ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 6/15 ojú ìwé 28
  • ‘Obìnrin Náà Kọ́ Wa Láti Ṣe Ohun Tó Bá Ìgbàgbọ́ Rẹ̀ Mu’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Obìnrin Náà Kọ́ Wa Láti Ṣe Ohun Tó Bá Ìgbàgbọ́ Rẹ̀ Mu’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipa Pàtàkì Tí Àwọn Nọ́ọ̀sì Ń Kó
    Jí!—2000
  • Àwọn Nọ́ọ̀sì—Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Jẹ́ Kòṣeémánìí?
    Jí!—2000
  • “Èmi Ti Pa Ìgbàgbọ́ Mọ́”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìbéèrè Ṣókí Tó Lè Mú Káwọn Èèyàn Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 6/15 ojú ìwé 28

‘Obìnrin Náà Kọ́ Wa Láti Ṣe Ohun Tó Bá Ìgbàgbọ́ Rẹ̀ Mu’

WỌ́N sọ fún obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Rovigo, ní orílẹ̀-èdè Ítálì pé apá ibì kan ń wú nínú ara rẹ̀ àti pé ó lè gbẹ́mìí rẹ̀. Nígbà tí obìnrin náà dé sílé lẹ́yìn tó ti gba ìtọ́jú fún àkókò díẹ̀ ní ọsibítù tó ti sọ pé kí wọ́n má ṣe fa ẹ̀jẹ̀ sí òun lára, àwọn nọ́ọ̀sì tó máa ń tọ́jú àwọn tó ní àìsàn jẹjẹrẹ ní ẹ̀ka ìpínlẹ̀ ibẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí i tọ́jú rẹ̀ nílé.

Ìgbàgbọ́ lílágbára àti ẹ̀mí ìmúratán tí ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì tó ń gbàtọ́jú yìí ní wú àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú rẹ̀ lórí gan-an ni. Nígbà tó kù díẹ̀ kí àìsàn jẹjẹrẹ yìí gbẹ̀mí obìnrin náà, ọ̀kan lára àwọn nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú rẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ nípa ìtọ́jú obìnrin yìí tó pe orúkọ rẹ̀ ní Angela sínú ìwé ìròyìn àwọn nọ́ọ̀sì.

Ohun tí nọ́ọ̀sì náà kọ ni pé, “Angela jẹ́ ọlọ́yàyà èèyàn, kò sì fẹ́ kú. Ó mọ irú ipò tóun wà, ó sì mọ bí àìsàn òun ṣe le tó, torí náà ó ń wá bí ara òun ṣe máa yá, ó ń wá oògùn lójú méjèèjì, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ṣe máa ṣe tó bá jẹ́ pé àwa ni. . . . Àwa nọ́ọ̀sì bẹ̀rẹ̀ sí dojúlùmọ̀ rẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Angela ò mú nǹkan ni wá lára rárá. Dípò ìyẹn, ńṣe ni jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni tí kì í fi dúdú pe funfun mú gbogbo nǹkan rọrùn fún wa. Ńṣe ni inú wa máa ń dùn tá a bá fẹ́ lọ tọ́jú ẹ̀, nítorí a mọ̀ pé èèyàn dáadáa là ń lọ bá àti pé àwa àtòun ló jọ máa jàǹfààní. . . . Kò pẹ́ tó fi sọ sí wa lọ́kàn pé ẹ̀sìn tó ń ṣe yóò mú kó ṣòro fún wa láti máa tọ́jú rẹ̀.” Èrò tí ọkùnrin nọ́ọ̀sì yìí ní nìyẹn nítorí ó gbà pé ó yẹ kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí Angela lára, àmọ́ Angela lóun ò gbẹ̀jẹ̀ sára.—Ìṣe 15:28, 29.

“Àwa tá a jẹ́ amọṣẹ́dunjú nínú iṣẹ́ ìṣègùn sọ fún Angela pé a ò fara mọ́ ìpinnu tó ṣe yẹn, àmọ́ Angela ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bí ẹ̀mí èèyàn ṣe ṣe pàtàkì tó lójú òun. A tún mọ bí ẹ̀sìn rẹ̀ ṣe ṣe pàtàkì tó sí òun àti ìdílé rẹ̀. Angela ò jẹ́ kó sú òun. Ó gbà pé àìsàn náà máa fi òun sílẹ̀. Alákíkanjú obìnrin ni. Kò fẹ́ kú, ó fẹ́ sa gbogbo ipá rẹ̀ láti wà láàyè kó sì máa gbé ilé ayé lọ. Ó ti sọ ìpinnu rẹ̀ àti nǹkan tó gbà gbọ́. A ò ní irú ìpinnu tó ní, ìgbàgbọ́ wa ò sì lágbára bíi tirẹ̀. . . . Angela jẹ́ ká mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti tọ́jú òun lọ́nà tó bá ìgbàgbọ́ òun mu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà iṣẹ́ wa lè máà fẹ́ gbà bẹ́ẹ̀. . . . A gbà gbọ́ pé ohun tí Angela kọ́ wa yìí ṣe pàtàkì gan-an, torí pé oríṣiríṣi èèyàn, oríṣiríṣi ipò, àtàwọn tó wá látinú onírúurú ẹ̀sìn la máa ń bá pàdé, a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lọ́dọ̀ gbogbo ẹni tá a bá bá pàdé, àwọn náà sì lè rí ohun kan kọ́ lọ́dọ̀ wa.”

Àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn náà tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Code of Professional Ethics for Italian Nurses (Ìlànà Iṣẹ́ Àwọn Nọ́ọ̀sì ti Orílẹ̀-Èdè Ítálì) tí wọ́n fọwọ́ sí lọ́dún 1999, tó sọ pé: “Nígbà táwọn nọ́ọ̀sì bá ń tọ́jú èèyàn kan, wọ́n ní láti fi ẹ̀sìn onítọ̀hún, ohun tó fẹ́ àti àṣà ìbílẹ̀ rẹ̀ sọ́kàn, títí kan ẹ̀yà rẹ̀ àti bóyá ọkùnrin ni àbí obìnrin.” Nígbà mìíràn, ó máa ń ṣòro fáwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì láti gbà pé àwọn á tọ́jú ẹni tó wá gbàtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn lọ́nà tó bá ìgbàgbọ́ onítọ̀hún mu, nítorí èyí, ó yẹ ká mọrírì àwọn tí wọ́n ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìpinnu tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lórí ọ̀ràn ìlera wọn àti nípa ìtọ́jú ìṣègùn jẹ́ èyí tí wọ́n ti ronú lé lórí dáadáa kí wọ́n to ṣe é. Wọ́n gbé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yẹ̀ wò dáadáa, àti pé, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ Angela ṣe fi hàn, wọn kì í ṣe agbawèrèmẹ́sìn. (Fílípì 4:5) Kárí ayé ni iye àwọn oníṣègùn amọṣẹ́dunjú tí wọ́n ṣe tán láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá ń gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́