Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Èé Ṣe Tí Dádì Fi Já Wa Sílẹ̀?
“Mi ò mọ ìdí tí dádì mi ṣe fi ilé sílẹ̀. Ohun tí ìyá mi sọ fún mi nìkan ni mo mọ̀ nípa rẹ̀.”—James.a
NÍGBÀ tí bàbá kan bá digbá dagbọ̀n tó sì fi ilé sílẹ̀, làásìgbò àti ìbànújẹ́ ló kó àwọn tó fi sílẹ̀ sí. James tí í ṣe ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú sọ pé: “Inú bí mi gan-an nígbà tí mọ́mì àti dádì mi kọ ara wọn sílẹ̀.” Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ńṣe ni bàbá kan fi ilé sílẹ̀ láìṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀, tó sì kọ̀ tí kò kàn sí wọn, àwọn ọmọ rẹ̀ lè máa bá ìdára-ẹni-lẹ́bi, ìpanitì, àti ìkórìíra jà fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn táwọn òbí wọn kọra wọn sílẹ̀.b
Bó bá ṣẹlẹ̀ pé bàbá tìrẹ ti fi ilé sílẹ̀, inú lè máa bí ọ nítorí ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Michael sọ pé: “Bàbá fi wá sílẹ̀ lọ bá obìnrin mìíràn ni. Mo ti rí àwọn méjèèjì pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan rí, ó sì bí mi nínú gan-an. Mo ronú pé ńṣe ni Dádì dà wá.” Ṣùgbọ́n nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, fífi tó fi ilé sílẹ̀ lè fi yín lọ́kàn balẹ̀. Melissa, tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ọ̀mùtí, sọ pé: “Ká ní kò fi ilé sílẹ̀ ni, nǹkan ì bá túbọ̀ ṣòro fún wa.”
Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀, àwọn ọmọ kò mọ ìdí tí bàbá wọn fi fi ilé sílẹ̀, èyí sì lè mú kó jọ pé àìsí níbẹ̀ rẹ̀ túbọ̀ ń dùn wọ́n gan-an. Ó ṣeé ṣe kí o mọ̀ pé àwọn òbí rẹ ní ìṣòro, ṣùgbọ́n o lè má ronú kàn án rí pé wọ́n á kọ́ra wọn sílẹ̀. Robert rántí pé: “Nígbà tí Dádì fi ilé sílẹ̀, gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ kò yé mi rárá. Gbogbo ohun tí mo kàn mọ̀ ni pé nǹkan ò rọgbọ nítorí pé gbogbo ìgbà làwọn òbí mi máa ń jà.”
Kí ló fà á ná táwọn bàbá kan fi ń fi ilé sílẹ̀? Bí bàbá tìrẹ bá ti fi ilé sílẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kí o wò ó bíi pé ìwọ ló kọ̀ sílẹ̀? Àti pé kí ló lè mú kí àwọn òbí rẹ máa lọ́ra láti sọ púpọ̀ fún ọ nípa rẹ̀? Ṣé kò yẹ kí wọ́n ṣàlàyé fún ọ ni?
Ìdí Tí Wọ́n Fi Mẹ́numọ́
Àwọn ìdí tí bàbá kan ṣe fi ilé sílẹ̀ kò lè jẹ́ ohun tó dùn mọ́ni. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó sábà máa ń jẹ́ nítorí ìwà panṣágà—ìwà àìtọ́ tí wọ́n sábà máa ń bò fún ìdílé wọn. Nígbà tí àṣírí irú ìwà àìtọ́ bẹ́ẹ̀ bá tú sọ́wọ́ ìyàwó, ó lè pinnu láti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. Ó tilẹ̀ lè ní kí ọkọ náà rọra fi ilé sílẹ̀ fún òun wọ́ọ́rọ́wọ́ kí wọ́n tó lọ jáwèé ìkọ̀sílẹ̀. Àwọn ọmọ lè má mọ ìdí tí èyí fi ń ṣẹlẹ̀ rárá.
Ṣùgbọ́n, gbìyànjú láti gba ti ìyá rẹ rò, kí o lóye ìdí tó fi lè máa lọ́ra láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ fún ọ. Fún ìdí kan, ó lè máa ronú pé sísọ fún ọ nípa ìwà àìtọ́ èyíkéyìí tí bàbá rẹ hù yóò wulẹ̀ fa ìdààmú ọkàn ni. Ó yẹ kí o tún mọ bí yóò ṣe dun obìnrin kan tó nígbà tó bá mọ̀ pé ọkọ òun ti hùwà ẹ̀tàn. (Málákì 2:13, 14) Nítorí náà, tó bá jẹ́ ìwà panṣágà ló mú kí àwọn òbí rẹ kọra wọn sílẹ̀, má ṣe jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu bí ọ̀ràn náà bá dun ìyá rẹ gan-an débi tí kò fi lè sọ nípa rẹ̀.
Bàbá rẹ kò ṣe sọ ọ́ fún ọ? Ó dájú pé tó bá jẹ́ pé ó hùwà ẹ̀tàn sí ìyá rẹ ni, ó lè má lè bá ọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ọkàn àwọn ọkùnrin kan máa ń dá wọn lẹ́bi gan-an nípa ìwà àìtọ́ wọn débi pé wọn kì í lè ko àwọn ọmọ wọn lójú! Ṣùgbọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìtìjú gbáà ni àwọn bàbá náà hù, púpọ̀ wọn ló ṣì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì lè gbìyànjú láti ṣì máa kàn sí wọn.
Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ohun tó máa ń jẹ́ kí bàbá fi ilé sílẹ̀ ni ìwà àìtọ́ tí ìyàwó rẹ̀ hù, ó sì ń sapá láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, kì í ṣe nítorí ìwà panṣágà ni wọ́n ṣe kọ ara wọn sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí àtifòpin sí ìṣòro òní-eré-ọ̀la-ìjà tí kò yéé ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó wọn.c (Òwe 18:24) Nítorí pé kò sẹ́ni tó ń gbọ́ ìjà wọn, o lè má mọ ohun tó ń fà á.
Bíbélì sọ nínú Òwe 25:9 pé: “Ro ẹjọ́ tìrẹ pẹ̀lú ọmọnìkejì rẹ, má sì ṣí ọ̀rọ̀ àṣírí ẹlòmíràn payá.” Nígbà mìíràn, awuyewuye tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó máa ń dá lórí àwọn ọ̀ràn àṣírí, tí etí kẹta kò gbọ́dọ̀ gbọ́. Ó lè ṣòro fún ọ láti gbà gbọ́ pé ì bá dára kí o máà gbọ́ nípa irú ohun bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ sí ìyẹn, lọ́pọ̀ ìgbà, ṣíṣí “ọ̀rọ̀ àṣírí” ẹlòmíràn payá máa ń mú kí ohun tó ti bà jẹ́ tẹ́lẹ̀ túbọ̀ bà jẹ́ sí i. O lè ṣe ọ́ bíi pé kí o gbè sẹ́yìn ẹnì kan—ìyẹn á wulẹ̀ máa fẹ ìṣòro ìdílé yín lójú sí i ni. Nítorí náà, lójú gbogbo ohun tí a ti jíròrò yìí, bóyá ohun tó lè ṣe ọ́ láǹfààní jù ni pé kí àwọn òbí rẹ má sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ awuyewuye àárín wọn fún ọ.
Gbìyànjú Láti Borí Ìkórìíra Nípa Níní Ìjìnlẹ̀ Òye
Síbẹ̀ náà, yóò ṣòro fún ọ láti má ṣe bínú, kí o sì fi ìkórìíra hàn nígbà tí o kò bá mọ ìdí tí bàbá rẹ fi fi ilé sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, nínú Òwe 19:11, Bíbélì sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú [kò di dandan kó mú un kúrò pátápátá].” Kì í sì í ṣe ọ̀ranyàn pé kí o mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà kí o tó ní ìjìnlẹ̀ òye.
Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn òbí wa jẹ́ aláìpé. Ó sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Títẹ́wọ́gba òtítọ́ tó korò yìí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ojú tí ó tọ́ wo àṣìṣe àwọn òbí rẹ. Fún àpẹẹrẹ, bí bàbá rẹ bá ti tàbùkù sí ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ìwà àìtọ́ gbáà nìyẹn—èyí tí yóò jíhìn fún Ọlọ́run nípa rẹ̀. (Hébérù 13:4) Ṣùgbọ́n kò fi dandan túmọ̀ sí pé ó ti kọ ìwọ sílẹ̀ tàbí pé kò nífẹ̀ẹ́ rẹ.
Gbogbo tọkọtaya ló ń ní “ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” (1 Kọ́ríńtì 7:28) Bó sì tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àwíjàre tí wọ́n lè wí tí wọ́n fi ní láti ṣe ohun tí wọ́n ṣe, ńṣe làwọn ọkùnrin àti obìnrin kan juwọ́ sílẹ̀ fún híhu ìwà àìtọ́ látàrí pákáǹleke ìgbésí ayé nínú ayé tó kún fún wàhálà yìí. Robert rántí pé: “Dádì fẹ́ ká gbádùn ara wa. Ó ṣètò kí ìdílé wa kó lọ sí àgbègbè kan tó rò pé òun lè ti máa rí owó dáadáa kí a lè ní ilé tó dára, kí ìdílé wa sì láyọ̀.” Ṣùgbọ́n èrò rere tí bàbá rẹ̀ ní tó fi gbìyànjú láti ṣètò kí ìdílé rẹ̀ lè gbé ìgbésí ayé tó túbọ̀ dára yọrí sí nǹkan míì. Robert ṣàlàyé pé: “Dádì kì í fi bẹ́ẹ̀ lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni mọ́. Lẹ́yìn náà, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tó ṣe, ó bẹ̀rẹ̀ sí hùwà àìdáa sí màmá mi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin.” Láìpẹ́, gbogbo nǹkan dorí kodò débi tí bàbá àti ìyá rẹ̀ fi kọ ara wọn sílẹ̀.
Robert ì bá ti bínú gidigidi nítorí àṣìṣe tí bàbá rẹ̀ ṣe. Ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ dín kù nítorí pé ó lóye ipò tí bàbá rẹ̀ wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbéyàwó àwọn òbí Robert tó túká bà á nínú jẹ́, ó kọ́ ọ ní ohun pàtàkì kan. Robert sọ pé: “Tí mo bá ní ìdílé tèmi, ohun tẹ̀mí ló gbọ́dọ̀ jẹ́ àkọ́kọ́.”
Ńṣe ni Michael, tí a mẹ́nu kàn níṣàájú, pẹ̀lú ṣèkáwọ́ inú tó ń bí i, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ì bá ṣòro gan-an fún un. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ ṣe ohun tí kò dára fún dádì mi nítorí ohun tó ṣe fún wa.” Ṣùgbọ́n kò jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín òun àti bàbá rẹ̀ bà jẹ́. Bí àkókò ti ń lọ, Michael ṣíwọ́ inú bíbí, ó sì ń bá ìgbésí ayé rẹ̀ lọ.
Á dára kí ìwọ pẹ̀lú mú kí àjọṣe tó wà láàárín ìwọ àti bàbá rẹ máa bá a lọ bí ipò nǹkan bá ṣe gbà. Lóòótọ́, nǹkan tó ṣe lè dun ìwọ àti mọ́mì rẹ o. Ṣùgbọ́n ó lè jẹ́ pé o kò mọ gbogbo ohun tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà. Kódà, bí o bá mọ̀ pé ó jẹ̀bi ìwà àìtọ́, òun ṣì ni bàbá rẹ. Ó kéré tán, ó di dandan fún ọ láti bọ̀wọ̀ fún un dé àyè kan. (Éfésù 6:1-3) Má ṣe gba “ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú” láyè nígbà tí o bá ń bá a sọ̀rọ̀. (Éfésù 4:31) Bó bá ṣeé ṣe, má ṣe dá sí ọ̀ràn awuyewuye tó ní í ṣe pẹ̀lú ipò lọ́kọláya àwọn òbí rẹ. Nípa mímú un dá àwọn òbí rẹ méjèèjì lójú pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, àjọṣe ìwọ àti àwọn méjèèjì kò ní bàjẹ́.
Ìwọ Kọ́ Lo Fà Á
Ó lè jẹ́ pé fífi tí bàbá rẹ fi ilé sílẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun ìbànújẹ́ tó burú jù lọ tó tíì ṣẹlẹ̀ sí ọ rí. Ṣùgbọ́n ká ní o kò tilẹ̀ mọ gbogbo ohun tó fà á tó ṣe fi ilé sílẹ̀, kò sí ìdí láti máa ronú pé ìwọ lo fà á. Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé ìwọ gangan ló kọ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n kì í sábà ṣẹlẹ̀ pé ọ̀ràn àwọn ọmọ ló mú kí ìgbéyàwó tú ká. Àwọn òbí rẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọ́run pé àwọn yóò wà pa pọ̀. Ẹrù iṣẹ́ wọn ni láti mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, kì í ṣe tìrẹ.—Oníwàásù 5:4-6.
Pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ti sọ yìí, bí ó bá ṣì rú ọ lójú, tí ọkàn rẹ ń dá ọ lẹ́bi, tàbí tí o ń rò pé ìwọ lo fà á, o ò ṣe gbìyànjú láti bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀? Wọ́n tilẹ̀ lè ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún ọ, kí wọ́n sì tún fún ọ ní àwọn ìdánilójú tí o nílò. James, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀ rí, mo máa ń rò pé èmi ni mo fà á, àyàfi ìgbà tí màmá àti bàbá mi bá mi sọ̀rọ̀.” Ọ̀dọ́mọdé Nancy pẹ̀lú lérò pé òun lòún fà á tí bàbá àti ìyá òun fi kọ ara wọn sílẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìjíròrò tí Nancy ní pẹ̀lú màmá rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún un láti parí èrò sí pé: “Kò yẹ kí àwọn ọmọ máa di ẹ̀bi ohun tí àwọn òbí wọn ṣe ru ara wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni, jíjẹ́ kí àwọn òbí rẹ ‘ru ẹrù ti ara wọn’ ní ti ojúṣe wọn lè yọ ọ́ nínú ìdààmú ọkàn. (Gálátíà 6:5) Àmọ́, báwo ni o ṣe lè fara dà á nísinsìnyí tí o ń gbé inú ìdílé kan tí kò ti sí bàbá? Àpilẹ̀kọ kan tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí yóò pèsè àwọn ìdáhùn díẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ táa gbé karí àkọlé náà, “Àwọn Ìdílé Tí Kò Ti Sí Bàbá—Fífòpin sí Ìṣòro Náà,” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde February 8, 2000.
c Àmọ́, Bíbélì sọ ní kedere pé ìdí kan ṣoṣo tí Ìwé Mímọ́ tì lẹ́yìn fún títú ìgbéyàwó kan ká, tí tọ̀tún tòsì wọn fi lè fẹ́ ẹlòmíràn ni àgbèrè.—Mátíù 19:9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Má ṣe di ẹ̀bi ìṣòro tí àwọn òbí rẹ ń ní nínú ìgbéyàwó wọn ru ara rẹ