserswerth, Jámánì. Nígbà tó yá, Florence lọ kàwé ní Paris, nígbà tó sì pé ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ó di ọ̀gá nọ́ọ̀sì ní ilé ìwòsàn àwọn obìnrin kan ní ìlú London.

Ṣùgbọ́n ó bá ìpèníjà tó le jù lọ pàdé nígbà tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti lọ tọ́jú àwọn sójà tó fara pa ní Crimea. Níbẹ̀, òun àti àwùjọ àwọn nọ́ọ̀sì tó kó lọ, tí iye wọ́n jẹ́ méjìdínlógójì, ní láti ṣàtúnṣe ilé ìwòsàn kan tí àwọn eku ti fi ṣe ilé. Iṣẹ́ tó bani lẹ́rù gan-an ni, nítorí lákọ̀ọ́kọ́ kò sí ọṣẹ, kò sí páànù tí wọ́n fi ń fọ nǹkan àti aṣọ ìnuwọ́, bákan náà ni kò sí bẹ́ẹ̀dì kíká, tìmùtìmù, àti báńdéèjì. Florence àti agbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ kojú ìpèníjà náà, nígbà tí ogun náà sì fi máa parí, ó ti mú kí àtúnṣe bá iṣẹ́ nọ́ọ̀sì àti àbójútó ilé ìwòsàn jákèjádò ayé. Ní ọdún 1860, ó dá Ilé Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Nọ́ọ̀sì ti Nightingale sílẹ̀ ní Ilé Ìwòsàn St. Thomas ní London—ó jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ nọ́ọ̀sì àkọ́kọ́ tí kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìsìn. Kó tó di pé ó kú ní ọdún 1910, ọ̀pọ̀ ọdún ni ó fi wà lórí àkéte àìsàn. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ń kọ àwọn ìwé àti ìwé ìléwọ́ kéékèèké gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àtimú kí iṣẹ́ ìtọ́jú aláìsàn lè sunwọ̀n sí i.

Àwọn kan ṣàtakò nípa ipò Florence Nightingale gẹ́gẹ́ bí afẹ́nifẹ́re, wọ́n sọ pé ó kéré tán, ó yẹ ká gbé oríyìn fún àwọn ẹlòmíràn nítorí ohun tí wọ́n gbé ṣe nínú iṣẹ́ nọ́ọ̀sì. Ní àfikún sí i, wọ́n jiyàn gan-an lórí orúkọ tó ní láwùjọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, A History of Nursing ti sọ, àwọn kan sọ pé ó jẹ́ “oníkanra, ajẹgàba, ajọra-ẹni-lójú, ayárabínú, àti atẹnilóríba,” ṣùgbọ́n ńṣe ni “ìgbọ́nṣámúṣámú àti ẹwà rẹ̀, okun yíyanilẹ́nu rẹ̀, àti onírúurú àkópọ̀ ìwà tó ní” fa àwọn mìíràn mọ́ra. Ohun yòówù kí ìwà rẹ̀ jẹ́ gan-an, ohun kan dájú, ìyẹn ni pé: Àwọn ìlànà iṣẹ́ nọ́ọ̀sì àti ọ̀nà àbójútó ilé ìwòsàn tí ó lò tàn kálẹ̀ dé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Wọ́n kà á sí aṣáájú nínú ìlànà iṣẹ́ nọ́ọ̀sì gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ lónìí.

[Àwòrán]

Ilé Ìwòsàn St. Thomas nìyí, lẹ́yìn tí wọ́n dá Ilé Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Nọ́ọ̀sì ti Nightingale sílẹ̀

[Credit Line]

Látọ̀dọ̀ National Library of Medicine

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Oríṣiríṣi Nọ́ọ̀sì Tó Wà

Nọ́ọ̀sì pọ́ńbélé: “Òun ni ẹnì kan tó di nọ́ọ̀sì nípasẹ̀ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó sì kúnjú àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n kan tí a là sílẹ̀ láti tóótun ní ti ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ nọ́ọ̀sì.”

Nọ́ọ̀sì tó gbàṣẹ: “Òun ni ẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nọ́ọ̀sì, tí a fún láṣẹ lábẹ́ òfin (ìyẹn ni pé ó gbàṣẹ) láti máa ṣiṣẹ́ nọ́ọ̀sì lẹ́yìn tó ti yege ìdánwò tí ìgbìmọ̀ tí ń ṣèdánwò fún àwọn nọ́ọ̀sì ṣe fún un . . . tó sì tóótun lábẹ́ òfin láti máa jẹ́ orúkọ náà, Nọ́ọ̀sì Tó Gbàṣẹ tàbí R.N. bí àwọn eléèbó ti ń pè é.”

Nọ́ọ̀sì àkànṣe: “Èyí ni nọ́ọ̀sì kan tó gbàṣẹ, ẹni tó ní ìmọ̀, àti òye, tó sì jáfáfá nínú àkànṣe ẹ̀ka iṣẹ́ nọ́ọ̀sì pàtó kan.”

Nọ́ọ̀sì agbẹ̀bí: “Òun ni ẹni tó gba ẹ̀kọ́ alápá méjì, ìyẹn ni, nínú iṣẹ́ nọ́ọ̀sì àti ti ìgbẹ̀bí.”

Nọ́ọ̀sì afòyemọṣẹ́: “Ẹni kan tó mọ bí wọ́n ṣe ń tọ́jú aláìsàn ṣùgbọ́n tí kò kẹ́kọ̀ọ́ gboyè jáde ní ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ nọ́ọ̀sì èyíkéyìí.”

Nọ́ọ̀sì tó gbàwé ẹ̀rí ìjọba: “Ẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè jáde ní ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ nọ́ọ̀sì kan . . . tí wọ́n ti fún láṣẹ lábẹ́ òfin láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi nọ́ọ̀sì kan tó gbàwé ẹ̀rí ìjọba.”

[Àwọn Credit Line]

Láti inú ìwé Dorland’s Illustrated Medical Dictionary tí wọ́n ṣe ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.

UN/J. Isaac

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

‘Igi Lẹ́yìn Ọgbà Iṣẹ́ Àbójútó Ìlera’

Níbi Àpérò Àyájọ́ Ọgọ́rùn-ún Ọdún Àjọ Àgbáyé ti Àwọn Nọ́ọ̀sì ní June ọdún 1999, Dókítà Gro Harlem Brundtland, ọ̀gá àgbà Àjọ Ìlera Àgbáyé, sọ pé:

“Gẹ́gẹ́ bí amọṣẹ́dunjú tó ṣe pàtàkì nínú ètò ìlera, àwọn nọ́ọ̀sì wà ní ipò aláìlẹ́gbẹ́ láti gbégbèésẹ̀ bí alágbàwí tí ó ní àṣẹ kí ìlera lè gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé yìí. . . . Níwọ̀n bí àwọn nọ́ọ̀sì àti àwọn agbẹ̀bí ti jẹ́ nǹkan bí ìpín ọgọ́rin nínú gbogbo àwọn tí ó tóótun, tó wà lára àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀ka ètò ìlera ní àwọn orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n dúró fún agbo tí agbára rẹ̀ yóò jọjú láti mú kí àwọn ìyípadà tí a nílò nínú Ètò Ìlera fún Gbogbo Ènìyàn ní Ọ̀rúndún Kọkànlélógún ṣeé ṣe. Láìṣe àní-àní, ipa tí wọ́n ń kó nínú ẹ̀ka ètò ìlera kó gbogbo apá tí ìtọ́jú àìsàn ní pọ̀. . . . Ó ṣe kedere pé àwọn nọ́ọ̀sì ni igi lẹ́yìn ọgbà ọ̀pọ̀ jù lọ agbo àwọn òṣìṣẹ́ ní ẹ̀ka ètò ìlera.”

Ààrẹ ilẹ̀ Mẹ́síkò tẹ́lẹ̀ rí, Ernesto Zedillo Ponce de León, gbóríyìn fún àwọn nọ́ọ̀sì ilẹ̀ Mẹ́síkò lákànṣe nínú ọ̀rọ̀ kan tí ó sọ pé: “Lójoojúmọ́, gbogbo yín . . . ń ya ìmọ̀ yín tó dára jù lọ, ìfìmọ̀ṣọ̀kan yín àti iṣẹ́ yín sọ́tọ̀ fún dídáàbòbo ìlera àwọn ará Mẹ́síkò àti mímú wọn lára dá. Lójoojúmọ́, ẹ ń fi iṣẹ́ amọṣẹ́dunjú yín ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tó nílò rẹ̀ bákan náà ni ẹ ń fi ìtùnú tó ń wá láti inú ìlànà ìfẹ́dàáfẹ́re jíjinlẹ̀ yín, ẹ̀mí jẹ̀lẹ́ńkẹ́, àti ẹ̀mí ìfọkànṣe yín ràn wọ́n lọ́wọ́. . . . Ẹ̀ka yín ló tóbi jù lọ lára àwọn ẹ̀ka ètò ìlera tí a ní . . . Nígbàkigbà tí a bá gba ẹ̀mí kan là, nígbàkigbà tí a bá fún ọmọdé kan lábẹ́rẹ́ àjẹsára, nígbàkigbà tí a bá gbẹ̀bí fún ẹnì kan, nígbàkigbà tí a bá sọ̀rọ̀ nípa ìlera, nígbàkigbà tí a bá mú ẹnì kan lára dá, nígbàkigbà tí aláìsàn kan bá rí ìtọ́jú àti ìṣírí tó lágbára gbà, iṣẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì wa kò gbẹ́yìn níbẹ̀.”

[Àwọn Credit Line]

Fọ́tò UN/DPI tí Greg Kinch yà

Fọ́tò UN/DPI tí Evan Schneider yà

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Dókítà Kan Tó Fi Ìmọrírì Hàn

Dókítà Sandeep Jauhar tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ìwòsàn New York Presbyterian gbà pé àwọn nọ́ọ̀sì tó dáńgájíá jẹ òun lógún. Nọ́ọ̀sì kan fọgbọ́n ṣàlàyé fún un pé yóò dára kí àwọ́n lo oògùn apàrora morphine díẹ̀ sí i fún aláìsàn kan tó ń kú lọ. Dókítà náà kọ̀wé pé: “Àwọn nọ́ọ̀sì tó dáńgájíá pẹ̀lú máa ń kọ́ àwọn dókítà ní nǹkan. Àwọn nọ́ọ̀sì tó ń ṣiṣẹ́ ní àwọn wọ́ọ̀dù ẹ̀ka ìtọ́jú àkànṣe bí ẹ̀ka ìtọ́jú àìsàn wà lára àwọn amọṣẹ́dunjú tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa jù lọ ní ilé ìwòsàn. Nígbà tí mo ń ṣe iṣẹ́ àfidánrawò, wọ́n kọ́ mi bí màá ṣe máa ti ọ̀pá oníhò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìṣègùn bọ inú ẹran ara, àti bí màá ṣe máa lo ẹ̀rọ àfimí. Wọ́n sọ fún mi nípa àwọn oògùn tó yẹ láti yàgò fún.”

Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Àwọn nọ́ọ̀sì ń ṣe ìtìlẹ́yìn tí àwọn aláìsàn nílò ní ti ìrònú òun ìhùwà àti ìmọ̀lára, nítorí pé àwọn ló ń lo àkókò tó pọ̀ jù pẹ̀lú wọn. . . . Bóyá ni ìgbà kan wà tí mo máa ń yára gbégbèésẹ̀ tó ìgbà tí nọ́ọ̀sì kan tí mo fọkàn tán bá sọ fún mi pé mo gbọ́dọ̀ yẹ aláìsàn kan wò ní kíá mọ́sá.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Mo ní ìfẹ́ àtọkànwá láti sin àwọn ẹlòmíràn.”—Terry Weatherson, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Nígbà tí mo lọ dúró ti bàbá mi ní ilé ìwòsàn, mo pinnu pé iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ni mo máa ṣe.”—Etsuko Kotani, Japan.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

‘Ìgbẹ̀bí ni ọ̀kan lára ìrírí tó dára jù lọ tí olùtọ́jú aláìsàn kan lè ní.’—Jolanda Gielen-Van Hooft, Netherlands.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn agbẹ̀bí máa ń ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tí wọ́n bá gbẹ̀bí ọmọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́