ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g03 5/8 ojú ìwé 31
  • Àṣà Tí Kò Pa Rẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àṣà Tí Kò Pa Rẹ́
  • Jí!—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kérésìmesì—Èé Ṣe Táwọn Ará Ìlà Oòrùn Ayé Pàápàá Fi Ń Ṣe É?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Keresimesi—Eeṣe Ti Ó Fi Gbajúmọ̀ Tobẹẹ ni Japan?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Kí Ni Keresimesi Túmọ̀ Sí fún Ọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Orísun Kérésìmesì Òde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Jí!—2003
g03 5/8 ojú ìwé 31

Àṣà Tí Kò Pa Rẹ́

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ

JÁKÈJÁDÒ ayé làwọn ọmọdé ń gbé e gẹ̀gẹ̀. Ní ọdún kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, lẹ́tà tí ilé iṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ ilẹ̀ Faransé gbà fún un fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì ọ̀kẹ́ [800,000], èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn lẹ́tà náà ló sì wá látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ta sí mẹ́jọ. Pẹ̀lú irùngbọ̀n rẹ̀ yẹ́úkẹ́ tó funfun àti aṣọ rẹ̀ pupa tí ìgbátí rẹ̀ funfun, ó dà bíi pé ẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí Baba Kérésì yìí tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí gan-an jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó gbayì jù lọ nínú pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún Kérésìmesì. Ǹjẹ́ kò ní yà ọ́ lẹ́nu tó o bá gbọ́ pé wọ́n dáná sun ère rẹ̀? Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn ní ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ ní àádọ́ta ọdún sígbà tá a wà yìí ní ìlú Dijon, ní orílẹ̀-èdè Faransé. Ní December 23, 1951, wọ́n dáná sun ère Baba Kérésì níwájú àádọ́ta lé rúgba [250] àwọn ọmọdé.

Kí nìdí tí wọ́n fi dáná sun ún? Ìwé ìròyìn France-Soir sọ pé bí wọ́n ṣe dáná sun ún náà “jẹ́ àṣẹ látọ̀dọ̀ àwùjọ àlùfáà, èyí tí gbogbo wọn fohùn ṣọ̀kan lé, látàrí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Baba Kérésì pé ó ń gba iyì tó yẹ káwọn èèyàn máa fún Kristi àti pé aládàámọ̀ ni,” bákan náà ni wọ́n tún fẹ̀sùn kàn án pé “ó ti sọ Kérésìmesì di ìbọ̀rìṣà.” Ìkéde pàtàkì kan tí àwọn àlùfáà tẹ̀ jáde sọ pé dídáná sun ún yìí jẹ́ “ẹ̀rí pé a lòdì sí i.” Ó fi kún un pé: “Irọ́ lásánlàsàn kò lè mú kí àwọn ọmọdé ní ẹ̀mí ìsìn, ó sì dájú pé èyí kì í ṣe ọ̀nà láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.”

Àwọn àlùfáà kan gbà pé àwọn àṣà tó so mọ́ Baba Kérésì ń mú káwọn èèyàn kẹ̀yìn sí ohun tí “jíjẹ́ Kristẹni túmọ̀ sí ní ti tòótọ́” nígbà ayẹyẹ Ìbí Jésù. Àní sẹ́, nínú ìwé ìròyìn Les Temps Modernes, ìtẹ̀jáde ti March 1952, Claude Lévi-Strauss tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá èèyàn sọ pé, gbígbàgbọ́ nínú Baba Kérésì “jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà tó ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ láàárín àwọn èèyàn ayé òde òní,” ó sì sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì náà ṣe dáadáa fún bó ṣe bẹnu àtẹ́ lu ìgbàgbọ́ yìí. Ọ̀gbẹ́ni Lévi-Strauss tún sọ pé a lè tọpa ibi tí Baba Kérésì ti ṣẹ̀ wá padà sí ọ̀dọ̀ ẹni tó jẹ́ ọba nígbà ayẹyẹ Saturnalia. Ọjọ́ kẹtàdínlógún sí ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù December ni wọ́n máa ń ṣayẹyẹ àjọ̀dún Saturnalia ní ìlú Róòmù ayé ọjọ́un. Láàárín ọ̀sẹ̀ náà, àwọn èèyàn máa ń fi ewéko tútù yọ̀yọ̀ ṣe ara ilé lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n a sì máa fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ síra wọn. Bíi ti Kérésìmesì, ayẹyẹ Saturnalia máa ń kún fún pọ̀pọ̀ṣìnṣìn.

Ní báyìí, lóhun tó ti lé ní àádọ́ta ọdún tí wọ́n dáná sun ère Baba Kérésì, ojú wo ni àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ilẹ̀ Faransé fi ń wò ó? Bí àwòrán Jésù tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran ṣe ṣe pàtàkì nínú ayẹyẹ Kérésìmesì ni Baba Kérésì tó jẹ́ ajogún ayẹyẹ Saturnalia ayé ọjọ́un ní ilẹ̀ Róòmù náà ṣe ṣe pàtàkì nínú ayẹyẹ Kérésìmesì. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àlùfáà kan á bẹnu àtẹ́ lu Baba Kérésì pé òwò ṣíṣe ló jẹ́, èyí tí kì í jẹ́ káwọn èèyàn ronú nípa Kristi nígbà ayẹyẹ Kérésìmesì. Àmọ́, ní gbogbo gbòò, àwọn èèyàn ti dágunlá sí ohunkóhun tí ì báà máa da ẹ̀rí ọkàn wọn láàmú nípa bí Baba Kérésì ṣe pilẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn kèfèrí, nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló tẹ́wọ́ gbà á.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

DR/© Cliché Bibliothèque nationale de France, Paris

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́