ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g01 3/8 ojú ìwé 14
  • ‘Wọn Yóò Fi Idà Wọn Rọ Abẹ Ohun Ìtúlẹ̀’—Nígbà Wo?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Wọn Yóò Fi Idà Wọn Rọ Abẹ Ohun Ìtúlẹ̀’—Nígbà Wo?
  • Jí!—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Gbé Ilé Jèhófà Lékè
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
  • Ta Ló Lè Mú Àlàáfíà Pípẹ́ Títí Wá?
    Jí!—1996
  • Ayé Kan Láìsí Ogun Yóò Dé Láìpẹ́
    Jí!—1996
  • Àlàáfíà Tòótọ́—Láti Orísun Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Jí!—2001
g01 3/8 ojú ìwé 14

‘Wọn Yóò Fi Idà Wọn Rọ Abẹ Ohun Ìtúlẹ̀’—Nígbà Wo?

ÈRE kan tí igba ojú mọ̀ tó wà lójúde àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní Ìlú New York, ń ṣàpèjúwe ọkùnrin kan tó ń fi idà rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀. Ère yìí dá lórí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó wà nínú ìwé Aísáyà orí kejì, ẹsẹ kẹrin, àti Míkà orí kẹrin, ẹsẹ kẹta. Àmọ́ báwo àti ìgbà wo ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí máa ní ìmúṣẹ?

Láìpẹ́ yìí, ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn The New York Times gbé àkọlé kan rù tó sọ pé, “Ohun Èèlò Ìjà Ogun Tí A Ń Tà Lágbàáyé Tí Ròkè Lálá Dórí Ọgbọ̀n Bílíọ̀nù Dọ́là”! Ní ọdún 1999, àwọn wo ni òléwájú nínú títa àwọn ohun èèlò ìjà ogun tó pọ̀ jàńtìrẹrẹ yìí? Orílẹ̀ Èdè Amẹ́ríkà ló ṣáájú, ó ta èyí tí owó rẹ̀ lé ní bílíọ̀nù mọ́kànlá dọ́là. Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ló ṣe ipò kejì, òun ta ohun tó dín sí ìlàjì iye tí Amẹ́ríkà tà. Síbẹ̀, iye tí Rọ́ṣíà tà yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì iye tó tà ní ọdún 1998. Lẹ́yìn èyí ló kan orílẹ̀- èdè Jámánì, China, ilẹ́ Faransé, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àti Ítálì. Ìròyìn náà ń báa lọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀, nǹkan bí ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta àwọn èèlò ìjà ogun tí wọ́n tà yìí ló jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ni wọ́n tà wọ́n fún.”

Lẹ́yìn ogun àgbáyé méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àtàwọn ogun pàtàkì mìíràn tó ti wáyé ní ọ̀rúndún ogún, tó jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù èèyàn ló kú tí ọ̀pọ̀ sì fara pa, èyí mú kéèyàn béèrè pé, “Ìgbà wo làwọn orílẹ̀ èdè máa tó bẹ̀rẹ̀ sí lépa àlàáfíà dípò ogun jíjà ná?” Bíbélì jẹ́ kó yé wa pé lílépa àlàáfíà yìí yóò jẹ́ ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” (Aísáyà 2:2) Ká sọ tòótọ́, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ń ní ìmúṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, níwọ̀n bí èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti di ẹni ‘tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’ Àbájáde rẹ̀ sì ni pé wọ́n ní ‘àlàáfíà tó pọ̀ yanturu.’—Aísáyà 54:13.

Láìpẹ́, Jèhófà yóò fòpin sí gbogbo ohun èèlò tí wọ́n fi ń jagun, ogun àtàwọn arógunyọ̀ yóò dópin, nítorí pé Jèhófà yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” Bóo bá fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa ìyípadà àgbàyanu yìí, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sí ojú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.—Ìṣípayá 11:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́