Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
July 8, 2002
Àwọn Ọlọ́pàá—Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Wọn?
Kárí ayé làwọn ọlọ́pàá ti ń kojú ìṣòro mímú kí àwọn aráàlú pa òfin mọ́ kí àlàáfíà sì wà láàárín ìlú. Ibo ni wọ́n bá akitiyan wọn dé?
3 Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Àwọn Ọlọ́pàá?
5 Ààbò Táwọn Ọlọ́pàá Ń Pèsè—Ìrètí àti Ìbẹ̀rù Táwọn Èèyàn Ní Nípa Rẹ̀
10 Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àjọ Ọlọ́pàá Lọ́jọ́ Iwájú?
17 Ìfiniṣẹrú—Kò Tí Ì Dáwọ́ Dúró
18 Ọjọ́ Pẹ́ Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣakitiyan Láti Fòpin Sí Ìfiniṣẹrú
20 Àkókò Tí Ìfiniṣẹrú Máa Dópin Ti Sún Mọ́lé!
28 Mímú Ara Aláìsàn Lọ́ Wọ́ọ́wọ́ Ṣáájú Iṣẹ́ Abẹ Kì Í Sábà Jẹ́ Kí Kòkòrò Àrùn Wọ Ojú Ọgbẹ́
Ìjọba Tó Fàyè Gba Onírúurú Ẹ̀sìn Láyé Ìgbà Tí Kò Sí Òmìnira Ìsìn 13
Kà nípa àwọn ọba kan tí irú wọn ṣọ̀wọ́n, ní ti pé, wọ́n gbé òmìnira ẹ̀sìn lárugẹ ní orílẹ̀-èdè tiwọn lákòókò kan tó jẹ́ pé àìsí òmìnira ẹ̀sìn ló gbayé kan.
Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè—Ṣé Nǹkan Ṣeréṣeré Lásán Ni Wọ́n? 25
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè? Ṣé ohun amóríyá lásán ni wọ́n wulẹ̀ jẹ́ ni? Àbí ewu gidi ni wọ́n jẹ́ sí ìwà títọ́ Kristẹni?